ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 4-5
Ohun Tá A Rí Kọ́ Nínú Ìwàásù Jésù Lórí Òkè
Ṣé àwọn àìní rẹ nípa tẹ̀mí ń jẹ ọ́ lọ́kàn?
Gbólóhùn náà “àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn” túmọ̀ sí àwọn tó ń bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀mí. (Mt 5:3.) A lè fi hàn pé ó wù wá gidigidi pé kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, tá a bá ń . . .
ka Bíbélì lójoojúmọ́
múra àwọn ìpàdé ìjọ sílẹ̀, ká sì máa lọ sípàdé déédéé
wá àyè láti ka àwọn ìtẹ̀jáde wa tó fi mọ́ àwọn nǹkan tó wà lórí ìkànnì wa
wo ètò òṣooṣù Tẹlifíṣọ̀n JW
Báwo ni mo ṣe lè túbọ̀ ṣètò ara mi kí n lè máa gbádùn oúnjẹ tẹ̀mí?