ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • th ẹ̀kọ́ 11 ojú ìwé 14
  • Ìtara

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtara
  • Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Máa Lo Ìtara Tó O Bá Ń Kọ́ni
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Ọ̀yàyà àti Ìfọ̀rọ̀rora-Ẹni-Wò
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Jẹ́ Kí Àwọn Èèyàn Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
Àwọn Míì
Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
th ẹ̀kọ́ 11 ojú ìwé 14

Ẹ̀KỌ́ 11

Ìtara

Ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí

Róòmù 12:11

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Máa fi ìtara sọ̀rọ̀. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ rẹ á ta àwọn olùgbọ́ rẹ jí, á sì fún wọn níṣìírí láti ṣiṣẹ́ lórí ohun tó ò ń sọ.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Sọ̀rọ̀ látọkàn wá. Bó o ṣe ń múra sílẹ̀ láti sọ ọ̀rọ̀ rẹ, ronú jinlẹ̀ nípa bí ọ̀rọ̀ náà ti ṣe pàtàkì tó. Rí i dájú pé ohun tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yé ẹ dáadáa débi tí wàá fi lè sọ̀rọ̀ látọkàn wá.

  • Ronú nípa àwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀. Ronú nípa àǹfààní táwọn èèyàn máa rí nínú ohun tó o fẹ́ kà tàbí ohun tó o fẹ́ kọ́ wọn. Ronú nípa bó o ṣe máa gbé ọ̀rọ̀ náà kalẹ̀ lọ́nà tó máa mú kí wọ́n mọyì ohun tó o sọ.

  • Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tani jí. Fi ìtara sọ̀rọ̀. Fara ṣàpèjúwe, kó o sì túra ká, ńṣe ni ìyẹn á fi hàn pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ orí ahọ́n lásán lò ń sọ.

    Àwọn àbá

    Ṣọ́ra kó o má ṣe máa fara ṣàpèjúwe lọ́nà kan náà ṣáá torí pé ó wulẹ̀ ti mọ́ ẹ lára; èyí kò ní nítumọ̀ kankan sí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀. Ńṣe ni kó o máa fara ṣàpèjúwe lọ́nà tó nítumọ̀. Tó o bá ń ṣàlàyé àwọn kókó tó gbàfiyèsí tó o sì fẹ́ fún àwọn èèyàn níṣìírí láti ṣe ohun tó yẹ, ìgbà yẹn ló ṣe pàtàkì jù pé kó o fi ìtara sọ̀rọ̀. Fi sọ́kàn pé ọ̀rọ̀ rẹ lè sú àwọn èèyàn tó o bá lo ìtara tó pọ̀ jù jálẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́