ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • th ẹ̀kọ́ 10 ojú ìwé 13
  • Yí Ohùn Pa Dà Bó Ṣe Yẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Yí Ohùn Pa Dà Bó Ṣe Yẹ
  • Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Yíyí Ohùn Padà Nínú Ọ̀rọ̀ Sísọ
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Lílo Ohùn Bí Ó Ti Yẹ
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ìtara
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Fi Ìdánilójú Sọ̀rọ̀
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
Àwọn Míì
Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
th ẹ̀kọ́ 10 ojú ìwé 13

Ẹ̀KỌ́ 10

Yí Ohùn Pa Dà Bó Ṣe Yẹ

Ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí

Òwe 8:4, 7

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Tó o bá ń gbóhùn sókè tó o sì ń rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ bó ṣe yẹ, tí ò ń lo oríṣiríṣi ìró ohùn, tó o sì ń yí bó o ṣe ń yára sọ̀rọ̀ àti bó o ṣe ń rọra sọ̀rọ̀ pa dà, ọ̀rọ̀ rẹ á ṣe kedere, á sì wọni lọ́kàn.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Máa gbóhùn sókè kó o sì máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ bó ṣe yẹ. Gbóhùn sókè tí o bá fẹ́ sọ àwọn kókó pàtàkì tó o fẹ́ kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ ṣiṣẹ́ lé lórí. Ohun kan náà ni kó o ṣe tó o bá fẹ́ ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́. Rẹ ohùn rẹ sílẹ̀ tó o bá fẹ́ kí àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀ máa fojú sọ́nà sí ohun tó o fẹ́ sọ tẹ̀ lé e tàbí tó o bá fẹ́ sọ ọ̀rọ̀ ẹni tí ẹ̀rù ń bà tàbí tí ọkàn rẹ̀ ò balẹ̀.

    Àwọn àbá

    Má ṣe jẹ́ kí ohùn rẹ máa fìgbà gbogbo lọ sókè kí àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀ má bàa rò pé ńṣe lò ń nà wọ́n lẹ́gba ọ̀rọ̀. Má ṣàṣejù nínú bó o ṣe ń lo ohùn rẹ, kó má bàa di pé ò ń pàfiyèsí sí ara rẹ.

  • Lo oríṣiríṣi ìró ohùn. Tí èdè rẹ bá fàyè gbà á, jẹ́ kí ohùn rẹ túbọ̀ rinlẹ̀ tó o bá fẹ́ fi ìtara sọ ọ̀rọ̀ kan tàbí tó o fẹ́ ṣàlàyé bí nǹkan ṣe tóbi tó tàbí bí ibì kan ṣe jìnnà tó. Ohùn tó dẹ̀ ni kó o fi sọ ọ̀rọ̀ ẹni tí inú rẹ̀ bà jẹ́ tàbí tí ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀.

  • Máa yí bó o ṣe ń yára sọ̀rọ̀ àti bó o ṣe ń rọra sọ̀rọ̀ pa dà. Yára sọ̀rọ̀ tó o bá fẹ́ sọ̀rọ̀ ẹni tí ara rẹ̀ yá gágá tí inú rẹ̀ sì ń dùn. Rọra sọ̀rọ̀ tó o bá fẹ́ sọ ọ̀rọ̀ pàtàkì.

    Àwọn àbá

    Tó o bá fẹ́ kí àwọn èèyàn máa fara balẹ̀ tẹ́tí gbọ́ ẹ, má kàn ṣàdédé yára sọ̀rọ̀ kó o sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í rọra sọ̀rọ̀ lójijì. Má ṣe rún ọ̀rọ̀ pọ̀ mọ́ra, torí pé kò ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ yé àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́