Pẹ́ Láyé Kí Ara Rẹ Sì Tún Le Dáadáa
KÁ SỌ pé ìwàláàyè ẹ̀dá jẹ́ eré ìje jíjìnnà, tí a sì ní láti fo àwọn ohun ìdènà kan bí a ti ń sáré náà. Gbogbo àwọn eléré náà ló jọ bẹ̀rẹ̀; ṣùgbọ́n bí wọ́n ti ń fò, tí wọ́n sì ń fẹsẹ̀ gbá ohun ìdènà náà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn eléré náà bẹ̀rẹ̀ sí dẹ eré, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ púpọ̀ nínú wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọsẹ̀ kúrò nínú eré náà.
Bẹ́ẹ̀ náà ló rí pé ìwàláàyè ẹ̀dá ní ìbẹ̀rẹ̀ àti àwọn ohun ìdènà gíga lójú ọ̀nà. Ènìyàn máa ń bá ọ̀pọ̀ ohun ìdènà pàdé nígbà ayé rẹ̀. Ríré ohun ìdènà kọ̀ọ̀kan kọjá ń sọ ọ́ di aláìlera sí i, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, á yọ kúrò nínú eré náà. Bí àwọn ohun ìdènà náà bá ṣe ga tó ni yóò fi tètè yọ kúrò lára àwọn eléré náà, tàbí ni yóò ṣe tètè kú. Bí èèyàn bá ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà, àkókò tí eré ìje rẹ̀ yóò dópin jẹ́ ìgbà tó bá pé bí ẹni ọdún márùnléláàádọ́rin. Sáà yìí ni a ń pè ní ìpíndọ́gba gígùn ẹ̀mí ènìyàn—nífiwéra pẹ̀lú bí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn eléré ṣe ń lọ jìnnà tó.a (Fi wé Sáàmù 90:10.) Síbẹ̀, àwọn èèyàn kan ń sá jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀mí àwọn díẹ̀ tilẹ̀ gùn dé ibi tí a ronú pé ó jẹ́ ìpẹ̀kun ibi tí ẹ̀mí èèyàn lè gùn dé, ọdún márùndínlọ́gọ́fà sí ọgọ́fà—ẹni bá pẹ́ tó yẹn ṣe bẹbẹ, kódà òkìkí ẹ̀ á kàn káyé.
Dídá Àwọn Ohun Ìdènà Náà Mọ̀
Nísinsìnyí, àwọn èèyàn lè máa bá eré ìje náà lọ fún nǹkan bí ìlọ́po méjì àkókò tí wọ́n lè lò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí. Èé ṣe? Ní pàtàkì nítorí pé aráyé ti rẹ àwọn ohun ìdènà náà sílẹ̀. Nígbà náà, kí ni àwọn ohun ìdènà wọ̀nyí? Àti pé ǹjẹ́ a tilẹ̀ lè túbọ̀ rẹ̀ wọ́n sílẹ̀?
Ògbógi kan nínú ìtọ́jú aráàlú tó ń bá Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) ṣiṣẹ́, ṣàlàyé pé díẹ̀ lára àwọn ohun ìdènà pàtàkì náà, tàbí okùnfà, tí ń nípa lórí iye ọdún tí a retí kí ẹ̀dá lò láyé ni àṣà ìṣeǹkan, àyíká, àti gbígba àbójútó lọ́dọ̀ oníṣègùn.b Nípa bẹ́ẹ̀, bí àṣà ìṣeǹkan rẹ bá ṣe dára tó, àti bí àyíká rẹ bá ṣe bójú mu tó, tí àbójútó ìlera rẹ sì ṣe dáa tó, bẹ́ẹ̀ náà ni ohun ìdènà wọ̀nyẹn yóò ṣe túbọ̀ rẹlẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ló ṣeé ṣe kí ẹ̀mí rẹ gùn tó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò ẹ̀dá yàtọ̀ síra gan-an, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé olúkúlùkù ènìyàn—láti orí ọ̀gá báńkì ní Sydney títí dórí ẹni tó ń tajà lójú pópó ní São Paulo—ló lè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá láti mú kí àwọn ewu ìgbésí ayé òun dín kù. Lọ́nà wo?
Àwọn Àṣà Tó Máa Nípa Lórí Àṣeyọrí Rẹ
Ìwé ìròyìn The New England Journal of Medicine sọ pé: “Kì í ṣe pé àwọn tí wọ́n ní àṣà bíbójútó ìlera wọn dáadáa máa ń pẹ́ láyé nìkan ni, àmọ́ ó máa ń pẹ́ kí irú wọ́n tó di hẹ́gẹhẹ̀gẹ, ó sì máa ń bọ́ sí ìwọ̀nba ọdún tó gbẹ̀yìn ìgbé ayé wọn.” Láìṣe àní-àní, a lè rẹ ohun ìdènà àkọ́kọ́ sílẹ̀ nípa yíyí àwọn àṣà bíi jíjẹun, mímutí, sísùn, mímu sìgá, àti ṣíṣeré ìmárale padà. Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn ti àṣà eré ìmárale yẹ̀ wò.
Àṣà eré ìmárale. Eré ìmárale tó mọ níwọ̀n lè ṣeni láǹfààní gan-an. (Wo àpótí “Báwo Ló Ṣe Yẹ Kí Eré Ìmárale Pọ̀ Tó, Irú Wo Sì Ni?”) Àwọn ìwádìí fi hàn pé àwọn eré ìmárale tó rọrùn tí a ń ṣe nínú ilé àti láyìíká ilé ń ran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́, títí kan ‘àwọn arúgbó kùjọ́kùjọ́,’ láti jèrè okun àti agbára padà. Fún àpẹẹrẹ, àwùjọ àwọn arúgbó kan tí wọ́n jẹ́ ẹni ọdún méjìléláàádọ́rin sí méjìdínlọ́gọ́rùn-ún rí i pé àwọn túbọ̀ lè sáré rìn, àwọn sì túbọ̀ lè fìrọ̀rùn pọ́nkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì lẹ́yìn tí àwọn ṣe eré ìmárale gbígbé irin wíwúwo fún ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá péré. Abájọ! Àwọn àyẹ̀wò tí a ṣe lẹ́yìn ìtòlẹ́sẹẹsẹ eré ìmárale náà fi hàn pé iṣu ẹran ara àwọn tó ṣeré náà lágbára sí i ní ìlọ́po méjì. Àwùjọ àwọn mìíràn, tó jẹ́ àwọn obìnrin tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọ́n máa ń jókòó tẹtẹrẹ, tí wọ́n tó ẹni àádọ́rin ọdún ń ṣe eré ìmárale lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀. Lẹ́yìn ọdún kan, iṣu ẹran ara wọ́n ti ki sí i, wọ́n sì lókun sí i, ara wọ́n túbọ̀ balẹ̀, egungun wọ́n sì túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Miriam Nelson, onímọ̀ nípa ìṣiṣẹ́ ẹ̀yà ara, tó ṣe àwọn àyẹ̀wò náà sọ pé: “Nígbà tí a bẹ̀rẹ̀, ẹ̀rù ń bà wá pé àá fọ́ oríkèé eegun eléegun, àá já iṣan oníṣan, àá já iṣu ẹran ara àwọn ẹni ẹlẹ́ni. Ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe lara wọ́n túbọ̀ le, tí ara wọ́n sì yá gágá sí i.”
Nígbà tí ìwé àkànlò kan ń ṣàkópọ̀ àbájáde àwọn ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì bíi mélòó kan tó dá lórí ọjọ́ ogbó àti eré ìmárale, ó sọ pé: “Eré ìmárale kì í jẹ́ kí èèyàn tètè darúgbó, ó máa ń mú kí ẹ̀mí gùn, ó sì máa ń dín àkókò tí a fi ń ṣòjòjò tó sábà máa ń ṣáájú ikú kù.”
Àṣà lílo ọpọlọ ẹni. Ó jọ pé kì í ṣe àwọn iṣu ẹran ara nìkan ni òwe tó sọ pé, “Lò ó bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wàá pàdánù rẹ̀,” kàn ṣùgbọ́n ó tún kan èrò inú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí a ti ń darúgbó sí i la máa ń gbàgbé nǹkan tó, ìwádìí kan tí Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ọjọ́ Ogbó ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ṣe fi hàn pé ọpọlọ ẹni tó ti darúgbó máa ń gbéṣẹ́ gan-an tó fi lè máa bá àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ogbó yí. Ìdí nìyẹn tí Dókítà Antonio R. Damasio tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ nípa iṣan ara fi sọ pé: “Èrò orí àwọn arúgbó lè máa báṣẹ́ lọ kó sì jí pépé.” Kí ló ń mú kí ọpọlọ àwọn arúgbó máa gbéṣẹ́?
Ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù sẹ́ẹ̀lì, tàbí iṣan ọpọlọ, ló wà nínú ọpọlọ, àti ẹgbàágbèje ohun tó so wọ́n pọ̀ mọ́ra. Àwọn ìsokọ́ra wọ̀nyí ń ṣiṣẹ́ bí ìsokọ́ra tẹlifóònù tó ń jẹ́ kí àwọn iṣan ọpọlọ máa bá ara wọn “sọ̀rọ̀” láti ṣẹ̀dá agbára ìrántí àti àwọn ohun mìíràn. Bí ọpọlọ ṣe ń gbó díẹ̀díẹ̀ ni àwọn iṣan ọpọlọ ń kú. (Wo àpótí “Yíyẹ Àwọn Sẹ́ẹ̀lì Ọpọlọ Wò Lákọ̀tun.”) Síbẹ̀, ọpọlọ àwọn arúgbó lè gba iṣẹ́ àwọn ṣẹ́ẹ̀lì iṣan tó kú ṣe. Ìgbàkigbà tí sẹ́ẹ̀lì iṣan kan bá kú, àwọn tó kù láyìíká rẹ̀ yóò múṣẹ́ ṣe nípa síso mọ́ àwọn iṣan ọpọlọ yòókù lákọ̀tun, wọn óò sì máa ṣe iṣẹ́ iṣan ọpọlọ tó kú. Lọ́nà yẹn, ọpọlọ ń gbé ẹrù iṣẹ́ kan láti àyíká ara kan lọ sí òmíràn ní gidi. Nítorí náà, ọ̀pọ̀ àwọn arúgbó ń ṣe irú iṣẹ́ ọpọlọ kan náà tí àwọn ọ̀dọ́ ń ṣe, ṣùgbọ́n ó lè jẹ́ apá mìíràn nínú ọpọlọ ni wọ́n fi ń ṣe é. Nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan, ọpọlọ arúgbó máa ń ṣe bí àgbàlagbà kan tó ń gbá tẹníìsì, bí kò tilẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ lágbára eré sísá mọ́, síbẹ̀ ó ń lo òye táwọn ọ̀dọ́ agbá-tẹníìsì kò ní. Síbẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àgbàlagbà náà ń lo ọgbọ́n tó yàtọ̀ sí ti àwọn tí kò tó o, ó ṣì ń rí ayò jẹ.
Kí ni àwọn arúgbó lè ṣe láti máa jayò lọ? Lẹ́yìn yíyẹ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ènìyàn tó wà láàárín àádọ́rin ọdún sí ọgọ́rin ọdún wò, Dókítà Marilyn Albert tó jẹ́ olùwádìí nípa ọjọ́ ogbó ṣàwárí pé lílo ọpọlọ jẹ́ ọ̀kan lára ohun tí ń pinnu èyí tí ìṣiṣẹ́ ọpọlọ rẹ̀ kò yingin lára àwọn arúgbó. (Wo àpótí “Mímú Kí Èrò Inú Gbéṣẹ́.”) Lílo ọpọlọ ń mú kí àwọn ìsokọ́ra ọpọlọ jí pépé. Àwọn ògbógi sọ pé, yàtọ̀ sí ìyẹn, ọpọlọ máa ń bẹ̀rẹ̀ sí jó rẹ̀yìn “nígbà tí àwọn ènìyàn kò bá lo ọpọlọ mọ́, tí wọ́n pinnu pé àwọn ò ní yọ ọpọlọ lẹ́nu mọ́, tí wọ́n sì sọ pé àwọn ò ní láti máa fọkàn bá ohun tí ń ṣẹlẹ̀ láyé lọ mọ́.”—Inside the Brain.
Nítorí náà, Dókítà Jack Rowe tó jẹ́ onímọ̀ nípa ọjọ́ ogbó ṣàlàyé pé ìròyìn ayọ̀ náà ni pé, “ó yẹ kí àwọn ohun tí a lè darí tàbí tí a lè yí padà pa kún agbára wa láti kẹ́sẹ járí nígbà arúgbó wa.” Ní àfikún sí i, kò tí ì pẹ́ jù láti bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn àṣà tó dára dàgbà. Olùwádìí kan sọ pé: “Kódà bó bá ṣẹlẹ̀ pé o kì í bójú tó ìlera rẹ dáadáa ní èyí tó pọ̀ jù nínú ìgbésí ayé rẹ, tí o sì yí padà ní ìgbà tí o ti darúgbó, ó yẹ kí o ṣì lè jẹ díẹ̀ lára èrè tí ń wá láti inú ọ̀nà ìgbésí ayé tó bójú mu.”
Àyíká Ṣe Pàtàkì
Bí a bá gbé ọmọbìnrin kan tí wọ́n bí ní London lónìí padà lọ sí London bó ṣe rí ní Sànmánì Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀làjú, iye ọdún tí a óò retí kó lò láyé kò ní tó ìdajì èyí tí a óò retí kó lò lóde òní. Kì í ṣe yíyí ipò ọmọ náà padà lójijì ni yóò fa ìyàtọ̀ náà bí kò ṣe bí àwọn ohun ìdènà méjì mìíràn ṣe yára ga sókè tó—àyíká àti àbójútó ìlera. Kọ́kọ́ gbé ọ̀ràn ti àyíká yẹ̀ wò.
Àyíká ẹni. Nígbà kan rí, àyíká ènìyàn—fún àpẹẹrẹ, ibùgbé rẹ̀—jẹ́ ewu fún ìlera gan-an. Àmọ́, ní àwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí, àwọn ewu tí àyíká ń fà ti dín kù. Ìmọ́tótó tó dáa, omi tó dáa, àti mímú kí iye kòkòrò apanilára tó wà nílé dín kù ti mú kí àyíká ẹ̀dá sunwọ̀n sí i, ó ti mú kí ìlera rẹ̀ gbé pẹ́ẹ́lí sí i, ó sì ń mú kí ẹ̀mí rẹ̀ túbọ̀ gùn. Ó wá yọrí sí pé ní àwọn apá ibi púpọ̀ lágbàáyé, ènìyàn ti ń pẹ́ láyé sí i.c Síbẹ̀, rírẹ àwọn ohun ìdènà yìí sílẹ̀ ń béèrè ju ṣíṣe nǹkan sí àyíká rẹ lọ. Ó tún ń béèrè pé kí o wà ní àyíká tó jọjú láwùjọ ẹ̀dá, kí o sì máa ṣe ìsìn tó bójú mu.
Àwùjọ ẹ̀dá tó yí ọ ká. Àwọn ènìyàn ló para pọ̀ di àwùjọ ẹ̀dá tó yí ọ ká—àwọn tí o ń bá gbé, tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, tí ẹ jọ ń jẹun, tí ẹ jọ ń jọ́sìn, tí ẹ sì jọ ń ṣeré. Bí o bá ń rí omi tó dára lò, àyíká rẹ yóò sunwọ̀n sí i; bákan náà àwùjọ ẹ̀dá tó yí ọ ká lè sunwọ̀n sí i tí o bá ń rí àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tó ṣeyebíye, ká wulẹ̀ sọ kókó pàtàkì kan péré. Níní àǹfààní láti ṣàjọpín ayọ̀ rẹ àti àwọn ohun tí ń bà ọ́ nínú jẹ́, àwọn ohun tí o ń fojú sọ́nà fún àti ìjákulẹ̀ tí o ń ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ń dín bí àwọn ohun ìdènà àyíká rẹ ṣe ń ga sókè kù, ó sì ń ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti lè lọ jìnnà sí i.
Àmọ́ òdì kejì rẹ̀ náà jẹ́ òótọ́. Àìní alábàákẹ́gbẹ́ lè fa ìdáwà àti títakété sí àwùjọ ẹ̀dá. Ó jọ pé okun máa ń tán nínú rẹ bí àwọn tó yí ọ ká kì í bá sọ ọ̀rọ̀ tó ń fi hàn pé àwọn bìkítà nípa rẹ. Obìnrin kan tó ń gbé ilé tí a ti ń tọ́jú àwọn arúgbó kọ̀wé sí ojúlùmọ̀ rẹ̀ kan pé: “Ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́rin ni mí, mo sì ti wà nílé àwọn arúgbó yìí fún ọdún mẹ́rìndínlógún gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ sẹ́yìn. Wọ́n ń ṣe wá dáadáa, ṣùgbọ́n nígbà mìíràn, ó máa ń ṣòro láti fara da dídáwà.” Ó bani nínú jẹ́ pé ipò tí ìyá yìí wà kò yàtọ̀ sí ti ọ̀pọ̀ àwọn arúgbó, ní pàtàkì ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń gbé àyíká àwọn ẹ̀dá tí kò fayé ni wọ́n lára ṣùgbọ́n tó jẹ́ agbára káká ló fi mọyì wọn. Ní àbájáde rẹ̀, James Calleja tó ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Tí Ń Rí sí Ọ̀ràn Nípa Ọjọ́ Ogbó Lágbàáyé sọ pé, “ìdáwà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn lájorí ipò tó ń wu àlàáfíà àwọn arúgbó léwu léraléra ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà.”
Ká sọ tòótọ́, o lè má lè yanjú ohun tó mú kí o ní ìṣòro ìdáwà—àwọn nǹkan bí ìfẹ̀yìntì kàn-ń-pá, àìlè máa lọ káàkiri, pípàdánù àwọn ọ̀rẹ́ àtijọ́, tàbí ikú ẹnì kejì ẹni nínú ìgbéyàwó—ṣùgbọ́n o ṣì lè gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan láti dín àwọn ohun ìdènà wọ̀nyí kù sí ìwọ̀n tó ṣeé fewé mọ́. Lákọ̀ọ́kọ́, rántí pé ọjọ́ ogbó kọ́ ló ń fa ìmọ̀lára ìdáwà; àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń nímọ̀lára ìdáwà pẹ̀lú. Jíjẹ́ arúgbó kọ́ ló ń fa ìṣòro náà—jíjìnnà sí àwùjọ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ló ń fà á. Kí lo lè ṣe láti má ṣe jìnnà sí àwọn ènìyàn?
Opó kan tó ti darúgbó gbani nímọ̀ràn pé: “Jẹ́ kí inú àwọn èèyàn máa dùn láti wà pẹ̀lú rẹ. Àwọn èèyàn tó ń gbádùn ìkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú oníbìínú kì í tó nǹkan. O ní láti sapá láti túra ká. Ká sọ tòótọ́, ó gba ìsapá, àmọ́ ipá tí o bá sà yóò ṣe ọ́ láǹfààní. Bù fún mi n bù fún ẹ lọ̀rọ̀ ayé.” Ó fi kún un pé: “Láti rí i dájú pé èmi àti àwọn tí mo ń bá pàdé jọ ń sọ ohun kan náà, yálà wọ́n jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà, mo máa ń gbìyànjú láti mọ ohun tó ń lọ nílùú nípa kíka àwọn ìwé ìròyìn tó ní ìsọfúnni nínú, mo sì máa ń gbọ́ ìròyìn.”
Àwọn àbá mìíràn nìwọ̀nyí: Kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí àwọn ẹlòmíràn fẹ́ràn. Béèrè ìbéèrè. Máa hùwà ọ̀làwọ́ bí o bá ṣe lè ṣe tó. Bí o kò bá ní nǹkan tí o lè fún wọn, yọ̀ǹda ara rẹ láti ṣe nǹkan fún wọn; ayọ̀ wà nínú fífúnni. Kọ lẹ́tà sáwọn èèyàn. Máa ṣe ìgbòkègbodò àfipawọ́ kan. Tẹ́wọ́ gba ìkésíni láti bẹ àwọn ẹlòmíràn wò tàbí láti bá wọn jáde. Jẹ́ kí ilé rẹ tu àlejò lára, kó sì wu àlejò. Ké sí àwọn aláìní, kí o sì ràn wọ́n lọ́wọ́.
Àyíká ti ìsìn. Ẹ̀rí tí ń pọ̀ sí i fi hàn pé àwọn ìgbòkègbodò ìsìn máa ń ran àwọn arúgbó lọ́wọ́ láti mọ̀ pé àwọn “já mọ́ nǹkan àti pé àwọn ṣe pàtàkì láyé àwọn” àti láti ní “ayọ̀,” “ìmọ̀lára pé àwọn wúlò,” “ìtẹ́lọ́rùn púpọ̀ nínú ìgbésí ayé,” àti “ìmọ̀lára jíjẹ́ ara àwùjọ ènìyàn, tó sì lálàáfíà.” Èé ṣe? Ìwé Later Life—The Realities of Aging ṣàlàyé pé: “Ìsìn ń jẹ́ kí àwọn ènìyàn rí bí ìgbésí ayé, onírúurú ìṣarasíhùwà, ìlànà ìhùwà, àti ìgbàgbọ́ ṣe rí ní kedere lọ́nà tó fi ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wòye kí wọ́n sì lóye àyíká wọn.” Láfikún sí i, àwọn ìgbòkègbodò ìsìn ń jẹ́ kí àwọn arúgbó pàdé àwọn ẹlòmíràn kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ “dín ṣíṣeéṣe pé kí wọ́n jìnnà sáwùjọ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tàbí kí wọ́n dá wà kù.”
Ní ti Louise àti Evelyn, àwọn opó méjèèjì náà jẹ́ ẹni ọgọ́rin ọdún, wọ́n sì ń dara pọ̀ mọ́ ọ̀kan nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn ìwádìí yìí wulẹ̀ fìdí ẹ̀rí ohun tí wọ́n ti mọ̀ fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún múlẹ̀ ni. Louise sọ pé: “Ní Gbọ̀ngàn Ìjọbad wa, mo máa ń gbádùn bíbá àwọn ẹlòmíràn fọ̀rọ̀wérọ̀, àtọmọdé àtàgbà. A ń kẹ́kọ̀ọ́ gan-an ní àwọn ìpàdé náà. Tí a bá ń kíra lẹ́yìn ìpàdé, a máa ń rẹ́rìn-ín dáadáa pẹ̀lú. Àkókò amóríyá ni.” Evelyn pẹ̀lú ń jàǹfààní láti inú àwọn ìgbòkègbodò ìsìn rẹ̀. Ó sọ pé: “Jíjáde lọ bá àwọn ará àdúgbò mi sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì kì í jẹ́ kí n ya ara mi sọ́tọ̀. Ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń fún mi láyọ̀ ni. Ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọ ohun tí ìgbésí ayé jẹ́ ní ti gidi jẹ́ iṣẹ́ tí ń fúnni ní ìtẹ́lọ́rùn.”
Ó ṣe kedere pé Louise àti Evelyn ní ète kan nínú ayé wọn. Ìmọ̀lára tí ń tinú ipò àlàáfíà tí wọ́n wà wá ń mú kí ohun ìdènà kejì lọ sílẹ̀—àyíká—ó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa bá eré ìje náà lọ láìjuwọ́sílẹ̀.—Fi wé Sáàmù 92:13, 14.
Àbójútó Ìlera Olówó Pọ́ọ́kú, Pẹ̀lú Ìtọ́jú Tó Pójú Owó, Wà Lárọ̀ọ́wọ́tó
Ìlọsíwájú nínú ìmọ̀ ìṣègùn ní ọ̀rúndún yìí ti mú kí ohun ìdènà kẹta lọ sílẹ̀ lọ́nà gbígbàfiyèsí, ìyẹn ni àbójútó ìlera—àmọ́ kì í ṣe jákèjádò ayé. Ní àwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan tí kò lọ́rọ̀, ìròyìn The World Health Report 1998 sọ pé, “ní gidi, iye ọdún tí a retí láti lò láyé dín kù láàárín ọdún 1975 sí 1995.” Ọ̀gá àgbà àjọ WHO sọ pé, “lónìí, ẹni mẹ́ta lára àwọn mẹ́rin ló ń kú kí wọ́n tó pé ẹni àádọ́ta ọdún ní àwọn orílẹ̀-èdè tí kò tí ì gòkè àgbà—iye tí a ṣàkọsílẹ̀ jákèjádò ayé ní àádọ́ta ọdún sẹ́yìn pé òun ni iye ọdún tí a retí kí ẹnì kan lò láyé.”
Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn àgbàlagbà àti ọ̀dọ́ púpọ̀ sí i ń rẹ ohun ìdènà yìí sílẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí kò lọ́rọ̀ nípa gbígba ìtọ́jú tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó tí agbára wọ́n sì ká. Bí àpẹẹrẹ, gbé ọ̀nà tuntun tí a ń gbà tọ́jú ikọ́ ẹ̀gbẹ (TB) yẹ̀ wò.
Jákèjádò ayé, àwọn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ń pa ju àwọn tí àpapọ̀ àrùn AIDS, ibà, àti àwọn àrùn ilẹ̀ olóoru ń pa lọ—ó ń pa ẹgbẹ̀jọ èèyàn lójoojúmọ́. Márùndínlọ́gọ́rùn-ún lára ọgọ́rùn-ún ènìyàn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ń ṣe ló ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Nǹkan bí ogún mílíọ̀nù ènìyàn ni ikọ́ ẹ̀gbẹ tí ń pani sára ń ṣe báyìí, nǹkan bí ọgbọ̀n mílíọ̀nù ló sì lè pa ní ọdún mẹ́wàá tó ń bọ̀, iye yẹn jẹ́ àpapọ̀ gbogbo olùgbé Bolivia, Cambodia, àti Màláwì.
Abájọ tí inú àjọ WHO ṣe dùn nígbà tó kéde ní ọdún 1997 pé àwọn ti ní ọ̀nà tí àwọn yóò máa gbà wo ikọ́ ẹ̀gbẹ láàárín oṣù mẹ́fà láìsí pé a dá ẹni tó ń ṣe dúró sílé ìwòsàn tàbí kí a lo ọgbọ́n iṣẹ́ ẹ̀rọ gíga. Ìwé tí àjọ WHO ṣe, The TB Treatment Observer, sọ pé: “Èyí jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí ayé yóò ní ohun èlò tí a fẹ̀rí tí lẹ́yìn àti ìlànà ìtọ́jú tí a óò fi ṣẹ́pá ikọ́ ẹ̀gbẹ ní àwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ àti ní àwọn orílẹ̀-èdè tí kò lọ́rọ̀ lágbàáyé.” Ìlànà ìtọ́jú yìí—tí àwọn kan pè ní “àṣeyọrí gíga jù lọ nínú ìmọ̀ ìṣègùn ní ẹ̀wádún yìí”—ni a ń pè ní ìlànà DOTS.e
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iye tí a ń ná lórí ìlànà ìtọ́jú yìí kéré gan-an sí àwọn ọ̀nà tí a sábà máa ń gbà tọ́jú ikọ́ ẹ̀gbẹ, àbájáde rẹ̀ ń fọkàn ẹni balẹ̀, ní pàápàá jù lọ fún àwọn tí ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Dókítà Arata Kochi, olùdarí Ètò Ìtọ́jú Ikọ́ Ẹ̀gbẹ Tí Àjọ WHO Ń Ṣe Jákèjádò Ayé, sọ pé: “Kò sí ìlànà ìtọ́jú ikọ́ ẹ̀gbẹ mìíràn tó tí ì wo àwọn èèyàn sàn tó bẹ́ẹ̀ léraléra. Ìlànà ìtọ́jú DOTS ń wo àwọn tí iye wọ́n tó ìpín márùndínlọ́gọ́rùn-ún nínú ìpín ọgọ́rùn-ún sàn, kódà ní àwọn orílẹ̀-èdè tó tòṣì jù lọ.” Lópin ọdún 1997, orílẹ̀-èdè mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún ti ń lo ìlànà ìtọ́jú DOTS. Ní báyìí, iye yẹn ti lọ sókè sí mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún. Àjọ WHO nírètí pé ìlànà ìtọ́jú yìí yóò dé ọ̀dọ̀ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ òtòṣì ènìyàn sí i ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, tí yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí wọ́n lè rẹ ohun ìdènà kẹta sílẹ̀ nínú eré ìje ìgbésí ayé.
Ènìyàn ti mú kí ìpíndọ́gba gígùn ẹ̀mí rẹ̀ àti iye ọdún tó retí láti lò láyé gùn sí i nípa yíyí àwọn àṣà rẹ̀ padà, mímú kí àyíká rẹ̀ sunwọ̀n sí i, àti mímú kí ọ̀nà tó ń gbà bójú tó ìlera rẹ̀ sunwọ̀n sí i. Ìbéèrè tó wá dìde ni pé, Ǹjẹ́ yóò ṣeé ṣe lọ́jọ́ kan pé kí ènìyàn fa ẹ̀mí ẹ̀dá gùn kọjá ìpẹ̀kun ibi tó lè gùn dé—bóyá kí ó tilẹ̀ wà láàyè títí fáàbàdà?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀ náà, “iye ọdún tí a retí láti lò láyé” àti “ìpíndọ́gba gígùn ẹ̀mí” fún ohun kan náà, wọ́n yàtọ̀ síra. “Iye ọdún tí a retí láti lò láyé” tọ́ka sí iye ọdún tí ẹnì kan lè retí pé òun yóò lò láyé, nígbà tí “ìpíndọ́gba gígùn ẹ̀mí” tọ́ka sí ìpíndọ́gba iye ọdún tí àpapọ̀ àwọn ènìyàn kan lò láyé ní gidi. Nípa bẹ́ẹ̀, ìdíwọ̀n iye ọdún tí a retí láti lò láyé sinmi lé ìpíndọ́gba gígùn ẹ̀mí àwọn èèyàn.
b Ní àfikún sí àwọn kókó abájọ tó ṣeé yí padà yìí, ó dájú pé apilẹ̀ àbùdá tí ènìyàn jogún, tí kò ṣeé yí padà ń nípa lórí ìlera rẹ̀ àti bí ẹ̀mí rẹ̀ yóò ṣe gùn tó. A óò jíròrò èyí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.
c Láti rí ìsọfúnni sí i nípa bí o ṣe lè mú kí àyíká ilé rẹ sunwọ̀n sí i nípa ṣíṣe àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, wo àpilẹ̀kọ “Kíkojú Ìpèníjà Ìmọ́fínnífínní” àti “Ohun Tí Ń Pinnu Ìlera Rẹ—Ohun Tí O Lè Ṣe,” nínú Jí!, ìtẹ̀jáde March 22, 1989, àti April 8, 1995.
d Ibi tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ló ń jẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Gbogbo èèyàn ló lè wá sí àwọn ìpàdé náà, a kì í gbowó lọ́wọ́ àwọn èèyàn.
e DOTS jẹ́ ìkékúrú ọ̀rọ̀ náà, ìtọ́jú lò-ó-lójú-mi ní tààràtà fún ìgbà díẹ̀ [directly observed treatment, short-course]. Láti rí ìsọfúnni sí i nípa ìlànà ìtọ́jú DOTS, wo àpilẹ̀kọ “Ọ̀nà Tuntun Tí A Ń Gbà Bá Ikọ́ Ẹ̀gbẹ Jà,” nínú Jí!, June 8, 1999.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
BÁWO LÓ ṢE YẸ KÍ ERÉ ÌMÁRALE PỌ̀ TÓ, IRÚ WO SÌ NI?
Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ọjọ́ Ogbó ní Amẹ́ríkà (NIA) sọ pé: “Ṣíṣe eré ìmárale tó mọ níwọ̀n fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lójoojúmọ́ dára.” Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé kí o fi ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ṣeré lẹ́ẹ̀kan náà. Wọ́n ní iye àǹfààní tí a óò jẹ bí a bá ṣe eré ìmárale nígbà mẹ́ta ní lílo ìṣẹ́jú mẹ́wàá nígbà kọ̀ọ̀kan ni a óò jẹ bí a bá lo ọgbọ̀n ìṣẹ́jú náà tán lẹ́ẹ̀kan láti ṣe irú eré ìmárale kan náà. Irú eré ìmárale wo lo lè ṣe? Ìwé pẹlẹbẹ tí àjọ NIA ṣe, Don’t Take It Easy: Exercise! dámọ̀ràn pé: “Àwọn ìgbòkègbodò onígbà kúkúrú, bíi pípọ́nkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì dípò lílo ẹ̀rọ agbéniròkè, tàbí rírìn dípò wíwakọ̀, lè para pọ̀ jẹ́ eré ìmárale tí a fi ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ṣe lọ́jọ́ kan. Fífi ìgbálẹ̀ gbá ewé, bíbá àwọn ọmọdé sá sókè sá sódò, ríroko, àti ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ilé pàápàá ni o lè papọ̀ fi ṣe iye eré ìmárale tó yẹ kí o ṣe lójúmọ́.” Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó dára kí o bá dókítà rẹ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ kí o tó bẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ eré ìmárale kan.
[Àwòrán]
Eré ìmáralé tó mọ níwọ̀n lè mú kí àwọn arúgbó jèrè okun àti agbára padà
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
MÍMÚ KÍ ÈRÒ INÚ GBÉṢẸ́
Àwọn ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tí a fi ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arúgbó ṣe rí àwọn ohun mélòó kan tó ń mú kí èrò inú arúgbó kan gbéṣẹ́. Lára wọn ni “kíkàwé dáadáa, rírìnrìn àjò, lílọ sí àwọn ayẹyẹ ìbílẹ̀, ẹ̀kọ́ ìwé, ṣíṣe ẹgbẹ́, àti wíwà nínú ẹgbẹ́ àwọn amọṣẹ́dunjú.” “Ṣe oríṣiríṣi nǹkan tí o bá lè ṣe.” “Máa ṣe iṣẹ́ rẹ. Má ṣe fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́.” “Pa tẹlifíṣọ̀n.” “Dáwọ́ lé ìmọ̀ ẹ̀kọ́ kan.” Àwọn èèyàn gbà gbọ́ pé kì í ṣe pé irú àwọn ìgbòkègbodò yẹn ń mú kí ara yá gágá nìkan ni àmọ́, wọ́n tún ń ṣẹ̀dá àwọn ẹ̀yà tuntun nínú ọpọlọ.
[Àwòrán]
Lílo ọpọlọ ń mú kí èrò inú gbéṣẹ́
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
ÌSỌFÚNNI NÍPA BÍ ÀWỌN ARÚGBÓ ṢE LÈ BÓJÚ TÓ ÌLERA WỌN
Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ọjọ́ Ogbó ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, tó jẹ́ apá kan Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìlera àti Ìrànwọ́ Ẹ̀dá ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, sọ pé, “a lè mú kí agbára láti ní ìlera pípé àti láti pẹ́ láyé sunwọ̀n sí i” nípa títẹ̀lé ìmọ̀ràn tó bọ́gbọ́n mu, bí àwọn tó tẹ̀ lé e yìí:
● Máa jẹ oúnjẹ tí èròjà rẹ̀ pé, títí kan èso àti ewébẹ̀.
● Bí o bá fẹ́ mutí, mu ìwọ̀nba.
● Má ṣe mu sìgá. Kò tí ì pẹ́ jù láti jáwọ́ ńbẹ̀.
● Máa ṣe eré ìmárale déédéé. Bá dókítà sọ̀rọ̀ nípa ìtòlẹ́sẹẹsẹ eré ìm rale kan kí o tó bẹ̀rẹ̀ rẹ̀.
● Máa kàn sí ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.
● Máa faápọn ṣiṣẹ́, máa ṣeré, sì fara mọ́ àwùjọ.
● Máa ní ìṣarasíhùwà títọ́ nípa ìgbésí ayé.
● Máa ṣe àwọn ohun tó ń fún ọ láyọ̀.
● Máa ṣàyẹ̀wò ìlera rẹ déédéé.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]
YÍYẸ ÀWỌN SẸ́Ẹ̀LÌ ỌPỌLỌ WÒ LÁKỌ̀TUN
Dókítà Marilyn Albert, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú àrùn ọpọlọ àti ètò iṣan ara, sọ pé: “Tẹ́lẹ̀ rí, a máa ń rò pé àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ọpọlọ rẹ ń dín kù lójoojúmọ́ ayé rẹ ni, ní gbogbo kọ̀rọ̀ ọpọlọ rẹ. Àmọ́, kò rí bẹ́ẹ̀ rárá—díẹ̀ máa ń dín kù bí o ti ń darúgbó sí i, àmọ́ kò le tó bẹ́ẹ̀, ó sì máa ń jẹ́ ní àwọn ibì kan pàtó nínú ọpọlọ.” Ìwé ìròyìn Scientific American ti November 1998 sọ pé, ní àfikún sí i, ó kéré tán, àwọn ìwádìí ẹnu ọjọ́ mẹ́ta yìí fi hàn pé àwọn ohun tí a tilẹ̀ ti gbà gbọ́ tipẹ́tipẹ́ pé sẹ́ẹ̀lì tuntun kò lè yọ nínú ọpọlọ èèyàn jẹ́ “àsọdùn gbáà.” Àwọn onímọ̀ nípa ètò iṣan ara sọ pé àwọn ti ní ẹ̀rí tí ń fi hàn pé àwọn arúgbó pàápàá “máa ń ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún iṣan ọpọlọ tuntun.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]
ṢÉ BÉÈYÀN ṢE Ń DARÚGBÓ LÓ Ń GBỌ́N SÍ I?
Bíbélì béèrè pé: “Ọgbọ́n kò ha wà láàárín àwọn àgbàlagbà àti òye nínú gígùn àwọn ọjọ́?” (Jóòbù 12:12) Kí ni ìdáhùn rẹ̀? Àwọn olùwádìí ṣàyẹ̀wò àwọn arúgbó láti ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ànímọ́ bí “ìfòyemọ̀, ṣíṣèpinnu yíyè kooro, èrò inú àti agbára láti gbé àwọn ìlànà tó takora yẹ̀ wò, kí a sì mọ àwọn ọ̀nà tó dára láti gbà yanjú ìṣòro.” Bí ìwé ìròyìn U.S.News & World Report ṣe sọ, àyẹ̀wò náà fi hàn pé “léraléra ni àwọn arúgbó ta àwọn ọ̀dọ́ yọ ní gbogbo ọ̀nà tó kan ká lo ọgbọ́n, ká gbani nímọ̀ràn tó bọ́gbọ́n mu, tó sì gbámúṣé.” Àwọn àyẹ̀wò tún fi hàn pé, “bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn arúgbó sábà máa ń pẹ́ ju àwọn ọ̀dọ́ lọ kí wọ́n tó lè ṣèpinnu lórí nǹkan, ìpinnu tiwọn ló sábà máa ń dáa jù.” Nítorí náà, bí ìwé Jóòbù nínú Bíbélì ṣe sọ, ìmòye ni ọjọ́ orí jẹ́ ní tòótọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ìgbésí ayé èèyàn dà bí eré ìje tó kún fún ohun ìdènà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Opó kan gbani nímọ̀ràn pé: “Jẹ́ kí inú àwọn èèyàn máa dùn láti wà pẹ̀lú rẹ”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
“Ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọ ohun tí ìgbésí ayé jẹ́ ní ti gidi jẹ́ iṣẹ́ tí ń fúnni ní ìtẹ́lọ́rùn.”—Evelyn
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
“Ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, mo máa ń gbádùn bíbá àwọn ẹlòmíràn fọ̀rọ̀wérọ̀, àtọmọdé àtàgbà.”—Louise