ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 21-22
Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Jọ Ẹ́ Lójú Bíi Ti Jèhófà
Ẹ̀mí ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà. Báwo làwa náà ṣe lè fi hàn pé ẹ̀mí jọ wá lójú?
Nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn látọkànwá, kó o sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn.—Mt 22:39; 1Jo 3:15
Fi kún ìtara ẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù kó lè hàn pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn lóòótọ́.—1Kọ 9:22, 23; 2Pe 3:9
Fi hàn pé ọ̀rọ̀ ààbò jẹ ẹ́ lógún.—Owe 22:3
Tí ẹ̀mí bá jọ wá lójú, báwo nìyẹn ò ṣe ní jẹ́ ká jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀?