ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÒWE 17-21
Máa Wà Ní Àlàáfíà Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíì
Àlááfíà tó wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà kì í ṣe èèṣì. Tí èdèkòyédè bá ṣẹlẹ̀, ó lè múnú bí wa gan-an, àmọ́ ìmọ̀ràn inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń pẹ̀tù sí wa lọ́kàn.
Tí àìgbọ́ra-ẹni-yé bá ṣẹlẹ̀, àwọn Kristẹni olóòótọ́ máa ń wá àlááfíà nípa . . .
ṣíṣàì-fara-ya
rírí i pé àwọn mọ gbogbo bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ kí wọ́n tó fèsì
jíjẹ́ kí ìfẹ́ mú kí wọ́n dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ wọ́n