ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | AÍSÁYÀ 6-10
Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà Tó Ní Ìmúṣẹ
Bíi Ti Orí Ìwé
Ní ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n tó bí Jésù, wòlíì Aísáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà máa wàásù ní “ẹkùn ilẹ̀ Jọ́dánì, Gálílì àwọn orílẹ̀-èdè.” Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ sí Jésù lára, ní ti pé ó rìnrìn àjò jákèjádò Gálílì ó ń wàásù ó sì ń kọ́ni ní ìhìn rere.—Ais 9:1, 2.
Ó ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àkọ́kọ́ —Jo 2:1-11 (Kánà)
Ó yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ —Mk 3:13, 14 (nítòsí Kápánáúmù)
Ó ṣe Ìwàásù Lórí Òkè —Mt 5:1–7:27 (nítòsí Kápánáúmù)
Ó jí ọmọ opó kan dìde —Lu 7:11-17 (Náínì)
Ó fara han nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] àwọn ọmọ ẹ̀yìn lẹ́yìn tó jíǹde—1Kọ 15:6 (Gálílì)