Orin 33
Ẹ Má Bẹ̀rù Wọn!
1. Ẹ máa báa ǹṣó, ènìyàn mi,
Ẹ kéde Ìjọba náà.
Má ṣe fòyà ọ̀tá wa.
Jẹ́ kólùfẹ́ òótọ́ mọ̀
Pé Kristi Ọmọ mi Ọba
Ti lé Èṣù jù sáyé,
Yóò sì de Sátánì láìpẹ́,
Yóò dá òǹdè rẹ̀ sílẹ̀.
(ÈGBÈ)
Má bẹ̀rù, ìwọ àyànfẹ́,
Bí wọ́n tilẹ̀ ń halẹ̀.
Mo máa pa ìránṣẹ́ mi mọ́
Bí ẹyin ojú mi gan-an.
2. Báwọn ọ̀tá yín tilẹ̀ pọ̀,
Tí wọ́n ń halẹ̀ mọ́ yín,
Bí wọ́n tilẹ̀ ń pọ́n yín,
Kí wọ́n lè ráyè tàn yín.
Ẹ má bẹ̀rù àwọn ọ̀tá,
Ẹ̀yin ọmọ ogun mi,
Èmi yóò pa olóòótọ́ mọ́
Tí yóò fi jagun ṣẹ́gun.
(ÈGBÈ)
Má bẹ̀rù, ìwọ àyànfẹ́,
Bí wọ́n tilẹ̀ ń halẹ̀.
Mo máa pa ìránṣẹ́ mi mọ́
Bí ẹyin ojú mi gan-an.
3. Má ṣe rò pé a gbàgbé rẹ;
Èmi ni agbára rẹ.
Bí o kú lójú ogun,
Èmi yóò ṣẹ́gun ikú.
Má bẹ̀rù àwọn tí ńpara
Tí wọn kò lè pa ọkàn.
Jẹ́ olóòótọ́ títí dópin;
Èmi yóò mú ọ làá já!
(ÈGBÈ)
Má bẹ̀rù, ìwọ àyànfẹ́,
Bí wọ́n tilẹ̀ ń halẹ̀.
Mo máa pa ìránṣẹ́ mi mọ́
Bí ẹyin ojú mi gan-an.
(Tún wo Diu. 32:10; Neh. 4:14; Sm. 59:1; 83:2, 3.)