ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌṢE 21-22
“Kí Ìfẹ́ Jèhófà Ṣẹ”
Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ ló ń darí òun lọ sí Jerúsálẹ́mù níbi tí òun máa ti dojú kọ ìṣòro. (Iṣe 20:22, 23) Torí náà, nígbà tí àwọn Kristẹni ń rọ Pọ́ọ̀lù pé kó má lọ, ṣe ló dá wọn lóhùn pé: “Kí ni ẹ ń ṣe nípa sísunkún, tí ẹ sì ń sọ mí di aláìlera ní ọkàn-àyà?” (Iṣe 21:13) Tẹ́nì kan bá fẹ́ yááfì àwọn nǹkan kan, kó bàa lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, a ò gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti paná ìtara tó ní.