Orin 23
Jèhófà, Okun Wa
1. Jèhófà agbára òun okun wa.
Ń’nú rẹ Olùgbàlà layọ̀ wa wà.
Àwa ni Ẹlẹ́rìí tí ńròyìn rẹ,
Bárayé fẹ́ gbọ́ tàbí wọn kò fẹ́.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, Àpáta òun okun wa,
A ńkéd’oókọ rẹ tọ̀sán-tòru.
Jèhófà Ọba, Olódùmarè,
Ibi ìsádi wa, Iléèṣọ́ wa.
2. Àwa tó ńsìn ọ́ ńyọ̀ ń’nú ìmọ́lẹ̀;
Ojú wa ti là, a sì ti róòótọ́.
A rí àṣẹ rẹ nínú Bíbélì;
A dúró ṣinṣin ti Ìjọba rẹ.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, Àpáta òun okun wa,
A ńkéd’oókọ rẹ tọ̀sán-tòru.
Jèhófà Ọba, Olódùmarè,
Ibi ìsádi wa, Iléèṣọ́ wa.
3. Ọlọ́run, àwa ńfayọ̀ ṣèfẹ́ rẹ.
Bí Èṣù ńgàn wá, a gbẹ́kẹ̀ lé ọ.
Ó lè pa wá, ṣùgbọ́n ràn wá lọ́wọ́
Ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí ọ láéláé.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, Àpáta òun okun wa,
A ńkéd’oókọ rẹ tọ̀sán-tòru.
Jèhófà Ọba, Olódùmarè,
Ibi ìsádi wa, Iléèṣọ́ wa.
(Tún wo 2 Sám. 22:3; Sm. 18:2; Aísá. 43:12.)