ÌDÁRÒ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 A fi Jerúsálẹ́mù wé obìnrin opó Ó dá jókòó, a sì ti pa á tì (1) Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí Síónì dá (8, 9) Ọlọ́run kọ Síónì sílẹ̀ (12-15) Kò sí ẹni tó máa tu Síónì nínú (17) 2 Ìbínú Jèhófà lórí Jerúsálẹ́mù Kò fi àánú hàn (2) Jèhófà ṣe bí ọ̀tá sí i (5) Jeremáyà sunkún nítorí Síónì (11-13) Àwọn tó ń kọjá lójú ọ̀nà fi ìlú tó rẹwà tẹ́lẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́ (15) Àwọn ọ̀tá ń yọ̀ lórí ìṣubú Síónì (17) 3 Jeremáyà sọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ àti ìrètí rẹ̀ ‘Màá fi sùúrù dúró dè ọ́’ (21) Tuntun ni àánú Ọlọ́run láràárọ̀ (22, 23) Ọlọ́run jẹ́ ẹni rere sí àwọn tó ní ìrètí nínú rẹ̀ (25) Ó dára kí àwọn ọ̀dọ́ ru àjàgà (27) Ọlọ́run fi àwọsánmà dí ọ̀nà tó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ (43, 44) 4 Ìnira tó dé bá Jerúsálẹ́mù nígbà tí wọ́n dó tì í Àìsí oúnjẹ (4, 5, 9) Àwọn obìnrin ń se àwọn ọmọ wọn (10) Jèhófà ti da ìbínú rẹ̀ jáde (11) 5 Àdúrà ìpadàbọ̀sípò tí àwọn èèyàn gbà “Rántí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa” (1) ‘A gbé; a ti dẹ́ṣẹ̀’ (16) ‘Mú wa pa dà, Jèhófà’ (21) “Sọ ọjọ́ wa di ọ̀tun” (21)