ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 4-5
“Màá Wà Pẹ̀lú Rẹ Bí O Ṣe Ń Sọ̀rọ̀”
Jèhófà ran Mósè lọ́wọ́ kó lè borí ìbẹ̀rù rẹ̀. Kí la rí kọ́ látinú ohun tí Jèhófà sọ fún Mósè?
Kò yẹ ká máa ronú jù nípa ibi tá a kù sí
Ká jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa fún wa ní ohunkóhun tá a bá nílò ká lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ wa
Tá a bá nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run, a ò ní bẹ̀rù èèyàn
Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ti gbà ràn mí lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro tí mo dojú kọ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?