ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • th ẹ̀kọ́ 5 ojú ìwé 8
  • Kàwé Lọ́nà Tó Tọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kàwé Lọ́nà Tó Tọ́
  • Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kíkàwé Lọ́nà Tó Tọ́
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Fi Ara Rẹ fún Ìwé Kíkà
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Bó O Ṣe Lè Jàǹfààní Púpọ̀ Látinú Bíbélì
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
th ẹ̀kọ́ 5 ojú ìwé 8

Ẹ̀KỌ́ 5

Kàwé Lọ́nà Tó Tọ́

Ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí

1 Tímótì 4:13

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Ka ọ̀rọ̀ inú ìwé bó ṣe wà níbẹ̀ gẹ́lẹ́.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Múra sílẹ̀ dáadáa. Ronú nípa ìdí tí ọ̀rọ̀ yẹn fi wà lákọsílẹ̀. Fi kọ́ra láti máa ka àwọn ọ̀rọ̀ bíi mélòó kan pa pọ̀, kó má ṣe jẹ́ ẹyọ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan ni wàá kàn máa kà. Má ṣe fi ọ̀rọ̀ kún un, má ṣe fo ọ̀rọ̀, má sì ṣe fi ọ̀rọ̀ kan pe òmíì. Máa kíyè sí àwọn àmì tá a fi ń pín gbólóhùn.

    Àwọn àbá

    Sọ fún ẹni kan pé kó tẹ́tí sí bó o ṣe ń kàwé, kó sì sọ àwọn ibi tó o bá ti ṣi ọ̀rọ̀ pè fún ẹ.

  • Pe ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan bó ṣe tọ́. Tí o kò bá mọ bó o ṣe máa pe ọ̀rọ̀ kan, o lè wo inú ìwé atúmọ̀ èdè, o lè tẹ́tí sí ìtẹ̀jáde náà tá a ti gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀, tàbí kó o sọ pé kí ẹnì kan tó mọ̀wé kà dáadáa ràn ẹ́ lọ́wọ́.

  • Sọ̀rọ̀ ketekete. Fara balẹ̀ pe ọ̀rọ̀, gbé orí sókè, kó o sì la ẹnu rẹ dáadáa. Rí i pé ò ń pè ọ̀rọ̀ lọ́nà tó ṣe kedere.

    Àwọn àbá

    Má ṣe máa pe ọ̀rọ̀ ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan débi tí ọ̀rọ̀ rẹ kò fi ní já geere.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́