ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Òní

Sunday, August 31

Àwọn tó ní ìjìnlẹ̀ òye máa lóye.—Dán. 12:10.

Ká tó lè lóye àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, àfi kí ẹnì kan ràn wá lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí ná. Ká sọ pé o fẹ́ lọ síbì kan tó ò mọ̀, àmọ́ ọ̀rẹ́ ẹ kan tó mọ ibẹ̀ dáadáa tẹ̀ lé ẹ lọ. Bẹ́ ẹ ṣe ń lọ, ó mọ ibi tẹ́ ẹ dé, ó sì mọ ibi tí ọ̀nà kọ̀ọ̀kan já sí. Ó dájú pé inú ẹ á dùn pé ọ̀rẹ́ ẹ bá ẹ lọ. Jèhófà ló dà bí ọ̀rẹ́ yẹn torí ó mọ ibi tí ọ̀rọ̀ ayé yìí dé àtohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, ká lè lóye àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ó yẹ ká fìrẹ̀lẹ̀ bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. (Dán. 2:28; 2 Pét. 1:​19, 20) Bíi ti òbí rere kan, Jèhófà fẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la àwọn ọmọ òun dáa. (Jer. 29:11) Àmọ́ Jèhófà yàtọ̀ sáwọn òbí wa torí pé òun lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, táá sì rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Ó ní kí wọ́n kọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ sínú Bíbélì ká lè mọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀.—Àìsá. 46:10. w23.08 8-9 ¶3-4

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Monday, September 1

Ojúmọ́ kan máa mọ́ wa láti ibi gíga.—Lúùkù 1:78.

Ọlọ́run fún Jésù lágbára láti yanjú ìṣòro aráyé. Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe fi hàn pé ó lágbára láti yanjú àwọn ìṣòro tá ò lè yanjú fúnra wa. Bí àpẹẹrẹ, ó lágbára láti gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún àtàwọn nǹkan tí ẹ̀ṣẹ̀ náà fà irú bí àìsàn àti ikú. (Mát. 9:​1-6; Róòmù 5:​12, 18, 19) Àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe fi hàn pé ó lè wo “onírúurú” àìsàn, ó sì lè jí òkú dìde. (Mát. 4:23; Jòh. 11:​43, 44) Bákan náà, ó lágbára láti dáwọ́ ìjì líle dúró, ó sì lágbára láti gba àwọn èèyàn sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀mí burúkú. (Máàkù 4:​37-39; Lúùkù 8:2) Àwọn nǹkan yìí jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà ti fún Ọmọ ẹ̀ lágbára láti yanjú àwọn ìṣòro wa! Ó dá wa lójú háún-háún pé Ọlọ́run máa ṣe àwọn ohun rere tó ṣèlérí nínú Ìjọba rẹ̀. Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé, ó máa ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ torí pé òun ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run. w23.04 3 ¶5-7

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Tuesday, September 2

Ẹ̀mí ń wá inú ohun gbogbo, títí kan àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 2:10.

Táwọn ará tó wà nínú ìjọ tó o wà bá pọ̀, ó lè má rọrùn fún ẹ láti dáhùn. Torí náà, má jẹ́ kó sú ẹ láti nawọ́ kó o lè dáhùn. Múra ìdáhùn tó pọ̀. Tí wọn ò bá pè ẹ́ níbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ náà, wọ́n ṣì lè pè ẹ́ bẹ́ ẹ ṣe ń bá ẹ̀kọ́ náà lọ. Tó o bá ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, ronú nípa bí ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan ṣe ṣàlàyé àkòrí ẹ̀kọ́ náà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè dáhùn lọ́nà tó máa gbé àwọn ará ró nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Yàtọ̀ síyẹn, o lè múra láti dáhùn àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀ tó lè nira fáwọn ará láti ṣàlàyé. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwọn tó máa nawọ́ láti dáhùn apá yìí kì í pọ̀. Ká sọ pé o ṣì rí i pé wọn kì í pè ẹ́ ńkọ́? Lọ bá ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀, kó o sì sọ ìpínrọ̀ tó o fẹ́ dáhùn fún un. w23.04 21-22 ¶9-10

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́