ORIN 113
Àlàáfíà Tó Wà Láàárín Wa
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Yin Ọlọ́run àlàáfíà,
Ọlọ́run ìfẹ́.
Ó máa fòpin sí ogun,
Yóò mú ‘rẹ́pọ̀ wá.
Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi
Ọba Àlàáfíà,
Yóò ja ìjà òdodo;
Yóò málàáfíà wá.
2. A kì í sọ̀rọ̀ búburú
Tó lè fa ìjà.
A ti dẹni àlàáfíà
Pẹ̀l’áwọn èèyàn.
Ó yẹ ká máa dárí ji
Àwọn tó ṣẹ̀ wá.
Yóò jẹ́ ká wà lálàáfíà
Bíi Jésù Kristi.
3. Àlàáfíà Ọlọ́run wa
Máa ń mú ‘bùkún wá.
Àwọn òfin rẹ̀ dára;
A ó máa ṣègbọràn.
Bó bá ti lè ṣeé ṣe tó,
Ká wà lálàáfíà.
Láìpẹ́, àlàáfíà máa wà
Ní gbogbo ayé.
(Tún wo Sm. 46:9; Àìsá. 2:4; Jém. 3:17, 18.)