ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp16 No. 5 ojú ìwé 16
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?
  • Ìgbà wo ni Ìjọba Ọlọ́run máa dé?
  • Ìjọba Ọlọ́run
    Jí!—2013
  • Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2020
  • Ṣé Ìjọba Kan Wà Tó Máa Mú Kí Àlàáfíà Wà Kárí Ayé?—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ohun Tó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Ìjọba Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2020
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
wp16 No. 5 ojú ìwé 16
Ìmọ́lẹ̀ tàn sáyé látọ̀run

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?

ÀWỌN KAN GBÀ GBỌ́ PÉ ó túmọ̀ sí kí Ọlọ́run máa jọba lọ́kàn èèyàn, àwọn míì sì rò pé ìsapá àwa èèyàn láti mú kí àlááfíà àti ìṣọ̀kan wà láyé ni Ìjọba Ọlọ́run. Kí lèrò rẹ?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. . . . Yóò fọ́ ìjọba [èèyàn] wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn.” (Dáníẹ́lì 2:44) Ìjọba gidi ni Ìjọba Ọlọ́run.

KÍ LÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÍ BÍBÉLÌ SỌ?

  • Ìjọba Ọlọ́run máa ṣàkóso láti ọ̀run.​—Mátíù 10:7; Lúùkù 10:9.

  • Ọlọ́run máa lo Ìjọba yìí láti mú kí ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ lọ́run àti lórí ilẹ̀ ayé.​—Mátíù 6:10.

Ìgbà wo ni Ìjọba Ọlọ́run máa dé?

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kò sí ẹni tó mọ̀

  • Láìpẹ́

  • Kò lè dé láéláé

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Tí a bá ti wàásù ìhìn rere náà dáadáa kárí ayé, lẹ́yìn náà ni Ìjọba Ọlọ́run máa mú ayé burúkú yìí lọ sópin.

KÍ LÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÍ BÍBÉLÌ SỌ?

  • Kò sí ẹnì kankan láyé yìí tó mọ àsìkò pàtó tí Ìjọba Ọlọ́run máa dé.​—Mátíù 24:36.

  • Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run máa dé láìpẹ́.​—Mátíù 24:3, 7, 12.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 8 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é

Ó tún wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́