ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ẹ̀kọ́ 42 ojú ìwé 230-ojú ìwé 233 ìpínrọ̀ 5
  • Jẹ́ Kí Àwùjọ Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Kí Àwùjọ Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tí Ń Múni Nífẹ̀ẹ́ Sí Ọ̀rọ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Fúnni Níṣìírí Láti Lo Bíbélì
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Nínasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ẹ̀kọ́ 42 ojú ìwé 230-ojú ìwé 233 ìpínrọ̀ 5

Ẹ̀KỌ́ 42

Jẹ́ Kí Àwùjọ Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ

Kí ló yẹ kí o ṣe?

Ó yẹ kí o kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tí ń múni ronú jinlẹ̀, tí yóò sì jẹ́ kí àwùjọ mọ̀ pé àwọn rí ẹ̀kọ́ gidi kọ́.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

Bó bá jẹ́ pé ohun táwọn èèyàn ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ lo kàn wá ń tún sọ fún wọn, kò ní pẹ́ tí ọkàn wọn á fi ṣí kúrò lórí ọ̀rọ̀ rẹ.

KÍ ÀWÙJỌ lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ, wàá ṣe kọjá wíwulẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí kókó kan tó ṣe pàtàkì. Bi ara rẹ pé: ‘Èé ṣe tó fi yẹ kí àwùjọ yìí gbọ́ nípa kókó yìí? Kí ni mo lè sọ tí àwùjọ yóò fi lè rí i pé àwọn jàǹfààní gan-an nínú ọ̀rọ̀ náà?’

Bí wọ́n bá ní kí o ṣàṣefihàn ní ilé ẹ̀kọ́ nípa bá a ṣe lè jẹ́rìí fún ẹnì kan, onílé rẹ ló máa dúró fún àwùjọ rẹ. Àwọn ìgbà mìíràn sì wà tó jẹ́ pé ìjọ lódindi ni wàá bá sọ̀rọ̀.

Ohun Tí Àwùjọ Mọ̀. Bi ara rẹ pé, ‘Kí ni àwùjọ mọ̀ nípa kókó yìí?’ Ìyẹn lo máa fi mọ ibi tó yẹ kí o ti mú ọ̀rọ̀ náà. Bó bá jẹ́ pé ìjọ tó ní ọ̀pọ̀ Kristẹni tó dàgbà dénú lò ń bá sọ̀rọ̀, má fi ọ̀rọ̀ rẹ mọ sórí kìkì àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, èyí tí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn yóò ti mọ̀. Ṣe ni kí o gbé àlàyé rẹ látorí ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ wọ̀nyẹn. Àmọ́ o, bí ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tuntun bá tún wà nínú àwùjọ náà, á dáa kí o gba ti àwùjọ àwọn èèyàn méjèèjì náà rò.

Bí àlàyé kókó kọ̀ọ̀kan inú ọ̀rọ̀ rẹ yóò ṣe gùn tó sinmi lórí ohun tí àwùjọ rẹ mọ̀. Bí o bá fi àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí ọ̀pọ̀ jù lọ mọ̀ kún ọ̀rọ̀ rẹ, má ṣàlàyé lọ bí ilẹ̀ bí ẹní lórí irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n fara balẹ̀ ṣàlàyé kíkún nígbà tó o bá ń sọ nǹkan tó jẹ́ tuntun létí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn olùgbọ́ rẹ, kí òye rẹ̀ lè yé wọn yékéyéké.

Ohun Tí Yóò Kọ́ Wọn Lẹ́kọ̀ọ́. Kò dìgbà téèyàn bá ń sọ ohun tuntun pọ́ńbélé kí ọ̀rọ̀ onítọ̀hún tóó kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn olùbánisọ̀rọ̀ kan mọ ọ̀nà rírọrùn tí wọ́n lè gbé ọ̀rọ̀ gbà nígbà tí wọ́n bá ń ṣàlàyé àwọn kókó kan tá a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀, tí á fi jẹ́ pé ìyẹn gan-an láá jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí ọ̀pọ̀ nínú àwùjọ máa kọ́kọ́ lóye kókó wọ̀nyẹn yékéyéké.

Lóde ẹ̀rí, àwọn èèyàn lè máà rí nǹkan gidi dì mú nínú ọ̀rọ̀ rẹ, tí o bá kàn sọ pé ìròyìn báyìí-báyìí fi hàn pé ọjọ́ ìkẹyìn la wà. Fi Bíbélì ṣàlàyé ohun tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà túmọ̀ sí. Ìyẹn máa jẹ́ kí onílé rí ẹ̀kọ́ gidi kọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tó o bá máa sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn òfin àbáláyé tàbí nípa irúgbìn tàbí ẹranko, kì í kàn-án ṣe ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tó wúni lórí tí onílé kò tíì gbọ́ rí lo fẹ́ ṣàlàyé fún un. Ó tì o. Ohun tó yẹ kó jẹ́ ìdí tí wàá fi sọ̀rọ̀ lọ síbẹ̀ ni pé o fẹ́ mú ẹ̀rí látinú ìṣẹ̀dá láti fi ṣàlàyé àwọn gbólóhùn kan tó wà nínú Bíbélì láti fi hàn pé Ẹlẹ́dàá kan wà tó nífẹ̀ẹ́ wa. Èyí ló máa jẹ́ kí ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú tuntun wo ọ̀ràn náà.

Ó lè má rọrùn láti sọ̀rọ̀ lórí kókó kan tí àwùjọ ti gbọ́ léraléra. Ṣùgbọ́n láti jẹ́ olùkọ́ tó múná dóko, ó yẹ kí o mọ bí o ṣe lè ṣe é láṣeyọrí. Báwo lo ṣe lè ṣe é?

Ìwádìí ni wàá ṣe. Dípò tí wàá kàn fi máa sọ̀rọ̀ nípa kìkì àwọn kókó tó bá sọ sí ọ lọ́kàn, lo àwọn ohun èlò tí a fi ń ṣèwádìí tá a jíròrò ní ojú ìwé 33 sí 38. Gbé àwọn àbá tó wà níbẹ̀ yẹ̀ wò nípa àwọn ohun tó yẹ kí o máa lépa. O lè rí i nígbà tó o bá ń ṣèwádìí pé ìtàn kan táwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ tan mọ́ kókó ọ̀rọ̀ rẹ. Tàbí kẹ̀, o lè gbọ́ nípa ìròyìn kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí tí yóò jẹ́ káwọn èèyàn tètè lóye kókó ọ̀rọ̀ rẹ.

Bí o ti ń gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò, kí ìwọ alára máa bi ara rẹ ní àwọn ìbéèrè tí yóò mú ọ ro àròjinlẹ̀, àwọn ìbéèrè bíi kí ni? èé ṣe? ìgbà wo ni? ibo ni? ta ni? àti báwo ni? Bí àpẹẹrẹ: Kí nìdí tí èyí fi jẹ́ bẹ́ẹ̀? Báwo ni mo ṣe lè fi hàn pé òótọ́ ni? Kí làwọn ìgbàgbọ́ tó gbilẹ̀ tó jẹ́ kí ó nira fáwọn kan láti lóye òtítọ́ Bíbélì yìí? Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì? Báwo ló ṣe yẹ kí èyí kan ìgbésí ayé ẹni? Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé àǹfààní wà nínú mímú un lò? Kí ni òtítọ́ Bíbélì yìí fi hàn nípa irú ẹni tí Jèhófà jẹ́? Ohun tó o bá ń sọ̀rọ̀ lé lórí ni yóò pinnu bóyá ó yẹ kí o béèrè irú ìbéèrè bíi: Ìgbà wo ló ṣẹlẹ̀? Báwo ni ọ̀rọ̀ yìí ṣe kàn wá lónìí? O tiẹ̀ lè máa béèrè irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀, kí o sì máa dáhùn wọn nígbà tó o bá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ láti fi mú kí ọ̀rọ̀ rẹ túbọ̀ tani jí.

Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí àwùjọ mọ̀ dunjú lè wà lára ẹsẹ tó máa di dandan pé kó o lò nígbà tó o bá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. Báwo lo ṣe lè lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí lọ́nà tí yóò kún fún ẹ̀kọ́? Má kàn kà wọ́n lásán; ṣùgbọ́n rí i dájú pé o ṣàlàyé wọn.

Jíjíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ táwọn èèyàn mọ̀ dunjú lè kún fún ẹ̀kọ́, tí o bá pín in sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, tí o fa ìsọ̀rí tó tan mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ yọ, tí o sì ṣàlàyé wọn. Gbé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Míkà 6:8 yẹ̀ wò nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Kí ni “ìdájọ́ òdodo”? Ìlànà ìdájọ́ òdodo ta ni à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ níhìn-ín? Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé ohun tó túmọ̀ sí pé ká “ṣe ìdájọ́ òdodo”? Tàbí báwo lo ṣe máa ṣàlàyé ohun tó túmọ̀ sí láti “nífẹ̀ẹ́ inú rere”? Kí ni ìmẹ̀tọ́mọ̀wà? Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé àwọn kókó yìí fún àgbàlagbà? Ṣùgbọ́n o, ìsọfúnni tó o máa lò gan-an yóò sinmi lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ, irú iṣẹ́ tó o fẹ́ jẹ́, àwùjọ rẹ àti àkókò tó o ní láti fi sọ ọ́.

Títúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ lọ́nà rírọrùn ló dáa jù. Ó máa ń ya àwọn kan lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ìtumọ̀ “ìjọba” tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Mátíù 6:10. Kódà, rírán ẹnì kan tó ti jẹ́ Kristẹni tipẹ́ létí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ kan lè jẹ́ kó túbọ̀ mòye ohun tí ẹsẹ kan ń sọ. Ohun tí à ń sọ yìí á ṣe kedere tá a bá ka 2 Pétérù 1:5-8, tá a sì ṣàlàyé ànímọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ẹsẹ wọ̀nyẹn mẹ́nu kàn, bíi: ìgbàgbọ́, ìwà funfun, ìmọ̀, ìkóra-ẹni-níjàánu, ìfaradà, ìfọkànsin Ọlọ́run, ìfẹ́ni ará àti ìfẹ́. Nígbà táwọn ọ̀rọ̀ tí ìtumọ̀ wọn kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ síra bá fara hàn lójú kan náà, sísọ ìtumọ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lè jẹ́ káwọn èèyàn mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín wọn. Àpẹẹrẹ irú ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ni ọgbọ́n, ìmọ̀, ìfòyemọ̀ àti òye, bó ṣe wà nínú ìwé Òwe 2:1-6.

Àwọn olùgbọ́ yóò rí ẹ̀kọ́ kọ́, bó bá jẹ́ àlàyé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lo kàn ṣe. Ìyàlẹ́nu ló máa ń jẹ́ fún ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà tí wọ́n bá kọ́kọ́ rí i kà ní Jẹ́nẹ́sísì 2:7, nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan, pé Ádámù jẹ́ alààyè ọkàn, tí wọ́n tún wá rí i kà ní Ìsíkíẹ́lì 18:4 pé ọkàn máa ń kú. Nígbà kan, Jésù ṣe ohun tó ya àwọn Sadusí lẹ́nu nígbà tó tọ́ka sí Ẹ́kísódù 3:6, ìyẹn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n sọ pé àwọn gbà gbọ́, tó sì wá fi ṣàlàyé àjíǹde àwọn òkú.—Lúùkù 20:37, 38.

Nígbà mìíràn, títọ́ka sí ìdí tí ọ̀rọ̀ kan fi wáyé nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n ń kọ ọ́ àti ẹni tó sọ ọ̀rọ̀ náà tàbí ẹni tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ yẹn sí máa ń lani lóye. Àwọn Farisí mọ Sáàmù àádọ́fà [110] bí ẹní mowó. Síbẹ̀, Jésù pe àfiyèsí wọn sí kókó pàtàkì kan tó wà ní ẹsẹ kìíní Sáàmù yẹn. Ó béèrè pé: “‘Kí ni ẹ̀yin rò nípa Kristi? Ọmọkùnrin ta ni ó jẹ́?’ Wọ́n wí fún un pé: ‘Ti Dáfídì.’ Ó wí fún wọn pé: ‘Báwo wá ni ó ṣe jẹ́ tí Dáfídì nípasẹ̀ ìmísí fi pè é ní “Olúwa,” ní wíwí pé, “Jèhófà wí fún Olúwa mi pé: ‘Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ’”? Nítorí náà, bí Dáfídì bá pè é ní “Olúwa,” báwo ni òun ṣe jẹ́ ọmọkùnrin rẹ̀?’” (Mát. 22:41-45) Nígbà tó o bá ṣe àlàyé Ìwé Mímọ́ gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe, wàá ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti máa túbọ̀ fara balẹ̀ ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ bá mẹ́nu kan ìgbà tí wọ́n kọ ìwé Bíbélì kan tàbí ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ kan wáyé, ó tún yẹ kó ṣàlàyé bí nǹkan ṣe rí nígbà yẹn. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwùjọ á túbọ̀ rí ìjẹ́pàtàkì ìwé náà tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Àfiwé tún máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ túbọ̀ kún fún ẹ̀kọ́. O lè ṣàlàyé ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó kan àti ojú tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wo nǹkan náà. Tàbí kẹ̀, o lè fi ìtàn kan náà tí Bíbélì ròyìn nínú ìwé méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wéra. Ǹjẹ́ ó níbi tí wọ́n ti yàtọ̀ síra? Kí nìdí? Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú wọn? Tí o bá ṣe èyí, ó lè mú kí kókó náà jẹ́ tuntun lójú àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀.

Bó bá jẹ́ pé wọ́n ní kí o sọ̀rọ̀ nípa àwọn apá kan lára iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni, o lè mú kí ọ̀rọ̀ rẹ lárinrin nípa kíkọ́kọ́ ṣe àkópọ̀ kókó inú rẹ̀. Ṣàlàyé ohun tó yẹ ní ṣíṣe, ìdí tó fi yẹ ní ṣíṣe àti bó ṣe kan ohun tí iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà fún lápapọ̀. Lẹ́yìn náà, ṣàlàyé ibi tí a ó ti ṣe iṣẹ́ náà, ìgbà tí a ó ṣe é àti bí a ó ṣe ṣe é.

Bí ó bá yẹ kí o ṣàlàyé “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” nínú ọ̀rọ̀ rẹ ńkọ́? (1 Kọ́r. 2:10) Bí o bá kọ́kọ́ fa àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ náà yọ, tí o sì ṣàlàyé wọn, kúlẹ̀kúlẹ̀ yòókù kò ní ṣòroó lóye. Bí ó bá jẹ́ àkópọ̀ àwọn kókó inú ọ̀rọ̀ rẹ lo fi kásẹ̀ ọ̀rọ̀ nílẹ̀, inú àwùjọ yóò dùn pé àwọn rí ẹ̀kọ́ gidi kọ́.

Ìmọ̀ràn Tó Dá Lórí Ìgbésí Ayé Kristẹni. Àwùjọ yóò jàǹfààní gan-an bí o bá jẹ́ kí wọ́n rí bí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe kan ìgbésí ayé wọn. Bí o ṣe ń ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ tá a yàn fún ọ, bi ara rẹ léèrè pé, ‘Kí nìdí tí ìsọfúnni yìí fi wà nínú Ìwé Mímọ́ títí di òní olónìí?’ (Róòmù 15:4; 1 Kọ́r. 10:11) Ronú nípa ìṣòro táwọn olùgbọ́ rẹ ń dojú kọ nínú ìgbésí ayé. Gbé ìṣòro wọ̀nyẹn yẹ̀ wò, kí o wo ìmọ̀ràn àti ìlànà Ìwé Mímọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa wọn. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ, mú àwọn kókó jáde látinú Ìwé Mímọ́ láti fi hàn pé Ìwé Mímọ́ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ ọgbọ́n tí wọ́n lè fi kojú ìṣòro wọ̀nyẹn. Má kàn sọ̀rọ̀ lóréfèé. Sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìwà àti ìgbésẹ̀ kan ní pàtó.

Láti tibi pẹlẹbẹ mọ́ọ̀lẹ̀ jẹ, mú ọ̀kan tàbí méjì lára àwọn àbá tó wà lókè yìí lò nínú ọ̀rọ̀ tí ò ń múra lọ́wọ́lọ́wọ́. Bó o ṣe ń ní ìrírí sí i, mú púpọ̀ sí i lára àbá wọ̀nyí lò. Bí àkókò ti ń lọ, wàá rí i pé àwùjọ á máa hára gàgà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, pẹ̀lú ìdánilójú pé àwọn yóò rí nǹkan kan gbọ́ tí yóò ṣe àwọn láǹfààní ní ti gidi.

BÍ O ṢE LÈ ṢE É

  • Ronú lórí ohun tí àwùjọ rẹ ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nípa kókó tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí.

  • Mọ bó ṣe yẹ kí àlàyé rẹ gùn tó, ìyẹn ni pé, má sọ̀rọ̀ pẹ́ lọ títí lórí kókó tí wọ́n mọ̀ dáadáa, fara balẹ̀ ṣàlàyé àwọn kókó tuntun.

  • Má kàn mẹ́nu kan kókó ọ̀rọ̀ nìkan; ṣàlàyé ìtumọ̀ wọn tàbí kí o sọ bí wọ́n ṣe wúlò sí.

  • Kí ìwọ alára bi ara rẹ ní àwọn ìbéèrè tí yóò mú ọ ro àròjinlẹ̀, àwọn ìbéèrè bíi: Kí ni? Èé ṣe? Ìgbà wo ni? Ibo ni? Ta ni? Báwo ni?

  • Fara balẹ̀ fèrò wérò látinú Ìwé Mímọ́; ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé lórí àwọn apá kan pàtó níbẹ̀.

  • Ṣàlàyé ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn kókó ọ̀rọ̀ kan.

  • Ṣe àkópọ̀ àwọn kókó tó wà nínú ọ̀rọ̀ rẹ ní ṣókí.

  • Jẹ́ kí àwùjọ mọ bí wọ́n ṣe lè fi ìsọfúnni náà yanjú àwọn ìṣòro, kí wọ́n sì fi ṣe àwọn ìpinnu.

ÌDÁNRAWÒ: (1) Ṣe ìwádìí láti rí apá tó kún fún ẹ̀kọ́ nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan táwọn èèyàn mọ̀ dunjú, bíi Mátíù 24:14 tàbí Jòhánù 17:3. (2) Ka Òwe 8:30, 31 àti Jòhánù 5:20. Báwo ni ṣíṣàṣàrò lórí àjọṣe àárín Jèhófà Ọlọ́run àti Kristi Jésù, bí ẹsẹ wọ̀nyẹn ṣe ṣàlàyé rẹ̀, ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi ẹsẹ wọ̀nyẹn ran ìdílé kan lọ́wọ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́