Ẹ̀KỌ́ 43
Mú Ọ̀rọ̀ Rẹ Jáde Láti Ibi Tí A Ti Yanṣẹ́ fún Ọ
BÍBÉLÌ fi ìjọ Kristẹni wé ara ènìyàn. Gbogbo ẹ̀yà ara ló jẹ́ kòṣeémánìí, ‘ṣùgbọ́n iṣẹ́ kan náà kọ́ ni gbogbo wọn ń ṣe.’ Torí ìdí yìí, ó yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú àǹfààní èyíkéyìí tá a bá nawọ́ rẹ̀ sí wa. Èyí ń béèrè pé ká lóye ọ̀rọ̀ èyíkéyìí tá a bá yàn fún wa, ká sì sọ ọ́ dáadáa, dípò kíka àwọn kókó kan sí èyí tí kò ṣe pàtàkì, nítorí a rò pé àwọn kókó mìíràn á dùn-ún sọ̀rọ̀ lé lórí jù wọ́n lọ. (Róòmù 12:4-8) Ojúṣe ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye ni láti fún wa ní oúnjẹ tẹ̀mí “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Mát. 24:45) Bí a bá sa gbogbo ipá wa láti múra ọ̀rọ̀ tá a yàn fún wa níbàámu pẹ̀lú ìtọ́ni tí wọ́n fún wa, ìyẹn á fi hàn pé a mọyì ìṣètò yẹn. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ kí gbogbo nǹkan máa lọ geerege nínú ìjọ lódindi.
Ìsọfúnni Tí Wàá Lò. Nígbà tá a bá ní kí o sọ̀rọ̀ lórí kókó kan ní ilé ẹ̀kọ́, rí i dájú pé kókó ọ̀rọ̀ yẹn lo múra sílẹ̀, kì í ṣe kókó ọ̀rọ̀ mìíràn. A ti sábà máa ń tọ́ka sí ìtẹ̀jáde tí wàá ti lọ mú ọ̀rọ̀ rẹ jáde. Bí a kò bá sọ ìtẹ̀jáde tí wàá ti mú ọ̀rọ̀ rẹ jáde, o lè kó ọ̀rọ̀ rẹ jọ látinú àwọn ìtẹ̀jáde tí o bá fẹ́. Àmọ́, bó o ti ń múra ọ̀rọ̀ rẹ, rí i dájú pé gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ dá lórí kókó ọ̀rọ̀ tí wọ́n ní kí o sọ̀rọ̀ lé lórí. Nígbà tí o bá ń kó ìsọfúnni tó o fẹ́ lò jọ, rántí àwùjọ tí o fẹ́ sọ ọ̀rọ̀ náà fún.
Fara balẹ̀ ka ìtẹ̀jáde tó o ti fẹ́ mú ọ̀rọ̀ jáde, kí o sì gbé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀ yẹ̀ wò. Wá ronú lórí bí o ṣe lè lò ó lọ́nà tó gbéṣẹ́ fún àǹfààní àwùjọ. Yan kókó méjì tàbí mẹ́ta látinú ìtẹ̀jáde náà, kí o sì fi wọ́n ṣe lájorí kókó ọ̀rọ̀ rẹ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, tún yan àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí o fẹ́ kà kí o sì ṣàlàyé rẹ̀ látinú ibi tí a ti yanṣẹ́ fún ọ.
Báwo ló ṣe yẹ kí ìsọfúnni tó o fẹ́ lò látinú ìtẹ̀jáde yẹn pọ̀ tó? Fi mọ sórí kìkì ohun tí wàá lè ṣàlàyé dáadáa. Má kàn lọ kó ìsọfúnni jọ rẹpẹtẹ, tó ò fi ní lè kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó múná dóko. Bí o bá rí lára ìsọfúnni náà tí kò bá kókó ọ̀rọ̀ rẹ mu, pa á tì, kí o sì gbájú mọ́ ìsọfúnni tí yóò gbé kókó ọ̀rọ̀ rẹ yọ. Wá ohun tó bá kún fún ẹ̀kọ́, tó sì máa wúlò fún àwùjọ gan-an. Ìyẹn ni kí o mú lò nínú ibi tí wọ́n ti yanṣẹ́ fún ọ. Ohun tí ò ń lépa lórí ìmọ̀ràn ọ̀rọ̀ sísọ yìí kì í ṣe bí ìsọfúnni tí o fẹ́ lò ṣe lè pọ̀ tó, bí kò ṣe gbígbé ọ̀rọ̀ rẹ ka ibi tá a ti yanṣẹ́ fún ọ.
A kò retí pé kí ọ̀rọ̀ rẹ wulẹ̀ jẹ́ àkópọ̀ ohun tá a ní kí o sọ̀rọ̀ lé lórí lásán. Ó yẹ kí o múra àtiṣàlàyé àwọn kókó kan, kí o fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́, kí o fi àpèjúwe gbé wọn jókòó, bí ó bá sì ṣeé ṣe, kí o sọ àpẹẹrẹ bá a ṣe lè fi wọ́n sílò. O lè lo àfikún ìsọfúnni láti fi ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ibi tá a ti yanṣẹ́ fún ọ, àmọ́ kì í ṣe pé kí o kúkú wá fi ọ̀rọ̀ mìíràn rọ́pò iṣẹ́ tá a yàn fún ọ.
Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, a lè ní kí àwọn arákùnrin tó jẹ́ olùkọ́ tó tóótun wá kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Wọ́n mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n lo ìsọfúnni tó wà nínú ibi tá a ti yanṣẹ́ fún wọn láti fi kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, dípò kí wọ́n lọ fi nǹkan míì rọ́pò rẹ̀. Bákan náà, a máa ń fún àwọn arákùnrin tí ń sọ àsọyé ní ìwé àsọyé tí wọ́n á lò. Èyí máa ń fún wọn láǹfààní láti gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀ bí wọ́n ṣe fẹ́. Àmọ́ ṣá o, àwọn kókó pàtàkì tí wọ́n ní láti sọ̀rọ̀ lé lórí àti àwọn àlàyé tí wọn ó fi tì í lẹ́yìn pẹ̀lú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó jẹ́ òpómúléró nínú ọ̀rọ̀ náà yóò ti wà nínú rẹ̀. Mímọ bó o ṣe lè gbé ọ̀rọ̀ rẹ ka ibi tá a ti yanṣẹ́ fún ọ jẹ́ apá pàtàkì nínú mímúra sílẹ̀ fún ìgbà tí a bá máa yan àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn fún ọ láti sọ.
Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí tún lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ń tẹ̀ síwájú. Á jẹ́ kí o mọ bí o ṣe lè fi ọ̀rọ̀ rẹ mọ sórí kókó tí ò ń kọ́ni, dípò fífi kókó ọ̀rọ̀ sílẹ̀ lọ máa ṣàlàyé àwọn nǹkan míì tó dùn mọ́ ọ láti sọ ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé àyàbá ni, tí kò sì ṣe pàtàkì nínú lílóye kókó tí ò ń fi kọ́ni. Àmọ́ tí òye ọ̀rọ̀ tí a ṣàlàyé yìí bá yé ọ dáadáa, o ò ní wonkoko mọ́ ohun tí ò ń kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ jù débi tí wàá fi máa gbójú fo àfikún àlàyé tó yẹ kó o ṣe fún akẹ́kọ̀ọ́.