ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | IṢE 6-8
Ìjọ Kristẹni Tuntun Kojú Ìṣòro
Àwọn opó tó ń sọ èdè Gíríìkì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìrìbọmi fẹ́ dúró fúngbà díẹ̀ sí i ní Jerúsálẹ́mù, àmọ́ àwọn kan nínú ìjọ ń hùwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà sí wọn. Ṣé ìyẹn mú wọn kọsẹ̀, àbí wọ́n dúró kí Jèhófà bójú tó ọ̀rọ̀ náà?
Lẹ́yìn tí wọ́n sọ Sítéfánù lókùúta, tí inúnibíni tó le gan-an sì mú kí àwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù sá lọ sí Jùdíà àti Samáríà, ṣé ìyẹn mú kí wọ́n dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
Pẹ̀lú ìtìlẹyìn Jèhófà, ìjọ Kristẹni tuntun fara da ìṣòro, wọ́n sì ń pọ̀ sí i.—Iṣe 6:7; 8:4.
BI ARA RẸ PÉ, ‘Tí mo bá níṣòro, báwo ni mo ṣe máa ń kojú ẹ̀?’