ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 JÒHÁNÙ 1-13; 3 JÒHÁNÙ 1-14–JÚÙDÙ 1-25
A Gbọ́dọ̀ Jà Fitafita Ká Lè Dúró Nínú Òtítọ́
Jésù gbà wá níyànjú pé: “Ẹ sa gbogbo ipá yín láti gba ẹnu ọ̀nà tóóró wọlé.” (Lk 13:24) Ọ̀rọ̀ Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé a gbọ́dọ̀ tiraka gan-an ká lè rí ojú rere Ọlọ́run. Lábẹ́ ìmísí, Júùdù tó jẹ́ àbúrò Jésù náà sọ ohun tó fara jọ èyí, ó ní: “Ẹ máa jà fitafita torí ìgbàgbọ́.” A gbọ́dọ̀ sapá gan-an ká tó lè ṣe àwọn nǹkan tá a tò sísàlẹ̀ yìí:
Ká sá fún ìṣekúṣe.—Jud 6, 7
Ká bọ̀wọ̀ fáwọn tó ń múpò iwájú.—Jud 8, 9
Ká mú kí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì túbọ̀ dá wa lójú, ìyẹn “ìgbàgbọ́ mímọ́ jù lọ” tá a ní.—Jud 20, 21