JEREMÁYÀ
1 Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ Jeremáyà,* ọmọ Hilikáyà, ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tó wà ní Ánátótì,+ ní ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì. 2 Jèhófà bá a sọ̀rọ̀ nígbà ayé Jòsáyà+ ọmọ Ámọ́nì,+ ọba Júdà, ní ọdún kẹtàlá tó ti ń jọba. 3 Ó tún bá a sọ̀rọ̀ nígbà ayé Jèhóákímù+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà, títí di òpin ọdún kọkànlá ìjọba Sedekáyà,+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà, títí Jerúsálẹ́mù fi lọ sí ìgbèkùn ní oṣù karùn-ún.+
4 Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:
Mo fi ọ́ ṣe wòlíì àwọn orílẹ̀-èdè.”
6 Ṣùgbọ́n mo sọ pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ!
Mi ò mọ ọ̀rọ̀ sọ,+ ọmọdé* lásán ni mí.”+
7 Ni Jèhófà bá sọ fún mi pé:
“Má sọ pé ‘ọmọdé lásán’ ni ọ́.
Torí o gbọ́dọ̀ lọ sọ́dọ̀ gbogbo àwọn tí mo bá rán ọ sí,
Kí o sì sọ gbogbo ohun tí mo bá pa láṣẹ fún ọ.+
9 Jèhófà wá na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi kan ẹnu mi.+ Jèhófà sì sọ fún mi pé: “Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ.+ 10 Wò ó, mo ti fàṣẹ yàn ọ́ lónìí lórí àwọn orílẹ̀-èdè àti lórí àwọn ìjọba, láti fà tu àti láti bì wó, láti pa run àti láti ya lulẹ̀, láti kọ́ àti láti gbìn.”+
11 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Jeremáyà, kí lo rí?” Mo sọ pé: “Ẹ̀ka igi álímọ́ńdì.”*
12 Jèhófà sọ fún mi pé: “Òótọ́ ni, òun ni, nítorí mo máa ń wà lójúfò láti mú ọ̀rọ̀ mi ṣẹ.”
13 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì pé: “Kí lo rí?” Torí náà, mo sọ pé: “Mo rí ìkòkò* tí ohun tó wà nínú rẹ̀ ń hó,* tí wọ́n da ẹnu rẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kí ó lè kọ ìdí sí àríwá.” 14 Ni Jèhófà bá sọ fún mi pé:
“Ìyọnu máa tú jáde láti àríwá
Sára gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà.+
15 Nítorí ‘mò ń pe gbogbo ìdílé àwọn ìjọba àríwá,’ ni Jèhófà wí,+
‘Wọ́n á wá, kálukú wọn á sì ṣe ìtẹ́ rẹ̀
Sí àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù,+
Wọ́n á gbé e ti gbogbo ògiri tó yí i ká
Wọ́n á sì gbé e ti gbogbo ìlú tó wà ní Júdà.+
16 Màá kéde ìdájọ́ mi lé wọn lórí nítorí gbogbo ìwà ibi wọn,
Torí pé wọ́n ti fi mí sílẹ̀,+
Wọ́n ń fi ẹbọ rú èéfín sí àwọn ọlọ́run mìíràn+
Wọ́n sì ń forí balẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn.’+
17 Àmọ́, gbára dì,*
Kí o sì dìde láti bá wọn sọ gbogbo ohun tí mo bá pa láṣẹ fún ọ.
Má ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà ọ́,+
Kí n má bàa jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́ níwájú wọn.
18 Lónìí, mo ti sọ ọ́ di ìlú olódi,
Òpó irin àti ògiri bàbà láti kojú gbogbo ilẹ̀ náà,+
Láti kojú àwọn ọba Júdà àti àwọn ìjòyè rẹ̀,
Láti kojú àwọn àlùfáà rẹ̀ àti àwọn èèyàn ilẹ̀ náà.+
19 Ó sì dájú pé wọ́n á bá ọ jà,
Ṣùgbọ́n wọn kò ní borí* rẹ,
Nítorí ‘mo wà pẹ̀lú rẹ + láti gbà ọ́’ ni Jèhófà wí.”
2 Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Lọ, kí o sì kéde sétí Jerúsálẹ́mù pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Mo ṣì rántí dáadáa, ìfọkànsìn* tí o ní nígbà èwe rẹ,+
Ìfẹ́ tí o ní sí mi nígbà tí mò ń fẹ́ ọ sọ́nà,+
Bí o ṣe ń tẹ̀ lé mi ní aginjù,
Ní ilẹ̀ tí a kò gbin nǹkan kan sí.+
3 Ísírẹ́lì jẹ́ mímọ́ lójú Jèhófà,+ ó jẹ́ èso tó kọ́kọ́ jáde nígbà ìkórè rẹ̀.”’
‘Ẹnikẹ́ni tó bá pa á run yóò jẹ̀bi.
Àjálù yóò dé bá wọn,’ ni Jèhófà wí.”+
4 Gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ìwọ ilé Jékọ́bù
Àti gbogbo ẹ̀yin ìdílé tó wà ní ilé Ísírẹ́lì.
5 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Ẹ̀sùn wo ni àwọn baba ńlá yín fi kàn mí,+
Tí wọ́n fi lọ jìnnà kúrò lọ́dọ̀ mi,
Tí wọ́n ń sin àwọn òrìṣà asán,+ tí àwọn fúnra wọn sì di asán?+
6 Wọn kò béèrè pé, ‘Ibo ni Jèhófà wà,
Ẹni tó mú wa jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+
Tó mú wa gba aginjù kọjá,
Tó mú wa gba aṣálẹ̀+ àti kòtò kọjá,
Tó mú wa gba ilẹ̀ aláìlómi + àti ilẹ̀ òkùnkùn biribiri kọjá,
Tó mú wa gba ilẹ̀ tí èèyàn kì í gbà kọjá,
Ilẹ̀ tí èèyàn kì í gbé?’
7 Lẹ́yìn náà, mo mú yín wá sí ilẹ̀ eléso,
Kí ẹ lè máa jẹ èso rẹ̀ àti àwọn ohun rere rẹ̀.+
Ṣùgbọ́n ẹ wọlé wá, ẹ sì sọ ilẹ̀ mi di ẹlẹ́gbin;
Ẹ sọ ogún mi di ohun ìríra.+
8 Àwọn àlùfáà kò béèrè pé, ‘Ibo ni Jèhófà wà?’+
Àwọn tó ń kọ́ni ní Òfin kò sì mọ̀ mí,
Àwọn olùṣọ́ àgùntàn ṣọ̀tẹ̀ sí mi,+
Àwọn wòlíì sọ tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ Báálì,+
Wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn tí kò lè ṣe wọ́n láǹfààní kankan.
9 ‘Nítorí náà, màá bá yín jà lẹ́ẹ̀kan sí i,’+ ni Jèhófà wí,
‘Màá sì bá àwọn ọmọ ọmọ yín jà.’
10 ‘Ṣùgbọ́n ẹ kọjá sí etíkun* àwọn ará Kítímù+ kí ẹ sì wò ó.
Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ ránṣẹ́ lọ sí Kídárì,+ kí ẹ sì fara balẹ̀ wò ó;
Kí ẹ sì wò ó bóyá ohun tó dà bí èyí ti ṣẹlẹ̀ rí.
11 Ǹjẹ́ orílẹ̀-èdè kan ti fi ohun tí kì í ṣe ọlọ́run rọ́pò ọlọ́run rẹ̀ rí?
Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn mi ti fi ohun tí kò wúlò rọ́pò ògo mi.+
12 Ẹ wò ó tìyanutìyanu, ẹ̀yin ọ̀run;
Kí ẹ̀rù sì mú yín gbọ̀n rìrì,’ ni Jèhófà wí,
13 ‘Nítorí ohun búburú méjì ni àwọn èèyàn mi ṣe:
Wọ́n ti fi èmi tí mo jẹ́ orísun omi ìyè sílẹ̀,+
Wọ́n sì gbẹ́ àwọn kòtò omi* fún ara wọn,
Àwọn kòtò omi tó ti ya, tí kò lè gba omi dúró.’
14 ‘Ṣé ìránṣẹ́ ni Ísírẹ́lì àbí ẹrú tí wọ́n bí sínú agbo ilé?
Kí wá nìdí tí wọ́n fi kó ẹrù rẹ̀ lọ?
Wọ́n sì sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ohun tó ń bani lẹ́rù.
Wọ́n ti sọ iná sí àwọn ìlú rẹ̀, tí kò fi sí ẹnì kankan tó ń gbé ibẹ̀.
16 Àwọn ará Nófì*+ àti àwọn Tápánésì+ ń kó ẹrù rẹ lọ.*
17 Ṣé kì í ṣe ọwọ́ rẹ lo fi fa èyí wá sórí ara rẹ
Tí o fi Jèhófà Ọlọ́run rẹ sílẹ̀+
Nígbà tó ń mú ọ rìn lọ lójú ọ̀nà?
19 Ìwà búburú rẹ ni yóò tọ́ ọ sọ́nà,
Ìwà àìṣòótọ́ rẹ ni yóò sì bá ọ wí.
Kí o lè mọ̀, kí o sì rí bí ó ti burú, tí ó sì korò tó+
Pé kí o fi Jèhófà Ọlọ́run rẹ sílẹ̀;
Ìwọ kò bẹ̀rù mi,’+ ni Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
20 ‘Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti ṣẹ́ àjàgà rẹ sí wẹ́wẹ́+
Mo sì já ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ rẹ.
Ṣùgbọ́n, o sọ pé: “Mi ò ní sìn ọ́,”
Torí pé orí gbogbo òkè àti abẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀+
Ni o nà gbalaja sí, tí ò ń ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó.+
21 Mo gbìn ọ́ bí àjàrà pupa tó dára,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ èso tí kò lábùkù;
Báwo lo ṣe wá di ọ̀mùnú àjàrà ilẹ̀ òkèèrè tí kò dára lójú mi?’+
22 ‘Bí o bá tiẹ̀ fi sódà* wẹ̀, tí o sì lo ọṣẹ púpọ̀,
Ẹ̀bi rẹ yóò ṣì jẹ́ àbààwọ́n níwájú mi,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
23 Báwo lo ṣe máa sọ pé, ‘Mi ò sọ ara mi di ẹlẹ́gbin.
Mi ò sì tẹ̀ lé Báálì’?
Wo ọ̀nà rẹ ní àfonífojì.
Wo ohun tí o ti ṣe.
O dà bí abo ọmọ ràkúnmí tó yára,
Tó ń sá lọ sá bọ̀ ní ọ̀nà rẹ̀ láìsí ohun tó ń lé e,
24 Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí aginjù ti mọ́ lára,
Tó ń ṣí imú kiri nítorí ìfẹ́ ọkàn* rẹ̀.
Ta ló lè dá a dúró nígbà tí ara rẹ̀ bá wà lọ́nà láti gùn?
Kò sí ìkankan lára àwọn tó ń wá a tó máa ní láti dààmú ara rẹ̀.
Torí wọ́n á rí i ní àkókò* rẹ̀.
25 Má ṣe rìn láìwọ bàtà
Má sì jẹ́ kí òùngbẹ gbẹ ọ́.
Ṣùgbọ́n, o sọ pé, ‘Kò sí ìrètí!+
26 Bí ojú ṣe máa ń ti olè nígbà tí wọ́n bá mú un,
Bẹ́ẹ̀ ni ojú ṣe ti ilé Ísírẹ́lì,
Àwọn àti àwọn ọba wọn pẹ̀lú àwọn ìjòyè wọn
Àti àwọn àlùfáà wọn àti àwọn wòlíì wọn.+
27 Wọ́n sọ fún igi pé, ‘Ìwọ ni bàbá mi’+
Àti fún òkúta pé, ‘Ìwọ ni o bí mi.’
Wọ́n kẹ̀yìn sí mi dípò kí wọ́n kọjú sọ́dọ̀ mi.+
Ní àkókò àjálù wọn, wọ́n á sọ pé,
‘Dìde, kí o sì gbà wá!’+
28 Ní báyìí, àwọn ọlọ́run tí o ṣe fún ara rẹ dà?+
Kí wọ́n dìde bí wọ́n bá lè gbà ọ́ ní àkókò àjálù rẹ,
Torí pé bí ìlú rẹ ṣe pọ̀ ni àwọn ọlọ́run rẹ ṣe pọ̀, ìwọ Júdà.+
29 ‘Kí nìdí tí ẹ fi ń bá mi jà?
Kí nìdí tí gbogbo yín fi ń ṣọ̀tẹ̀ sí mi?’+ ni Jèhófà wí.
30 Lásán ni mo lu àwọn ọmọ yín.+
31 Áà ìran yìí, ẹ kíyè sí ọ̀rọ̀ Jèhófà.
Ṣé mo ti dà bí aginjù lójú Ísírẹ́lì ni
Tàbí ilẹ̀ òkùnkùn biribiri?
Kí ló dé tí àwọn èèyàn mi yìí fi sọ pé, ‘À ń rìn kiri fàlàlà.
A kò ní wá sọ́dọ̀ rẹ mọ́’?+
32 Ǹjẹ́ wúńdíá lè gbàgbé ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀,
Àbí ìyàwó lè gbàgbé ọ̀já ìgbàyà* rẹ̀?
Síbẹ̀, àwọn èèyàn mi ti gbàgbé mi tipẹ́tipẹ́.+
33 Ìwọ obìnrin yìí, kí nìdí tó fi jẹ́ pé oríṣiríṣi ọgbọ́n lò ń dá láti máa wá ìfẹ́ kiri?
O ti fi ohun búburú kọ́ ara rẹ.+
34 Kódà, ẹ̀jẹ̀ àwọn* aláìní tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ ti ta sí ọ láṣọ,+
Kì í ṣe torí pé wọ́n ń fọ́lé ni o fi pa wọ́n;
Síbẹ̀, mo ṣì rí ẹ̀jẹ̀ wọn lára gbogbo aṣọ rẹ.+
35 Ṣùgbọ́n, o sọ pé, ‘Aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ ni mí.
Ó dájú pé ìbínú rẹ̀ ti kúrò lórí mi.’
Ní báyìí màá dá ọ lẹ́jọ́
Torí o sọ pé, ‘Mi ò dẹ́ṣẹ̀.’
36 Kí nìdí tí o fi fojú kékeré wo ọ̀nà rẹ tí kò gún?
37 Nítorí èyí, ìwọ yóò káwọ́ lérí jáde,+
Torí pé Jèhófà ti kọ àwọn tí o gbọ́kàn lé;
Wọn ò ní ṣe ọ́ ní àǹfààní kankan.”
3 Àwọn èèyàn béèrè pé: “Bí ọkùnrin kan bá lé ìyàwó rẹ̀ lọ, tí obìnrin náà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, tó sì lọ fẹ́ ọkùnrin míì, ṣé ó yẹ kí ọkùnrin náà tún lọ bá obìnrin yẹn?”
Ǹjẹ́ wọn ò ti sọ ilẹ̀ náà di ẹlẹ́gbin pátápátá?+
“O ti bá ọ̀pọ̀ àwọn tí ò ń bá kẹ́gbẹ́ ṣe ìṣekúṣe,+
Ṣé ó wá yẹ kí o pa dà sọ́dọ̀ mi?” ni Jèhófà wí.
2 “Gbé ojú rẹ sókè kí o sì wo orí àwọn òkè.
Ibo ni wọn ò ti bá ọ lò pọ̀?
Ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà lo jókòó sí dè wọ́n,
Bí àwọn alárìnkiri* nínú aginjù.
O sì ń fi iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ àti ìwà búburú rẹ
Sọ ilẹ̀ náà di ẹlẹ́gbin.+
3 Torí náà ni òjò kò fi rọ̀,+
Tí kò sì sí òjò ní ìgbà ìrúwé.
4 Àmọ́ ní báyìí ò ń ké pè mí, o ní,
‘Bàbá mi, ìwọ ni ọ̀rẹ́ tí mo ní láti ìgbà èwe mi!+
5 Ṣé títí ayé ni wàá fi máa bínú ni,
Tàbí ṣé ìgbà gbogbo ni wàá fi dì mí sínú?’
Ohun tí ò ń sọ nìyí,
Àmọ́ gbogbo ìwà ibi tí o mọ̀ lò ń hù ṣáá.”+
6 Nígbà ayé Ọba Jòsáyà,+ Jèhófà sọ fún mi pé: “‘Ṣé o ti rí ohun tí Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ ṣe? Ó ti lọ sórí gbogbo òkè ńlá àti sábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, kí ó lè ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó.+ 7 Kódà lẹ́yìn tó ti ṣe gbogbo nǹkan yìí, mò ń sọ fún un pé kó pa dà sọ́dọ̀ mi,+ àmọ́ kò pa dà; Júdà sì ń wo arábìnrin rẹ̀ oníbékebèke+ níran. 8 Nígbà tí mo rí ìyẹn, mo lé Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ lọ, mo sì já ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀+ fún un nítorí àgbèrè rẹ̀.+ Síbẹ̀, ẹ̀rù kò ba Júdà arábìnrin rẹ̀ tó ń ṣe békebèke; ṣe ni òun náà tún lọ ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó.+ 9 Kò ka iṣẹ́ aṣẹ́wó tó ń ṣe sí àìdáa, ó ń sọ ilẹ̀ náà di ẹlẹ́gbin, ó sì ń bá àwọn òkúta àti igi ṣe àgbèrè.+ 10 Láìka gbogbo èyí sí, Júdà arábìnrin rẹ̀ tó ń ṣe békebèke kò fi gbogbo ọkàn rẹ̀ pa dà sọ́dọ̀ mi, ṣe ló ń díbọ́n,’ ni Jèhófà wí.”
11 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún mi pé: “Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ ti fi hàn pé òun* jẹ́ olódodo ju Júdà oníbékebèke lọ.+ 12 Lọ, kí o sì kéde ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àríwá pé:+
“‘“Pa dà, ìwọ Ísírẹ́lì ọ̀dàlẹ̀,” ni Jèhófà wí.’+ ‘“Mi ò ní wò ọ́ tìbínútìbínú,*+ nítorí adúróṣinṣin ni mí,” ni Jèhófà wí.’ ‘“Mi ò sì ní máa bínú títí láé. 13 Kìkì pé kí o mọ ẹ̀bi rẹ lẹ́bi, nítorí o ti ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ. Ò ń bá àwọn àjèjì* lò pọ̀ lábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, àmọ́ o kò fetí sí ohùn mi,” ni Jèhófà wí.’”
14 “Ẹ pa dà, ẹ̀yin ọ̀dàlẹ̀ ọmọ,” ni Jèhófà wí. “Nítorí mo ti di ọ̀gá* yín; màá mú yín, ọ̀kan nínú ìlú kan àti méjì nínú ìdílé kan, màá sì mú yín wá sí Síónì.+ 15 Màá fún yín ní àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ọkàn mi fẹ́,+ wọ́n á sì fi ìmọ̀ àti ìjìnlẹ̀ òye bọ́ yín. 16 Ẹ ó di púpọ̀, ẹ ó sì so èso ní ilẹ̀ náà ní àwọn àkókò yẹn,” ni Jèhófà wí.+ “Wọn ò tún ní sọ pé, ‘Àpótí májẹ̀mú Jèhófà!’ Kò ní wá sí wọn lọ́kàn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní rántí rẹ̀ mọ́ tàbí kí wọ́n ṣàárò rẹ̀, wọn kò sì ní ṣe òmíràn mọ́. 17 Ní àkókò yẹn, wọ́n á pe Jerúsálẹ́mù ní ìtẹ́ Jèhófà;+ gbogbo orílẹ̀-èdè á kóra jọ ní orúkọ Jèhófà sí Jerúsálẹ́mù,+ wọn kò ní ya alágídí, wọn kò sì ní ṣe ohun tí ọkàn búburú wọn sọ fún wọn mọ́.”
18 “Ní àkókò yẹn, ilé Júdà àti ilé Ísírẹ́lì yóò rìn pa pọ̀,+ wọ́n á sì jọ wá láti ilẹ̀ àríwá sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín láti jogún.+ 19 Mo sọ lọ́kàn mi pé, ‘Wo bí mo ṣe fi ọ́ sáàárín àwọn ọmọ tí mo sì fún ọ ní ilẹ̀ tó dára, ogún tó rẹwà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè!’*+ Mo tún sọ lọ́kàn mi pé, ẹ ó pè mí ní, ‘Bàbá mi!’ ẹ kò sì ní pa dà lẹ́yìn mi. 20 ‘Lóòótọ́, gẹ́gẹ́ bí aya tó hùwà àìṣòótọ́, tó sì kúrò lọ́dọ̀ ọkọ* rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì ṣe hùwà àìṣòótọ́ sí mi,’+ ni Jèhófà wí.”
21 A gbọ́ ìró kan lórí àwọn òkè kéékèèké,
Ẹkún àti àrọwà àwọn èèyàn Ísírẹ́lì,
Nítorí wọ́n lọ́ ọ̀nà wọn po;
Wọ́n ti gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run wọn.+
22 “Ẹ pa dà, ẹ̀yin ọ̀dàlẹ̀ ọmọ.
Màá wo ọkàn ọ̀dàlẹ̀ yín sàn.”+
“Àwa nìyí! A ti wá sọ́dọ̀ rẹ,
Torí ìwọ, Jèhófà, ni Ọlọ́run wa.+
23 Lóòótọ́, àwọn òkè kéékèèké àti rúkèrúdò tó wà lórí àwọn òkè ńlá jẹ́ ẹ̀tàn.+
Àmọ́, ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa ni ìgbàlà Ísírẹ́lì wà.+
24 Látìgbà èwe wa ni ohun ìtìjú* ti gba gbogbo èrè iṣẹ́ àṣekára àwọn baba ńlá wa,+
Ó gba agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran wọn,
Àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn.
25 Ẹ jẹ́ ká dùbúlẹ̀ nínú ìtìjú wa,
Kí ìtìjú wa sì bò wá mọ́lẹ̀,
Nítorí a ti dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run wa,+
Àwa àti àwọn bàbá wa látìgbà èwe wa títí di òní yìí,+
A kò sì ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run wa.”
4 “Bí o bá máa pa dà, ìwọ Ísírẹ́lì,” ni Jèhófà wí,
“Bí o bá máa pa dà sọ́dọ̀ mi
Kí o mú òrìṣà ẹ̀gbin rẹ kúrò níwájú mi,
Nígbà náà, ìwọ kò ní jẹ́ ìsáǹsá.+
2 Bí o bá ń ṣe òtítọ́ àti òdodo pẹ̀lú ẹ̀tọ́, bí o ti ń búra pé,
‘Bí Jèhófà ti wà láàyè!’
Nígbà náà, àwọn orílẹ̀-èdè á gba ìbùkún látọ̀dọ̀ rẹ̀,
Wọ́n á sì máa ṣògo nínú rẹ̀.”+
3 Ohun tí Jèhófà sọ fún àwọn ọkùnrin Júdà àti fún Jerúsálẹ́mù nìyí:
“Ẹ tú ilẹ̀ tó dáa fún ọ̀gbìn,
Ẹ má sì máa fúnrúgbìn sáàárín ẹ̀gún.+
4 Ẹ kọ ara yín nílà* fún Jèhófà,
Ẹ̀yin èèyàn Júdà àti ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerúsálẹ́mù,
Kí ìbínú mi má bàa ru jáde bí iná
Kí ó sì máa jó, tí kò fi ní sí ẹni tó lè pa á,
Nítorí ìwà ibi yín.”+
5 Ẹ kéde rẹ̀ ní Júdà, ẹ sì polongo rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù.
Ẹ kígbe, kí ẹ sì fun ìwo jákèjádò ilẹ̀ náà.+
Ẹ gbóhùn sókè, kí ẹ sì sọ pé: “Ẹ kóra jọ,
Ẹ sì jẹ́ kí a sá wọ àwọn ìlú olódi.+
6 Ẹ gbé àmì kan dúró* tó ń tọ́ka sí Síónì.
Ẹ wá ibi ààbò, ẹ má sì dúró tẹtẹrẹ,”
Nítorí mò ń mú àjálù bọ̀ láti àríwá,+ yóò sì jẹ́ ìparun tó bùáyà.
Ó ti jáde kúrò ní àyè rẹ̀ kí ó lè sọ ilẹ̀ rẹ di ohun àríbẹ̀rù.
Àwọn ìlú rẹ yóò di àwókù tí kò ní sí ẹni tó ń gbé ibẹ̀ mọ́.+
Ẹ ṣọ̀fọ̀,* kí ẹ sì pohùn réré ẹkún,
Nítorí ìbínú Jèhófà tó ń jó bí iná kò tíì kúrò lórí wa.
9 “Ní ọjọ́ náà, ọkàn ọba á domi,”*+ ni Jèhófà wí
“Àti ọkàn àwọn ìjòyè;*
Ẹ̀rù á ba àwọn àlùfáà, kàyéfì á sì ṣe àwọn wòlíì.”+
10 Ni mo bá sọ pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! O ti tan àwọn èèyàn yìí+ àti Jerúsálẹ́mù jẹ pátápátá, o sọ pé, ‘Ẹ máa ní àlàáfíà,’+ nígbà tó jẹ́ pé idà ló wà lọ́rùn wa.”*
11 Nígbà yẹn, a ó sọ fún àwọn èèyàn yìí àti Jerúsálẹ́mù pé:
“Ẹ̀fúùfù gbígbóná láti orí àwọn òkè tó wà ní aṣálẹ̀ tí kò sí ohunkóhun tó hù lórí wọn
Ló máa gbá ọmọbìnrin* àwọn èèyàn mi lọ;
Kì í ṣe pé ó máa wá fẹ́ ọkà tàbí pàǹtírí.
12 Èmi ni mo sọ pé kí ẹ̀fúùfù líle fẹ́ wá láti orí àwọn òkè.
Ní báyìí, màá kéde ìdájọ́ lé wọn lórí.
13 Wò ó! Ọ̀tá yóò wá bí òjò tó ṣú,
Àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ á sì wá bí ìjì.+
Àwọn ẹṣin rẹ̀ yára ju ẹyẹ idì lọ.+
A gbé, torí pé a ti di ahoro!
14 Wẹ ìwà burúkú kúrò lọ́kàn rẹ, kí o lè rí ìgbàlà, ìwọ Jerúsálẹ́mù.+
Ìgbà wo lo máa tó mú èrò burúkú kúrò lọ́kàn rẹ?
15 Nítorí ohùn kan ròyìn láti Dánì,+
Ó sì kéde àjálù láti àwọn òkè Éfúrémù.
16 Ẹ ròyìn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni, ẹ ròyìn rẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè;
Ẹ kéde rẹ̀ sórí Jerúsálẹ́mù.”
“Àwọn ẹ̀ṣọ́* ń bọ̀ láti ilẹ̀ tó jìnnà,
Wọ́n á sì gbé ohùn wọn sókè sí àwọn ìlú Júdà.
17 Wọ́n yí Jerúsálẹ́mù ká bí ìgbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ bá ń ṣọ́ pápá gbalasa,+
Nítorí pé ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi,”+ ni Jèhófà wí.
18 “Ọ̀nà rẹ àti ìṣe rẹ á yí dà lé ọ lórí.+
Wo bí àjálù rẹ á ti korò tó!
Nítorí ó ti dé inú ọkàn rẹ.”
19 Ìrora mi pọ̀,* ìrora mi pọ̀!
Ọkàn mi* gbọgbẹ́.
Àyà mi ń lù kìkì.
Mi ò lè dákẹ́,
Nítorí mo* ti gbọ́ ìró ìwo
20 Àjálù lórí àjálù ni ìròyìn tí à ń gbọ́,
Nítorí pé wọ́n ti pa gbogbo ilẹ̀ náà run.
Lójijì, wọ́n pa àgọ́ mi run,
Ní ìṣẹ́jú kan, wọ́n pa aṣọ àgọ́ mi run.+
22 “Nítorí àwọn èèyàn mi gọ̀;+
Wọn ò kà mí sí.
Ọmọ tí kò gbọ́n ni wọ́n, wọn ò sì lóye.
Ọ̀jáfáfá* ni wọ́n nínú ìwà ibi,
Àmọ́, wọn ò mọ bí a ti ń ṣe rere.”
23 Mo rí ilẹ̀ náà, sì wò ó! ó ṣófo, ó sì dahoro.+
Mo bojú wo ọ̀run, ìmọ́lẹ̀ wọn kò sì sí mọ́.+
24 Mo rí àwọn òkè ńlá, sì wò ó! wọ́n ń mì tìtì,
Àwọn òkè kéékèèké sì ń mì.+
25 Mo wò ó, kíyè sí i! kò sí èèyàn kankan níbẹ̀,
Gbogbo àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ti fò lọ.+
26 Mo wò ó, kíyè sí i! ọgbà eléso ti di aginjù,
Gbogbo àwọn ìlú rẹ̀ ti wó lulẹ̀.+
Nítorí Jèhófà ni,
Torí ìbínú rẹ̀ tó ń jó fòfò ni.
29 Nítorí ìró àwọn agẹṣin àti àwọn tafàtafà,
Gbogbo ìlú sá lọ.+
Wọ́n wọnú igbó,
Wọ́n sì gun àwọn àpáta.+
Gbogbo ìlú ni wọ́n ti fi sílẹ̀,
Kò sì sí èèyàn kankan tó ń gbé inú wọn.”
30 Ní báyìí tí o ti di ahoro, kí lo máa ṣe?
O ti máa ń wọ aṣọ rírẹ̀dòdò tẹ́lẹ̀,
O ti máa ń fi ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ṣe ara rẹ lóge,
O sì ti máa ń fi tìróò* sọ ojú rẹ di ńlá.
Àmọ́ lásán lo ṣe ara rẹ lóge,+
Àwọn tí ìfẹ́ rẹ ti kó sí lórí ti pa ọ́ tì;
31 Nítorí mo gbọ́ ohùn kan tó dà bíi ti obìnrin tó ń ṣàìsàn,
Ìdààmú bíi ti obìnrin tó ń rọbí àkọ́bí ọmọ rẹ̀,
Ohùn ọmọbìnrin Síónì tó ń mí gúlegúle.
Bó ṣe tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, ó ń sọ pé:+
“Mo gbé, àárẹ̀ ti mú mi* nítorí àwọn apààyàn!”
5 Ẹ lọ káàkiri àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù.
Ẹ wò yí ká, kí ẹ sì kíyè sí i.
Ẹ wo àwọn ojúde rẹ̀
2 Bí wọ́n bá tiẹ̀ sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè!”
Irọ́ ni wọ́n ṣì máa pa.+
3 Jèhófà, ǹjẹ́ kì í ṣe àwọn olóòótọ́ ni ojú rẹ ń wò?+
O lù wọ́n, ṣùgbọ́n wọn ò mọ̀ ọ́n lára.*
O pa wọ́n run, àmọ́ wọn ò gba ìbáwí.+
4 Ṣùgbọ́n mo sọ lọ́kàn mi pé: “Ó dájú pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan.
Wọ́n hùwà òmùgọ̀, torí pé wọn ò mọ ọ̀nà Jèhófà,
Wọn ò mọ òfin Ọlọ́run wọn.
5 Màá lọ sọ́dọ̀ àwọn olókìkí èèyàn, màá sì bá wọn sọ̀rọ̀,
Torí wọ́n á ti mọ ọ̀nà Jèhófà,
Wọ́n á ti mọ òfin Ọlọ́run wọn.+
Àmọ́ gbogbo wọn ti ṣẹ́ àjàgà
Wọ́n sì ti fa ìdè* já.”
6 Ìdí nìyẹn tí kìnnìún inú igbó fi bẹ́ mọ́ wọn,
Tí ìkookò inú aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ń pa wọ́n jẹ,
Tí àmọ̀tẹ́kùn sì lúgọ ní àwọn ìlú wọn.
Gbogbo ẹni tó ń jáde láti inú wọn ló máa fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.
Torí pé ìṣìnà wọn pọ̀;
Ìwà àìṣòótọ́ wọn sì pọ̀.+
7 Báwo ni mo ṣe lè dárí ohun tí o ṣe yìí jì ọ́?
Àwọn ọmọ rẹ ti fi mí sílẹ̀,
Wọ́n sì ń fi ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run búra.+
Gbogbo ohun tí wọ́n fẹ́ ni mo fún wọn,
Ṣùgbọ́n wọn ò jáwọ́ nínú àgbèrè,
Wọ́n sì ń rọ́ lọ sí ilé aṣẹ́wó.
9 “Ǹjẹ́ kò yẹ kí n pè wọ́n wá jíhìn nítorí nǹkan wọ̀nyí?” ni Jèhófà wí.
“Ǹjẹ́ kò yẹ kí n* gbẹ̀san lára orílẹ̀-èdè tó ṣe irú èyí?”+
Ẹ gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ,
Nítorí wọn kì í ṣe ti Jèhófà.
11 Nítorí ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà
Ti hùwà àìṣòótọ́ sí mi gan-an,” ni Jèhófà wí.+
Àjálù kankan kò ní bá wa;
A kò ní rí idà tàbí ìyàn.’+
13 Àwọn wòlíì jẹ́ àgbá òfìfo,
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò sì sí lẹ́nu wọn.
Kí ó rí bẹ́ẹ̀ fún wọn!”
14 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:
“Nítorí ohun tí àwọn èèyàn yìí sọ,
Wò ó, màá sọ ọ̀rọ̀ mi di iná ní ẹnu rẹ,+
Àwọn èèyàn yìí yóò sì dà bí igi,
Yóò sì jó wọn run.”+
15 “Wò ó, màá mú orílẹ̀-èdè kan láti ibi tó jìnnà wá bá yín, ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì,”+ ni Jèhófà wí.
“Orílẹ̀-èdè tó ti wà tipẹ́tipẹ́ ni.
16 Apó wọn dà bíi sàréè tó la ẹnu sílẹ̀;
Jagunjagun ni gbogbo wọn.
17 Wọ́n á jẹ irè oko rẹ àti oúnjẹ rẹ.+
Wọ́n á pa àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ.
Wọ́n á jẹ àwọn agbo ẹran rẹ àti àwọn ọ̀wọ́ ẹran rẹ.
Wọ́n á jẹ àjàrà rẹ àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ.
Wọ́n á fi idà pa ìlú olódi rẹ tí o gbẹ́kẹ̀ lé run.”
18 “Kódà ní àkókò yẹn,” ni Jèhófà wí, “Mi ò ní pa yín run pátápátá.+ 19 Tí wọ́n bá sì béèrè pé, ‘Kí ló dé tí Jèhófà Ọlọ́run wa fi ṣe gbogbo nǹkan yìí sí wa?’ kí o sọ fún wọn pé, ‘Bí ẹ ṣe fi mí sílẹ̀ láti sin ọlọ́run àjèjì ní ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ ó sin àwọn àjèjì ní ilẹ̀ kan tí kì í ṣe tiyín.’”+
20 Ẹ kéde èyí ní ilé Jékọ́bù,
Ẹ sì polongo rẹ̀ ní Júdà pé:
21 “Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin òmùgọ̀ àti aláìlọ́gbọ́n:*+
22 ‘Ṣé ẹ kò bẹ̀rù mi ni?’ ni Jèhófà wí,
‘Ṣé kò yẹ kí ẹ̀rù bà yín níwájú mi?
Èmi ni mo fi iyanrìn pààlà òkun,
Ó jẹ́ ìlànà tó wà títí láé tí òkun kò lè ré kọjá.
Bí àwọn ìgbì rẹ̀ tiẹ̀ ń bì síwá-sẹ́yìn, wọn kò lè borí;
Bí wọ́n tiẹ̀ pariwo, síbẹ̀, wọn kò lè ré e kọjá.+
23 Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn yìí jẹ́ alágídí ọkàn, wọ́n sì ya ọlọ̀tẹ̀;
Wọ́n fi ọ̀nà mi sílẹ̀, wọ́n sì bá ọ̀nà wọn lọ.+
24 Wọn ò sì sọ lọ́kàn wọn pé:
“Ẹ jẹ́ ká bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run wa,
Ẹni tó ń fúnni ní òjò ní àsìkò rẹ̀,
Òjò ìgbà ìkórè àti òjò ìgbà ìrúwé,
Ẹni tí kò jẹ́ kí àwọn ọ̀sẹ̀ ìkórè wa yẹ̀.”+
25 Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín kò jẹ́ kí gbogbo nǹkan yìí wáyé;
Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín sì ti gba ohun rere kúrò lọ́wọ́ yín.+
26 Nítorí àwọn èèyàn burúkú wà láàárín àwọn èèyàn mi.
Wọ́n ń wò bí àwọn pẹyẹpẹyẹ tó lúgọ.
Wọ́n ń dẹ pańpẹ́ ikú.
Èèyàn ni wọ́n ń mú.
27 Bí àgò tí ẹyẹ kún inú rẹ̀,
Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀tàn kún ilé wọn.+
Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi di alágbára tí wọ́n sì lọ́rọ̀.
28 Wọ́n ti sanra, ara wọn sì ń dán;
Iṣẹ́ ibi kún ọwọ́ wọn fọ́fọ́.
29 “Ǹjẹ́ kò yẹ kí n pè wọ́n wá jíhìn nítorí nǹkan wọ̀nyí?” ni Jèhófà wí.
“Ǹjẹ́ kò yẹ kí n* gbẹ̀san lára orílẹ̀-èdè tó ṣe irú èyí?
30 Ohun burúkú àti ẹ̀rù ti ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà:
31 Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́,+
Àwọn àlùfáà sì ń fi àṣẹ wọn tẹ àwọn èèyàn lórí ba.
Àwọn èèyàn mi sì fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀.+
Àmọ́, kí lẹ máa ṣe nígbà tí òpin bá dé?”
6 Ẹ wá ibi ààbò kúrò ní Jerúsálẹ́mù, ẹ̀yin ọmọ Bẹ́ńjámínì.
Torí pé àjálù ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀ láti àríwá, àjálù ńlá.+
2 Ọmọbìnrin Síónì jọ arẹwà obìnrin tó gbẹgẹ́.+
3 Àwọn olùṣọ́ àgùntàn àti agbo ẹran wọn yóò wá.
4 “Ẹ múra* láti bá a jagun!
Ẹ dìde, ẹ jẹ́ ká bá a jà ní ọ̀sán gangan!”
“A gbé! Nítorí ọjọ́ ti lọ,
Ilẹ̀ sì ti ń ṣú.”
5 “Ẹ dìde, ẹ jẹ́ ká bá a jà ní òru
Ká sì pa àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò run.”+
6 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:
“Gé igi lulẹ̀, kí o sì mọ òkìtì láti dó ti Jerúsálẹ́mù.+
Ìlú tí ó gbọ́dọ̀ jíhìn ni;
Ìnilára nìkan ló wà nínú rẹ̀.+
7 Bí omi tútù ṣe máa ń wà nínú àmù,*
Bẹ́ẹ̀ ni ìwà burúkú ṣe wà nínú ìlú yìí.
Ìwà ipá àti ìparun ni ìròyìn tí à ń gbọ́ nínú rẹ̀;+
Àìsàn àti àjálù ni mò ń rí níbẹ̀ nígbà gbogbo.
8 Gba ìkìlọ̀, ìwọ Jerúsálẹ́mù, kí n* má bàa bínú fi ọ́ sílẹ̀;+
Màá sọ ọ́ di ahoro, ilẹ̀ tí kò sí ẹni tó ń gbé ibẹ̀.”+
9 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:
“Wọ́n á fara balẹ̀ ṣa* èyí tó ṣẹ́ kù lára Ísírẹ́lì bí èso àjàrà tó kẹ́yìn.
Pa dà lọ ṣà wọ́n bí ẹni tó ń ṣa èso àjàrà lórí àwọn àjàrà.”
10 “Ta ló yẹ kí n bá sọ̀rọ̀, kí n sì kìlọ̀ fún?
Ta ló máa gbọ́?
Wò ó! Etí wọn ti di,* tí wọn kò fi lè fetí sílẹ̀.+
Wò ó! Ọ̀rọ̀ Jèhófà ti di ohun tí wọ́n fi ń ṣe ẹlẹ́yà;+
Inú wọn ò sì dùn sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
11 Torí náà, ìbínú Jèhófà ti kún inú mi,
Ara mi ò sì gbà á mọ́.”+
“Dà á sórí ọmọ tó wà lójú ọ̀nà,+
Sórí àwọn àwùjọ ọ̀dọ́kùnrin tó kóra jọ.
Gbogbo wọn ni ọwọ́ máa tẹ̀, láìyọ ọkùnrin kan àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀,
12 Ilé wọn máa di ti àwọn ẹlòmíì,
Títí kan àwọn oko wọn àti ìyàwó wọn.+
Torí màá na ọwọ́ mi sí àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà,” ni Jèhófà wí.
13 “Látorí ẹni kékeré títí dórí ẹni ńlá, kálukú wọn ń jẹ èrè tí kò tọ́;+
Látorí wòlíì títí dórí àlùfáà, kálukú wọn ń lu jìbìtì.+
Nígbà tí kò sí àlàáfíà.+
15 Ǹjẹ́ ojú tì wọ́n nítorí àwọn ohun ìríra tí wọ́n ṣe?
Ojú kì í tì wọ́n!
Àní wọn ò tiẹ̀ lójútì rárá!+
Torí náà, wọ́n á ṣubú láàárín àwọn tó ti ṣubú.
Nígbà tí mo bá fìyà jẹ wọ́n, wọ́n á kọsẹ̀,” ni Jèhófà wí.
16 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Ẹ dúró ní oríta, kí ẹ sì wò.
Ṣùgbọ́n wọ́n sọ pé: “A ò ní rin ọ̀nà náà.”+
Àmọ́ wọ́n sọ pé: “A ò ní fetí sí i.”+
18 “Torí náà, ẹ gbọ́, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè!
Kí o sì mọ̀, ìwọ àpéjọ,
Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn.
19 Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè ayé!
Màá mú àjálù bá àwọn èèyàn yìí+
Wọ́n á jèrè èrò ibi wọn,
Torí wọn kò fiyè sí ọ̀rọ̀ mi
Wọ́n sì kọ òfin* mi.”
20 “Kò já mọ́ nǹkan kan lójú mi pé ẹ̀ ń mú oje igi tùràrí wá láti Ṣébà
Àti pòròpórò olóòórùn dídùn* láti ilẹ̀ tó jìnnà.
Àwọn odindi ẹbọ sísun yín kò ní ìtẹ́wọ́gbà,
Àwọn ẹbọ yín kò sì mú inú mi dùn.”+
21 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Wò ó, màá fi àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ sí iwájú àwọn èèyàn yìí,
Wọ́n á sì mú wọn kọsẹ̀,
Àwọn bàbá àti àwọn ọmọ,
Aládùúgbò àti ọ̀rẹ́,
Gbogbo wọn yóò sì ṣègbé.”+
22 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Wò ó! Àwọn èèyàn kan ń bọ̀ láti ilẹ̀ àríwá,
Orílẹ̀-èdè ńlá kan yóò ta jí láti ibi tó jìnnà jù lọ láyé.+
23 Wọ́n á di ọfà* àti ọ̀kọ̀* mú.
Ìkà ni wọ́n, wọn ò sì lójú àánú.
Ìró wọn dà bíi ti òkun,
Wọ́n sì gun ẹṣin.+
Wọ́n to ara wọn bí àwọn jagunjagun láti bá ọ jà, ìwọ ọmọbìnrin Síónì.”
24 A ti gbọ́ ìròyìn nípa rẹ̀.
25 Má ṣe lọ sí oko,
Má sì rìn lójú ọ̀nà,
Nítorí ọ̀tá ní idà;
Ìpayà sì wà níbi gbogbo.
Ṣọ̀fọ̀ bí ẹni tí ọmọkùnrin rẹ̀ kan ṣoṣo kú, kí o sì sunkún gidigidi,+
Torí lójijì ni apanirun máa dé bá wa.+
27 “Mo ti fi ọ́* ṣe ẹni tó ń yọ́ wúrà àti fàdákà mọ́,
Nítorí o ní láti yọ́ àwọn èèyàn mi mọ́;
Màá fiyè sí wọn, màá sì ṣàyẹ̀wò ohun tí wọ́n ń ṣe.
Wọ́n dà bíi bàbà àti irin;
Ìwà ìbàjẹ́ kún ọwọ́ gbogbo wọn.
29 Ẹwìrì* wọn ti jóná.
Òjé ló ń jáde látinú iná wọn.
30 Ó dájú pé fàdákà tí a kọ̀ ni àwọn èèyàn máa pè wọ́n,
Nítorí Jèhófà ti kọ̀ wọ́n.”+
7 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jeremáyà sọ nìyí, ó ní: 2 “Dúró sí ẹnubodè ilé Jèhófà, kí o sì kéde ọ̀rọ̀ yìí níbẹ̀ pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin èèyàn Júdà tó ń gba àwọn ẹnubodè yìí wọlé láti wá forí balẹ̀ fún Jèhófà. 3 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Ẹ tún ọ̀nà yín àti ìwà yín ṣe, màá sì jẹ́ kí ẹ máa gbé ibí yìí.+ 4 Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tí wọ́n ń sọ pé, ‘Èyí ni* tẹ́ńpìlì Jèhófà, tẹ́ńpìlì Jèhófà, tẹ́ńpìlì Jèhófà!’+ 5 Tí ẹ bá tún ọ̀nà yín àti ìwà yín ṣe lóòótọ́, tó bá sì jẹ́ pé òótọ́ lẹ ṣe ìdájọ́ òdodo láàárín èèyàn kan àti ọmọnìkejì rẹ̀,+ 6 bí ẹ kò bá ni àjèjì lára àti ọmọ aláìlóbìí,* pẹ̀lú àwọn opó,+ tí ẹ kò ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí, tí ẹ kò sì tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì tó máa yọrí sí ìṣeléṣe yín; + 7 nígbà náà, màá jẹ́ kí ẹ máa gbé ibí yìí, ní ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín títí láé.”’”*
8 “Àmọ́, ẹ̀ ń gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn,+ kò ní ṣe yín láǹfààní kankan. 9 Ṣé ẹ lè máa jalè+ tàbí kí ẹ máa pa èèyàn, kí ẹ máa ṣe àgbèrè tàbí kí ẹ máa búra èké,+ kí ẹ máa rú ẹbọ* sí Báálì,+ kí ẹ sì máa tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì tí ẹ kò mọ̀, 10 kí ẹ wá dúró níwájú mi nínú ilé yìí tí a fi orúkọ mi pè, kí ẹ sì sọ pé, ‘A ó rí ìgbàlà,’ pẹ̀lú gbogbo ohun ìríra tí ẹ ti ṣe yìí? 11 Ṣé ilé yìí tí a fi orúkọ mi pè ti wá di ihò tí àwọn olè ń fara pa mọ́ sí lójú yín ni?+ Èmi fúnra mi ti rí ohun tí ẹ̀ ń ṣe,” ni Jèhófà wí.
12 “‘Àmọ́, ní báyìí ẹ lọ sí àyè mi ní Ṣílò,+ níbi tí mo mú kí orúkọ mi wà ní ìbẹ̀rẹ̀,+ kí ẹ sì wo ohun tí mo ṣe sí i nítorí ìwà búburú àwọn èèyàn mi, Ísírẹ́lì.+ 13 Ṣùgbọ́n ẹ̀ ń ṣe gbogbo nǹkan yìí,’ ni Jèhófà wí, ‘àní bí mo tiẹ̀ bá yín sọ̀rọ̀ léraléra,* ẹ kò fetí sílẹ̀.+ Mo sì ń pè yín ṣáá, ṣùgbọ́n ẹ kò dá mi lóhùn.+ 14 Bí mo ti ṣe sí Ṣílò, bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe sí ilé tí a fi orúkọ mi pè,+ èyí tí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé+ àti sí ibi tí mo fún ẹ̀yin àti àwọn baba ńlá yín.+ 15 Màá lé yín síta kúrò níwájú mi, bí mo ṣe lé gbogbo àwọn arákùnrin yín síta, gbogbo àwọn ọmọ Éfúrémù.’+
16 “Ní tìrẹ, má ṣe gbàdúrà nítorí àwọn èèyàn yìí. Má ṣe sunkún tàbí kí o gbàdúrà tàbí kí o bẹ̀ mí nítorí wọn,+ torí mi ò ní fetí sí ọ.+ 17 Ṣé o ò rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àwọn ìlú Júdà àti ní àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù ni? 18 Àwọn ọmọ ń kó igi jọ, àwọn bàbá ń dá iná, àwọn ìyàwó sì ń po ìyẹ̀fun láti fi ṣe àkàrà ìrúbọ sí Ọbabìnrin Ọ̀run,*+ wọ́n sì ń da ọrẹ ohun mímu sí àwọn ọlọ́run míì láti mú mi bínú.+ 19 ‘Àmọ́ ṣé èmi ni wọ́n ń mú bínú?’* ni Jèhófà wí. ‘Ǹjẹ́ kì í ṣe ara wọn ni wọn ń ṣe, tí wọ́n ń dójú ti ara wọn?’+ 20 Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Wò ó! Ìbínú mi àti ìrunú mi yóò dà sórí ibí yìí,+ sórí èèyàn àti ẹranko, sórí igi oko àti èso ilẹ̀. Ìbínú mi yóò máa jó bí iná tí kò ṣeé pa.’+
21 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Ẹ lọ, kí ẹ fi odindi ẹbọ sísun yín kún àwọn ẹbọ yín yòókù, kí ẹ sì jẹ ẹran rẹ̀.+ 22 Torí láti ọjọ́ tí mo ti mú àwọn baba ńlá yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, mi ò bá wọn sọ̀rọ̀ tàbí kí n pàṣẹ fún wọn lórí àwọn odindi ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ.+ 23 Ṣùgbọ́n, mo pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, màá sì di Ọlọ́run yín, ẹ ó sì di èèyàn mi.+ Kí ẹ máa rìn ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún yín, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún yín.”’+ 24 Ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sí mi, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sílẹ̀,+ kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń rìn nínú ètekéte* wọn, wọ́n ya alágídí, wọ́n sì ń ṣe ohun tí ọkàn búburú wọn sọ,+ ńṣe ni wọ́n ń pa dà sẹ́yìn, wọn ò lọ síwájú, 25 láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá yín ti jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì títí di òní.+ Torí náà, mò ń rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sí yín, mò ń rán wọn lójoojúmọ́, mo sì ń rán wọn léraléra.*+ 26 Ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sí mi, wọn kò sì fetí sílẹ̀.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ya alágídí,* wọ́n sì ṣe ohun tó burú ju ti àwọn baba ńlá wọn lọ!
27 “Wàá sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún wọn,+ ṣùgbọ́n wọn ò ní fetí sí ọ. Wàá pè wọ́n, ṣùgbọ́n wọn ò ní dá ọ lóhùn. 28 Wàá sì sọ fún wọn pé, ‘Orílẹ̀-èdè tí kò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ nìyí, kò sì gba ìbáwí. Kò sí òtítọ́ mọ́, a ò tiẹ̀ gbúròó rẹ̀ láàárín wọn mọ́.’*+
29 “Fá irun gígùn* rẹ, kí o dà á nù, kí o sì kọ orin arò* lórí àwọn òkè, nítorí pé Jèhófà ti kọ ìran àwọn èèyàn tó mú un bínú yìí, yóò sì pa á tì. 30 ‘Nítorí àwọn èèyàn Júdà ti ṣe ohun tó burú ní ojú mi,’ ni Jèhófà wí. ‘Wọ́n ti gbé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn kalẹ̀ sínú ilé tí a fi orúkọ mi pè, láti sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin.+ 31 Wọ́n ti kọ́ àwọn ibi gíga Tófétì, èyí tó wà ní Àfonífojì Ọmọ Hínómù,*+ láti sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná,+ ohun tí mi ò pa láṣẹ, tí kò sì wá sí mi lọ́kàn rí.’*+
32 “‘Nítorí náà, wò ó! ọjọ́ ń bọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘tí a kò ní pè é ní Tófétì tàbí Àfonífojì Ọmọ Hínómù mọ́,* àmọ́ Àfonífojì Ìpànìyàn la ó máa pè é. Wọ́n á sin òkú ní Tófétì títí kò fi ní sí àyè mọ́.+ 33 Òkú àwọn èèyàn yìí á di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko orí ilẹ̀, láìsí ẹnikẹ́ni tó máa lé wọn dà nù.+ 34 Màá fòpin sí ìró ayọ̀ àti ìró ìdùnnú, ohùn ọkọ ìyàwó àti ohùn ìyàwó+ ní àwọn ìlú Júdà àti ní àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù, nítorí ilẹ̀ náà yóò di ahoro.’”+
8 Jèhófà sọ pé: “Ní àkókò yẹn, wọ́n á kó egungun àwọn ọba Júdà àti egungun àwọn ìjòyè rẹ̀, egungun àwọn àlùfáà àti egungun àwọn wòlíì pẹ̀lú egungun àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù jáde kúrò nínú sàréè wọn. 2 A ó dà wọ́n síta lábẹ́ oòrùn, òṣùpá àti lábẹ́ gbogbo ọmọ ogun ọ̀run tí wọ́n nífẹ̀ẹ́, tí wọ́n jọ́sìn, tí wọ́n tẹ̀ lé, tí wọ́n wá, tí wọ́n sì forí balẹ̀ fún.+ A ò ní kó wọn jọ, bẹ́ẹ̀ ni a ò ní sin wọ́n. Wọn á dà bí ajílẹ̀ lórí ilẹ̀.”+
3 “Àwọn tó bá sì ṣẹ́ kù lára ìdílé búburú yìí á yan ikú dípò ìyè ní gbogbo ibi tí mo bá fọ́n wọn ká sí,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
4 “Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Tí wọ́n bá ṣubú, ṣé wọn ò ní dìde mọ́ ni?
Tí ẹnì kìíní bá sì yí pa dà, ṣé ẹnì kejì náà kò ní yí pa dà ni?
5 Kí ló dé tí àwọn èèyàn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù ò fi jáwọ́ nínú ìwà àìṣòótọ́ tí wọ́n ń hù sí mi?
Wọn ò jáwọ́ nínú ẹ̀tàn;
Wọn ò sì yí pa dà.+
6 Mo fiyè sí wọn, mo sì ń fetí sílẹ̀, àmọ́ bí wọ́n ṣe sọ̀rọ̀ kò dáa.
Kò sí ẹnì kankan tó ronú pìwà dà ìwà burúkú rẹ̀ tàbí kó sọ pé, ‘Kí ni mo ṣe yìí?’+
Kálukú wọn ń pa dà lọ ṣe ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe, bí ẹṣin tó ń já lọ sójú ogun.
7 Kódà ẹyẹ àkọ̀ tó ń fò lójú ọ̀run mọ àkókò rẹ̀;*
Oriri àti ẹyẹ olófèéèré àti ẹ̀gà* kì í yẹ àkókò tí wọ́n máa pa dà.*
Àmọ́ àwọn èèyàn mi ò mọ ìdájọ́ Jèhófà.”’+
8 ‘Báwo ni ẹ ṣe lè sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n ni wá, a sì ní òfin* Jèhófà”?
Nígbà tó jẹ́ pé, kìkì irọ́ ni àwọn akọ̀wé òfin* ń fi kálàmù* èké*+ wọn kọ.
9 Ojú ti àwọn ọlọ́gbọ́n.+
Àyà wọn já, a ó sì mú wọn.
Wò ó! Wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ Jèhófà,
Ọgbọ́n wo sì ni wọ́n ní?
10 Torí náà, màá fi ìyàwó wọn fún àwọn ọkùnrin míì,
Màá fi oko wọn fún àwọn tó máa gbà á;+
Látorí ẹni kékeré títí dórí ẹni ńlá, kálukú wọn ń jẹ èrè tí kò tọ́;+
Látorí wòlíì títí dórí àlùfáà, kálukú wọn ń lu jìbìtì.+
Nígbà tí kò sí àlàáfíà.+
12 Ǹjẹ́ ojú tì wọ́n nítorí àwọn ohun ìríra tí wọ́n ṣe?
Ojú kì í tì wọ́n!
Àní wọn ò tiẹ̀ lójútì rárá!+
Torí náà, wọ́n á ṣubú láàárín àwọn tó ti ṣubú.
Nígbà tí mo bá fìyà jẹ wọ́n, wọ́n á kọsẹ̀,’+ ni Jèhófà wí.
13 ‘Nígbà tí mo bá kó wọn jọ, màá pa wọ́n run,’ ni Jèhófà wí.
‘Kò ní sí èso tó máa ṣẹ́ kù lórí igi àjàrà, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí èso kankan lórí igi ọ̀pọ̀tọ́, àwọn ewé rẹ̀ yóò sì rọ.
Wọ́n á pàdánù àwọn ohun tí mo fún wọn.’”
14 “Kí nìdí tí a fi jókòó síbí?
Ẹ jẹ́ ká kóra jọ, ká wọnú àwọn ìlú olódi,+ ká sì ṣègbé síbẹ̀.
15 À ń retí àlàáfíà, àmọ́ ohun rere kan ò dé,
À ń retí àkókò ìwòsàn, àmọ́ ìpayà là ń rí!+
16 À ń gbọ́ bí àwọn ẹṣin wọn ṣe ń fọn imú láti Dánì.
Nígbà tí àwọn akọ ẹṣin rẹ̀ bá yán,
Ìró wọn á mú gbogbo ilẹ̀ náà mì tìtì.
Wọ́n wọlé wá, wọ́n sì jẹ ilẹ̀ náà run àti gbogbo ohun tó wà lórí rẹ̀,
Ìlú náà àti àwọn tó ń gbé inú rẹ̀.”
17 “Wò ó, màá rán àwọn ejò sí àárín yín,
Àwọn ejò olóró tí kò ṣeé tù lójú,
Ó dájú pé wọ́n á bù yín ṣán,” ni Jèhófà wí.
18 Ẹ̀dùn ọkàn mi kò ṣeé wò sàn;
Ọkàn mi ń ṣàárẹ̀.
19 Igbe ìrànlọ́wọ́ wá láti ilẹ̀ tó jìnnà
Látọ̀dọ̀ ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi pé:
“Ṣé kò sí Jèhófà ní Síónì ni?
Àbí ọba rẹ̀ kò sí níbẹ̀ ni?”
“Kí ló dé tí wọ́n fi fi ère gbígbẹ́ wọn mú mi bínú,
Pẹ̀lú àwọn ọlọ́run àjèjì wọn tí kò ní láárí?”
20 “Ìkórè ti kọjá, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti parí,
Ṣùgbọ́n a kò tíì rí ìgbàlà!”
21 Ẹ̀dùn ọkàn bá mi nítorí àárẹ̀ ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi;+
Ìbànújẹ́ sorí mi kodò.
Àyà fò mí torí ìbẹ̀rù.
22 Ṣé kò sí básámù* ní Gílíádì+ ni?
Àbí ṣé kò sí oníwòsàn* níbẹ̀ ni?+
Kí ló wá dé tí ara ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi kò fi tíì yá?+
9 Ká ní orí mi jẹ́ omi,
Tí ojú mi sì jẹ́ orísun omijé!+
Mi ò bá sunkún tọ̀sántòru
Nítorí àwọn èèyàn mi tí wọ́n pa.
2 Ká ní mo ní ibi tí àwọn arìnrìn-àjò lè dé sí ní aginjù!
Mi ò bá fi àwọn èèyàn mi sílẹ̀, kí n sì kúrò lọ́dọ̀ wọn,
Nítorí alágbèrè ni gbogbo wọn,+
Àwùjọ àwọn oníbékebèke.
3 Wọ́n tẹ ahọ́n wọn bí ọrun;
Èké ṣíṣe ló gba ilẹ̀ náà kan, kì í ṣe òtítọ́.+
“Wọ́n ń tinú ibi bọ́ sínú ibi,
Wọn ò sì kà mí sí,”+ ni Jèhófà wí.
4 “Kí kálukú yín ṣọ́ra lọ́dọ̀ ọmọnìkejì rẹ̀,
Kódà, ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé arákùnrin yín.
5 Kálukú ń rẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀ jẹ,
Kò sì sí ẹni tó ń sọ òtítọ́.
Wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn láti máa pa irọ́.+
Wọ́n ṣe ohun tí kò tọ́ títí ó fi rẹ̀ wọ́n.
6 Ò ń gbé láàárín ẹ̀tàn.
Ẹ̀tàn wọn ni kò jẹ́ kí wọ́n mọ̀ mí,” ni Jèhófà wí.
7 Torí náà, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:
“Màá yọ́ wọn mọ́, màá sì yẹ̀ wọ́n wò,+
Àbí kí ni kí n tún ṣe sí ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi?
8 Ahọ́n wọn tó ń sọ ẹ̀tàn jẹ́ ọfà tó ń pani.
Ẹnì kan ń fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ àlàáfíà fún ọmọnìkejì rẹ̀,
Àmọ́, ńṣe ló lúgọ dè é ní ọkàn rẹ̀.”
9 “Ǹjẹ́ kò yẹ kí n pè wọ́n wá jíhìn nítorí nǹkan wọ̀nyí?” ni Jèhófà wí.
“Ǹjẹ́ kò yẹ kí n* gbẹ̀san lára orílẹ̀-èdè tó ṣe irú èyí?+
10 Màá sunkún, màá sì kédàárò nítorí àwọn òkè
Màá sì kọ orin arò* nítorí àwọn ibi ìjẹko tó wà ní aginjù,
Torí a ti dáná sun wọ́n kí ẹnì kankan má bàa gba ibẹ̀ kọjá,
A ò gbọ́ ìró ẹran ọ̀sìn níbẹ̀ mọ́.
Àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ti sá, gbogbo wọn ti lọ.+
11 Màá sọ Jerúsálẹ́mù di òkìtì òkúta,+ ibùgbé àwọn ajáko,*+
Màá sì sọ àwọn ìlú Júdà di ahoro, tí ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀.+
12 Ta ni ó gbọ́n tó lè lóye èyí?
Ta ni Jèhófà bá sọ̀rọ̀, kó lè kéde rẹ̀?
Kí nìdí tí ilẹ̀ náà fi pa run?
Kí nìdí tí iná fi jó o gbẹ bí aṣálẹ̀,
Tí kò fi sí ẹnì kankan tó ń gba ibẹ̀ kọjá?”
13 Jèhófà fèsì pé: “Torí pé wọ́n kọ òfin* tí mo fún wọn, wọn ò tẹ̀ lé e, wọn ò sì ṣègbọràn sí ohùn mi. 14 Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ya alágídí, wọ́n ń ṣe ohun tí ọkàn búburú wọn sọ,+ wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn ère Báálì bí àwọn bàbá wọn ṣe kọ́ wọn.+ 15 Nítorí náà, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ pé, ‘Wò ó, màá mú kí àwọn èèyàn yìí jẹ iwọ,* màá sì mú kí wọ́n mu omi tó ní májèlé.+ 16 Màá tú wọn ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn pẹ̀lú àwọn baba wọn kò mọ̀,+ màá sì rán idà sí wọn títí màá fi pa wọ́n run.’+
17 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí,
‘Ẹ fi òye hùwà.
Ẹ pe àwọn obìnrin tó ń kọ orin arò,*+
Kí ẹ sì ránṣẹ́ pe àwọn obìnrin tó já fáfá,
18 Kí wọ́n yára, kí wọ́n sì ké ìdárò nítorí wa,
Kí omijé lè kún ojú wa
Kí omi sì lè máa dà lójú wa pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀.+
19 Nítorí a ti gbọ́ ohùn ìdárò láti Síónì:+
“Ẹ wo bí wọ́n ṣe sọ wá di ahoro!
Ẹ wo bí ìtìjú wa ṣe pọ̀ tó!
Nítorí wọ́n ti lé wa kúrò ní ilẹ̀ náà, wọ́n sì ti wó àwọn ilé wa lulẹ̀.”+
20 Ẹ̀yin obìnrin, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.
Ẹ jẹ́ kí etí yín gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀.
21 Nítorí ikú ti gba ojú fèrèsé* wa wọlé;
Ó ti wọ àwọn ilé gogoro wa tó láàbò
Láti mú àwọn ọmọ kúrò ní àwọn ojú ọ̀nà
Àti láti mú àwọn ọ̀dọ́kùnrin kúrò ní àwọn ojúde ìlú.’+
22 Sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Òkú àwọn èèyàn á dà bí ajílẹ̀ lórí ilẹ̀
Àti bí ìtí ọkà tí olùkórè ṣẹ̀ṣẹ̀ gé sílẹ̀,
Tí ẹnì kankan kò ní kó jọ.”’”+
23 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Kí ọlọ́gbọ́n má ṣe yangàn nítorí ọgbọ́n rẹ̀;+
Kí alágbára má ṣe yangàn nítorí agbára rẹ̀;
Kí ọlọ́rọ̀ má sì yangàn nítorí ọrọ̀ rẹ̀.”+
24 “Ṣùgbọ́n kí ẹni tó bá fẹ́ yangàn máa yangàn nítorí ohun yìí:
Pé òun ní ìjìnlẹ̀ òye àti ìmọ̀ nípa mi,+
Pé èmi ni Jèhófà, Ẹni tí ìfẹ́ rẹ̀ kì í yẹ̀, tó ń ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ àti òdodo ní ayé,+
Nítorí nǹkan wọ̀nyí ni inú mi dùn sí,”+ ni Jèhófà wí.
25 Jèhófà sọ pé, “Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀ tí màá mú kí gbogbo àwọn tó kọlà* àmọ́ tí wọn ò kọlà* lóòótọ́ jíhìn+ 26 àti Íjíbítì àti + Júdà+ àti Édómù+ àti àwọn ọmọ Ámónì+ àti Móábù+ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí wọ́n gé irun wọn mọ́lẹ̀ ní ẹ̀bátí, tí wọ́n ń gbé ní aginjù.+ Nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè jẹ́ aláìkọlà,* gbogbo ilé Ísírẹ́lì sì jẹ́ aláìkọlà* ọkàn.”+
10 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà sí yín, ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì. 2 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Ẹ má ṣe kọ́ ọ̀nà àwọn orílẹ̀-èdè,+
Ẹ má sì ṣe jẹ́ kí àwọn àmì ojú ọ̀run dẹ́rù bà yín
Nítorí wọ́n ti dẹ́rù ba àwọn orílẹ̀-èdè.+
3 Àṣà àwọn èèyàn náà jẹ́ ẹ̀tàn.*
5 Wọ́n dà bí aṣọ́komásùn tó wà nínú oko kùkúńbà,* wọn ò lè sọ̀rọ̀;+
Ńṣe là ń gbé wọn, torí wọn ò lè rìn.+
Má bẹ̀rù wọn, torí wọn ò lè pani lára,
Bẹ́ẹ̀ ni wọn ò lè ṣeni lóore kankan.”+
6 Jèhófà, kò sí ẹni tó dà bí rẹ.+
O tóbi, orúkọ rẹ tóbi, ó sì kàmàmà.
7 Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ, ìwọ Ọba àwọn orílẹ̀-èdè,+ nítorí ó yẹ bẹ́ẹ̀;
Láàárín gbogbo ọlọ́gbọ́n tó wà ní àwọn orílẹ̀-èdè àti ní gbogbo ìjọba wọn,
Kò sí ẹnì kankan tó dà bí rẹ.+
8 Gbogbo wọn jẹ́ aláìnírònú àti òmùgọ̀.+
Ìmọ̀ràn látọ̀dọ̀ igi jẹ́ kìkìdá ẹ̀tàn.*+
9 Àwọn fàdákà pẹlẹbẹ tí wọ́n kó wá láti Táṣíṣì+ àti wúrà láti Úfásì,
Ohun tí oníṣẹ́ ọnà ṣe àti ohun tí oníṣẹ́ irin ṣe.
Aṣọ wọn jẹ́ fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti òwú aláwọ̀ pọ́pù.
Gbogbo wọn jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọ̀jáfáfá.
10 Ṣùgbọ́n Jèhófà ni Ọlọ́run lóòótọ́.
Òun ni Ọlọ́run alààyè+ àti Ọba ayérayé.+
Nítorí ìbínú rẹ̀, ayé á mì jìgìjìgì,+
Kò sì sí orílẹ̀-èdè tó lè fara da ìdálẹ́bi rẹ̀.
11 * Ohun tí o máa sọ fún wọn nìyí:
“Àwọn ọlọ́run tí kò dá ọ̀run àti ayé
Yóò ṣègbé kúrò ní ayé àti kúrò lábẹ́ ọ̀run yìí.”+
12 Òun ni Aṣẹ̀dá ayé tó fi agbára rẹ̀ dá a,
Ẹni tó fi ọgbọ́n rẹ̀ dá ilẹ̀ tó ń mú èso jáde+
Tó sì fi òye rẹ̀ na ọ̀run bí aṣọ.+
14 Kálukú ń hùwà láìronú, wọn ò sì ní ìmọ̀.
15 Ẹ̀tàn* ni wọ́n, iṣẹ́ yẹ̀yẹ́ sì ni wọ́n.+
Nígbà tí ọjọ́ ìbẹ̀wò wọn bá dé, wọ́n á ṣègbé.
16 Ọlọ́run* Jékọ́bù kò dà bí àwọn nǹkan yìí,
Nítorí òun ni Ẹni tó dá ohun gbogbo,
Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.+
17 Kó ẹrù rẹ kúrò nílẹ̀,
Ìwọ obìnrin tó ń gbé nínú ìlú tí wọ́n gbógun tì.
18 Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
Ọgbẹ́ mi kò ṣeé wò sàn.
Mo sì sọ pé: “Ó dájú pé àìsàn mi nìyí, màá sì fara dà á.
20 Wọ́n ti sọ àgọ́ mi di ahoro, wọ́n sì ti fa gbogbo okùn àgọ́ mi já.+
Àwọn ọmọkùnrin mi ti fi mí sílẹ̀, wọn kò sì sí mọ́.+
Kò sí ẹni tó ṣẹ́ kù tó máa gbé àgọ́ mi ró tàbí tó máa ta aṣọ àgọ́ mi.
Ìdí nìyẹn tí wọn kò fi fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà,
Tí gbogbo agbo ẹran wọn sì fi tú ká.”+
22 Fetí sílẹ̀! Ìròyìn kan ń bọ̀!
23 Jèhófà, mo mọ̀ dáadáa pé ọ̀nà èèyàn kì í ṣe tirẹ̀.
Àní kò sí ní ìkáwọ́ èèyàn tó ń rìn láti darí ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.+
25 Da ìrunú rẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè tó pa ọ́ tì+
Àti sórí àwọn ìdílé tí kì í ké pe orúkọ rẹ.
Nítorí wọ́n ti jẹ Jékọ́bù run,+
Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ti jẹ ẹ́ ní àjẹtán títí wọ́n fi pa á run,+
Wọ́n sì ti sọ ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ di ahoro.+
11 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Jeremáyà nìyí, ó ní: 2 “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí!
“Sọ* ọ́ fún àwọn èèyàn Júdà àti fún àwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù, 3 kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Ègún ni fún ẹni tí kò bá pa ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí mọ́,+ 4 tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín ní ọjọ́ tí mo mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ kúrò nínú iná ìléru tí wọ́n fi ń yọ́ irin,+ pé, ‘Ẹ ṣègbọràn sí ohùn mi, ẹ sì ṣe gbogbo ohun tí mo bá pa láṣẹ fún yín, ẹ ó sì di èèyàn mi, màá sì di Ọlọ́run yín,+ 5 kí n lè mú ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́ fún àwọn baba ńlá yín ṣẹ, pé màá fún wọn ní ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ bó ṣe rí lónìí.’”’”
Mo sì dáhùn pé: “Àmín,* Jèhófà.”
6 Jèhófà sì sọ fún mi pé: “Kéde gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní àwọn ìlú Júdà àti ní àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù pé: ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí, kí ẹ sì pa wọ́n mọ́. 7 Nítorí mo kìlọ̀ fún àwọn baba ńlá yín gidigidi ní ọjọ́ tí mò ń mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì títí di òní, léraléra ni mo sì ń kìlọ̀* fún wọn pé: “Ẹ ṣègbọràn sí ohùn mi.”+ 8 Ṣùgbọ́n wọn ò tẹ́tí sí mi, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò fetí sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, kálukú wọn ya alágídí, wọ́n sì ń ṣe ohun tí ọkàn búburú wọn sọ.+ Torí náà, mo mú gbogbo ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí wá sórí wọn, èyí tí mo pa láṣẹ fún wọn, tí wọn ò sì pa mọ́.’”
9 Jèhófà sì sọ fún mi pé: “Àwọn èèyàn Júdà àti àwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù ń dìtẹ̀. 10 Wọ́n ti pa dà sínú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn àtijọ́ tí wọ́n kọ̀ láti ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ mi.+ Àwọn náà tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, wọ́n sì sìn wọ́n.+ Ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà ti da májẹ̀mú mi tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá.+ 11 Torí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Wò ó, màá mú àjálù+ tí wọn kò ní lè bọ́ nínú rẹ̀ wá bá wọn. Nígbà tí wọ́n bá ké pè mí fún ìrànlọ́wọ́, mi ò ní fetí sí wọn.+ 12 Ìgbà náà ni àwọn ìlú Júdà àti àwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù yóò wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́run tí wọ́n ń rú ẹbọ* sí,+ ṣùgbọ́n wọn ò ní lè gbà wọ́n lọ́nàkọnà ní àkókò àjálù wọn. 13 Torí pé bí ìlú rẹ ṣe pọ̀ tó ni àwọn ọlọ́run rẹ ṣe pọ̀ tó, ìwọ Júdà, o sì ti ṣe pẹpẹ tó pọ̀ bí àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù ṣe pọ̀ fún ohun ìtìjú* láti máa fi rú ẹbọ sí Báálì.’+
14 “Ní tìrẹ,* má ṣe gbàdúrà nítorí àwọn èèyàn yìí. Má sì sunkún nítorí wọn tàbí kí o gbàdúrà fún wọn,+ torí mi ò ní fetí sílẹ̀ tí wọ́n bá ń ké pè mí nígbà àjálù wọn.
15 Ẹ̀tọ́ wo ni olólùfẹ́ mi ní láti wà nínú ilé mi
Nígbà tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nínú wọn ń ṣe ibi tó wà lọ́kàn wọn?
Ṣé ẹran mímọ́* tí wọ́n fi ń rúbọ lè mú àjálù kúrò nígbà tó bá dé bá ọ?
Ǹjẹ́ inú rẹ máa dùn nígbà náà?
16 Nígbà kan Jèhófà pè ọ́ ní igi ólífì tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀,
Tó rẹwà tó sì ní èso tó dáa.
Ó ti sọ iná sí i pẹ̀lú ariwo ńlá,
Wọ́n sì ti ṣẹ́ àwọn ẹ̀ka rẹ̀.
17 “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ẹni tó gbìn ọ́,+ ti kéde pé àjálù yóò bá ọ nítorí ìwà ibi tí ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà hù, tí wọ́n ń mú mi bínú bí wọ́n ṣe ń rú ẹbọ sí Báálì.”+
18 Jèhófà sọ fún mi kí n lè mọ̀;
Ní àkókò yẹn, o jẹ́ kí n rí ohun tí wọ́n ń ṣe.
19 Mo dà bí ọ̀dọ́ àgùntàn tí kò lágbaja tí wọ́n ń mú bọ̀ níbi tí wọ́n ti fẹ́ pa á.
Mi ò mọ̀ pé wọ́n ń gbèrò ohun búburú sí mi pé:+
“Ẹ jẹ́ ká pa igi náà àti èso rẹ̀ run,
Ká sì gé e kúrò ní ilẹ̀ alààyè,
Kí a má bàa rántí orúkọ rẹ̀ mọ́.”
Jẹ́ kí n rí ẹ̀san rẹ lára wọn,
Nítorí ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹjọ́ mi lé.
21 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà sọ sí àwọn èèyàn Ánátótì+ tí wọ́n fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ,* tí wọ́n sì sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ Jèhófà,+ àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ a ó fi ọwọ́ ara wa pa ọ́.” 22 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Wò ó, màá pè wọ́n wá jíhìn. Idà ni yóò pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn,+ ìyàn sì ni yóò pa àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn.+ 23 Àní kò ní sí ẹnì kankan tó máa ṣẹ́ kù lára wọn, nítorí màá mú àjálù bá àwọn èèyàn Ánátótì+ ní ọdún tí màá pè wọ́n wá jíhìn.”
12 Olódodo ni ọ́, Jèhófà,+ nígbà tí mo gbé ẹjọ́ mi wá sọ́dọ̀ rẹ,
Nígbà tí mo sọ nípa ìdájọ́ òdodo fún ọ.
Àmọ́ kí nìdí tí ọ̀nà àwọn ẹni burúkú fi ń yọrí sí rere,+
Kí sì nìdí tí ọkàn àwọn oníbékebèke fi balẹ̀?
2 O gbìn wọ́n, wọ́n sì ti ta gbòǹgbò.
Wọ́n ti dàgbà, wọ́n sì ti so èso.
O wà lórí ètè wọn, ṣùgbọ́n èrò inú wọn* jìnnà sí ọ.+
Mú wọn bí àgùntàn tí wọ́n fẹ́ lọ pa,
Kí o sì yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ọjọ́ pípa.
4 Ìgbà wo ni ilẹ̀ náà kò ní ṣá mọ́
Tí koríko gbogbo ilẹ̀ kò sì ní gbẹ dà nù?+
Nítorí ìwà ibi àwọn tó ń gbé lórí rẹ̀,
A ti gbá àwọn ẹranko àti àwọn ẹyẹ lọ.
Torí wọ́n sọ pé: “Kò rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa.”
Ká tiẹ̀ ní ọkàn rẹ balẹ̀ ní ilẹ̀ tó ní àlàáfíà,
Báwo lo ti máa ṣe é ní àárín igbó kìjikìji tó wà ní ẹ̀gbẹ́ odò Jọ́dánì?
6 Kódà, àwọn arákùnrin rẹ, ìyẹn àwọn ará ilé bàbá rẹ,
Ti hùwà àìṣòótọ́ sí ọ.+
Wọ́n ti kígbe lé ọ lórí.
Má gbà wọ́n gbọ́,
Kódà tí wọ́n bá tiẹ̀ sọ àwọn ohun rere fún ọ.
7 “Mo ti pa ilé mi tì,+ mo sì ti pa ogún mi tì.+
Mo ti fa olólùfẹ́ mi ọ̀wọ́n* lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.+
8 Ogún mi ti dà bíi kìnnìún inú igbó sí mi.
Ó ti bú mọ́ mi.
Ìdí nìyẹn tí mo fi kórìíra rẹ̀.
9 Lójú mi, ogún mi ti dà bí ẹyẹ aṣọdẹ tó ní oríṣiríṣi àwọ̀;*
Àwọn ẹyẹ aṣọdẹ míì yí i ká, wọ́n sì bá a jà.+
Ẹ wá, ẹ kóra jọ, gbogbo ẹ̀yin ẹran inú igbó,
Ẹ wá jẹun.+
Wọ́n ti sọ oko mi tó dára di aginjù.
11 Ó ti di ahoro.
Wọ́n ti sọ gbogbo ilẹ̀ náà di ahoro,
Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tó fọkàn sí i.+
12 Gbogbo ọ̀nà tó ń dán tó wà ní aginjù ni àwọn apanirun gbà wá,
Idà Jèhófà ń pani run láti ìkángun kan títí dé ìkángun kejì ilẹ̀ náà.+
Kò sí ẹni* tó ní àlàáfíà.
13 Wọ́n ti gbin àlìkámà,* àmọ́ ẹ̀gún ni wọ́n kórè.+
Wọ́n ti ṣiṣẹ́ bí ẹní-máa-kú, àmọ́ wọn ò jèrè nǹkan kan.
Irè oko wọn á dójú tì wọ́n
Nítorí ìbínú Jèhófà tó ń jó fòfò.”
14 Ohun tí Jèhófà sọ nípa gbogbo aládùúgbò mi burúkú, tí wọ́n ń fọwọ́ kan ogún tí mo fún àwọn èèyàn mi, Ísírẹ́lì nìyí:+ “Wò ó, màá fà wọ́n tu kúrò ní ilẹ̀ wọn,+ màá sì fa ilé Júdà tu kúrò ní àárín wọn. 15 Àmọ́ lẹ́yìn tí mo bá fà wọ́n tu, màá tún ṣàánú wọn, màá sì mú kálukú wọn pa dà sí ogún rẹ̀ àti sí ilẹ̀ rẹ̀.”
16 “Tí wọ́n bá sì sapá láti kọ́ ọ̀nà àwọn èèyàn mi, tí wọ́n sì fi orúkọ mi búra pé, ‘Bí Jèhófà ti wà láàyè!’ bí àwọn náà ṣe kọ́ àwọn èèyàn mi láti máa fi Báálì búra, ìgbà náà ni wọn yóò rí àyè láàárín àwọn èèyàn mi. 17 Àmọ́ bí wọn kò bá ṣègbọràn, ńṣe ni màá fa orílẹ̀-èdè yẹn tu, màá fà á tu, màá sì pa á run,” ni Jèhófà wí.+
13 Ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí: “Lọ ra àmùrè aṣọ ọ̀gbọ̀,* kí o sì dè é mọ́ ìbàdí rẹ, àmọ́ má ṣe tì í bọ omi.” 2 Nítorí náà, mo ra àmùrè náà bí Jèhófà ṣe sọ, mo sì dè é mọ́ ìbàdí mi. 3 Jèhófà sì tún bá mi sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì pé: 4 “Mú àmùrè tí o rà, tí o dè mọ́ ìbàdí rẹ, sì dìde, lọ sí odò Yúfírétì, kí o sì fi pa mọ́ sínú pàlàpálá àpáta.” 5 Nítorí náà, mo lọ, mo sì fi pa mọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Yúfírétì bí Jèhófà ṣe pàṣẹ fún mi.
6 Ṣùgbọ́n ní ọ̀pọ̀ ọjọ́ lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún mi pé: “Dìde, lọ sí odò Yúfírétì, kí o sì mú àmùrè tí mo pàṣẹ pé kí o fi pa mọ́ náà kúrò níbẹ̀.” 7 Torí náà, mo lọ sí odò Yúfírétì, mo walẹ̀, mo sì mú àmùrè náà ní ibi tí mo fi pa mọ́ sí, sì wò ó! àmùrè náà ti bà jẹ́, kò sì wúlò fún ohunkóhun mọ́.
8 Nígbà náà, Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀: 9 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ọ̀nà kan náà ni màá gbà ba ògo Júdà àti ògo ńlá Jerúsálẹ́mù jẹ́.+ 10 Àwọn èèyàn búburú yìí, tí kò ṣègbọràn sí ohùn mi,+ àwọn alágídí tó ń ṣe ohun tí ọkàn wọn ń sọ,+ tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, tí wọ́n ń sìn wọ́n, tí wọ́n sì ń forí balẹ̀ fún wọn, àwọn náà yóò dà bí àmùrè yìí tí kò wúlò fún ohunkóhun mọ́.’ 11 ‘Nítorí bí àmùrè ṣe ń lẹ̀ mọ́ ìbàdí èèyàn, bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́ kí gbogbo ilé Ísírẹ́lì àti gbogbo ilé Júdà lẹ̀ mọ́ mi,’ ni Jèhófà wí, ‘kí wọ́n lè di èèyàn kan,+ orúkọ kan,+ ìyìn kan àti ohun ẹlẹ́wà fún mi. Ṣùgbọ́n wọn kò ṣègbọràn.’+
12 “Kí o sì jẹ́ iṣẹ́ yìí fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Ẹ pọn wáìnì kún inú gbogbo ìṣà ńlá.”’ Wọ́n á fèsì pé, ‘Ṣé a ò mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ó yẹ kí a pọn wáìnì kún inú gbogbo ìṣà ńlá ni?’ 13 Kí o wá sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Wò ó, màá rọ gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà yó,+ látorí àwọn ọba tó ń jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì dórí àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù. 14 Màá gbé wọn kọ lu ara wọn, àwọn bàbá àti àwọn ọmọ,” ni Jèhófà wí.+ “Mi ò ní yọ́nú sí wọn tàbí kí n bá wọn kẹ́dùn, bẹ́ẹ̀ ni mi ò ní ṣàánú wọn. Kò sì sí ohun tó máa dá mi dúró láti pa wọ́n run.”’+
15 Ẹ gbọ́, ẹ sì fetí sílẹ̀.
Ẹ má ṣe gbéra ga, torí Jèhófà ti sọ̀rọ̀.
16 Ẹ fi ògo fún Jèhófà Ọlọ́run yín
Kí ó tó mú òkùnkùn wá
Kí ẹ sì tó fẹsẹ̀ kọ lórí àwọn òkè nígbà tí ilẹ̀ ń ṣú.
17 Bí ẹ kò bá sì fetí sílẹ̀,
Màá* sunkún ní ìkọ̀kọ̀ torí ìgbéraga yín.
19 A ti ti àwọn ìlú gúúsù pa,* kò sì sẹ́ni tó máa ṣí wọn.
A ti kó gbogbo èèyàn Júdà lọ sí ìgbèkùn, gbogbo wọn ni a ti kó lọ pátápátá.+
20 Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wo àwọn tó ń bọ̀ láti àríwá.+
Ibo ni agbo ẹran tí wọ́n fún ọ wà, àwọn àgùntàn rẹ tó lẹ́wà?+
21 Kí lo máa sọ nígbà tí ìyà rẹ bá dé
Látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ tí o ní láti ìbẹ̀rẹ̀?+
Ǹjẹ́ irú ìrora tí obìnrin máa ń ní nígbà ìbímọ kò ní bá ọ?+
22 Nígbà tí o bá sì sọ ní ọkàn rẹ pé, ‘Kí ló dé tí àwọn nǹkan yìí fi ṣẹlẹ̀ sí mi?’+
Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tó pọ̀ ni wọ́n ṣe ká aṣọ rẹ sókè +
Tí wọ́n sì fìyà jẹ gìgísẹ̀ rẹ.
23 Ǹjẹ́ ọmọ Kúṣì* lè yí àwọ̀ rẹ̀ pa dà, àbí ṣé àmọ̀tẹ́kùn lè yí àmì ara rẹ̀ pa dà?+
Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ẹ lè ṣe rere,
Ẹ̀yin tí wọ́n ti kọ́ láti máa ṣe búburú.
24 Nítorí náà, màá fọ́n wọn ká bíi pòròpórò tí ẹ̀fúùfù láti aṣálẹ̀ ń gbá lọ.+
25 Ìpín rẹ nìyí, ìpín tí mo wọ̀n fún ọ,” ni Jèhófà wí,
26 Nítorí náà, màá ká aṣọ rẹ sókè bò ọ́ lójú,
Wọ́n á sì rí ìtìjú rẹ,+
27 Ìwà àgbèrè rẹ + àti bí o ṣe ń yán bí ẹṣin tó fẹ́ gùn,
Ìṣekúṣe rẹ tó ń ríni lára.*
Lórí àwọn òkè àti ní pápá,
Mo ti rí ìwà ẹ̀gbin rẹ.+
O gbé, ìwọ Jerúsálẹ́mù!
Títí dìgbà wo lo fi máa jẹ́ aláìmọ́?”+
14 Ohun tí Jèhófà bá Jeremáyà sọ nípa ọ̀dá* nìyí:+
2 Júdà ń ṣọ̀fọ̀,+ àwọn ẹnubodè rẹ̀ ti dá páropáro.
Wọ́n ti wọlẹ̀ torí pé wọ́n ti pa á tì,
Igbe ẹkún Jerúsálẹ́mù ti dé ọ̀run.
3 Àwọn ọ̀gá wọn ń rán àwọn ìránṣẹ́* wọn lọ pọn omi.
Wọ́n dé ìdí àwọn kòtò omi,* àmọ́ wọn ò rí omi kankan.
Òfìfo ìkòkò ni wọ́n gbé pa dà.
Ojú tì wọ́n, ìjákulẹ̀ bá wọn,
Wọ́n sì bo orí wọn.
5 Kódà, abo àgbọ̀nrín inú pápá ń pa àwọn ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí tì
Nítorí kò sí koríko.
6 Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí àwọn òkè.
7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà wa jẹ́rìí sí i pé a ti ṣe àṣìṣe,
Jèhófà, ràn wá lọ́wọ́ nítorí orúkọ rẹ.+
Nítorí ìwà àìṣòótọ́ wa pọ̀,+
Ìwọ sì ni a dẹ́ṣẹ̀ sí.
Àti bí arìnrìn-àjò tó kàn dúró láti sùn mọ́jú?
9 Kí nìdí tí o fi dà bí ọkùnrin tí nǹkan tojú sú,
Bí alágbára ọkùnrin tí kò lè gbani là?
Má fi wá sílẹ̀.
10 Ohun tí Jèhófà sọ nípa àwọn èèyàn yìí rèé: “Wọ́n fẹ́ láti máa rìn kiri,+ wọn ò ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ wọn.+ Nítorí náà, inú Jèhófà ò dùn sí wọn.+ Ní báyìí, á rántí àṣìṣe wọn, á sì pè wọ́n wá jíhìn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”+
11 Jèhófà sì sọ fún mi pé: “Má ṣe gbàdúrà pé kí ire bá àwọn èèyàn yìí.+ 12 Tí wọ́n bá gbààwẹ̀, mi ò ní fetí sí ẹ̀bẹ̀ wọn,+ tí wọ́n bá sì fi odindi ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà rúbọ, inú mi ò ní dùn sí wọn,+ nítorí pé idà àti ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn* ni màá fi pa wọ́n.”+
13 Ni mo bá sọ pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Wò ó, àwọn wòlíì ń sọ fún wọn pé, ‘Ẹ kò ní rí idà, ìyàn kò sì ní dé bá yín, ṣùgbọ́n Ọlọ́run á fún yín ní àlàáfíà gidi ní ibí yìí.’”+
14 Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni àwọn wòlíì náà ń sọ ní orúkọ mi.+ Mi ò rán wọn, bẹ́ẹ̀ ni mi ò pàṣẹ fún wọn, mi ò sì bá wọn sọ̀rọ̀.+ Ìran èké àti ìwoṣẹ́ asán àti ẹ̀tàn ọkàn wọn ni wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín.+ 15 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Ní ti àwọn wòlíì tó ń sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ mi, bó tilẹ̀ jẹ pé mi ò rán wọn, tí wọ́n ń sọ pé idà tàbí ìyàn kò ní wáyé ní ilẹ̀ yìí, idà àti ìyàn ni yóò pa àwọn wòlíì náà.+ 16 Àwọn èèyàn tí wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún yóò di òkú tí wọ́n á gbé jù sí àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù nítorí ìyàn àti idà. Ẹnì kankan kò sì ní sin wọ́n,+ látorí àwọn fúnra wọn dórí àwọn ìyàwó wọn àti àwọn ọmọkùnrin wọn pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin wọn, torí màá mú àjálù tí ó tọ́ sí wọn bá wọn.’+
17 “Sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn pé,
‘Kí omijé ṣàn ní ojú mi tọ̀sántòru, kí ó má sì dá,+
Nítorí wọ́n ti lu wúńdíá àwọn èèyàn mi ní àlùbolẹ̀,+
Wọ́n sì dá ọgbẹ́ sí i lára yánnayànna.
18 Bí mo bá jáde lọ sínú pápá, tí mo sì wò,
Àwọn tí idà pa ni mò ń rí!+
Bí mo bá sì wá sínú ìlú,
Àwọn àrùn tí ìyàn fà ni mò ń rí!+
Nítorí wòlíì àti àlùfáà ti lọ káàkiri ní ilẹ̀ tí wọn ò mọ̀.’”+
19 Ṣé o kọ Júdà sílẹ̀ pátápátá ni, àbí o* ti kórìíra Síónì dé góńgó ni?+
Kí nìdí tí o fi lù wá débi tí a ò fi lè rí ìwòsàn?+
À ń retí àlàáfíà, àmọ́ ohun rere kan ò dé,
À ń retí àkókò ìwòsàn, àmọ́ ìpayà là ń rí!+
21 Nítorí orúkọ rẹ, má kọ̀ wá sílẹ̀;+
Má ṣe fojú àbùkù wo ìtẹ́ ògo rẹ.
Rántí, má sì da májẹ̀mú tí o bá wa dá.+
22 Ǹjẹ́ ìkankan lára àwọn òrìṣà lásánlàsàn tí àwọn orílẹ̀-èdè ń bọ lè rọ òjò,
Àbí ṣé ọ̀run fúnra rẹ̀ pàápàá lè dá rọ ọ̀wààrà òjò?
Ìwọ nìkan lo lè ṣe é, Jèhófà Ọlọ́run wa.+
A sì ní ìrètí nínú rẹ,
Nítorí ìwọ nìkan ló ń ṣe gbogbo nǹkan yìí.
15 Nígbà náà, Jèhófà sọ fún mi pé: “Bí Mósè àti Sámúẹ́lì bá tiẹ̀ dúró níwájú mi,+ mi ò ní ṣojúure sí* àwọn èèyàn yìí. Lé wọn kúrò níwájú mi, kí wọ́n máa lọ. 2 Bí wọ́n bá sì bi ọ́ pé, ‘Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí wa?’ kí o sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Àjàkálẹ̀ àrùn máa pa àwọn kan lára yín!
Idà máa pa àwọn kan lára yín!+
Ìyàn máa pa àwọn míì lára yín!
Àwọn kan lára yín sì máa lọ sóko ẹrú!”’+
3 “‘Màá yan ìyọnu mẹ́rin lé wọn lórí,’*+ ni Jèhófà wí, ‘idà láti pa wọ́n, àwọn ajá láti wọ́ òkú wọn lọ àti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run pẹ̀lú àwọn ẹranko orí ilẹ̀ láti jẹ wọ́n àti láti run wọ́n.+ 4 Màá sì sọ wọ́n di ohun àríbẹ̀rù lójú gbogbo ìjọba ayé+ nítorí ohun tí Mánásè ọmọ Hẹsikáyà, ọba Júdà ṣe ní Jerúsálẹ́mù.+
5 Ta ló máa ṣàánú rẹ, ìwọ Jerúsálẹ́mù,
Ta ló máa bá ọ kẹ́dùn,
Ta ló sì máa yà wá béèrè àlàáfíà rẹ?’
6 ‘O ti fi mí sílẹ̀,’ ni Jèhófà wí.+
Torí náà, màá na ọwọ́ mi sí ọ, màá sì pa ọ́ run.+
Mo ti ṣàánú rẹ títí, ó ti sú mi.*
7 Màá fi àmúga fẹ́ wọn bí ọkà ní àwọn ẹnubodè ilẹ̀ náà.
Màá mú kí wọ́n ṣòfò ọmọ.+
Màá pa àwọn èèyàn mi run,
Nítorí wọn ò yí pa dà kúrò nínú ọ̀nà wọn.+
8 Màá mú kí àwọn opó wọn pọ̀ ju iyanrìn òkun lọ.
Màá mú apanirun wá bá wọn ní ọ̀sán gangan, yóò wá bá àwọn ìyá àti àwọn ọ̀dọ́kùnrin.
Màá sì mú ìrúkèrúdò àti ẹ̀rù wá bá wọn lójijì.
9 Ó ti rẹ obìnrin tó bí ọmọ méje tẹnutẹnu;
Ó* ń mí gúlegúle.
Oòrùn rẹ̀ ti wọ̀ ní ọ̀sán gangan,
Ìtìjú ti bá a, ó sì ti tẹ́.’*
‘Àwọn díẹ̀ tó sì ṣẹ́ kù lára wọn
Ni màá jẹ́ kí àwọn ọ̀tá wọn fi idà pa,’ ni Jèhófà wí.”+
10 Ìwọ ìyá mi, mo gbé nítorí pé o bí mi,+
Ọkùnrin tí gbogbo ilẹ̀ náà ń bá jà, tí wọ́n sì ń bá fa wàhálà.
Mi ò yáni lówó, bẹ́ẹ̀ ni mi ò yáwó lọ́wọ́ ẹnì kankan;
Àmọ́ gbogbo wọn ń gbé mi ṣépè.
11 Jèhófà sọ pé: “Màá tì ọ́ lẹ́yìn;
Màá bá ọ bá ọ̀tá sọ̀rọ̀ ní àkókò àjálù
Àti ní àkókò ìdààmú.
12 Ṣé a rí ẹni tó lè ṣẹ́ irin sí wẹ́wẹ́,
Irin tó wá láti àríwá, tàbí tó lè ṣẹ́ bàbà sí wẹ́wẹ́?
13 Màá jẹ́ kí wọ́n kó àwọn ohun àmúṣọrọ̀ rẹ àti ìṣúra rẹ lọ,+
Kì í ṣe láti gba owó, àmọ́ ó jẹ́ nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí o dá ní gbogbo ilẹ̀ rẹ.
14 Màá kó wọn fún àwọn ọ̀tá rẹ
Kí wọ́n lè kó wọn lọ sí ilẹ̀ tí ìwọ kò mọ̀.+
Torí ìbínú mi ti mú kí iná kan ràn,
Á sì máa jó lára rẹ.”+
15 Ìwọ fúnra rẹ mọ̀, Jèhófà,
Rántí mi kí o sì kíyè sí mi.
Gbẹ̀san mi lára àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi.+
Má ṣe jẹ́ kí n ṣègbé* torí o kì í tètè bínú.
O ṣáà mọ̀ pé nítorí rẹ ni mo ṣe ń fara da ẹ̀gàn yìí.+
16 Mo rí ọ̀rọ̀ rẹ, mo sì jẹ ẹ́;+
Ọ̀rọ̀ rẹ sì di ayọ̀ fún mi àti ìdùnnú ọkàn mi,
Nítorí wọ́n ti fi orúkọ rẹ pè mí, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.
17 Mi ò jókòó ní àwùjọ àwọn alárìíyá, kí n sì máa yọ̀.+
18 Kí nìdí tí ìrora mi ò fi lọ, tí ọgbẹ́ mi ò sì ṣeé wò sàn?
Tí ó kọ̀ tí kò sàn.
Ṣé o máa wá dà bí orísun omi tó ń tanni jẹ sí mi
Tí kò ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé ni?
19 Torí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Bí o bá pa dà, nígbà náà, màá mú ọ bọ̀ sípò,
Wàá sì dúró níwájú mi.
Tí o bá ya ohun tó ṣeyebíye sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ohun tí kò ní láárí,
Wàá ṣe agbẹnusọ fún mi.*
Àwọn ló máa wá sọ́dọ̀ rẹ,
Àmọ́ ìwọ kò ní lọ bá wọn.”
20 “Màá sọ ọ́ di odi bàbà tó lágbára sí àwọn èèyàn yìí.+
Ó dájú pé wọ́n á bá ọ jà,
Torí mo wà pẹ̀lú rẹ, láti gbà ọ́ àti láti dá ọ sílẹ̀,” ni Jèhófà wí.
21 “Màá sì gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú
Màá rà ọ́ pa dà kúrò lọ́wọ́ àwọn aláìláàánú.”
16 Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i pé: 2 “O ò gbọ́dọ̀ fẹ́ ìyàwó, o ò sì gbọ́dọ̀ ní àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin ní ibí yìí. 3 Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nípa àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n bí ní ibí yìí àti nípa àwọn ìyá wọn àti àwọn bàbá wọn tó bí wọn ní ilẹ̀ yìí ni pé: 4 ‘Àrùn burúkú ni yóò pa wọ́n,+ ẹnì kankan ò ní ṣọ̀fọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ní sin wọ́n; wọ́n á dà bí ajílẹ̀ lórí ilẹ̀.+ Idà àti ìyàn ni yóò pa wọ́n,+ òkú wọn yóò sì di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko orí ilẹ̀.’
5 Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí,
‘Má wọnú ilé tí àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ ti ń jẹ àsè,
Má lọ bá wọn pohùn réré ẹkún, má sì bá wọn kẹ́dùn.’+
‘Torí mo ti mú àlàáfíà mi kúrò lọ́dọ̀ àwọn èèyàn yìí,’ ni Jèhófà wí,
‘Títí kan ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ àti àánú mi.+
6 Àti ẹni ńlá àti ẹni kékeré, gbogbo wọn ni yóò kú ní ilẹ̀ yìí.
A kò ní sin wọ́n,
Ẹnì kankan ò ní ṣọ̀fọ̀ wọn,
Bẹ́ẹ̀ ni ẹnì kankan ò ní fi abẹ kọ ara rẹ̀ tàbí kó mú orí ara rẹ̀ pá nítorí wọn.*
7 Ẹnì kankan ò ní fún àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ lóúnjẹ,
Láti tù wọ́n nínú nítorí èèyàn wọn tó kú;
Bẹ́ẹ̀ ni ẹnì kankan ò ní fún wọn ní ife wáìnì mu láti tù wọ́n nínú
Nítorí bàbá àti ìyá wọn tó ṣaláìsí.
8 Ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ wọ ilé tí wọ́n ti ń se àsè
Láti bá wọn jókòó, láti jẹ àti láti mu.’
9 “Nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Wò ó ní ibí yìí, lójú rẹ àti ní ìgbà ayé rẹ, màá fòpin sí ìró ayọ̀ àti ìdùnnú, ohùn ọkọ ìyàwó àti ohùn ìyàwó.’+
10 “Nígbà tí o bá sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn èèyàn yìí, wọ́n á béèrè lọ́wọ́ rẹ pé, ‘Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé kí gbogbo àjálù ńlá yìí dé bá wa? Kí la ṣe, ẹ̀ṣẹ̀ wo la ṣẹ Jèhófà Ọlọ́run wa?’+ 11 Kí o fún wọn lésì pé, ‘“Nítorí pé àwọn baba ńlá yín fi mí sílẹ̀,”+ ni Jèhófà wí, “wọ́n ń tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, wọ́n ń sìn wọ́n, wọ́n sì ń forí balẹ̀ fún wọn.+ Ńṣe ni wọ́n fi mí sílẹ̀, wọn kò sì pa òfin mi mọ́.+ 12 Ẹ ti ṣe ohun tó burú gan-an ju ti àwọn baba ńlá yín lọ,+ gbogbo yín ya alágídí, ẹ sì ń ṣe ohun tí ọkàn búburú yín sọ dípò kí ẹ máa ṣègbọràn sí mi.+ 13 Nítorí náà, màá lé yín jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí sí ilẹ̀ tí ẹ̀yin tàbí àwọn baba ńlá yín kò mọ̀,+ ibẹ̀ ni ẹ ó ti sin àwọn ọlọ́run míì tọ̀sántòru,+ torí mi ò ní ṣojú rere sí yín.”’
14 “‘Síbẹ̀, ìgbà kan ń bọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘tí wọn ò ní máa sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, ẹni tó mú àwọn èèyàn Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì!”+ 15 kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n á máa sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, ẹni tó mú àwọn èèyàn Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ àríwá àti gbogbo ilẹ̀ tó tú wọn ká sí!” màá sì mú wọn pa dà wá sí ilẹ̀ wọn, èyí tí mo fún àwọn baba ńlá wọn.’+
16 ‘Wò ó, màá ránṣẹ́ pe ọ̀pọ̀ apẹja,’ ni Jèhófà wí,
‘Wọ́n á sì mú wọn bí ẹja.
Lẹ́yìn ìyẹn, màá ránṣẹ́ pe ọ̀pọ̀ ọdẹ,
Wọ́n á sì máa dọdẹ wọn kiri lórí gbogbo òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèké
Àti nínú àwọn pàlàpálá àpáta.
17 Nítorí ojú mi wà lára gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe.*
Wọn ò pa mọ́ lójú mi,
Bẹ́ẹ̀ ni àṣìṣe wọn kò ṣókùnkùn sí mi.
18 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, màá san ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tó yẹ wọ́n nítorí àṣìṣe wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn,+
Nítorí wọ́n ti fi àwọn ère aláìlẹ́mìí* ti òrìṣà ẹ̀gbin wọn sọ ilẹ̀ mi di aláìmọ́
Wọ́n sì ti fi àwọn ohun ìríra wọn kún inú ogún mi.’”+
19 Jèhófà, ìwọ ni okun mi àti ibi ààbò mi,
Ibi tí mò ń sá sí ní ọjọ́ ìdààmú,+
Ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá láti gbogbo ìkángun ayé,
Wọ́n á sì sọ pé: “Kìkìdá èké ni àwọn baba ńlá wa jogún,
Asán àti àwọn nǹkan tí kò wúlò fún ohunkóhun.”+
20 Ǹjẹ́ èèyàn lè ṣe àwọn ọlọ́run fún ara rẹ̀
Nígbà tí wọn kì í ṣe ọlọ́run ní ti gidi?+
21 “Nítorí náà, màá jẹ́ kí wọ́n mọ̀,
Lọ́tẹ̀ yìí, màá jẹ́ kí wọ́n mọ agbára àti okun mi,
Wọ́n á sì gbà pé Jèhófà ni orúkọ mi.”
17 “Ẹ̀ṣẹ̀ Júdà ni a ti fi kálàmù* irin kọ sílẹ̀.
A ti fi ṣóńṣó dáyámọ́ǹdì fín in sára wàláà ọkàn wọn
Àti sára àwọn ìwo pẹpẹ wọn,
2 Nígbà tí àwọn ọmọ wọn rántí pẹpẹ wọn àti òpó òrìṣà* wọn+
Lẹ́gbẹ̀ẹ́ igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, lórí àwọn ibi tó ga,+
3 Lórí àwọn òkè ní àwọn ìgbèríko tó tẹ́jú.
Àwọn ohun àmúṣọrọ̀ rẹ, gbogbo ìṣúra rẹ ni màá jẹ́ kí wọ́n kó lọ+
Títí kan àwọn ibi gíga rẹ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí o dá ní gbogbo ìpínlẹ̀ rẹ.+
4 Ìwọ fúnra rẹ máa yọ̀ǹda ogún tí mo fún ọ.+
Yóò máa jó títí lọ.”
5 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
6 Yóò dà bí igi tó dá wà ní aṣálẹ̀.
Kò ní rí i nígbà tí ohun rere bá dé,
Ṣùgbọ́n àwọn ibi tó gbẹ nínú aginjù ni yóò máa gbé,
Ní ilẹ̀ iyọ̀ tí kò sí ẹnì kankan tó lè gbé ibẹ̀.
8 Yóò dà bí igi tí a gbìn sí etí omi,
Tó na gbòǹgbò rẹ̀ sínú odò.
Kò ní mọ̀ ọ́n lára nígbà tí ooru bá dé,
Ṣùgbọ́n àwọn ewé rẹ̀ yóò máa tutù yọ̀yọ̀ ní gbogbo ìgbà.+
Ní ọdún ọ̀gbẹlẹ̀, kò ní ṣàníyàn,
Bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní yéé so èso.
9 Ọkàn ń tanni jẹ* ju ohunkóhun lọ, kò sóhun tí kò lè ṣe.*+
Ta ló lè mọ̀ ọ́n?
10 Èmi, Jèhófà, ń wá inú ọkàn,+
Mo sì ń ṣàyẹ̀wò èrò inú,*
Kí n lè san èrè fún ẹnì kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀
Àti gẹ́gẹ́ bí èso iṣẹ́ rẹ̀.+
Wọ́n á fi í sílẹ̀ ní ọ̀sán gangan ayé rẹ̀,
Ní ìkẹyìn, á wá hàn pé òmùgọ̀ ni.”
12 Ìtẹ́ ológo tí a gbé ga láti ìbẹ̀rẹ̀,
Ni ibi mímọ́ wa jẹ́.+
13 Jèhófà, ìwọ ni ìrètí Ísírẹ́lì,
Ojú máa ti gbogbo àwọn tó bá fi ọ́ sílẹ̀.
Àwọn tó bá pẹ̀yìn dà lọ́dọ̀ rẹ* ni a ó kọ orúkọ wọn sórí eruku ilẹ̀,+
Torí pé wọ́n ti fi Jèhófà sílẹ̀, ẹni tó jẹ́ orísun omi ìyè.+
14 Wò mí sàn, Jèhófà, ara mi á sì dá.
Gbà mí là, màá sì rí ìgbàlà,+
Nítorí ìwọ ni èmi yóò máa yìn.
15 Wò ó! Àwọn kan ń sọ fún mi pé:
“Ọ̀rọ̀ Jèhófà dà?+
Jọ̀wọ́, jẹ́ kó wá!”
16 Ṣùgbọ́n ní tèmi, mi ò sá kúrò lẹ́yìn rẹ bí mo ti ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn,
Mi ò sì máa retí pé kí ọjọ́ àjálù dé.
Gbogbo ohun tí mo fi ètè mi sọ lo mọ̀ dáadáa;
Ìṣojú rẹ ni gbogbo rẹ̀ wáyé!
17 Má ṣe jẹ́ ohun ẹ̀rù fún mi.
Ìwọ ni ibi ààbò mi ní ọjọ́ àjálù.
18 Jẹ́ kí ojú ti àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi,+
Àmọ́ má ṣe jẹ́ kí ojú tì mí.
Jẹ́ kí jìnnìjìnnì bá wọn,
Àmọ́ má ṣe jẹ́ kí jìnnìjìnnì bá mi.
19 Ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí: “Lọ, kí o sì dúró ní ẹnubodè àwọn ọmọ èèyàn náà, èyí tí àwọn ọba Júdà ń gbà wọlé, tí wọ́n sì ń gbà jáde àti ní gbogbo ẹnubodè Jerúsálẹ́mù.+ 20 Sọ fún wọn pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin ọba Júdà àti gbogbo ẹ̀yin èèyàn Júdà pẹ̀lú gbogbo ẹ̀yin tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù, tí ẹ̀ ń gba àwọn ẹnubodè yìí wọlé. 21 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ẹ ṣọ́ ara* yín, ẹ má sì ru ẹrù èyíkéyìí ní ọjọ́ Sábáàtì tàbí kí ẹ gbé e gba àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù wọlé.+ 22 Ẹ kò gbọ́dọ̀ gbé ẹrù kankan jáde láti inú ilé yín ní ọjọ́ Sábáàtì, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.+ Ẹ jẹ́ kí ọjọ́ Sábáàtì máa jẹ́ mímọ́, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe pa á láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín.+ 23 Ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sí mi, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sílẹ̀, wọ́n ya alágídí* kí wọ́n má bàa ṣègbọràn, kí wọ́n má sì gba ìbáwí.”’+
24 “‘“Àmọ́, bí ẹ bá ṣègbọràn sí mi délẹ̀délẹ̀,” ni Jèhófà wí, “tí ẹ kò gbé ẹrù kankan gba àwọn ẹnubodè ìlú yìí wọlé ní ọjọ́ Sábáàtì, tí ẹ sì jẹ́ kí ọjọ́ Sábáàtì máa jẹ́ mímọ́ ní ti pé ẹ kò ṣe iṣẹ́ kankan lọ́jọ́ náà,+ 25 nígbà náà, àwọn ọba àti àwọn ìjòyè, tí wọ́n jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì,+ tí wọ́n gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn ẹṣin, àwọn àti àwọn ìjòyè wọn, àwọn èèyàn Júdà àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù, máa gba àwọn ẹnubodè ìlú yìí wọlé,+ àwọn èèyàn á sì máa gbé inú ìlú yìí títí láé. 26 Àwọn èèyàn á sì wá láti àwọn ìlú Júdà àti láti àyíká Jerúsálẹ́mù àti láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì+ àti láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ + àti láti àwọn agbègbè olókè àti láti Négébù.* Wọ́n á máa mú odindi ẹbọ sísun + àti ẹbọ+ àti ọrẹ ọkà+ àti oje igi tùràrí wá, wọ́n á sì máa mú ẹbọ ìdúpẹ́ wá sínú ilé Jèhófà.+
27 “‘“Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá ṣègbọràn sí àṣẹ tí mo pa pé kí ẹ jẹ́ kí ọjọ́ Sábáàtì máa jẹ́ mímọ́, tí ẹ̀ ń ru ẹrù, tí ẹ sì ń gbé e gba àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ Sábáàtì, ṣe ni màá sọ iná sí àwọn ẹnubodè rẹ̀, ó sì dájú pé á jó àwọn ilé gogoro tó láàbò ní Jerúsálẹ́mù run,+ a kò sì ní pa iná náà.”’”+
18 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jeremáyà sọ nìyí, ó ní: 2 “Dìde, kí o sì lọ sí ilé amọ̀kòkò,+ ibẹ̀ sì ni màá ti jẹ́ kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.”
3 Torí náà, mo lọ sí ilé amọ̀kòkò, ó sì ń ṣiṣẹ́ lórí àgbá kẹ̀kẹ́ amọ̀kòkò. 4 Àmọ́, ohun tí amọ̀kòkò ń fi amọ̀ ṣe bà jẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Amọ̀kòkò náà wá fi ṣe ohun míì, bó ṣe dáa lójú rẹ̀.*
5 Ìgbà náà ni Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 6 “‘Ṣé mi ò lè ṣe yín bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe ni, ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì?’ ni Jèhófà wí. ‘Wò ó! Bí amọ̀ ṣe rí lọ́wọ́ amọ̀kòkò, bẹ́ẹ̀ ni ẹ rí lọ́wọ́ mi, ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì.+ 7 Nígbà tí mo bá sọ pé màá fa orílẹ̀-èdè kan tàbí ìjọba kan tu, tí mo sọ pé màá ya á lulẹ̀, tí màá sì pa á run,+ 8 bí orílẹ̀-èdè náà bá jáwọ́ nínú ìwà burúkú rẹ̀ tí mo kìlọ̀ fún un, èmi náà á pèrò dà* lórí àjálù tí mo ti sọ pé màá jẹ́ kó dé bá a.+ 9 Àmọ́, tí mo bá sọ pé màá kọ́ orílẹ̀-èdè kan tàbí ìjọba kan, tí mo sọ pé màá gbìn ín, 10 tó bá ṣe ohun tó burú lójú mi, tí kò sì ṣègbọràn sí ohùn mi, ńṣe ni màá pèrò dà* nípa ohun rere tí mo sọ pé màá ṣe fún un.’
11 “Ní báyìí, jọ̀wọ́ sọ fún àwọn èèyàn Júdà àti àwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Wò ó, mò ń ṣètò àjálù kan fún yín, mo sì ń pète ohun kan fún yín. Torí náà, ẹ jọ̀wọ́, ẹ yí pa dà kúrò ní ọ̀nà búburú yín, kí ẹ sì tún ọ̀nà yín àti ìwà yín ṣe.”’”+
12 Àmọ́ wọ́n sọ pé: “Kò sí ìrètí!+ Torí pé tinú wa la máa ṣe, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa ya alágídí, tí á sì máa ṣe ohun tí ọkàn burúkú rẹ̀ ń sọ.”+
13 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Ẹ jọ̀wọ́, ẹ béèrè lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.
Ta ló ti gbọ́ irú èyí rí?
Wúńdíá Ísírẹ́lì ti ṣe ohun tó burú jù lọ.+
14 Ṣé yìnyín lè yọ́ kúrò lára àwọn àpáta tó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Lẹ́bánónì?
Tàbí ṣé omi tútù tó ń ṣàn bọ̀ láti ibi tó jìnnà lè gbẹ?
15 Àmọ́ àwọn èèyàn mi ti gbàgbé mi.+
Torí pé wọ́n ń rú ẹbọ* sí àwọn ohun tí kò ní láárí,+
Wọ́n ń mú kí àwọn èèyàn fẹsẹ̀ kọ ní ọ̀nà wọn, àwọn ojú ọ̀nà àtijọ́,+
Láti rìn ní ọ̀nà gbágungbàgun, ọ̀nà tí kò dán, tí kò sì tẹ́jú,*
16 Láti sọ ilẹ̀ wọn di ohun àríbẹ̀rù+
Tí á sì di ohun àrísúfèé títí láé.+
Gbogbo ẹni tó bá ń gba ibẹ̀ kọjá á wò ó, ẹ̀rù á bà á, á sì mi orí rẹ̀.+
17 Màá tú wọn ká níwájú ọ̀tá bí ẹ̀fúùfù láti ìlà oòrùn.
Ẹ̀yìn ni màá kọ sí wọn, mi ò ní kọ ojú sí wọn, ní ọjọ́ àjálù wọn.”+
18 Wọ́n sì sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gbìmọ̀ ibi sí Jeremáyà,+ nítorí òfin* kò ní kúrò lọ́dọ̀ àwọn àlùfáà, ìmọ̀ràn kò sì ní kúrò lọ́dọ̀ àwọn amòye, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò ní kúrò lọ́dọ̀ àwọn wòlíì. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a sọ̀rọ̀ burúkú sí i,* kí a má sì fiyè sí ohun tó ń sọ.”
19 Fiyè sí mi, Jèhófà,
Sì fetí sí ohun tí àwọn alátakò mi ń sọ.
20 Ṣé ó yẹ kéèyàn fi ibi san ire?
Nítorí wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún ẹ̀mí* mi.+
Rántí bí mo ṣe dúró níwájú rẹ láti sọ ohun tó dáa nípa wọn,
Kí o lè yí ìbínú rẹ kúrò lórí wọn.
21 Torí náà, fi àwọn ọmọ wọn fún ìyàn,
Sì fi àwọn fúnra wọn fún idà.+
Kí àwọn ìyàwó wọn ṣòfò ọmọ, kí wọ́n sì di opó.+
Kí àjàkálẹ̀ àrùn pa àwọn ọkùnrin wọn,
Kí idà sì pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn lójú ogun.+
22 Jẹ́ kí a gbọ́ igbe ẹkún láti inú ilé wọn
Nígbà tí o bá mú àwọn jàǹdùkú* wá bá wọn lójijì.
Nítorí wọ́n ti gbẹ́ kòtò láti fi mú mi
Wọ́n sì ti dẹ pańpẹ́ fún ẹsẹ̀ mi.+
23 Ṣùgbọ́n, ìwọ Jèhófà,
O mọ gbogbo ètekéte wọn dáadáa, bí wọ́n ṣe fẹ́ pa mí.+
Má bo àṣìṣe wọn,
Má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúrò níwájú rẹ.
19 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Lọ ra ṣágo* amọ̀ lọ́dọ̀ amọ̀kòkò.+ Mú lára àwọn àgbààgbà àwọn èèyàn náà àti lára àwọn àgbààgbà nínú àwọn àlùfáà, 2 kí o sì jáde lọ sí Àfonífojì Ọmọ Hínómù,+ tó wà ní ibi àtiwọ Ẹnubodè Èéfọ́ Ìkòkò. Ibẹ̀ sì ni kí o ti kéde àwọn ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún ọ. 3 Kí o sọ pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin ọba Júdà àti ẹ̀yin tó ń gbé Jerúsálẹ́mù. Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí:
“‘“Màá tó mú àjálù kan wá bá ibí yìí, etí ẹnikẹ́ni tó bá sì gbọ́ nípa rẹ̀ máa hó yee. 4 Nítorí pé wọ́n ti fi mí sílẹ̀,+ wọ́n sì ti sọ ibí yìí di ibi tí kò ṣeé dá mọ̀.+ Ibẹ̀ ni wọ́n ti ń rú ẹbọ sí àwọn ọlọ́run míì, tí àwọn pẹ̀lú àwọn baba ńlá wọn àti àwọn ọba Júdà kò mọ̀, wọ́n sì ti fi ẹ̀jẹ̀ àwọn aláìṣẹ̀ kún ibí yìí.+ 5 Wọ́n kọ́ àwọn ibi gíga Báálì láti sun àwọn ọmọ wọn nínú iná bí odindi ẹbọ sísun sí Báálì,+ ohun tí mi ò pa láṣẹ tàbí sọ nípa rẹ̀, tí kò sì wá sí mi lọ́kàn rí.”’*+
6 “‘“Nítorí náà, wò ó! ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “tí a kò ní pe ibí yìí ní Tófétì tàbí Àfonífojì Ọmọ Hínómù mọ́, àmọ́ Àfonífojì Ìpànìyàn la ó máa pè é.+ 7 Màá sọ ohun tí Júdà àti Jerúsálẹ́mù ń gbèrò di asán ní ibí yìí, màá jẹ́ kí àwọn ọ̀tá fi idà pa wọ́n, màá sì jẹ́ kí àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí* wọn rí wọn pa. Màá jẹ́ kí òkú wọn di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko orí ilẹ̀.+ 8 Màá sọ ìlú yìí di ohun àríbẹ̀rù àti ohun àrísúfèé. Gbogbo ẹni tó bá ń gba ibẹ̀ kọjá á wò ó, ẹ̀rù á bà á, á sì súfèé nítorí ìyọnu rẹ̀.+ 9 Màá sì mú kí wọ́n jẹ ẹran ara àwọn ọmọkùnrin wọn àti ti àwọn ọmọbìnrin wọn, kálukú wọn á sì jẹ ẹran ara ọmọnìkejì rẹ̀, nítorí ogun tó dó tì wọ́n àti ìdààmú tó bá wọn nígbà tí àwọn ọ̀tá wọn àti àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí* wọn há wọn mọ́.”’+
10 “Lẹ́yìn náà, fọ́ ṣágo náà mọ́lẹ̀ lójú àwọn ọkùnrin tó tẹ̀ lé ọ lọ, 11 kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Bí màá ṣe fọ́ àwọn èèyàn yìí àti ìlú yìí nìyẹn bí ìgbà tí èèyàn fọ́ ohun tí amọ̀kòkò ṣe mọ́lẹ̀, tí kò fi ní àtúnṣe mọ́. Wọ́n á sì sin òkú ní Tófétì títí kò fi ní sí àyè mọ́ láti sìnkú.”’+
12 “‘Ohun tí màá ṣe sí ibí yìí rèé,’ ni Jèhófà wí, ‘àti sí àwọn tó ń gbé ibẹ̀, láti ṣe ìlú yìí bíi Tófétì. 13 Àwọn ilé Jerúsálẹ́mù àti ilé àwọn ọba Júdà á sì di aláìmọ́ bí ibí yìí, bíi Tófétì,+ àní títí kan gbogbo ilé tí wọ́n ń rú ẹbọ ní òrùlé rẹ̀ sí gbogbo ọmọ ogun ọ̀run,+ tí wọ́n sì ti ń da ọrẹ ohun mímu sí àwọn ọlọ́run míì.’”+
14 Nígbà tí Jeremáyà dé láti Tófétì, níbi tí Jèhófà rán an lọ láti sọ tẹ́lẹ̀, ó dúró ní àgbàlá ilé Jèhófà, ó sì sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà pé: 15 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Wò ó, màá mú gbogbo àjálù tí mo sọ nípa rẹ̀ wá sórí ìlú yìí àti sórí gbogbo ìlú tó yí i ká, nítorí wọ́n ti ya alágídí,* wọn kò sì ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ mi.’”+
20 Ó ṣẹlẹ̀ pé Páṣúrì, ọmọ Ímérì, àlùfáà, tó tún jẹ́ olórí àwọn kọmíṣọ́nnà nínú ilé Jèhófà fetí sí Jeremáyà nígbà tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan yìí. 2 Ni Páṣúrì bá lu wòlíì Jeremáyà, ó sì fi í sínú àbà+ tó wà ní Ẹnubodè Òkè ti Bẹ́ńjámínì, tó wà ní ilé Jèhófà. 3 Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì, nígbà tí Páṣúrì tú Jeremáyà sílẹ̀ nínú àbà, Jeremáyà sọ fún un pé:
“Jèhófà ti fún ọ lórúkọ, o kì í ṣe Páṣúrì mọ́, bí kò ṣe Ẹ̀rù Yí Mi Ká.+ 4 Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Màá sọ ọ́ di ohun ẹ̀rù sí ara rẹ àti sí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, àwọn ọ̀tá wọn á sì fi idà pa wọ́n ní ìṣojú rẹ.+ Màá fa gbogbo Júdà lé ọwọ́ ọba Bábílónì, á kó wọn lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì, á sì fi idà pa wọ́n.+ 5 Màá fi gbogbo ọrọ̀ ìlú yìí, gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun iyebíye rẹ̀ àti gbogbo ìṣúra àwọn ọba Júdà lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́.+ Wọ́n á gba tọwọ́ wọn, wọ́n á mú wọn, wọ́n á sì kó wọn lọ sí Bábílónì.+ 6 Ní tìrẹ, ìwọ Páṣúrì àti gbogbo àwọn tó ń gbé inú ilé rẹ, ẹ ó lọ sí oko ẹrú. Wàá lọ sí Bábílónì, ibẹ̀ ni wàá kú sí, ibẹ̀ sì ni wọ́n á sin ìwọ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ sí torí o ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún wọn.’”+
7 O ti yà mí lẹ́nu, Jèhófà, ẹnu sì yà mí.
O lo agbára rẹ lórí mi, o sì borí.+
Mo di ẹni ẹ̀sín láti àárọ̀ ṣúlẹ̀;
Gbogbo èèyàn ló ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.+
8 Nítorí nígbàkigbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ṣe ni mò ń ké jáde, tí mo sì ń kéde pé,
“Ìwà ipá àti ìparun!”
Nítorí pé ọ̀rọ̀ Jèhófà ti di ohun tó ń fa èébú àti yẹ̀yẹ́ fún mi láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.+
Àmọ́ nínú ọkàn mi, ńṣe ló dà bí iná tó ń jó, tí wọ́n sé mọ́ inú egungun mi,
Mi ò lè pa á mọ́ra mọ́,
Mi ò sì lè fara dà á mọ́.+
10 Nítorí mo ti gbọ́ ọ̀pọ̀ àhesọ ọ̀rọ̀ tó burú;
Ohun ẹ̀rù yí mi ká.+
“Ẹ fẹ̀sùn kàn án; ẹ jẹ́ ká fẹ̀sùn kàn án!”
Gbogbo àwọn tó ń sọ pé àwọn fẹ́ àlàáfíà fún mi, ìṣubú mi ni wọ́n ń wá:+
“Bóyá ó máa ṣàṣìṣe torí pé kò kíyè sára,
Tí a ó sì lè borí rẹ̀, kí a sì gbẹ̀san lára rẹ̀.”
11 Ṣùgbọ́n Jèhófà wà pẹ̀lú mi bíi jagunjagun tó ń bani lẹ́rù.+
Ìdí nìyẹn tí àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi á fi fẹsẹ̀ kọ, wọn ò sì ní borí.+
Ojú á tì wọ́n wẹ̀lẹ̀mù, torí pé wọn ò ní ṣàṣeyọrí.
Wọ́n á tẹ́ títí láé, ẹ̀tẹ́ wọn ò sì ní ṣeé gbàgbé.+
13 Ẹ kọrin sí Jèhófà! Ẹ yin Jèhófà!
Nítorí ó ti gba àwọn aláìní* sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn aṣebi.
14 Ègún ni fún ọjọ́ tí wọ́n bí mi!
Kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má gba ìbùkún! +
15 Ègún ni fún ọkùnrin tó mú ìròyìn ayọ̀ wá fún bàbá mi pé:
“Ìyàwó rẹ ti bímọ, ọkùnrin ló bí!”
Tó mú inú rẹ̀ dùn gidigidi.
16 Kí ọkùnrin yẹn dà bí àwọn ìlú tí Jèhófà wó lulẹ̀ láìkẹ́dùn.
Kí ó gbọ́ igbe ẹkún ní òwúrọ̀ àti ìró ogun ní ọ̀sán gangan.
17 Kí nìdí tí ò kúkú fi pa mí nígbà tí mo wà nínú ikùn,
Kí inú ìyá mi lè di ibi ìsìnkú mi
Kí oyún wà nínú ikùn rẹ̀ nígbà gbogbo?+
18 Kí nìdí tí mo fi jáde kúrò nínú ikùn
Láti rí ìdààmú àti ẹ̀dùn ọkàn,
Láti mú kí àwọn ọjọ́ mi dópin nínú ìtìjú?+
21 Jeremáyà gbọ́ ọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ Jèhófà, nígbà tí Ọba Sedekáyà+ rán Páṣúrì+ ọmọ Málíkíjà àti Sefanáyà+ ọmọ Maaseáyà, àlùfáà sí i, pé: 2 “Jọ̀wọ́ bá wa wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, torí pé Nebukadinésárì* ọba Bábílónì ń bá wa jà.+ Bóyá Jèhófà á ṣe ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ àrà rẹ̀ nítorí wa, kí ọba yìí lè pa dà lẹ́yìn wa.”+
3 Jeremáyà sọ fún wọn pé: “Ẹ sọ fún Sedekáyà pé, 4 ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Wò ó, màá jẹ́ kí àwọn ohun ìjà tó wà ní ọwọ́ yín dojú kọ yín,* àwọn ohun tí ẹ fi ń bá ọba Bábílónì jà+ pẹ̀lú àwọn ará Kálídíà tí wọ́n dó tì yín lẹ́yìn odi. Màá sì kó wọn jọ sí àárín ìlú yìí. 5 Èmi fúnra mi máa na apá mi àti ọwọ́ mi tó lágbára jáde láti bá yín jà+ pẹ̀lú ìbínú àti ìrunú àti ìkannú ńlá.+ 6 Màá pa àwọn tó ń gbé ìlú yìí, látorí èèyàn dórí ẹranko. Àjàkálẹ̀ àrùn* ńlá ni yóò sì pa wọ́n.”’+
7 “‘Jèhófà sọ pé, “Lẹ́yìn náà, màá fi Sedekáyà ọba Júdà àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn èèyàn ìlú yìí, ìyẹn àwọn tó bọ́ lọ́wọ́ àjàkálẹ̀ àrùn, idà àti ìyàn, lé ọwọ́ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn àti lé ọwọ́ àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí wọn.*+ Á fi idà pa wọ́n. Kò ní bá wọn kẹ́dùn, bẹ́ẹ̀ ni kò ní yọ́nú sí wọn tàbí kó ṣàánú wọn.”’+
8 “Kí o sì sọ fún àwọn èèyàn yìí pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Wò ó, mò ń fi ọ̀nà ìyè àti ọ̀nà ikú síwájú yín. 9 Idà àti ìyàn pẹ̀lú àjàkálẹ̀ àrùn ni yóò pa àwọn tó bá dúró nínú ìlú yìí. Àmọ́ ẹni tó bá jáde, tó sì fi ara rẹ̀ lé ọwọ́ àwọn ará Kálídíà tí wọ́n dó tì yín, á máa wà láàyè, á sì jèrè ẹ̀mí rẹ̀.”’*+
10 “‘“Nítorí mo ti dojú mi kọ ìlú yìí láti mú àjálù bá a, kì í ṣe fún ire,”+ ni Jèhófà wí. “Màá fi lé ọba Bábílónì lọ́wọ́,+ á sì dáná sun ún.”+
11 “‘Ẹ̀yin agbo ilé ọba Júdà: Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà. 12 Ẹ̀yin ilé Dáfídì, ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Ẹ máa dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́ ní àràárọ̀,
Kí ẹ sì gba ẹni tí àwọn oníjìbìtì jà lólè sílẹ̀,+
Kí ìbínú mi má bàa sọ bí iná+
Tó ń jó tí ẹnì kankan kò lè pa
Nítorí ìwà ibi yín.”’+
13 ‘Wò ó, mo dojú kọ ọ́, ìwọ tó ń gbé àfonífojì,*
Ìwọ àpáta tó wà ní ilẹ̀ tó tẹ́jú,’ ni Jèhófà wí.
‘Ní ti ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ pé: “Ta ló lè wá bá wa jà?
Ta ló sì lè ya wọnú àwọn ibùgbé wa?”
14 Màá mú kí ẹ jíhìn
Gẹ́gẹ́ bí ìṣe yín,’+ ni Jèhófà wí.
‘Màá dáná sun igbó rẹ̀,
Á sì jó gbogbo ohun tó yí i ká run.’”+
22 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Lọ sí ilé* ọba Júdà, kí o sì jẹ́ iṣẹ́ yìí. 2 Kí o sọ pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ìwọ ọba Júdà tí o jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì, ìwọ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti àwọn èèyàn rẹ, àwọn tó ń gba àwọn ẹnubodè yìí wọlé. 3 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ẹ máa dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, kí ẹ sì máa ṣe òdodo. Ẹ gba ẹni tí àwọn oníjìbìtì jà lólè sílẹ̀. Ẹ má ṣe ni àjèjì èyíkéyìí lára, ẹ má ṣèkà sí ọmọ aláìníbaba* èyíkéyìí tàbí opó.+ Ẹ má sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí.+ 4 Torí bí ẹ bá ṣe ohun tí mo sọ yìí tọkàntọkàn, nígbà náà àwọn ọba tó ń jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì+ máa gba àwọn ẹnubodè ilé yìí wọlé, àwọn àti àwọn ìránṣẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn èèyàn wọn á gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn ẹṣin.”’+
5 “‘Àmọ́ bí ẹ ò bá ṣe ohun tí mo sọ yìí, mo fi ara mi búra pé, ilé yìí máa di ahoro,’+ ni Jèhófà wí.
6 “Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nípa ilé ọba Júdà nìyí,
‘Bíi Gílíádì lo rí sí mi,
Bí orí òkè Lẹ́bánónì.
Ṣùgbọ́n màá sọ ọ́ di aginjù;
Kò ní sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú rẹ tó máa ṣeé gbé.+
Wọ́n á gé àwọn tó dára jù lọ lára igi kédárì rẹ lulẹ̀
Wọ́n á sì mú kí wọ́n ṣubú sínú iná.+
8 “‘Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè máa kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìlú yìí, wọ́n á sì bi ara wọn pé: “Kí nìdí tí Jèhófà fi ṣe irú èyí sí ìlú ńlá yìí?”+ 9 Wọ́n á fèsì pé: “Torí pé wọ́n fi májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run wọn sílẹ̀, wọ́n forí balẹ̀ fún àwọn ọlọ́run míì, wọ́n sì ń sìn wọ́n.”’+
10 Ẹ má sunkún nítorí ẹni tó ti kú,
Ẹ má sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀.
Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ nítorí ẹni tó ń lọ,
Torí kò ní pa dà mọ́ láti rí ilẹ̀ tí wọ́n bí i sí.
11 “Èyí ni ohun tí Jèhófà sọ nípa Ṣálúmù*+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà tó ń jọba nípò Jòsáyà bàbá rẹ̀,+ ẹni tó jáde kúrò ní ibí yìí: ‘Kò ní pa dà mọ́. 12 Nítorí ibi tí wọ́n mú un lọ ní ìgbèkùn ló máa kú sí, kò sì ní rí ilẹ̀ yìí mọ́.’+
13 Ẹni tó ń fi àìṣòdodo kọ́ ilé rẹ̀ ti gbé!
Tó ń fi àìṣẹ̀tọ́ kọ́ àwọn yàrá òkè rẹ̀,
Tó ń mú kí ọmọnìkejì rẹ̀ sìn ín láìgba nǹkan kan,
Tí kò sì fún un ní owó iṣẹ́ rẹ̀;+
14 Ẹni tó sọ pé, ‘Màá kọ́ ilé ńlá fún ara mi
Tí àwọn yàrá òkè rẹ̀ tóbi.
Màá ṣe àwọn fèrèsé* sí i
Màá fi igi kédárì bò ó, màá sì fi ọ̀dà tó pupa fòò kùn ún.’
15 Ṣé wàá máa ṣàkóso lọ torí pé àwọn igi kédárì tí ò ń lò pọ̀ ju ti àwọn míì lọ ni?
16 Ó gbèjà ẹ̀tọ́ àwọn tí ìyà ń jẹ àti àwọn aláìní,
Nǹkan sì lọ dáadáa.
‘Ǹjẹ́ kì í ṣe ohun tó fi hàn pé ẹnì kan mọ̀ mí nìyẹn?’ ni Jèhófà wí.
17 ‘Àmọ́ ojú rẹ àti ọkàn rẹ ò kúrò lórí bí o ṣe máa jẹ èrè tí kò tọ́,
Lórí bí o ṣe máa ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀
Àti lórí bí o ṣe máa lu jìbìtì àti bí o ṣe máa lọ́ni lọ́wọ́ gbà.’
18 “Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nípa Jèhóákímù+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà nìyí,
‘Wọn kò ní ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ pé:
“Áà, arákùnrin mi! Áà, arábìnrin mi!”
Wọn kò sì ní ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ pé:
“Áà, ọ̀gá! Áà, kábíyèsí!”
19 Bí wọ́n ṣe ń sin kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni wọ́n máa sin ín,+
Wọ́n á wọ́ ọ kiri, wọ́n á sì gbé e sọ nù,
Sí ìta ẹnubodè Jerúsálẹ́mù.’+
20 Gòkè lọ sí Lẹ́bánónì kí o sì ké,
Gbé ohùn rẹ sókè ní Báṣánì,
Sì ké láti Ábárímù,+
Torí pé gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ àtàtà ni wọ́n ti pa.+
21 Mo bá ọ sọ̀rọ̀ nígbà tí o rò pé kò séwu.
Àmọ́, o sọ pé, ‘Mi ò ní ṣègbọràn.’+
Bí o ṣe máa ń ṣe nìyẹn láti ìgbà èwe rẹ,
Nítorí ìwọ kò ṣègbọràn sí ohùn mi.+
Ìgbà yẹn ni ojú máa tì ọ́, wàá sì di ẹni ẹ̀tẹ́ nítorí gbogbo àjálù rẹ.
23 Ẹ̀yin tó ń gbé ní Lẹ́bánónì,+
Tí ìtẹ́ yín wà láàárín igi kédárì,+
Ẹ wo bí ẹ ó ti kérora tó nígbà tí ìrora bá dé bá yín,
24 “‘Bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà wí, ‘kódà bí Konáyà*+ ọmọ Jèhóákímù,+ ọba Júdà, bá tiẹ̀ jẹ́ òrùka èdìdì ní ọwọ́ ọ̀tún mi, ibẹ̀ ni màá ti yọ ọ́ kúrò! 25 Màá fi ọ́ lé ọwọ́ àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ,* lé ọwọ́ àwọn tí ò ń bẹ̀rù, lé ọwọ́ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì àti lé ọwọ́ àwọn ará Kálídíà.+ 26 Màá fi ẹ̀yin àti ìyá tó bí yín lọ́mọ sọ̀kò sí ilẹ̀ míì tí kì í ṣe ibi tí wọ́n bí yín sí, ibẹ̀ sì ni ẹ máa kú sí. 27 Wọn kò sì ní lè pa dà láé sí ilẹ̀ tí ọkàn wọn fẹ́.*+
28 Ṣé ọkùnrin yìí, Konáyà, jẹ́ ẹni ẹ̀sín, ìkòkò tó ti fọ́,
Ohun èlò tí ẹnikẹ́ni kò fẹ́?
Kí nìdí tí a fi wó òun pẹ̀lú àtọmọdọ́mọ rẹ̀ lulẹ̀
Tí a sì sọ wọ́n sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀?’+
29 “Ìwọ ilẹ̀, ilẹ̀, ilẹ̀, gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.
30 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
‘Ẹ kọ ọ́ sílẹ̀ pé ọkùnrin yìí kò bímọ,
Pé ọkùnrin yìí kò ní ṣe àṣeyọrí kankan jálẹ̀ ayé rẹ̀,*
Nítorí kò sí ìkankan nínú àtọmọdọ́mọ rẹ̀ tó máa ṣàṣeyọrí
Láti jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì kí ó sì ṣàkóso ní Júdà lẹ́ẹ̀kan sí i.’”+
23 “Ẹ gbé, ẹ̀yin olùṣọ́ àgùntàn tó ń pa àwọn àgùntàn ibi ìjẹko mi run, tí ẹ sì ń tú wọn ká!” ni Jèhófà wí.+
2 Torí náà, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ sí àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó ń bójú tó àwọn èèyàn mi nìyí: “Ẹ ti tú àwọn àgùntàn mi ká, ẹ sì ń fọ́n wọn ká ṣáá, ẹ kò sì tọ́jú wọn.”+
“Torí náà màá fìyà jẹ yín nítorí ìwà ibi yín,” ni Jèhófà wí.
3 “Ìgbà náà ni màá kó àwọn tó ṣẹ́ kù lára àgùntàn mi jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo fọ́n wọn ká sí,+ màá sì mú wọn pa dà wá sí ibi ìjẹko wọn,+ wọ́n á máa bímọ, wọ́n á sì di púpọ̀.+ 4 Màá sì gbé àwọn olùṣọ́ àgùntàn dìde lórí wọn tí á máa bójú tó wọn dáadáa.+ Ẹ̀rù ò ní bà wọ́n mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ní jáyà, kò sì sí ìkankan nínú wọn tó máa sọ nù,” ni Jèhófà wí.
5 “Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “tí màá gbé èéhù* kan tó jẹ́ olódodo dìde fún Dáfídì.+ Ọba kan máa jẹ,+ á sì fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà, á dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, á sì ṣe òdodo ní ilẹ̀ náà.+ 6 Júdà máa rí ìgbàlà ní ìgbà ayé rẹ̀,+ Ísírẹ́lì sì máa wà ní ààbò.+ Orúkọ tí a ó sì máa pè é ni, Jèhófà Ni Òdodo Wa.”+
7 “Síbẹ̀, ìgbà kan ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “tí wọn ò ní máa sọ pé: ‘Bí Jèhófà ti wà láàyè, ẹni tó mú àwọn èèyàn Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì!’+ 8 kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n á máa sọ pé: ‘Bí Jèhófà ti wà láàyè, ẹni tó mú àwọn ọmọ ilé Ísírẹ́lì jáde kúrò, tó sì mú wọn wọlé wá láti ilẹ̀ àríwá àti gbogbo ilẹ̀ tó tú wọn ká sí!’ wọ́n á sì máa gbé lórí ilẹ̀ tiwọn.”+
9 Ní ti àwọn wòlíì:
Ọkàn mi bà jẹ́ nínú mi.
Gbogbo egungun mi ń gbọ̀n.
Mo dà bí ọkùnrin tó ti mutí yó
Àti bí ọkùnrin tí wáìnì ń pa,
Nítorí Jèhófà àti nítorí àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀.
10 Nítorí àwọn alágbèrè ló kún ilẹ̀ náà;+
Nítorí ègún, ilẹ̀ náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀fọ̀+
Àwọn ibi ìjẹko inú aginjù ti gbẹ.+
Ọ̀nà wọn jẹ́ ibi, wọ́n sì ń ṣi agbára wọn lò.
11 “Nítorí pé wòlíì àti àlùfáà ti di eléèérí.*+
Kódà, mo ti rí ìwà búburú wọn nínú ilé mi,”+ ni Jèhófà wí.
12 “Nítorí náà, ọ̀nà wọn á di ibi tó ń yọ̀, tó sì ṣókùnkùn;+
A ó tì wọ́n, wọ́n á sì ṣubú.
Torí pé màá mú àjálù bá wọn
Ní ọdún ìbẹ̀wò,” ni Jèhófà wí.
13 “Mo ti rí ohun ìríra nínú àwọn wòlíì Samáríà.+
Báálì ló ń mú kí wọ́n lè sọ àsọtẹ́lẹ̀,
Wọ́n sì ń kó àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì ṣìnà.
14 Mo ti rí àwọn ohun tó burú nínú àwọn wòlíì Jerúsálẹ́mù.
Wọ́n ń ṣe àgbèrè,+ wọ́n sì ń rìn nínú èké;+
Wọ́n ń ti àwọn aṣebi lẹ́yìn,*
Wọn ò sì jáwọ́ nínú ìwà burúkú wọn.
15 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ sí àwọn wòlíì náà nìyí:
Nítorí láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì Jerúsálẹ́mù ni ìpẹ̀yìndà ti tàn káàkiri ilẹ̀ náà.”
16 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:
“Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún yín.+
Wọ́n ń tàn yín ni.*
Wọ́n sì ń sọ fún gbogbo ẹni tó ní agídí ọkàn pé,
‘Àjálù kankan kò ní bá yín.’+
18 Ta ló ti dúró láàárín àwọn èèyàn tó sún mọ́ Jèhófà
Kí ó lè rí, kí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀?
Ta ló ti fiyè sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kí ó lè gbọ́ ọ?
19 Wò ó! Ìjì Jèhófà máa fi ìbínú tú jáde;
Bí ìjì líle tó ń fẹ́ yí ká, á tú jáde sí orí àwọn ẹni burúkú.+
20 Ìbínú Jèhófà kò ní dáwọ́ dúró
Títí á fi ṣe ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀, tí á sì mú èrò rẹ̀ ṣẹ.
Ní àkókò òpin, ọ̀rọ̀ yìí á yé yín dáadáa.
21 Mi ò rán àwọn wòlíì náà, síbẹ̀ wọ́n sáré.
Mi ò bá wọn sọ̀rọ̀, síbẹ̀ wọ́n sọ tẹ́lẹ̀.+
22 Àmọ́ tó bá jẹ́ pé wọ́n wà láàárín àwọn èèyàn tó sún mọ́ mi,
Wọ́n á ti jẹ́ kí àwọn èèyàn mi gbọ́ ọ̀rọ̀ mi
Wọ́n á sì ti mú kí wọ́n yí pa dà kúrò ní ọ̀nà búburú wọn àti kúrò nínú ìwà ibi wọn.”+
23 “Ṣé tòsí nìkan ni mo ti jẹ́ Ọlọ́run,” ni Jèhófà wí, “ṣé mi kì í ṣe Ọlọ́run láti ọ̀nà jíjìn ni?”
24 “Ṣé ibì kan wà téèyàn lè sá pa mọ́ sí tí mi ò ní lè rí i?”+ ni Jèhófà wí.
“Ǹjẹ́ ohunkóhun wà láyé tàbí lọ́run tí ojú mi ò tó?”+ ni Jèhófà wí.
25 “Mo ti gbọ́ ohun tí àwọn wòlíì tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi sọ, pé, ‘Mo lá àlá! Mo lá àlá!’+ 26 Ìgbà wo ni àwọn wòlíì ò ní yéé sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké tó wà lọ́kàn wọn? Wọ́n jẹ́ àwọn wòlíì tó ń sọ ẹ̀tàn inú ọkàn wọn.+ 27 Wọ́n fẹ́ kí àwọn èèyàn mi gbàgbé orúkọ mi nípasẹ̀ àwọn àlá tí wọ́n ń rọ́ fún ọmọnìkejì wọn, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ti gbàgbé orúkọ mi nítorí Báálì.+ 28 Ẹ jẹ́ kí wòlíì tó bá lá àlá rọ́ àlá náà, ṣùgbọ́n kí ẹni tí ó ní ọ̀rọ̀ mi sọ ọ́ pẹ̀lú òtítọ́.”
“Kí ni pòròpórò ní í ṣe pẹ̀lú ọkà?” ni Jèhófà wí.
29 “Ǹjẹ́ kì í ṣe bí iná ni ọ̀rọ̀ mi rí,”+ ni Jèhófà wí “àti bí òòlù irin* tó ń fọ́ àpáta sí wẹ́wẹ́?”+
30 “Nítorí náà, mo dojú ìjà kọ àwọn wòlíì, àwọn tó ń jí ọ̀rọ̀ mi gbé lọ lọ́dọ̀ ọmọnìkejì wọn,” ni Jèhófà wí.+
31 “Wò ó, mo dojú ìjà kọ àwọn wòlíì,” ni Jèhófà wí, “àwọn tó ń fi ahọ́n wọn sọ pé, ‘Ó wí pé!’”+
32 “Wò ó, mo dojú ìjà kọ àwọn wòlíì tó ń lá àlá èké,” ni Jèhófà wí, “àwọn tó ń rọ́ àlá, tí wọ́n sì ń kó àwọn èèyàn mi ṣìnà nítorí irọ́ wọn àti bí wọ́n ṣe ń fọ́nnu.”+
“Ṣùgbọ́n mi ò rán wọn, bẹ́ẹ̀ ni mi ò pàṣẹ fún wọn. Nítorí náà, wọn ò ní ṣe àwọn èèyàn yìí láǹfààní kankan,”+ ni Jèhófà wí.
33 “Nígbà tí àwọn èèyàn yìí tàbí wòlíì tàbí àlùfáà kan bá béèrè lọ́wọ́ rẹ pé, ‘Kí ni ẹrù tó wúwo* látọ̀dọ̀ Jèhófà?’ kí o sọ fún wọn pé, ‘“Ẹ̀yin gan-an ni ẹrù tó wúwo náà! Màá sì lé yín dà nù,”+ ni Jèhófà wí.’ 34 Ní ti wòlíì tàbí àlùfáà tàbí àwọn èèyàn tó bá sọ pé, ‘Ẹrù* tó wúwo látọ̀dọ̀ Jèhófà nìyí!’ Ńṣe ni màá dojú kọ ọkùnrin yẹn àti agbo ilé rẹ̀. 35 Ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín ń sọ fún ẹnì kejì rẹ̀ àti fún arákùnrin rẹ̀ ni pé, ‘Kí ni ìdáhùn Jèhófà? Kí sì ni ohun tí Jèhófà sọ?’ 36 Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe mẹ́nu kan ẹrù* tó wúwo látọ̀dọ̀ Jèhófà mọ́, nítorí ẹrù* tó wúwo náà jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan yín, ẹ sì ti yí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run alààyè pa dà, ọ̀rọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run wa.
37 “Ohun tí wàá béèrè lọ́wọ́ wòlíì náà nìyí, ‘Kí ni Jèhófà fi dá ọ lóhùn? Kí sì ni Jèhófà sọ? 38 Bí o bá ṣì ń sọ pé “Ẹrù* tó wúwo látọ̀dọ̀ Jèhófà!” ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Nítorí ẹ̀ ń sọ pé, ‘Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ẹrù* tó wúwo látọ̀dọ̀ Jèhófà,’ lẹ́yìn tí mo ti sọ fún ọ pé, ‘Ẹ kò gbọ́dọ̀ sọ pé: “Ẹrù* tó wúwo látọ̀dọ̀ Jèhófà!”’ 39 wò ó! Màá gbé yín sókè, màá sì sọ yín nù kúrò níwájú mi, ẹ̀yin àti ìlú tí mo fún ẹ̀yin àti àwọn baba ńlá yín. 40 Ńṣe ni màá mú ìtìjú tí kò lópin àti ẹ̀tẹ́ ayérayé bá yín, èyí tí kò ní ṣeé gbàgbé.”’”+
24 Lẹ́yìn náà, Jèhófà fi apẹ̀rẹ̀ méjì tí ọ̀pọ̀tọ́ wà nínú wọn níwájú tẹ́ńpìlì Jèhófà hàn mí. Èyí wáyé lẹ́yìn tí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì mú Jekonáyà*+ ọmọ Jèhóákímù,+ ọba Júdà lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn ìjòyè Júdà àti àwọn oníṣẹ́ ọnà pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ irin.* Ó kó wọn láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì.+ 2 Ọ̀pọ̀tọ́ inú apẹ̀rẹ̀ àkọ́kọ́ dára gan-an, ó dà bí àkọ́pọ́n èso ọ̀pọ̀tọ́, àmọ́ ọ̀pọ̀tọ́ inú apẹ̀rẹ̀ kejì ti bà jẹ́ gan-an débi pé kò ṣeé jẹ.
3 Jèhófà wá bi mí pé: “Jeremáyà, kí lo rí?” Torí náà, mo sọ pé: “Èso ọ̀pọ̀tọ́ ni. Àwọn tó dára, dára gan-an, àwọn tó sì bà jẹ́ ti bà jẹ́ gan-an débi pé wọn ò ṣeé jẹ.”+
4 Ìgbà náà ni Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 5 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Bí àwọn ọ̀pọ̀tọ́ yìí ṣe dára, bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe fi ojú tó dára wo àwọn ará Júdà tó wà ní ìgbèkùn, àwọn tí mo rán lọ kúrò ní ibí yìí sí ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà. 6 Ojú mi yóò wà lára wọn láti ṣe wọ́n lóore, màá sì mú kí wọ́n pa dà sí ilẹ̀ yìí.+ Màá gbé wọn ró, mi ò sì ní ya wọ́n lulẹ̀, màá gbìn wọ́n, mi ò sì ní fà wọ́n tu.+ 7 Màá fún wọn ní ọkàn tí á jẹ́ kí wọ́n fẹ́ láti mọ̀ mí, pé èmi ni Jèhófà.+ Wọ́n á di èèyàn mi, màá sì di Ọlọ́run wọn,+ nítorí wọ́n á fi gbogbo ọkàn wọn pa dà sọ́dọ̀ mi.+
8 “‘Àmọ́ ní ti ọ̀pọ̀tọ́ tó ti bà jẹ́ débi pé kò ṣeé jẹ,+ ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Bákan náà ni màá ṣe sí Sedekáyà+ ọba Júdà àti àwọn ìjòyè rẹ̀ pẹ̀lú àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù tó wà ní ilẹ̀ yìí àti àwọn tó ń gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 9 Màá sọ wọ́n di ohun àríbẹ̀rù àti àjálù lójú gbogbo ìjọba ayé,+ màá jẹ́ kí wọ́n di ẹni ẹ̀gàn àti ẹni àfipòwe, ẹni ẹ̀sín àti ẹni ègún + ní gbogbo ibi tí màá fọ́n wọn ká sí.+ 10 Màá rán idà+ àti ìyàn pẹ̀lú àjàkálẹ̀ àrùn* sí wọn,+ títí wọ́n á fi ṣègbé kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún àwọn àti àwọn baba ńlá wọn.”’”
25 Ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà gbọ́ nípa gbogbo àwọn èèyàn Júdà ní ọdún kẹrin Jèhóákímù+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà, ìyẹn ní ọdún kìíní Nebukadinésárì* ọba Bábílónì. 2 Ohun tí wòlíì Jeremáyà sọ nípa* gbogbo àwọn èèyàn Júdà àti gbogbo àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù nìyí:
3 “Láti ọdún kẹtàlá ìjọba Jòsáyà+ ọmọ Ámọ́nì, ọba Júdà, títí di òní yìí, ọdún kẹtàlélógún rèé tí Jèhófà ti ń bá mi sọ̀rọ̀, léraléra ni mo sì ń bá yín sọ̀rọ̀,* ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sílẹ̀.+ 4 Jèhófà sì rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì sí yín, léraléra ló ń rán wọn,* ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò dẹ etí yín sílẹ̀ láti gbọ́.+ 5 Wọ́n ń sọ pé, ‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ yí pa dà, kí kálukú yín kúrò nínú ọ̀nà búburú rẹ̀ àti kúrò nínú ìwà ibi rẹ̀,+ kí ẹ lè máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ tí Jèhófà ti fún ẹ̀yin àti àwọn baba ńlá yín tipẹ́tipẹ́. 6 Ẹ má ṣe tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, ẹ má sìn wọ́n, ẹ má forí balẹ̀ fún wọn, kí ẹ má sì fi iṣẹ́ ọwọ́ yín mú mi bínú, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣe ni màá mú àjálù bá yín.’
7 “‘Ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sí mi,’ ni Jèhófà wí. ‘Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe lẹ̀ ń fi iṣẹ́ ọwọ́ yín mú mi bínú, tí èyí sì ń fa àjálù bá yín.’+
8 “Nítorí náà, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘“Nítorí pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí mi lẹ́nu, 9 Màá ránṣẹ́ pe gbogbo ìdílé tó wà ní àríwá,”+ ni Jèhófà wí, “màá ránṣẹ́ sí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, ìránṣẹ́ mi,+ màá mú wọn wá láti gbéjà ko ilẹ̀ yìí+ àti àwọn tó ń gbé lórí rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo orílẹ̀-èdè tó yí i ká.+ Màá pa wọ́n run pátápátá, màá sì sọ wọ́n di ohun àríbẹ̀rù àti ohun àrísúfèé àti ibi àwókù títí láé. 10 Màá fòpin sí ìró ayọ̀ àti ìró ìdùnnú láàárín wọn,+ màá sì tún fòpin sí ohùn ọkọ ìyàwó àti ohùn ìyàwó,+ ìró ọlọ àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà. 11 Gbogbo ilẹ̀ yìí á di àwókù àti ohun àríbẹ̀rù, àwọn orílẹ̀-èdè yìí á sì ní láti fi àádọ́rin (70) ọdún sin ọba Bábílónì.”’+
12 “‘Ṣùgbọ́n tí àádọ́rin (70) ọdún bá pé,+ màá pe ọba Bábílónì àti orílẹ̀-èdè yẹn wá jíhìn* nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,’+ ni Jèhófà wí, ‘màá sì sọ ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà di ahoro títí láé.+ 13 Màá mú gbogbo ọ̀rọ̀ mi ṣẹ sórí ilẹ̀ náà, èyí tí mo ti sọ sí i, ìyẹn gbogbo ohun tó wà nínú ìwé yìí tí Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. 14 Nítorí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba ńlá+ á sọ wọ́n di ẹrú,+ màá sì san èrè wọn pa dà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìwà àti iṣẹ́ ọwọ́ wọn.’”+
15 Nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ fún mi nìyí: “Gba ife wáìnì ìbínú yìí ní ọwọ́ mi, kí o sì mú kí gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo bá rán ọ sí mu ún. 16 Wọ́n á mu, wọ́n á ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n, wọ́n á sì máa ṣe bíi wèrè nítorí idà tí màá rán sí àárín wọn.”+
17 Torí náà, mo gba ife náà lọ́wọ́ Jèhófà, mo sì mú kí gbogbo orílẹ̀-èdè tí Jèhófà rán mi sí mu ún:+ 18 bẹ̀rẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù àti àwọn ìlú Júdà,+ àwọn ọba rẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀, láti sọ wọ́n di ahoro, ohun àríbẹ̀rù, ohun àrísúfèé àti ẹni ègún,+ bó ṣe rí lónìí, 19 lẹ́yìn náà, Fáráò ọba Íjíbítì àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ìjòyè rẹ̀ àti gbogbo èèyàn rẹ̀+ 20 àti onírúurú àjèjì tó wà láàárín wọn, gbogbo ọba ilẹ̀ Úsì, gbogbo ọba ilẹ̀ Filísínì+ àti Áṣíkẹ́lónì+ àti Gásà àti Ẹ́kírónì àti àwọn tó ṣẹ́ kù ní Áṣídódì, 21 Édómù,+ Móábù+ àti àwọn ọmọ Ámónì,+ 22 gbogbo ọba Tírè, gbogbo ọba Sídónì+ àti àwọn ọba erékùṣù tó wà ní ẹ̀gbẹ́ òkun, 23 Dédánì,+ Témà, Búsì àti gbogbo àwọn tí wọ́n gé irun wọn mọ́lẹ̀ ní ẹ̀bátí,+ 24 gbogbo ọba àwọn ará Arébíà+ àti gbogbo ọba onírúurú àjèjì tó ń gbé ní aginjù, 25 gbogbo ọba Símírì, gbogbo ọba Élámù+ àti gbogbo ọba àwọn ará Mídíà,+ 26 àti gbogbo ọba àríwá, ti tòsí àti ti ọ̀nà jíjìn, ọ̀kan tẹ̀ lé èkejì àti gbogbo ìjọba yòókù tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ọba Ṣéṣákì*+ pẹ̀lú á mu wáìnì náà lẹ́yìn wọn.
27 “Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nìyí: “Ẹ mu, kí ẹ sì yó, ẹ bì, kí ẹ sì ṣubú, tí ẹ kò fi ní lè dìde+ nítorí idà tí màá rán sáàárín yín.”’ 28 Bí wọn ò bá sì gba ife náà lọ́wọ́ rẹ láti mu ún, kí o sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Ẹ gbọ́dọ̀ mu ún! 29 Nítorí tó bá jẹ́ pé ìlú tí à ń fi orúkọ mi+ pè ni màá kọ́kọ́ mú àjálù bá, ṣé ẹ̀yin á wá lọ láìjìyà ni?”’+
“‘Ẹ ò ní lọ láìjìyà, nítorí màá pe idà wá bá gbogbo àwọn tó ń gbé láyé,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
30 “Sọ àsọtẹ́lẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún wọn, kí o sì sọ fún wọn pé,
‘Láti ibi gíga ni Jèhófà á ti bú ramúramù
Àti láti ibùgbé rẹ̀ mímọ́ ni á ti mú kí a gbọ́ ohùn rẹ̀.
Á bú ramúramù mọ́ ibi gbígbé rẹ̀.
Á hó yèè bíi ti àwọn tó ń tẹ àjàrà níbi tí wọ́n ti ń fún wáìnì,
Á sì máa kọrin ìṣẹ́gun lórí gbogbo àwọn tó ń gbé láyé.’
31 ‘Ariwo kan á dún títí dé ìkángun ayé,
Nítorí Jèhófà ní ẹjọ́ kan pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè.
Òun fúnra rẹ̀ á ṣe ìdájọ́ gbogbo àwọn èèyàn.*+
Á sì fi idà pa àwọn ẹni burúkú,’ ni Jèhófà wí.
32 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:
‘Wò ó! Àjálù kan ń ṣẹlẹ̀ kiri láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè,+
A ó sì tú ìjì líle jáde láti ibi tó jìnnà jù lọ láyé.+
33 “‘Àwọn tí Jèhófà máa pa ní ọjọ́ yẹn máa pọ̀ láti ìkángun kan ayé títí dé ìkángun kejì. A ò ní ṣọ̀fọ̀ wọn, a ò ní kó wọn jọ, bẹ́ẹ̀ ni a ò ní sin wọ́n. Wọ́n á dà bí ajílẹ̀ lórí ilẹ̀.’
34 Ẹ pohùn réré ẹkún, ẹ̀yin olùṣọ́ àgùntàn, kí ẹ sì ké!
Ẹ yíràá, ẹ̀yin ọlọ́lá inú agbo ẹran,
Nítorí ọjọ́ tí wọ́n á pa yín, tí wọ́n á sì tú yín ká ti pé,
Ẹ ó sì bọ́ lulẹ̀ bí ìgbà tí ohun èlò tó ṣeyebíye bá bọ́ lulẹ̀!
35 Àwọn olùṣọ́ àgùntàn kò rí ibì kankan sá sí,
Kò sì sí ọ̀nà láti sá àsálà fún àwọn ọlọ́lá inú agbo ẹran.
36 Ẹ fetí sílẹ̀! Ẹ gbọ́ igbe àwọn olùṣọ́ àgùntàn
Àti ìpohùnréré ẹkún àwọn ọlọ́lá inú agbo ẹran,
Nítorí Jèhófà ń ba ibi ìjẹko wọn jẹ́.
37 Ibi gbígbé tó ní àlàáfíà sì ti di aláìlẹ́mìí
Nítorí ìbínú Jèhófà tó ń jó fòfò.
38 Ó ti fi ibùgbé rẹ̀ sílẹ̀ bí ọmọ kìnnìún,*+
Torí ilẹ̀ wọn ti di ohun àríbẹ̀rù
Nítorí idà tó ń hanni léèmọ̀
Àti nítorí ìbínú rẹ̀ tó ń jó fòfò.”
26 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Jèhóákímù+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà, ọ̀rọ̀ yìí wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, pé: 2 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Dúró sí àgbàlá ilé Jèhófà, kí o sì sọ̀rọ̀ fún* gbogbo àwọn ará ìlú Júdà tó wá ń jọ́sìn* ní ilé Jèhófà. Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ ni kí o sọ fún wọn, má ṣe yọ ọ̀rọ̀ kankan kúrò. 3 Bóyá wọ́n á fetí sílẹ̀, tí kálukú wọn á yí pa dà kúrò ní ọ̀nà búburú wọn, tí màá sì pèrò dà* lórí àjálù tí mo fẹ́ mú bá wọn nítorí ìwà ibi wọn.+ 4 Sọ fún wọn pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Bí ẹ kò bá fetí sí mi láti máa tẹ̀ lé òfin* mi tí mo fún yín, 5 láti máa fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì, tí mò ń rán sí yín léraléra,* àwọn tí ẹ kì í fetí sí,+ 6 nígbà náà, ńṣe ni màá ṣe ilé yìí bíi Ṣílò,+ màá sì sọ ìlú yìí di ibi ègún lójú gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé.’”’”+
7 Àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì àti gbogbo èèyàn náà sì gbọ́ tí Jeremáyà ń sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ilé Jèhófà.+ 8 Nígbà tí Jeremáyà parí gbogbo ohun tí Jèhófà pàṣẹ fún un pé kó sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà, ńṣe ni àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì pẹ̀lú gbogbo àwọn èèyàn náà gbá a mú, wọ́n sì sọ pé: “Ó dájú pé o máa kú. 9 Kí nìdí tí o fi sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ Jèhófà, pé, ‘Ilé yìí máa dà bíi Ṣílò, ìlú yìí á sì di ahoro tí kò ní sí ẹnì kankan tí á máa gbé ibẹ̀’?” Gbogbo àwọn èèyàn náà sì pé jọ yí Jeremáyà ká ní ilé Jèhófà.
10 Nígbà tí àwọn ìjòyè Júdà gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n wá láti ilé* ọba sí ilé Jèhófà, wọ́n sì jókòó sí ibi àtiwọ ẹnubodè tuntun ti Jèhófà.+ 11 Àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì sì sọ fún àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn èèyàn náà pé: “Ikú tọ́ sí ọkùnrin yìí,+ nítorí ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìlú yìí, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fi etí ara yín gbọ́ ọ.”+
12 Jeremáyà wá sọ fún gbogbo àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn èèyàn náà pé: “Jèhófà ló rán mi láti sọ gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tí ẹ ti gbọ́ nípa ilé yìí àti nípa ìlú yìí.+ 13 Torí náà, ẹ tún ọ̀nà àti ìwà yín ṣe, ẹ sì ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín, Jèhófà sì máa pèrò dà* lórí àjálù tó ti sọ pé òun máa mú bá yín.+ 14 Àmọ́ ní tèmi, èmi rèé lọ́wọ́ yín. Ẹ ṣe ohunkóhun tó bá dáa, tó sì tọ́ lójú yín sí mi. 15 Àmọ́, kó dá yín lójú pé, bí ẹ bá pa mí, ẹ ó mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ wá sórí ara yín àti sórí ìlú yìí àti sórí àwọn tó ń gbé ibẹ̀, torí pé òótọ́ ni Jèhófà rán mi sí yín pé kí n sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí létí yín.”
16 Ìgbà náà ni àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn èèyàn náà sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì pé: “Ikú kò tọ́ sí ọkùnrin yìí, torí ó bá wa sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa.”
17 Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan lára àwọn àgbààgbà ilẹ̀ náà dìde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwùjọ* àwọn èèyàn náà pé: 18 “Míkà+ ti Móréṣétì sọ tẹ́lẹ̀ nígbà ayé Hẹsikáyà+ ọba Júdà, ó sì sọ fún gbogbo èèyàn Júdà pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:
“Wọ́n á túlẹ̀ Síónì bíi pápá,
Jerúsálẹ́mù á di àwókù,+
19 “Ṣé Ọba Hẹsikáyà ti Júdà àti gbogbo àwọn èèyàn Júdà wá pa á ni? Ǹjẹ́ kò bẹ̀rù Jèhófà, tó sì bẹ Jèhófà pé kó ṣojú rere sí òun,* tí Jèhófà fi pèrò dà* lórí àjálù tó sọ pé òun máa mú bá wọn?+ Nítorí náà, àjálù ńlá ni a fẹ́ fà wá bá ara* wa yìí o.
20 “Ọkùnrin kan tún wà tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ Jèhófà, Úríjà ọmọ Ṣemáyà láti Kiriati-jéárímù,+ tí ọ̀rọ̀ tó sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìlú yìí àti ilẹ̀ yìí dà bíi ti Jeremáyà. 21 Ọba Jèhóákímù+ àti gbogbo àwọn ọkùnrin rẹ̀ alágbára àti gbogbo ìjòyè sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọba sì wá ọ̀nà láti pa á.+ Nígbà tí Úríjà gbọ́ nípa rẹ̀, lójú ẹsẹ̀, ẹ̀rù bà á, ó sì sá lọ sí Íjíbítì. 22 Ni Ọba Jèhóákímù bá rán Élínátánì+ ọmọ Ákíbórì àti àwọn ọkùnrin míì pẹ̀lú rẹ̀ lọ sí Íjíbítì. 23 Wọ́n mú Úríjà wá láti Íjíbítì, wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ Ọba Jèhóákímù, ó fi idà pa á,+ ó sì ju òkú rẹ̀ sí ibi tí wọ́n ń sin àwọn èèyàn lásán sí.”
24 Àmọ́ Áhíkámù+ ọmọ Ṣáfánì+ ran Jeremáyà lọ́wọ́, kí wọ́n má bàa fi í lé àwọn èèyàn náà lọ́wọ́ láti pa á.+
27 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Jèhóákímù ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà, Jeremáyà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí látọ̀dọ̀ Jèhófà: 2 “Ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí, ‘Ṣe àwọn ọ̀já àti àwọn ọ̀pá àjàgà fún ara rẹ, kí o sì fi wọ́n sí ọrùn rẹ. 3 Lẹ́yìn náà, fi wọ́n ránṣẹ́ sí ọba Édómù,+ ọba Móábù,+ ọba àwọn ọmọ Ámónì,+ ọba Tírè+ àti ọba Sídónì+ nípasẹ̀ àwọn òjíṣẹ́ tó wá sí Jerúsálẹ́mù sọ́dọ̀ Sedekáyà ọba Júdà. 4 Ní kí wọ́n sọ fún ọ̀gá wọn, pé:
“‘“Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ohun tí ẹ ó sọ fún àwọn ọ̀gá yín rèé, 5 ‘Èmi ni mo dá ayé, èèyàn àti ẹranko tó wà lórí ilẹ̀ nípa agbára ńlá mi àti nípa apá mi tí mo nà jáde, mo sì ti fún ẹni tí mo fẹ́.*+ 6 Ní báyìí, mo ti fi gbogbo ilẹ̀ yìí lé ọwọ́ ìránṣẹ́ mi, Nebukadinésárì+ ọba Bábílónì, kódà mo ti fún un ní àwọn ẹran inú igbó kí wọ́n lè máa sìn ín. 7 Gbogbo orílẹ̀-èdè yóò máa sin òun àti ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ ọmọ rẹ̀, títí di àkókò tí ìjọba rẹ̀ máa dópin,+ tí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba ńlá yóò sì sọ ọ́ di ẹrú wọn.’+
8 “‘“‘Tí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba èyíkéyìí bá kọ̀ láti sin Ọba Nebukadinésárì ti Bábílónì, tí kò sì fi ọrùn rẹ̀ sábẹ́ àjàgà ọba Bábílónì, ńṣe ni màá fìyà jẹ orílẹ̀-èdè yẹn nípa idà,+ ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn,’* ni Jèhófà wí, ‘títí màá fi run wọ́n láti ọwọ́ rẹ̀.’
9 “‘“‘Torí náà, ẹ má fetí sí àwọn wòlíì yín, àwọn woṣẹ́woṣẹ́ yín, àwọn alálàá yín, àwọn onídán yín àti àwọn oníṣẹ́ oṣó yín, tí wọ́n ń sọ fún yín pé: “Ẹ kò ní sin ọba Bábílónì.” 10 Nítorí èké ni wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín, kí ẹ lè lọ jìnnà kúrò lórí ilẹ̀ yín, kí n lè fọ́n yín ká, kí ẹ sì ṣègbé.
11 “‘“‘Àmọ́, orílẹ̀-èdè tó bá fi ọrùn rẹ̀ sábẹ́ àjàgà ọba Bábílónì, tí ó sì sìn ín, ni màá jẹ́ kó dúró* sórí ilẹ̀ rẹ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘láti máa ro ó, kí ó sì máa gbé orí rẹ̀.’”’”
12 Mo tún bá Ọba Sedekáyà+ ti Júdà sọ̀rọ̀ lọ́nà kan náà pé: “Ẹ mú ọrùn yín wá sábẹ́ àjàgà ọba Bábílónì, kí ẹ sì sin òun àti àwọn èèyàn rẹ̀, kí ẹ lè máa wà láàyè.+ 13 Kí ló dé tí ẹ ó fi jẹ́ kí idà,+ ìyàn+ àti àjàkálẹ̀ àrùn+ pa yín bí Jèhófà ti sọ nípa orílẹ̀-èdè tí kò bá sin ọba Bábílónì? 14 Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tó ń sọ fún yín pé, ‘Ẹ kò ní sin ọba Bábílónì,’+ nítorí èké ni wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín.+
15 “‘Nítorí mi ò rán wọn,’ ni Jèhófà wí, ‘ṣùgbọ́n wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi, kí n lè fọ́n yín ká, kí ẹ sì ṣègbé, ẹ̀yin àti àwọn wòlíì tó ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín.’”+
16 Mo sọ fún àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn èèyàn yìí pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yín tó ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín, pé: “Ẹ wò ó! Àwọn nǹkan èlò ilé Jèhófà ni a ó kó pa dà láti Bábílónì láìpẹ́!”+ nítorí èké ni wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín.+ 17 Ẹ má fetí sí wọn. Ẹ sin ọba Bábílónì kí ẹ sì máa wà láàyè.+ Kí ló dé tí ìlú yìí fi máa di àwókù? 18 Àmọ́ tó bá jẹ́ pé wòlíì ni wọ́n, tí ọ̀rọ̀ Jèhófà sì wà lẹ́nu wọn, ẹ jọ̀ọ́, ẹ jẹ́ kí wọ́n bẹ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, pé kí wọ́n má ṣe kó àwọn nǹkan èlò tó ṣẹ́ kù ní ilé Jèhófà àti ní ilé* ọba Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì.’
19 “Nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí nípa àwọn òpó,+ Òkun,*+ àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù+ àti àwọn nǹkan èlò tó ṣẹ́ kù nínú ìlú yìí, 20 èyí tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì ò kó lọ nígbà tó mú Jekonáyà ọmọ Jèhóákímù, ọba Júdà, láti Jerúsálẹ́mù lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì pẹ̀lú gbogbo àwọn èèyàn pàtàkì Júdà àti Jerúsálẹ́mù.+ 21 Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nípa àwọn nǹkan èlò tó ṣẹ́ kù ní ilé Jèhófà àti ní ilé* ọba Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù nìyí: 22 ‘“Bábílónì ni a ó kó wọn wá,+ ibẹ̀ sì ni wọ́n á máa wà títí di ọjọ́ tí màá yí ojú mi sí wọn,” ni Jèhófà wí. “Ìgbà náà ni màá mú wọn pa dà wá, tí màá sì mú wọn bọ̀ sípò ní ibí yìí.”’”+
28 Ní ọdún yẹn kan náà, ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekáyà+ ọba Júdà, ní ọdún kẹrin, ní oṣù karùn-ún, wòlíì Hananáyà ọmọ Ásúrì láti Gíbíónì+ sọ fún mi ní ilé Jèhófà lójú àwọn àlùfáà àti lójú gbogbo àwọn èèyàn náà pé: 2 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Màá ṣẹ́ àjàgà ọba Bábílónì.+ 3 Kí ọdún* méjì tó pé, gbogbo nǹkan èlò ilé Jèhófà tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì kó láti ibí yìí lọ sí Bábílónì ni màá kó pa dà wá sí ibí yìí.’”+ 4 “‘Màá sì mú Jekonáyà+ ọmọ Jèhóákímù,+ ọba Júdà àti gbogbo ará Júdà tó wà ní ìgbèkùn ní Bábílónì+ pa dà wá sí ibí yìí,’ ni Jèhófà wí, ‘nítorí màá ṣẹ́ àjàgà ọba Bábílónì.’”
5 Ìgbà náà ni wòlíì Jeremáyà bá wòlíì Hananáyà sọ̀rọ̀ lójú àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn tó dúró ní ilé Jèhófà. 6 Wòlíì Jeremáyà sọ pé: “Àmín!* Kí Jèhófà ṣe bẹ́ẹ̀! Kí Jèhófà mú ọ̀rọ̀ rẹ ṣẹ pé kí àwọn nǹkan èlò ilé Jèhófà àti gbogbo àwọn tó wà ní ìgbèkùn ní Bábílónì pa dà wá sí ibí yìí! 7 Síbẹ̀, jọ̀wọ́, gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mò ń sọ létí rẹ àti létí gbogbo èèyàn. 8 Tipẹ́tipẹ́ ni àwọn wòlíì tó wà ṣáájú mi àti ṣáájú rẹ ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọ̀pọ̀ ilẹ̀ àti àwọn ìjọba ńlá, nípa ogun, àjálù àti àjàkálẹ̀ àrùn.* 9 Tí wòlíì kan bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àlàáfíà, tí ọ̀rọ̀ wòlíì náà sì ṣẹ, ìgbà náà la máa mọ̀ pé Jèhófà ló rán wòlíì náà lóòótọ́.”
10 Ni wòlíì Hananáyà bá mú ọ̀pá àjàgà tó wà lọ́rùn wòlíì Jeremáyà kúrò, ó sì ṣẹ́ ẹ.+ 11 Hananáyà sì sọ lójú gbogbo àwọn èèyàn náà pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Bí màá ṣe ṣẹ́ àjàgà Nebukadinésárì ọba Bábílónì kúrò ní ọrùn gbogbo orílẹ̀-èdè nìyí kí ọdún méjì tó pé.’”+ Wòlíì Jeremáyà sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.
12 Lẹ́yìn tí wòlíì Hananáyà ti ṣẹ́ ọ̀pá àjàgà tó mú kúrò lọ́rùn wòlíì Jeremáyà, Jèhófà wá sọ fún Jeremáyà pé: 13 “Lọ sọ fún Hananáyà pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “O ti ṣẹ́ ọ̀pá àjàgà igi,+ àmọ́ dípò rẹ̀, ọ̀pá àjàgà irin lo máa ṣe.” 14 Nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nìyí: “Màá fi ọ̀pá àjàgà irin sí ọrùn gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yìí, láti sin Nebukadinésárì ọba Bábílónì, wọ́n sì gbọ́dọ̀ sìn ín.+ Kódà màá fún un ní àwọn ẹran inú igbó.”’”+
15 Wòlíì Jeremáyà wá sọ fún wòlíì Hananáyà+ pé: “Jọ̀wọ́, fetí sílẹ̀, ìwọ Hananáyà! Jèhófà kò rán ọ, àmọ́ o ti mú kí àwọn èèyàn yìí gbẹ́kẹ̀ lé irọ́.+ 16 Torí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Wò ó! Màá mú ọ kúrò lórí ilẹ̀. Ọdún yìí ni wàá kú, nítorí o ti mú kí àwọn èèyàn dìtẹ̀ sí Jèhófà.’”+
17 Torí náà, wòlíì Hananáyà kú ní ọdún yẹn, ní oṣù keje.
29 Èyí ni ọ̀rọ̀ inú lẹ́tà tí wòlíì Jeremáyà fi ránṣẹ́ láti Jerúsálẹ́mù sí àwọn àgbààgbà tó ṣẹ́ kù lára àwọn tó wà nígbèkùn àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn èèyàn náà, àwọn tí Nebukadinésárì kó láti Jerúsálẹ́mù lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì, 2 lẹ́yìn tí Ọba Jekonáyà,+ ìyá ọba,*+ àwọn òṣìṣẹ́ ààfin, àwọn ìjòyè Júdà àti Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ọnà àti àwọn oníṣẹ́ irin* ti jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù.+ 3 Ó fi lẹ́tà náà rán Élásà ọmọ Ṣáfánì+ àti Gemaráyà ọmọ Hilikáyà, ẹni tí Ọba Sedekáyà+ ti Júdà rán sí Bábílónì sí Ọba Nebukadinésárì ti Bábílónì. Ó sọ pé:
4 “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ fún gbogbo àwọn tó wà nígbèkùn, ìyẹn àwọn tó mú kí wọ́n lọ sí ìgbèkùn kúrò ní Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì. 5 ‘Ẹ kọ́ ilé, kí ẹ sì máa gbé inú wọn. Ẹ gbin ọgbà kí ẹ sì máa jẹ èso wọn. 6 Ẹ fẹ́ ìyàwó kí ẹ sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin; ẹ fẹ́ ìyàwó fún àwọn ọmọkùnrin yín kí ẹ sì fi àwọn ọmọbìnrin yín fún ọkọ, kí àwọn náà lè bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. Ẹ di púpọ̀ níbẹ̀, kí ẹ má sì dín kù. 7 Ẹ máa wá àlàáfíà ní ìlú tí mo kó yín lọ ní ìgbèkùn, ẹ sì máa gbàdúrà sí Jèhófà nítorí rẹ̀, nítorí bí ó bá wà ní àlàáfíà, ẹ̀yin náà á wà ní àlàáfíà.+ 8 Nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn wòlíì yín àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́ yín tó wà láàárín yín tàn yín jẹ,+ ẹ má sì fetí sí àlá tí wọ́n ń lá. 9 Nítorí ‘èké ni wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín ní orúkọ mi. Mi ò rán wọn,’+ ni Jèhófà wí.”’”
10 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Tó bá ti pé àádọ́rin (70) ọdún tí ẹ ti wà ní Bábílónì, màá yí ojú mi sí yín,+ màá sì mú ìlérí mi ṣẹ láti mú yín pa dà wá sí ibí yìí.’+
11 “‘Nítorí mo mọ èrò tí mò ń rò nípa yín dáadáa,’ ni Jèhófà wí, ‘èrò àlàáfíà, kì í ṣe ti àjálù,+ láti fún yín ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.+ 12 Ẹ ó pè mí, ẹ ó sì wá gbàdúrà sí mi, màá sì fetí sí yín.’+
13 “‘Ẹ ó wá mi, ẹ ó sì rí mi,+ nítorí gbogbo ọkàn yín ni ẹ ó fi wá mi.+ 14 Màá sì jẹ́ kí ẹ rí mi,’+ ni Jèhófà wí. ‘Màá kó yín pa dà láti oko ẹrú, màá sì kó yín jọ láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè àti gbogbo ibi tí mo fọ́n yín ká sí,’+ ni Jèhófà wí. ‘Màá sì mú yín pa dà wá sí ibi tí mo ti jẹ́ kí wọ́n kó yín lọ sí ìgbèkùn.’+
15 “Ṣùgbọ́n ẹ sọ pé, ‘Jèhófà ti gbé àwọn wòlíì dìde fún wa ní Bábílónì.’
16 “Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí fún ọba tó jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì+ àti gbogbo àwọn èèyàn tó ń gbé inú ìlú yìí, ìyẹn àwọn arákùnrin yín tí kò bá yín lọ sí ìgbèkùn, 17 ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Wò ó, màá rán idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn*+ sí wọn, màá sì ṣe wọ́n bí ọ̀pọ̀tọ́ jíjẹrà* tó ti bà jẹ́ débi pé kò ṣeé jẹ.”’+
18 “‘Màá fi idà,+ ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn lé wọn, màá sọ wọ́n di ohun àríbẹ̀rù lójú gbogbo ìjọba ayé,+ màá sì sọ wọ́n di ẹni ègún àti ohun ìyàlẹ́nu, ohun àrísúfèé+ àti ẹni ẹ̀gàn láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè tí màá fọ́n wọn ká sí,+ 19 nítorí wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi, tí mo fi ránṣẹ́ sí wọn nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì,’ ni Jèhófà wí, ‘tí mò ń rán wọn léraléra.’*+
“‘Ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sílẹ̀,’+ ni Jèhófà wí.
20 “Torí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin tó wà nígbèkùn, tí mo rán lọ láti Jerúsálẹ́mù sí Bábílónì. 21 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí nípa Áhábù ọmọ Koláyà àti nípa Sedekáyà ọmọ Maaseáyà, àwọn tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún yín ní orúkọ mi,+ ‘Wò ó, màá fi wọ́n lé ọwọ́ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, á sì pa wọ́n lójú yín. 22 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn á di ohun tí gbogbo àwọn ará Júdà tó wà ní ìgbèkùn ní Bábílónì á máa sọ, tí wọ́n bá fẹ́ gégùn-ún fún àwọn èèyàn, wọ́n á ní: “Kí Jèhófà ṣe ọ́ bíi Sedekáyà àti Áhábù, àwọn tí ọba Bábílónì yan nínú iná!” 23 nítorí pé wọ́n ti hùwà àìnítìjú ní Ísírẹ́lì,+ wọ́n ń bá aya ọmọnìkejì wọn ṣe àgbèrè, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ èké ní orúkọ mi, èyí tí mi ò pa láṣẹ fún wọn.+
“‘“Èmi ni Ẹni tí ó mọ̀, èmi sì ni ẹlẹ́rìí,”+ ni Jèhófà wí.’”
24 “Kí o sọ fún Ṣemáyà+ ará Néhélámù pé, 25 ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nìyí: “Nítorí pé o fi àwọn lẹ́tà ránṣẹ́ ní orúkọ rẹ sí gbogbo àwọn èèyàn tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti sí Sefanáyà+ ọmọ Maaseáyà tó jẹ́ àlùfáà àti sí gbogbo àwọn àlùfáà, pé, 26 ‘Jèhófà ti sọ ọ́ di àlùfáà dípò Jèhóádà àlùfáà láti di alábòójútó ilé Jèhófà, láti máa kápá ẹnikẹ́ni tó ya wèrè tó sì ń ṣe bíi wòlíì, kí o sì fi í sínú àbà àti sínú egìran;*+ 27 kí wá nìdí tí o kò fi bá Jeremáyà ará Ánátótì+ wí, ẹni tó ń ṣe wòlíì fún yín?+ 28 Torí ó ránṣẹ́ sí wa ní Bábílónì pé: “Ó máa pẹ́ gan-an! Ẹ kọ́ ilé, kí ẹ sì máa gbé inú wọn. Ẹ gbin ọgbà kí ẹ sì máa jẹ èso wọn,+—”’”’”
29 Nígbà tí àlùfáà Sefanáyà+ ka lẹ́tà yìí létí wòlíì Jeremáyà, 30 Jèhófà bá Jeremáyà sọ̀rọ̀, ó ní: 31 “Ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn tó wà ní ìgbèkùn pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nípa Ṣemáyà ará Néhélámù nìyí: “Nítorí pé Ṣemáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ fún yín, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò rán an, tó sì fẹ́ mú kí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé irọ́,+ 32 nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Wò ó, màá fìyà jẹ Ṣemáyà ará Néhélámù àti àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Kò ní sí ọkùnrin kankan tó jẹ́ tirẹ̀ tó máa yè bọ́ lára àwọn èèyàn yìí, kò sì ní rí ohun rere tí màá ṣe fún àwọn èèyàn mi,’ ni Jèhófà wí, ‘nítorí ó ti mú kí wọ́n dìtẹ̀ sí Jèhófà.’”’”
30 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jeremáyà sọ nìyí, ó ní: 2 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún ọ sínú ìwé kan. 3 Nítorí, “wò ó! ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “tí màá kó àwọn èèyàn mi, Ísírẹ́lì àti Júdà, tó wà lóko ẹrú jọ,”+ ni Jèhófà wí, “màá mú wọn pa dà wá sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn, yóò sì pa dà jẹ́ tiwọn.”’”+
4 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Ísírẹ́lì àti Júdà nìyí.
5 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“A ti gbọ́ ìró àwọn tí jìnnìjìnnì bá;
Ẹ̀rù ló wà, kò sí àlàáfíà.
6 Ẹ jọ̀wọ́, ẹ bá mi béèrè bóyá ọkùnrin lè bímọ.
Kí wá nìdí tí gbogbo ọ̀dọ́kùnrin tí mo rí fi ń fọwọ́ ti ikùn*
Bí obìnrin tó ń rọbí?+
Kí nìdí tí gbogbo ojú sì fi funfun?
7 Ó mà ṣe o! Nítorí ọjọ́ burúkú* ni ọjọ́ yẹn máa jẹ́.+
Kò sí irú rẹ̀,
Àkókò wàhálà ni fún Jékọ́bù.
Ṣùgbọ́n a ó gbà á là.”
8 “Ní ọjọ́ yẹn,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí, “màá ṣẹ́ àjàgà kúrò ní ọrùn wọn, màá sì já ọ̀já* wọn sí méjì; àwọn àjèjì* ò sì ní fi wọ́n* ṣe ẹrú mọ́. 9 Wọ́n á máa sin Jèhófà Ọlọ́run wọn àti Dáfídì ọba wọn, ẹni tí màá gbé dìde fún wọn.”+
10 “Ní tìrẹ, ìwọ Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi, má fòyà,” ni Jèhófà wí,
“Má sì jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, ìwọ Ísírẹ́lì.+
Nítorí màá gbà ọ́ láti ibi tó jìnnà réré
Àti àwọn ọmọ rẹ láti oko ẹrú tí wọ́n wà.+
Jékọ́bù á pa dà, ara rẹ̀ á balẹ̀, kò ní rí ìyọlẹ́nu,
Ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.”+
11 “Nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ,” ni Jèhófà wí, “láti gbà ọ́.
Ṣùgbọ́n màá pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí mo tú ọ ká sí àárín wọn run;+
Àmọ́ ní tìrẹ, mi ò ní pa ọ́ run.+
12 Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Kò sí ìwòsàn fún àárẹ̀ tó ń ṣe ọ́.+
Ọgbẹ́ rẹ kò ṣeé wò sàn.
13 Kò sí ẹni tó máa gba ẹjọ́ rẹ rò,
Egbò rẹ kò ṣeé wò sàn.
Kò sí ìwòsàn fún ọ.
14 Gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ àtàtà ti gbàgbé rẹ.+
Wọn kò wá ọ mọ́.
Nítorí mo nà ọ́ bí ìgbà tí ọ̀tá ẹni bá nani,+
Pẹ̀lú ìyà tí ìkà èèyàn fi ń jẹni,
Nítorí o ti jẹ ẹ̀bi lé ẹ̀bi, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ sì ti pọ̀.+
15 Kí nìdí tí o fi ń ké nítorí àárẹ̀ tó ń ṣe ọ́?
Ìrora rẹ kò ṣeé wò sàn!
Nítorí o ti jẹ ẹ̀bi lé ẹ̀bi, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ sì ti pọ̀+
Ni mo fi ṣe èyí sí ọ.
16 Nítorí náà, gbogbo àwọn tó ń pa àwọn èèyàn rẹ run ni a ó pa run,+
Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ á sì lọ sí oko ẹrú.+
Àwọn tó ń fi ogun kó ọ ni a ó fi ogun kó,
Àwọn tó ń kó ọ lẹ́rù ni màá sì jẹ́ kí wọ́n kó lẹ́rù lọ.”+
17 “Ṣùgbọ́n màá mú ọ lára dá, màá sì wo ọgbẹ́ rẹ sàn,”+ ni Jèhófà wí,
“Bí wọ́n tiẹ̀ pè ọ́ ní ẹni ìtanù:
‘Síónì, tí ẹnikẹ́ni kò fẹ́.’”+
18 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Wò ó, màá kó àwọn tó lọ sí oko ẹrú láti àgọ́ Jékọ́bù jọ,+
Máa sì ṣojú àánú sí àwọn àgọ́ ìjọsìn rẹ̀.
Wọ́n á tún ìlú náà kọ́ sórí òkìtì rẹ̀,+
Ibi tó sì yẹ ni wọ́n á kọ́ ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò sí.
19 Ìdúpẹ́ àti ohùn ẹ̀rín á ti ọ̀dọ̀ wọn wá.+
20 Àwọn ọmọ rẹ̀ á dà bíi ti ìgbà àtijọ́,
Àpéjọ rẹ̀ á sì fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in níwájú mi.+
Màá sì fìyà jẹ gbogbo àwọn tó ń ni ín lára.+
21 Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni olórí rẹ̀ ti máa wá,
Láti àárín rẹ̀ sì ni alákòóso ti máa jáde wá.
Màá mú kí ó sún mọ́ tòsí, á sì wá bá mi.”
“Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ta ló tó bẹ́ẹ̀* láti wá bá mi?” ni Jèhófà wí.
22 “Ẹ ó di èèyàn mi,+ màá sì di Ọlọ́run yín.”+
23 Wò ó! Ìjì Jèhófà máa fi ìbínú tú jáde,+
Ìjì líle tó ń gbá nǹkan lọ, tó sì ń tú jáde sórí àwọn ẹni burúkú.
24 Ìbínú Jèhófà tó ń jó bí iná kò ní dáwọ́ dúró
Títí á fi ṣe ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀, tí á sì mú èrò rẹ̀ ṣẹ.+
Ní àkókò òpin, ọ̀rọ̀ yìí á yé yín.+
31 “Ní àkókò yẹn,” ni Jèhófà wí, “màá di Ọlọ́run gbogbo ìdílé Ísírẹ́lì, wọ́n á sì di èèyàn mi.”+
2 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Àwọn tó bọ́ lọ́wọ́ idà rí ojú rere ní aginjù
Nígbà tí Ísírẹ́lì ń rìn lọ sí ibi ìsinmi rẹ̀.”
3 Jèhófà ti fara hàn mí láti ọ̀nà jíjìn, ó sì sọ pé:
“Ìfẹ́ tí mo ní sí ọ jẹ́ ìfẹ́ ayérayé.
Ìdí nìyẹn tí mo fi fà ọ́ mọ́ra pẹ̀lú ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.*+
4 Síbẹ̀ náà, màá tún ọ kọ́ bí ilé, wàá sì dà bí ilé tí a tún kọ́.+
6 Nítorí ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí àwọn olùṣọ́ tó wà lórí àwọn òkè Éfúrémù máa ké jáde pé:
‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ ká lọ sí Síónì, sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa.’”+
7 Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Ẹ fi ìdùnnú kọrin sí Jékọ́bù.
Ẹ sì kígbe ayọ̀ nítorí ẹ ti ga ju àwọn orílẹ̀-èdè lọ.+
Ẹ kéde rẹ̀; ẹ yin Ọlọ́run, kí ẹ sì sọ pé,
‘Jèhófà, gba àwọn èèyàn rẹ là, àwọn tó ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì.’+
8 Màá mú wọn pa dà wá láti ilẹ̀ àríwá.+
Màá sì kó wọn jọ láti ibi tó jìnnà jù lọ láyé.+
Àwọn afọ́jú àti àwọn arọ máa wà lára wọn,+
Aboyún àti ẹni tó ń rọbí, gbogbo wọn pa pọ̀.
Bí ìjọ ńlá ni wọ́n máa pa dà sí ibí yìí.+
9 Wọ́n á wá pẹ̀lú ẹkún.+
Màá máa darí wọn bí wọ́n ṣe ń wá ojú rere.
Nítorí èmi ni Bàbá Ísírẹ́lì, Éfúrémù sì ni àkọ́bí mi.”+
10 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,
Ẹ sì kéde rẹ̀ láàárín àwọn erékùṣù tó jìnnà réré pé:+
“Ẹni tó tú Ísírẹ́lì ká máa kó o jọ.
Á máa bójú tó o bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe ń bójú tó agbo ẹran rẹ̀.+
12 Wọ́n á wá, wọ́n á sì kígbe ayọ̀ ní ibi gíga Síónì+
Inú wọn á dùn nítorí oore* Jèhófà,
Nítorí ọkà àti wáìnì tuntun+ pẹ̀lú òróró,
Nítorí àwọn ọmọ inú agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran.+
13 “Ní àkókò yẹn, wúńdíá á máa jó ijó ayọ̀,
Àwọn ọ̀dọ́kùnrin àti àwọn àgbà ọkùnrin á máa jó pa pọ̀.+
Màá sọ ọ̀fọ̀ wọn di ìdùnnú.+
Màá tù wọ́n nínú, màá sì fún wọn ní ayọ̀ dípò ẹ̀dùn ọkàn tí wọ́n ní.+
14 Màá fi ọ̀pọ̀ nǹkan* tẹ́ àwọn àlùfáà* lọ́rùn,
Oore mi á sì tẹ́ àwọn èèyàn mi lọ́rùn,”+ ni Jèhófà wí.
15 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
‘A gbọ́ ohùn kan ní Rámà,+ ìdárò àti ẹkún kíkorò:
Réṣẹ́lì ń sunkún nítorí àwọn ọmọkùnrin* rẹ̀.+
Wọ́n tù ú nínú nítorí àwọn ọmọ rẹ̀, àmọ́ kò gbà,
Torí pé wọn kò sí mọ́.’”+
16 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“‘Má sunkún mọ́, má sì da omi lójú mọ́,
Nítorí èrè wà fún iṣẹ́ rẹ,’ ni Jèhófà wí.
‘Wọ́n á pa dà láti ilẹ̀ ọ̀tá.’+
17 ‘Ìrètí wà fún ọ ní ọjọ́ ọ̀la,’+ ni Jèhófà wí.
‘Àwọn ọmọ rẹ á sì pa dà sí ilẹ̀ wọn.’”+
18 “Mo ti gbọ́ tí Éfúrémù ń kérora,
‘O ti tọ́ mi sọ́nà, mo sì ti gba ìtọ́sọ́nà,
Bí ọmọ màlúù tí a kò fi iṣẹ́ kọ́.
Mú mi pa dà, màá sì ṣe tán láti yí pa dà,
Nítorí ìwọ ni Jèhófà Ọlọ́run mi.
Ojú tì mí, ẹ̀tẹ́ sì bá mi,+
Nítorí mo ti ru ẹ̀gàn ìgbà èwe mi.’”
20 “Ǹjẹ́ Éfúrémù kì í ṣe ọmọ mi àtàtà, ọmọ tí mo nífẹ̀ẹ́?+
Torí bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ sí i tó, síbẹ̀ mo ṣì ń rántí rẹ̀.
Ìdí nìyẹn tí ọkàn* mi fi gbé sókè nítorí rẹ̀.+
Ó sì dájú pé màá ṣàánú rẹ̀,” ni Jèhófà wí.+
21 “Ri àwọn àmì ojú ọ̀nà mọ́lẹ̀ fún ará rẹ,
Ri àwọn òpó àmì mọ́lẹ̀.+
Fiyè sí òpópónà, ọ̀nà tí o máa gbà.+
Pa dà, ìwọ wúńdíá Ísírẹ́lì, pa dà wá sí àwọn ìlú rẹ.
22 Ìgbà wo lo máa ṣiyèméjì dà, ìwọ aláìṣòótọ́ ọmọbìnrin?
Nítorí Jèhófà ti dá ohun tuntun kan sí ayé:
Obìnrin kan á máa fìtara lé ọkùnrin kan kiri.”
23 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Wọ́n á tún ọ̀rọ̀ yìí sọ ní ilẹ̀ Júdà àti ní àwọn ìlú rẹ̀, nígbà tí mo bá kó àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà lóko ẹrú pa dà: ‘Kí Jèhófà bù kún ọ, ìwọ ibùgbé òdodo,+ ìwọ òkè mímọ́.’+ 24 Inú rẹ̀ ni Júdà àti gbogbo àwọn ìlú rẹ̀ á jọ máa gbé, àwọn àgbẹ̀ àti àwọn tó ń da agbo ẹran.+ 25 Nítorí ẹni* tí àárẹ̀ mú ni màá tẹ́ lọ́rùn, màá sì pèsè fún gbogbo ẹni* tó jẹ́ aláìní.”+
26 Bí mo ṣe gbọ́ èyí ni mo jí, mo la ojú mi, oorun mi sì dùn mọ́ mi.
27 “Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “tí màá sọ àtọmọdọ́mọ* ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà di púpọ̀, tí màá sì sọ àwọn ẹran agbéléjẹ̀ wọn di púpọ̀.”+
28 “Bí mo ṣe kíyè sí wọn láti fà wọ́n tu, láti ya wọ́n lulẹ̀, láti fà wọ́n ya, láti pa wọ́n run àti láti ṣe wọ́n léṣe,+ bẹ́ẹ̀ ni màá kíyè sí wọn láti kọ́ wọn bí ilé àti láti gbìn wọ́n,”+ ni Jèhófà wí. 29 “Ní àkókò yẹn, wọn kò tún ní sọ pé, ‘Àwọn baba jẹ èso àjàrà kíkan, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ni eyín kan.’*+ 30 Àmọ́ nígbà náà, kálukú máa kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ẹni tó bá sì jẹ èso àjàrà kíkan ni eyín máa kan.”
31 “Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “tí màá bá ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà dá májẹ̀mú tuntun.+ 32 Kò ní dà bíi májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá ní ọjọ́ tí mo dì wọ́n lọ́wọ́ mú láti mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ ‘májẹ̀mú mi tí wọ́n dà,+ bó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi ni ọ̀gá wọn tòótọ́,’* ni Jèhófà wí.”
33 “Nítorí májẹ̀mú tí màá bá ilé Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn ìgbà yẹn nìyí,” ni Jèhófà wí. “Màá fi òfin mi sínú wọn,+ inú ọkàn wọn sì ni màá kọ ọ́ sí.+ Màá di Ọlọ́run wọn, wọ́n á sì di èèyàn mi.”+
34 “Kálukú wọn kò tún ní máa kọ́ ẹnì kejì rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀ mọ́ pé, ‘Ẹ mọ Jèhófà!’+ nítorí gbogbo wọn á mọ̀ mí, látorí ẹni tó kéré jù lọ dórí ẹni tó tóbi jù lọ láàárín wọn,”+ ni Jèhófà wí. “Nítorí màá dárí àṣìṣe wọn jì wọ́n, mi ò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.”+
35 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,
Ẹni tó ń mú kí oòrùn máa tan ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán,
Tó sì ṣe òfin* pé kí òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ máa tàn ní òru,
Ẹni tó ń ru òkun sókè, tó sì ń mú kí ìgbì rẹ̀ máa pariwo,
Ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun:+
36 “‘Bí àwọn ìlànà yìí bá yí pa dà
Nìkan ni àtọmọdọ́mọ Ísírẹ́lì kò fi ní jẹ́ orílẹ̀-èdè níwájú mi mọ́,’ ni Jèhófà wí.”+
37 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “‘Àyàfi bí a bá lè díwọ̀n ọ̀run lókè, tí a sì lè wá ìpìlẹ̀ ayé kàn nísàlẹ̀, ni màá tó kọ gbogbo àtọmọdọ́mọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ torí àwọn ohun tí wọ́n ti ṣe,’ ni Jèhófà wí.”+
38 “Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “nígbà tí wọ́n á kọ́ ìlú+ fún Jèhófà láti Ilé Gogoro Hánánélì+ dé Ẹnubodè Igun.+ 39 Okùn ìdíwọ̀n+ máa jáde lọ tààrà sí òkè Gárébù, á sì yíjú sí Góà. 40 Gbogbo àfonífojì* àwọn òkú àti ti eérú* pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ onípele títí dé Àfonífojì Kídírónì,+ títí lọ dé igun Ẹnubodè Ẹṣin,+ lápá ìlà oòrùn, yóò jẹ́ ohun mímọ́ fún Jèhófà.+ A kò ní fà á tu láé, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní ya á lulẹ̀.”
32 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jeremáyà sọ ní ọdún kẹwàá Sedekáyà ọba Júdà, ìyẹn ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Nebukadinésárì.*+ 2 Ní àkókò yẹn, àwọn ọmọ ogun ọba Bábílónì dó ti Jerúsálẹ́mù, wòlíì Jeremáyà sì wà ní àhámọ́ ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́+ ní ilé* ọba Júdà. 3 Nítorí Sedekáyà ọba Júdà ti fi í sí àhámọ́,+ ọba sì sọ pé, “Kí nìdí tí o fi sọ tẹ́lẹ̀ báyìí? O sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Màá fi ìlú yìí lé ọwọ́ ọba Bábílónì, á sì gbà á,+ 4 Sedekáyà ọba Júdà kò ní lè sá mọ́ àwọn ará Kálídíà lọ́wọ́, nítorí ó dájú pé a ó fi í lé ọba Bábílónì lọ́wọ́, wọ́n á jọ rí ara wọn, wọ́n á sì sọ̀rọ̀ lójúkojú.”’+ 5 ‘Á mú Sedekáyà lọ sí Bábílónì, ibẹ̀ ló sì máa wà títí màá fi yíjú sí i,’ ni Jèhófà wí. ‘Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ ń bá àwọn ará Kálídíà jà, ẹ kò ní borí.’”+
6 Jeremáyà sọ pé: “Jèhófà ti bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, 7 ‘Wò ó, Hánámélì ọmọ Ṣálúmù, arákùnrin bàbá rẹ á wá bá ọ, á sì sọ pé: “Ra ilẹ̀ mi tó wà ní Ánátótì,+ torí pé ìwọ lo lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ́kọ́ tún un rà.”’”+
8 Hánámélì ọmọ arákùnrin bàbá mi wá bá mi, bí Jèhófà ti sọ, nínú Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́, ó sì sọ fún mi pé: “Jọ̀wọ́, ra ilẹ̀ mi tó wà ní Ánátótì, nílẹ̀ Bẹ́ńjámínì, torí pé ìwọ ló tọ́ sí, kí o sì tún un rà. Rà á fún ara rẹ.” Ìgbà náà ni mo wá mọ̀ pé ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ ló ṣẹ yẹn.
9 Nítorí náà, mo ra ilẹ̀ tó wà ní Ánátótì lọ́wọ́ Hánámélì ọmọ arákùnrin bàbá mi. Mo sì wọn owó+ fún un, ṣékélì* méje àti ẹyọ fàdákà mẹ́wàá. 10 Lẹ́yìn náà, mo ṣe ìwé àdéhùn,+ mo sì gbé èdìdì lé e, mo pe àwọn ẹlẹ́rìí wá,+ mo sì wọn owó náà lórí òṣùwọ̀n. 11 Mo mú ìwé àdéhùn tí mo fi ra ilẹ̀ náà, èyí tó ní èdìdì gẹ́gẹ́ bí àṣẹ àti òfin ti sọ àti èyí tí kò ní èdìdì, 12 mo sì fún Bárúkù,+ ọmọ Neráyà,+ ọmọ Maseáyà ní ìwé àdéhùn náà lójú Hánámélì ọmọ arákùnrin bàbá mi àti lójú àwọn ẹlẹ́rìí tó buwọ́ lu ìwé àdéhùn náà àti lójú gbogbo àwọn Júù tó jókòó sí Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.+
13 Mo wá pàṣẹ fún Bárúkù lójú wọn, pé: 14 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Mú ìwé àdéhùn méjèèjì yìí, ìwé àdéhùn tí o fi ra ilẹ̀ náà, èyí tó ní èdìdì àti èyí tí kò ní èdìdì, kí o sì fi wọ́n sínú ìkòkò, kí a lè tọ́jú wọn, kí wọ́n sì pẹ́.’ 15 Nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Àwọn èèyàn á tún ra ilé àti ilẹ̀ àti ọgbà àjàrà ní ilẹ̀ yìí.’”+
16 Lẹ́yìn náà, mo gbàdúrà sí Jèhófà lẹ́yìn tí mo fún Bárúkù ọmọ Neráyà ní ìwé àdéhùn tí mo fi ra ilẹ̀ náà, mo sọ pé: 17 “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Wò ó! Agbára ńlá rẹ+ àti apá rẹ tí o nà jáde lo fi dá ọ̀run àti ayé. Kò sí ohun tó ṣòroó ṣe fún ọ, 18 ìwọ Ẹni tó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, àmọ́ tí ò ń bẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wò lára* àwọn ọmọ tí wọ́n fi sílẹ̀,+ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́, tí o jẹ́ Ẹni ńlá àti alágbára ńlá, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ. 19 Ìpinnu rẹ* ga, àwọn iṣẹ́ rẹ sì tóbi,+ ìwọ tí ojú rẹ ń wo gbogbo ọ̀nà àwọn èèyàn,+ láti san èrè fún ẹnì kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ṣe.+ 20 O ti ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Íjíbítì, tí a mọ̀ títí di òní yìí, o sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣe orúkọ fún ara rẹ ní Ísírẹ́lì àti láàárín aráyé+ bó ṣe rí lónìí yìí. 21 O sì mú àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu àti ọwọ́ agbára àti apá tó nà jáde pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ tó ń bani lẹ́rù.+
22 “Nígbà tó yá, o fún wọn ní ilẹ̀ yìí tí o búra pé wàá fún àwọn baba ńlá wọn,+ ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.+ 23 Wọ́n sì wọlé wá, wọ́n sì gbà á, ṣùgbọ́n wọn kò ṣègbọràn sí ohùn rẹ, wọn kò sì tẹ̀ lé òfin rẹ. Wọn kò ṣe ìkankan nínú ohun tí o pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n ṣe, torí náà, o mú kí gbogbo àjálù yìí bá wọn.+ 24 Wò ó! Àwọn èèyàn ti wá mọ òkìtì láti dó ti ìlú náà kí wọ́n lè gbà á,+ ó sì dájú pé idà+ àti ìyàn pẹ̀lú àjàkálẹ̀ àrùn*+ yóò mú kí ìlú náà ṣubú sọ́wọ́ àwọn ará Kálídíà tó ń bá a jà; gbogbo ohun tí o sọ ló ti ṣẹ bí ìwọ náà ṣe rí i báyìí. 25 Àmọ́, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, o ti sọ fún mi pé, ‘Fi owó ra ilẹ̀ náà fún ara rẹ, kí o sì pe àwọn ẹlẹ́rìí wá,’ bó tilẹ̀ jẹ́ pé, a ó fi ìlú náà lé ọwọ́ àwọn ará Kálídíà dájúdájú.”
26 Ìgbà náà ni Jèhófà bá Jeremáyà sọ̀rọ̀, ó ní: 27 “Èmi rèé, Jèhófà, Ọlọ́run gbogbo aráyé.* Ǹjẹ́ ohun kan wà tó ṣòroó ṣe fún mi? 28 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Wò ó, màá fi ìlú yìí lé ọwọ́ àwọn ará Kálídíà àti Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, á sì gbà á.+ 29 Àwọn ará Kálídíà tó ń bá ìlú yìí jà máa wọlé wá, wọ́n á sọ iná sí i, wọ́n á sì sun ún kanlẹ̀+ pẹ̀lú àwọn ilé tí àwọn èèyàn náà ti ń rú ẹbọ lórí òrùlé wọn sí Báálì, tí wọ́n sì ti ń da ọrẹ ohun mímu sí àwọn ọlọ́run míì láti mú mi bínú.’+
30 “‘Nítorí pé kìkì ohun tó burú lójú mi ni àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti ti Júdà ń ṣe láti ìgbà èwe wọn wá;+ ńṣe ni àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ń fi iṣẹ́ ọwọ́ wọn mú mi bínú,’ ni Jèhófà wí. 31 ‘Nítorí ìlú yìí, láti ọjọ́ tí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ dó, títí di òní yìí, jẹ́ ohun tó ń fa ìbínú àti ìrunú fún mi,+ màá sì mú un kúrò níwájú mi,+ 32 nítorí gbogbo ìwà ibi tí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti ti Júdà ti hù láti mú mi bínú, látorí àwọn fúnra wọn, àwọn ọba wọn,+ àwọn ìjòyè wọn,+ àwọn àlùfáà wọn àti àwọn wòlíì wọn,+ dórí àwọn èèyàn Júdà àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù. 33 Wọ́n ń kẹ̀yìn sí mi dípò kí wọ́n máa yíjú sí mi; + bí mo tiẹ̀ ń kọ́ wọn léraléra,* kò sí ìkankan nínú wọn tó fetí sílẹ̀, tó sì gba ìbáwí.+ 34 Wọ́n gbé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn sínú ilé tí a fi orúkọ mi pè, láti sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin.+ 35 Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n kọ́ àwọn ibi gíga Báálì, tó wà ní Àfonífojì Ọmọ Hínómù,*+ láti sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná fún Mólékì,+ ohun tí mi ò pa láṣẹ fún wọn,+ tí kò sì wá sí mi lọ́kàn rí* pé kí wọ́n ṣe irú ohun ìríra bẹ́ẹ̀ láti mú kí Júdà dẹ́ṣẹ̀.’
36 “Nítorí náà, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí nípa ìlú tí ẹ̀ ń sọ pé a ó fi lé ọwọ́ ọba Bábílónì nípasẹ̀ idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn, 37 ‘Wò ó, màá kó wọn jọ láti inú gbogbo ilẹ̀ tí mo fọ́n wọn ká sí nínú ìbínú mi àti nínú ìrunú mi àti nínú ìkannú ńlá mi,+ màá sì mú wọn pa dà wá sí ibí yìí láti máa gbé lábẹ́ ààbò.+ 38 Wọ́n á jẹ́ èèyàn mi, màá sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.+ 39 Màá fún wọn ní ọkàn kan+ àti ọ̀nà kan kí wọ́n lè máa bẹ̀rù mi nígbà gbogbo, fún ire wọn àti ti àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn wọn.+ 40 Màá sì bá wọn dá májẹ̀mú tó máa wà títí láé,+ pé mi ò ní jáwọ́ nínú ṣíṣe rere fún wọn;+ màá fi ìbẹ̀rù mi sínú ọkàn wọn, kí wọ́n má bàa kúrò lọ́dọ̀ mi.+ 41 Ṣe ni inú mi á máa dùn nítorí wọn láti máa ṣe rere fún wọn,+ màá sì fi gbogbo ọkàn mi àti gbogbo ara* mi gbìn wọ́n sí ilẹ̀ yìí.’”+
42 “Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Bí mo ti mú gbogbo àjálù ńlá yìí bá àwọn èèyàn yìí, bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe mú gbogbo oore* tí mo ṣèlérí fún wọn wá sórí wọn.+ 43 Àwọn èèyàn á tún ra ilẹ̀ ní ilẹ̀ yìí,+ bí ẹ tilẹ̀ ń sọ pé: “Ahoro ni, tí kò sí èèyàn àti ẹranko lórí rẹ̀, a sì ti fi í lé ọwọ́ àwọn ará Kálídíà.”’
44 “‘Àwọn èèyàn á fi owó ra ilẹ̀, wọ́n á ṣe ìwé àdéhùn tí wọ́n fi rà á, wọ́n á gbé èdìdì lé e, wọ́n á sì pe àwọn ẹlẹ́rìí ní ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì,+ ní agbègbè Jerúsálẹ́mù àti ní àwọn ìlú Júdà,+ ní àwọn ìlú tó wà ní àwọn agbègbè olókè àti ní àwọn ìlú tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀+ pẹ̀lú àwọn ìlú tó wà ní gúúsù, torí pé màá mú àwọn èèyàn wọn tó wà lóko ẹrú pa dà wá,’+ ni Jèhófà wí.”
33 Jèhófà bá Jeremáyà sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì, nígbà tó ṣì wà ní àhámọ́ ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́,+ pé: 2 “Ohun tí Jèhófà, Aṣẹ̀dá ayé sọ nìyí, Jèhófà tó dá ayé tó sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in; Jèhófà ni orúkọ rẹ̀, 3 ‘Ké pè mí, màá sì dá ọ lóhùn, mo ṣe tán láti sọ nípa àwọn ohun ńlá tí kò ṣeé lóye fún ọ, àwọn ohun tí ìwọ kò tíì mọ̀.’”+
4 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí nípa àwọn ilé tó wà ní ìlú yìí àti ilé àwọn ọba Júdà tí wọ́n wó lulẹ̀ nípasẹ̀ àwọn òkìtì tí wọ́n mọ láti dó ti ìlú yìí àti nípasẹ̀ idà,+ 5 nípa àwọn tó ń bọ̀ wá bá àwọn ará Kálídíà jà, tí wọ́n á fi òkú àwọn èèyàn tí mo ti pa nínú ìbínú àti ìrunú mi kún gbogbo ibí yìí, àwọn tí ìwà ibi wọn ti mú kí n fi ojú mi pa mọ́ kúrò lára ìlú yìí: 6 ‘Wò ó, màá mú kí ara rẹ̀ kọ́fẹ, màá sì fún un ní ìlera,+ màá mú wọn lára dá, màá sì fún wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà àti òtítọ́.+ 7 Màá mú àwọn ará Júdà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà lóko ẹrú pa dà,+ màá sì fún wọn lókun bí mo ti ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀.+ 8 Ṣe ni màá wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò nínú ẹ̀bi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá sí mi,+ màá sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n àti àwọn àṣìṣe wọn.+ 9 Orúkọ ìlú yìí máa gbé mi ga, á sì mú kí wọ́n máa yìn mí, kí wọ́n sì máa fi ògo fún mi láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè ayé tó máa gbọ́ nípa gbogbo oore tí mo ṣe fún ìlú náà.+ Ẹ̀rù á bà wọ́n, wọ́n á sì máa gbọ̀n+ nítorí gbogbo oore àti àlàáfíà tí màá mú bá ìlú náà.’”+
10 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ní ibí yìí tí ẹ̀ ń sọ pé ó jẹ́ aṣálẹ̀, tí kò sí èèyàn tàbí ẹran ọ̀sìn níbẹ̀, ní àwọn ìlú Júdà àti àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù tó ti di ahoro, tí kò sí èèyàn tàbí ẹni tó ń gbé ibẹ̀ àti ẹran ọ̀sìn, ibẹ̀ ni a ó tún ti pa dà gbọ́ 11 ìró ayọ̀ àti ìró ìdùnnú,+ ohùn ọkọ ìyàwó àti ohùn ìyàwó, ohùn àwọn tó ń sọ pé: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, nítorí Jèhófà jẹ́ ẹni rere;+ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì wà títí láé!”’+
“‘Wọ́n á mú ẹbọ ìdúpẹ́ wá sínú ilé Jèhófà,+ nítorí màá mú àwọn tí wọ́n kó lọ sí oko ẹrú láti ilẹ̀ náà pa dà wá bíi ti ìbẹ̀rẹ̀,’ ni Jèhófà wí.”
12 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: ‘Ní aṣálẹ̀ yìí, tí kò sí èèyàn tàbí ẹran ọ̀sìn nínú rẹ̀ àti ní gbogbo àwọn ìlú rẹ̀, ibi ìjẹko yóò tún pa dà wà fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí agbo ẹran wọn máa dùbúlẹ̀ sí.’+
13 “‘Ní àwọn ìlú tó wà ní agbègbè olókè àti ní àwọn ìlú tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ní àwọn ìlú tó wà ní gúúsù àti ní ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì, ní agbègbè Jerúsálẹ́mù+ àti ní àwọn ìlú Júdà,+ agbo ẹran yóò tún pa dà kọjá lábẹ́ ọwọ́ ẹni tó ń kà wọ́n,’ ni Jèhófà wí.”
14 “‘Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘tí màá mú ìlérí tí mo ṣe nípa ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà ṣẹ.+ 15 Nígbà yẹn àti ní àkókò yẹn, màá mú kí èéhù* òdodo kan hù jáde fún Dáfídì,+ á sì ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ àti òdodo ní ilẹ̀ náà.+ 16 Ní àkókò yẹn, a ó gba Júdà là,+ Jerúsálẹ́mù á sì máa wà ní ààbò.+ Ohun tí a ó sì máa pè é ni: Jèhófà Ni Òdodo Wa.’”+
17 “Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Kò ní ṣàìsí ọkùnrin kan láti ìlà Dáfídì tí yóò máa jókòó sórí ìtẹ́ ilé Ísírẹ́lì,+ 18 bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà tó jẹ́ ọmọ Léfì kò ní ṣàìní ọkùnrin kan tí yóò máa dúró níwájú mi láti rú odindi ẹbọ sísun, láti máa sun ọrẹ ọkà àti láti máa rú àwọn ẹbọ.’”
19 Jèhófà sì tún bá Jeremáyà sọ̀rọ̀, pé: 20 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Bí ẹ bá lè ba májẹ̀mú mi nípa ọ̀sán àti májẹ̀mú mi nípa òru jẹ́, pé kí ọ̀sán àti òru má ṣe wà ní àkókò wọn+ 21 nìkan ni májẹ̀mú tí mo bá Dáfídì ìránṣẹ́ mi dá tó lè bà jẹ́,+ tí kò fi ní máa ní ọmọ tó ń jọba lórí ìtẹ́ rẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ náà ni májẹ̀mú tí mo bá àwọn àlùfáà tó jẹ́ ọmọ Léfì dá, àwọn òjíṣẹ́ mi.+ 22 Bí a kò ti lè ka àwọn ọmọ ogun ọ̀run, tí a kò sì lè wọn iyanrìn òkun, bẹ́ẹ̀ ni màá sọ àtọmọdọ́mọ* Dáfídì ìránṣẹ́ mi àti àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n ń ṣe ìránṣẹ́ fún mi di púpọ̀.’”
23 Jèhófà sì tún bá Jeremáyà sọ̀rọ̀, ó ní: 24 “Ǹjẹ́ o ò kíyè sí ohun tí àwọn èèyàn yìí ń sọ, pé, ‘Jèhófà máa kọ ìdílé méjì tó ti yàn’? Wọn kò bọ̀wọ̀ fún àwọn èèyàn mi, wọn ò sì kà wọ́n sí orílẹ̀-èdè mọ́.
25 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Bí mo ṣe fìdí májẹ̀mú mi nípa ọ̀sán àti òru múlẹ̀+ àti òfin* nípa ọ̀run àti ayé,+ 26 bẹ́ẹ̀ ni mi ò jẹ́ kọ àtọmọdọ́mọ* Jékọ́bù àti ti Dáfídì ìránṣẹ́ mi, kí n bàa lè máa mú lára ọmọ* rẹ̀ láti jẹ́ alákòóso lórí àtọmọdọ́mọ* Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù. Nítorí màá kó àwọn tó wà ní oko ẹrú lára wọn jọ,+ màá sì ṣàánú wọn.’”+
34 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jeremáyà sọ nìyí, nígbà tí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ìjọba ayé tó wà lábẹ́ ìjọba rẹ̀ àti gbogbo èèyàn ń bá Jerúsálẹ́mù jà àti gbogbo ìlú tó yí i ká:+
2 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Lọ bá Sedekáyà+ ọba Júdà sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún un pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Wò ó, màá fi ìlú yìí lé ọwọ́ ọba Bábílónì, á sì dáná sun ún.+ 3 Ìwọ kò sì ní lè sá mọ́ ọn lọ́wọ́, torí ó dájú pé wọ́n á mú ọ, wọ́n á sì fà ọ́ lé e lọ́wọ́.+ Ìwọ àti ọba Bábílónì máa rí ara yín, á sì bá ọ sọ̀rọ̀ lójúkojú, wàá sì lọ sí Bábílónì.’+ 4 Síbẹ̀, gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ìwọ Sedekáyà ọba Júdà, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nípa rẹ nìyí: “Idà ò ní pa ọ́. 5 Ńṣe ni wàá fọwọ́ rọrí kú,+ wọ́n á sun tùràrí nítorí rẹ bí wọ́n ti ṣe fún àwọn baba rẹ, àwọn ọba tó wà ṣáájú rẹ, wọ́n á sì ṣọ̀fọ̀ rẹ pé, ‘Áà, ọ̀gá!’ nítorí ‘mo ti sọ ọ̀rọ̀ náà,’ ni Jèhófà wí.”’”’”
6 Wòlíì Jeremáyà sì bá Sedekáyà ọba Júdà sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní Jerúsálẹ́mù, 7 nígbà tí àwọn ọmọ ogun ọba Bábílónì ń bá Jerúsálẹ́mù àti gbogbo ìlú tó ṣẹ́ kù ní Júdà jà,+ tí wọ́n sì ń bá Lákíṣì+ àti Ásékà jà;+ nítorí àwọn nìkan ni ìlú olódi tó ṣẹ́ kù lára àwọn ìlú Júdà.
8 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jeremáyà sọ nìyí, lẹ́yìn tí Ọba Sedekáyà bá gbogbo èèyàn tó wà ní Jerúsálẹ́mù dá májẹ̀mú láti kéde òmìnira fún wọn,+ 9 pé kí kálukú wọn dá àwọn ẹrú wọn tó jẹ́ Hébérù sílẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, kí ẹnikẹ́ni má bàa fi Júù bíi tirẹ̀ ṣe ẹrú. 10 Nítorí náà, gbogbo àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn èèyàn náà ṣègbọràn. Wọ́n dá májẹ̀mú pé kí kálukú wọn dá àwọn ẹrú wọn lọ́kùnrin àti lóbìnrin sílẹ̀, kí wọ́n má sì jẹ́ ẹrú wọn mọ́. Wọ́n ṣègbọràn, wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n lọ. 11 Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n tún lọ mú àwọn ẹrú tí wọ́n ti dá sílẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, wọ́n sì sọ wọ́n di ẹrú pa dà tipátipá. 12 Nítorí náà, Jèhófà bá Jeremáyà sọ̀rọ̀, Jèhófà sọ pé:
13 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘mo bá àwọn baba ńlá yín+ dá májẹ̀mú ní ọjọ́ tí mo mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní oko ẹrú,+ pé: 14 “Nígbà tí ọdún méje bá pé, kí kálukú yín dá arákùnrin rẹ̀ tó jẹ́ Hébérù sílẹ̀, tí wọ́n tà fún un, tó sì ti fi ọdún mẹ́fà sìn ín; ó gbọ́dọ̀ jẹ́ kó lọ ní òmìnira.”+ Ṣùgbọ́n àwọn baba ńlá yín kò fetí sí mi, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ṣègbọràn. 15 Lẹ́nu àìpẹ́* yìí, ẹ̀yin fúnra yín yí pa dà, ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi torí pé ẹ kéde òmìnira fún ọmọnìkejì yín, ẹ sì dá májẹ̀mú níwájú mi nínú ilé tí a fi orúkọ mi pè. 16 Àmọ́ lẹ́yìn náà, ẹ yí pa dà, ẹ sì kó ẹ̀gàn bá orúkọ mi,+ nítorí kálukú yín mú ẹrú rẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin pa dà wá, àwọn tí ẹ ti jẹ́ kí wọ́n lọ ní òmìnira bó ṣe wù wọ́n,* ẹ sì tún sọ wọ́n di ẹrú pa dà tipátipá.’
17 “Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Ẹ kò ṣègbọràn sí mi, torí pé kálukú yín kò kéde òmìnira fún arákùnrin rẹ̀ àti ọmọnìkejì rẹ̀.+ Òmìnira tí màá kéde fún yín nìyí, ni Jèhófà wí, idà, àjàkálẹ̀ àrùn* àti ìyàn ni yóò pa yín,+ màá sì sọ yín di ohun àríbẹ̀rù lójú gbogbo ìjọba ayé.+ 18 Ohun tó sì máa ṣẹlẹ̀ nìyí sí àwọn tó da májẹ̀mú mi, tí wọn kò mú ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí wọ́n dá lójú mi ṣẹ, nígbà tí wọ́n gé ọmọ màlúù sí méjì, tí wọ́n sì gba àárín rẹ̀ kọjá,+ 19 ìyẹn, àwọn ìjòyè Júdà àti àwọn ìjòyè Jerúsálẹ́mù, àwọn òṣìṣẹ́ ààfin àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú gbogbo èèyàn ilẹ̀ náà tí wọ́n kọjá láàárín ọmọ màlúù tí wọ́n gé sí méjì náà: 20 Ṣe ni màá fà wọ́n lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn àti àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí wọn,* òkú wọn á sì di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹran orí ilẹ̀.+ 21 Màá sì fi Sedekáyà ọba Júdà àti àwọn ìjòyè rẹ̀ lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn àti àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí wọn* àti lé ọwọ́ àwọn ọmọ ogun ọba Bábílónì+ tó ṣígun kúrò lọ́dọ̀ yín.’+
22 “‘Wò ó, màá pàṣẹ,’ ni Jèhófà wí, ‘màá sì mú wọn pa dà wá sí ìlú yìí, wọ́n á bá a jà, wọ́n á gbà á, wọ́n á sì dáná sun ún;+ màá sọ àwọn ìlú Júdà di ahoro tí ò ní sí ẹnì kankan tí á máa gbé ibẹ̀.’”+
35 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jeremáyà sọ nígbà ayé Jèhóákímù+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà nìyí, ó ní: 2 “Lọ sí ilé àwọn ọmọ Rékábù,+ kí o bá wọn sọ̀rọ̀, kí o sì mú wọn wá sínú ilé Jèhófà, sí ọ̀kan lára àwọn yàrá ìjẹun;* kí o sì fi wáìnì lọ̀ wọ́n pé kí wọ́n mu.”
3 Torí náà, mo mú Jaasanáyà ọmọ Jeremáyà ọmọ Habasináyà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọmọ rẹ̀ àti agbo ilé àwọn ọmọ Rékábù 4 wá sínú ilé Jèhófà. Mo mú wọn wá sínú yàrá ìjẹun àwọn ọmọ Hánánì ọmọ Igidaláyà, èèyàn Ọlọ́run tòótọ́, èyí tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ yàrá ìjẹun àwọn ìjòyè, tó sì wà lókè yàrá ìjẹun Maaseáyà ọmọ Ṣálúmù tó jẹ́ aṣọ́nà. 5 Ni mo bá gbé àwọn ife àti àwọn aago tí wáìnì kún inú wọn síwájú àwọn èèyàn ilé Rékábù, mo sì sọ fún wọn pé: “Ẹ mu wáìnì.”
6 Ṣùgbọ́n wọ́n sọ pé: “À kò ní mu wáìnì, nítorí Jèhónádábù*+ ọmọ Rékábù, baba ńlá wa, tí pàṣẹ fún wa pé, ‘Ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín kò gbọ́dọ̀ mu wáìnì láé. 7 Ẹ kò gbọ́dọ̀ kọ́ ilé, ẹ kò gbọ́dọ̀ fún irúgbìn, ẹ kò gbọ́dọ̀ gbin ọgbà àjàrà, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ kò gbọ́dọ̀ ní ọgbà àjàrà. Kàkà bẹ́ẹ̀, inú àgọ́ ni kí ẹ máa gbé, kí ẹ bàa lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ ti jẹ́ àjèjì.’ 8 Nítorí náà, à ń ṣègbọràn sí ohùn Jèhónádábù ọmọ Rékábù baba ńlá wa nínú ohun gbogbo tó pa láṣẹ fún wa, a kò sì jẹ́ fẹnu kan wáìnì, àwa fúnra wa, àwọn ìyàwó wa, àwọn ọmọkùnrin wa àti àwọn ọmọbìnrin wa. 9 Àti pé a ò kọ́ ilé láti máa gbé, a kò sì ní ọgbà àjàrà tàbí oko tàbí irúgbìn. 10 À ń gbé inú àgọ́, a sì ń ṣègbọràn sí gbogbo ohun tí Jèhónádábù* baba ńlá wa pa láṣẹ fún wa. 11 Àmọ́ nígbà tí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì wá gbéjà ko ilẹ̀ tí à ń gbé,+ a sọ pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a wọnú Jerúsálẹ́mù kí a má bàa bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Kálídíà àti ti Síríà.’ Bó ṣe di pé à ń gbé Jerúsálẹ́mù nìyẹn.”
12 Jèhófà bá Jeremáyà sọ̀rọ̀, ó ní: 13 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Lọ sọ fún àwọn èèyàn Júdà àti àwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù pé: “Ǹjẹ́ kì í ṣe léraléra ni mo gbà yín níyànjú pé kí ẹ ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ mi?”+ ni Jèhófà wí. 14 “Jèhónádábù ọmọ Rékábù pàṣẹ fún àtọmọdọ́mọ rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe mu wáìnì, wọ́n ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọn kò sì mu wáìnì títí di òní yìí, nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣègbọràn sí àṣẹ baba ńlá wọn.+ Àmọ́, léraléra ni mo ti bá yín sọ̀rọ̀,* síbẹ̀ ẹ kò ṣègbọràn sí mi.+ 15 Mo sì ń rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sí yín, mò ń rán wọn léraléra,*+ wọ́n ń sọ pé, ‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ yí pa dà, kí kálukú yín kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀,+ kí ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́! Ẹ má ṣe tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, ẹ má sì sìn wọ́n. Nígbà náà, ẹ ó máa gbé ní ilẹ̀ tí mo fún ẹ̀yin àti àwọn baba ńlá yín.’+ Ṣùgbọ́n ẹ kò dẹ etí yín sílẹ̀, ẹ kò sì fetí sí mi. 16 Àwọn ọmọ Jèhónádábù ọmọ Rékábù tẹ̀ lé àṣẹ tí baba ńlá wọn pa fún wọn,+ ṣùgbọ́n àwọn èèyàn yìí kò fetí sí mi.”’”
17 “Nítorí náà, ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Wò ó, màá mú gbogbo àjálù tí mo ti kìlọ̀ fún Júdà àti gbogbo àwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù wá sórí wọn,+ torí pé mo ti bá wọn sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n wọn kò fetí sílẹ̀, mo sì ń pè wọ́n, ṣùgbọ́n wọn kò dáhùn.’”+
18 Jeremáyà sì sọ fún agbo ilé àwọn ọmọ Rékábù pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Nítorí pé ẹ ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhónádábù baba ńlá yín, tí ẹ̀ ń pa gbogbo àṣẹ rẹ̀ mọ́, tí ẹ sì ń ṣe ohun tó pa láṣẹ fún yín gẹ́lẹ́, 19 ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nìyí: “Kò sígbà tí kò ní sí ẹnì kan lára àtọmọdọ́mọ Jèhónádábù* ọmọ Rékábù tí yóò máa sìn níwájú mi.”’”
36 Ó ṣẹlẹ̀ pé ní ọdún kẹrin Jèhóákímù+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà, Jèhófà bá Jeremáyà sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Mú àkájọ ìwé kan, kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo bá ọ sọ sínú rẹ̀, ọ̀rọ̀ tí mo sọ sí Ísírẹ́lì àti Júdà+ àti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè,+ láti ọjọ́ tí mo kọ́kọ́ bá ọ sọ̀rọ̀ nígbà ayé Jòsáyà, títí di òní yìí.+ 3 Bóyá nígbà tí àwọn ará ilé Júdà bá gbọ́ nípa gbogbo àjálù tí mo fẹ́ mú bá wọn, wọ́n á lè yí pa dà kúrò nínú ìwà ibi wọn, kí n sì dárí àṣìṣe wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n.”+
4 Jeremáyà bá pe Bárúkù+ ọmọ Neráyà, Jeremáyà sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà ti bá a sọ, Bárúkù sì ń kọ ọ́ sínú àkájọ ìwé náà.+ 5 Ni Jeremáyà bá pàṣẹ fún Bárúkù pé: “Inú àhámọ́ ni mo wà, mi ò sì lè wọ ilé Jèhófà. 6 Torí náà, ìwọ ni kí o wọ ibẹ̀, kí o sì ka ọ̀rọ̀ Jèhófà sókè látinú àkájọ ìwé tí o kọ ọ̀rọ̀ tí o gbọ́ lẹ́nu mi sí. Kà á sí etí àwọn èèyàn tó wà ní ilé Jèhófà ní ọjọ́ ààwẹ̀; wàá tipa bẹ́ẹ̀ kà á fún gbogbo èèyàn Júdà tí wọ́n wá láti àwọn ìlú wọn. 7 Bóyá Jèhófà á gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn, tí á sì ṣojú rere sí wọn, tí kálukú wọn á sì yí pa dà kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀, torí pé ìbínú àti ìrunú tó kàmàmà ni Jèhófà ti kéde sórí àwọn èèyàn yìí.”
8 Nítorí náà, Bárúkù ọmọ Neráyà ṣe gbogbo ohun tí wòlíì Jeremáyà pa láṣẹ fún un; ó ka ọ̀rọ̀ Jèhófà sókè látinú àkájọ ìwé* náà ní ilé Jèhófà.+
9 Ó ṣẹlẹ̀ pé ní ọdún karùn-ún Jèhóákímù+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà, ní oṣù kẹsàn-án, gbogbo èèyàn Jerúsálẹ́mù àti gbogbo àwọn tó wá sí Jerúsálẹ́mù láti àwọn ìlú Júdà kéde ààwẹ̀ níwájú Jèhófà.+ 10 Bárúkù bá ka ọ̀rọ̀ Jeremáyà sókè látinú àkájọ ìwé* náà ní ilé Jèhófà sí etí gbogbo àwọn èèyàn náà, ní yàrá* Gemaráyà+ ọmọ Ṣáfánì+ adàwékọ,* ní àgbàlá òkè tó wà ní àtiwọ ẹnubodè tuntun ilé Jèhófà.+
11 Nígbà tí Mikáyà ọmọ Gemaráyà ọmọ Ṣáfánì gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà nínú àkájọ ìwé* náà, 12 ó lọ sí ilé* ọba, sí yàrá akọ̀wé. Gbogbo àwọn ìjòyè* jókòó síbẹ̀: Élíṣámà+ akọ̀wé, Deláyà ọmọ Ṣemáyà, Élínátánì+ ọmọ Ákíbórì,+ Gemaráyà ọmọ Ṣáfánì, Sedekáyà ọmọ Hananáyà àti gbogbo àwọn ìjòyè yòókù. 13 Mikáyà sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tó gbọ́ nígbà tí Bárúkù ka àkájọ ìwé* náà sí etí àwọn èèyàn náà fún wọn.
14 Ìgbà náà ni gbogbo àwọn ìjòyè rán Jéhúdì ọmọ Netanáyà ọmọ Ṣelemáyà ọmọ Kúúṣì sí Bárúkù pé: “Wá, kí o sì mú àkájọ ìwé tí o kà ní etí àwọn èèyàn náà dání.” Bárúkù ọmọ Neráyà mú àkájọ ìwé náà dání, ó sì wọlé lọ bá wọn. 15 Wọ́n sọ fún un pé: “Jọ̀wọ́, jókòó, kí o sì kà á sókè fún wa.” Torí náà, Bárúkù kà á fún wọn.
16 Gbàrà tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ náà, wọ́n wo ojú ara wọn tẹ̀rùtẹ̀rù, wọ́n sì sọ fún Bárúkù pé: “A gbọ́dọ̀ sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún ọba.” 17 Wọ́n wá béèrè lọ́wọ́ Bárúkù pé: “Jọ̀wọ́, sọ bí o ṣe kọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún wa. Ṣé bó ṣe ń sọ ọ́ lò ń kọ ọ́ ni?” 18 Bárúkù dá wọn lóhùn pé: “Ó sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún mi ni, mo sì fi yíǹkì kọ ọ́ sínú àkájọ ìwé* yìí bó ṣe ń sọ ọ́.” 19 Àwọn ìjòyè sọ fún Bárúkù pé: “Lọ fara pa mọ́, ìwọ àti Jeremáyà, ẹ má sì jẹ́ kí ẹnì kankan mọ ibi tí ẹ wà.”+
20 Lẹ́yìn náà, wọ́n wọlé lọ bá ọba ní àgbàlá, wọ́n fi àkájọ ìwé náà sí yàrá ìjẹun Élíṣámà akọ̀wé, wọ́n sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ náà fún ọba.
21 Nítorí náà, ọba rán Jéhúdì+ láti lọ mú àkájọ ìwé náà wá, ó sì mú un wá láti yàrá ìjẹun Élíṣámà akọ̀wé. Jéhúdì sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á sí etí ọba àti gbogbo àwọn ìjòyè tó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọba. 22 Ọba jókòó nínú ilé ìgbà òtútù, ní oṣù kẹsàn-án,* iná sì ń jó nínú àdògán iwájú rẹ̀. 23 Lẹ́yìn tí Jéhúdì bá ti ka abala mẹ́ta tàbí mẹ́rin, ọba á fi ọ̀bẹ akọ̀wé gé apá ibẹ̀ dà nù, á sì sọ ọ́ sínú iná tó ń jó nínú àdògán náà, ó ṣe bẹ́ẹ̀ títí tó fi sọ gbogbo àkájọ ìwé náà sínú iná àdògán. 24 Ẹ̀rù ò bà wọ́n rárá, bẹ́ẹ̀ sì ni ọba àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí kò fa ẹ̀wù wọn ya. 25 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Élínátánì+ àti Deláyà+ pẹ̀lú Gemaráyà+ bẹ ọba pé kó má sun àkájọ ìwé náà, kò gbọ́ tiwọn. 26 Yàtọ̀ síyẹn, ọba pàṣẹ fún Jéráméélì ọmọ ọba àti Seráyà ọmọ Ásíríẹ́lì pẹ̀lú Ṣelemáyà ọmọ Ábídélì pé kí wọ́n mú Bárúkù akọ̀wé àti wòlíì Jeremáyà, àmọ́ Jèhófà fi wọ́n pa mọ́.+
27 Jèhófà tún bá Jeremáyà sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí ọba ti sun àkájọ ìwé tí Bárúkù kọ ọ̀rọ̀ tó gbọ́ lẹ́nu Jeremáyà sí,+ ó ní: 28 “Mú àkájọ ìwé míì, kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ kan náà tó wà nínú àkájọ ìwé àkọ́kọ́ sínú rẹ̀, èyí tí Jèhóákímù ọba Júdà sun.+ 29 Sọ fún Jèhóákímù ọba Júdà pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “O ti sun àkájọ ìwé yìí, o sì sọ pé, ‘Kí nìdí tí o fi kọ ọ́ sínú rẹ̀ pé: “Ó dájú pé ọba Bábílónì máa wá pa ilẹ̀ yìí run, á sì pa èèyàn àti ẹranko rẹ́ kúrò lórí rẹ̀”?’+ 30 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí sí Jèhóákímù ọba Júdà, ‘Kò ní lẹ́nì kankan tó máa jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì,+ òkú rẹ̀ á sì wà ní ìta nínú ooru lọ́sàn-án àti nínú òtútù lóru.+ 31 Màá pe òun àti àtọmọdọ́mọ* rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wá jíhìn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, màá sì mú gbogbo àjálù tí mo sọ sí wọn wá sórí wọn àti sórí àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn èèyàn Júdà,+ àmọ́ wọn kò fetí sílẹ̀.’”’”+
32 Lẹ́yìn náà, Jeremáyà mú àkájọ ìwé míì, ó fún Bárúkù ọmọ Neráyà, akọ̀wé,+ ó sì ń kọ ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà ń sọ fún un sínú rẹ̀, ó kọ gbogbo ọ̀rọ̀ inú àkájọ ìwé* tí Jèhóákímù ọba Júdà sun nínú iná.+ Ọ̀rọ̀ púpọ̀ tó dà bí èyí tó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ ni a sì fi kún un.
37 Ọba Sedekáyà+ ọmọ Jòsáyà bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò Konáyà*+ ọmọ Jèhóákímù, nítorí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì fi jẹ ọba ní ilẹ̀ Júdà.+ 2 Àmọ́ òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn ilẹ̀ náà kò fetí sí ọ̀rọ̀ Jèhófà tí wòlíì Jeremáyà sọ.
3 Ọba Sedekáyà rán Jéhúkálì + ọmọ Ṣelemáyà àti Sefanáyà+ ọmọ àlùfáà Maaseáyà sí wòlíì Jeremáyà pé: “Jọ̀wọ́, bá wa gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run wa.” 4 Jeremáyà ń rìn fàlàlà láàárín àwọn èèyàn náà, torí wọn kò tíì fi í sẹ́wọ̀n.+ 5 Nígbà náà, àwọn ọmọ ogun Fáráò jáde kúrò ní Íjíbítì,+ àwọn ará Kálídíà tí wọ́n dó ti Jerúsálẹ́mù sì gbọ́ ìròyìn nípa wọn. Torí náà, wọ́n ṣígun kúrò ní Jerúsálẹ́mù.+ 6 Ìgbà náà ni Jèhófà bá wòlíì Jeremáyà sọ̀rọ̀, ó ní: 7 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Ohun tí ẹ máa sọ fún ọba Júdà, tó rán yín wá sọ́dọ̀ mi láti wádìí nìyí: “Wò ó! Àwọn ọmọ ogun Fáráò tó ń bọ̀ wá ràn yín lọ́wọ́ yóò ní láti pa dà sí Íjíbítì, ilẹ̀ wọn.+ 8 Àwọn ará Kálídíà á sì pa dà wá, wọ́n á bá ìlú yìí jà, wọ́n á gbà á, wọ́n á sì dáná sun ún.”+ 9 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, “Ẹ má tan ara* yín jẹ pé, ‘Àwọn ará Kálídíà kò ní pa dà wá,’ torí ó dájú pé wọ́n á pa dà wá. 10 Kódà bí ẹ bá pa gbogbo ọmọ ogun Kálídíà tó ń bá yín jà, tó sì jẹ́ pé àwọn tó fara pa nìkan ló ṣẹ́ kù, wọ́n ṣì máa wá látinú àgọ́ wọn, wọ́n á sì dáná sun ìlú yìí.”’”+
11 Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Kálídíà ti ṣígun kúrò ní Jerúsálẹ́mù nítorí àwọn ọmọ ogun Fáráò,+ 12 Jeremáyà jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù lọ sí ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì+ láti lọ gba ìpín rẹ̀ tó wà láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ níbẹ̀. 13 Àmọ́ nígbà tó dé Ẹnubodè Bẹ́ńjámínì, ọ̀gá tó ń bójú tó àwọn ẹ̀ṣọ́, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Íríjà ọmọ Ṣelemáyà ọmọ Hananáyà mú wòlíì Jeremáyà, ó sì sọ pé: “Ọ̀dọ̀ àwọn ará Kálídíà lò ń sá lọ!” 14 Ṣùgbọ́n Jeremáyà sọ pé: “Rárá o! Mi ò sá lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Kálídíà.” Àmọ́ kò gbọ́ tirẹ̀. Torí náà Íríjà mú Jeremáyà, ó sì mú un wá sọ́dọ̀ àwọn ìjòyè. 15 Inú bí àwọn ìjòyè gan-an sí Jeremáyà,+ wọ́n lù ú, wọ́n sì fi í sẹ́wọ̀n*+ ní ilé Jèhónátánì akọ̀wé, tí wọ́n ti sọ di ọgbà ẹ̀wọ̀n. 16 Wọ́n fi Jeremáyà sínú ẹ̀wọ̀n abẹ́ ilẹ̀,* nínú àwọn yàrá tó láàbò, ọ̀pọ̀ ọjọ́ ló sì fi wà níbẹ̀.
17 Lẹ́yìn náà, Ọba Sedekáyà ránṣẹ́ pè é, ọba sì bi í ní ìbéèrè ní bòókẹ́lẹ́ nínú ilé* rẹ̀.+ Ó bi í pé, “Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ kankan wà látọ̀dọ̀ Jèhófà?” Jeremáyà fèsì pé, “Ó wà!” ó sì fi kún un pé, “A ó fi ọ́ lé ọwọ́ ọba Bábílónì!”+
18 Jeremáyà tún sọ fún Ọba Sedekáyà pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ ìwọ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ pẹ̀lú àwọn èèyàn yìí, tí ẹ fi fi mí sẹ́wọ̀n? 19 Ibo wá ni àwọn wòlíì yín wà, àwọn tó sọ tẹ́lẹ̀ fún yín pé, ‘Ọba Bábílónì kò ní wá gbéjà ko ẹ̀yin àti ilẹ̀ yìí’?+ 20 Jọ̀wọ́, ní báyìí, fetí sílẹ̀, olúwa mi ọba. Jọ̀wọ́, gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, kí o sì ṣojú rere sí mi. Má ṣe dá mi pa dà sí ilé Jèhónátánì+ akọ̀wé, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ibẹ̀ ni màá kú sí.”+ 21 Nítorí náà, Ọba Sedekáyà ní kí wọ́n fi Jeremáyà sínú àhámọ́ ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́,+ wọ́n sì ń fún un ní ìṣù búrẹ́dì ribiti kan lójúmọ́ láti òpópónà àwọn tó ń ṣe búrẹ́dì,+ títí gbogbo búrẹ́dì ìlú náà fi tán.+ Jeremáyà kò sì kúrò ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.
38 Ìgbà náà ni Ṣẹfatáyà ọmọ Mátánì, Gẹdaláyà ọmọ Páṣúrì, Júkálì+ ọmọ Ṣelemáyà àti Páṣúrì + ọmọ Málíkíjà gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà ń sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà pé: 2 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ẹni tó bá dúró sí ìlú yìí ni idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn* yóò pa.+ Àmọ́, ẹni tó bá fi ara rẹ̀ lé* ọwọ́ àwọn ará Kálídíà á máa wà láàyè, á jèrè ẹ̀mí rẹ̀, á sì wà láàyè.’*+ 3 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ó dájú pé ìlú yìí ni a ó fà lé ọwọ́ àwọn ọmọ ogun ọba Bábílónì, yóò sì gbà á.’”+
4 Àwọn ìjòyè sọ fún ọba pé: “Jọ̀wọ́, ní kí wọ́n pa ọkùnrin yìí,+ torí bó ṣe máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn* àwọn ọmọ ogun tó ṣẹ́ kù nínú ìlú yìí àti gbogbo àwọn èèyàn náà nìyẹn, tó ń sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ fún wọn. Nítorí kì í ṣe àlàáfíà àwọn èèyàn yìí ni ọkùnrin yìí ń wá, bí kò ṣe àjálù wọn.” 5 Ọba Sedekáyà dáhùn pé: “Ẹ wò ó! Ọwọ́ yín ni ọkùnrin náà wà, torí kò sí nǹkan kan tí ọba lè ṣe láti dá yín dúró.”
6 Torí náà, wọ́n mú Jeremáyà, wọ́n sì jù ú sínú kòtò omi Málíkíjà ọmọ ọba, èyí tó wà ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.+ Wọ́n fi okùn sọ Jeremáyà kalẹ̀. Nígbà yẹn, kò sí omi nínú kòtò omi náà, àfi ẹrẹ̀ nìkan, Jeremáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì sínú ẹrẹ̀ náà.
7 Ebedi-mélékì+ ará Etiópíà, tó jẹ́ ìwẹ̀fà* ní ilé* ọba gbọ́ pé wọ́n ti ju Jeremáyà sínú kòtò omi. Lásìkò yìí, ọba wà níbi tó jókòó sí ní Ẹnubodè Bẹ́ńjámínì,+ 8 torí náà, Ebedi-mélékì jáde kúrò ní ilé* ọba, ó sì sọ fún ọba pé: 9 “Olúwa mi ọba, ìwà ìkà gbáà ni àwọn ọkùnrin yìí hù sí wòlíì Jeremáyà! Wọ́n ti jù ú sínú kòtò omi, ibẹ̀ ló sì máa kú sí nítorí ìyàn, torí kò sí búrẹ́dì mọ́ ní ìlú yìí.”+
10 Ìgbà náà ni ọba pàṣẹ fún Ebedi-mélékì ará Etiópíà pé: “Mú ọgbọ̀n (30) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ láti ibí yìí, kí o sì gbé wòlíì Jeremáyà gòkè láti inú kòtò omi kí ó tó kú.” 11 Torí náà, Ebedi-mélékì kó àwọn ọkùnrin náà, ó sì lọ sí ilé* ọba, sí apá kan lábẹ́ ibi ìṣúra,+ wọ́n sì kó àwọn àkísà àti àwọn àjákù aṣọ níbẹ̀, wọ́n sì fi okùn sọ̀ wọ́n sísàlẹ̀ sí Jeremáyà nínú kòtò omi náà. 12 Ni Ebedi-mélékì ará Etiópíà bá sọ fún Jeremáyà pé: “Jọ̀wọ́, fi àwọn àkísà náà àti àwọn àjákù aṣọ náà tẹ́ abíyá rẹ lórí okùn náà.” Jeremáyà sì ṣe bẹ́ẹ̀, 13 wọ́n fi okùn náà fa Jeremáyà jáde, wọ́n sì gbé e gòkè kúrò nínú kòtò omi náà. Jeremáyà sì wà ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.+
14 Ọba Sedekáyà ránṣẹ́ sí wòlíì Jeremáyà pé kó wá sọ́dọ̀ òun ní àbáwọlé kẹta, tó wà ní ilé Jèhófà, ọba sì sọ fún Jeremáyà pé: “Ohun kan wà tí mo fẹ́ bi ọ́. Má fi ohunkóhun pa mọ́ fún mi.” 15 Jeremáyà wá sọ fún Sedekáyà pé: “Tí mo bá sọ fún ọ, ó dájú pé wàá pa mí. Tí mo bá sì fún ọ nímọ̀ràn, o ò ní fetí sí mi.” 16 Torí náà, Ọba Sedekáyà búra ní bòókẹ́lẹ́ fún Jeremáyà pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, ẹni tó fún wa ní ẹ̀mí wa,* mi ò ní pa ọ́, mi ò sì ní fà ọ́ lé ọwọ́ àwọn èèyàn tó fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ.”*
17 Jeremáyà wá sọ fún Sedekáyà pé: “Ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Bí o bá fi ara rẹ lé* àwọn ìjòyè ọba Bábílónì lọ́wọ́, wọ́n á dá ẹ̀mí rẹ sí,* wọn kò ní dáná sun ìlú yìí, wọn kò sì ní pa ìwọ àti agbo ilé rẹ.+ 18 Àmọ́, bí o kò bá fi ara rẹ lé* àwọn ìjòyè ọba Bábílónì lọ́wọ́, a ó fa ìlú yìí lé àwọn ará Kálídíà lọ́wọ́, wọ́n á dáná sun ún,+ o ò sì ní lè sá mọ́ wọn lọ́wọ́.’”+
19 Ìgbà náà ni Ọba Sedekáyà sọ fún Jeremáyà pé: “Ẹ̀rù àwọn Júù tí wọ́n ti sá lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Kálídíà ń bà mí, nítorí tí wọ́n bá fà mí lé wọn lọ́wọ́, wọ́n lè ṣe mí ṣúkaṣùka.” 20 Ṣùgbọ́n Jeremáyà sọ pé: “Wọn kò ní fà ọ́ lé wọn lọ́wọ́. Jọ̀wọ́, ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà lórí ohun tí mò ń sọ fún ọ, nǹkan á lọ dáadáa fún ọ, wàá* sì máa wà láàyè. 21 Àmọ́, bí o bá kọ̀ láti fi ara rẹ lé* wọn lọ́wọ́, ohun tí Jèhófà fi hàn mí nìyí: 22 Wò ó! Gbogbo obìnrin tó ṣẹ́ kù sí ilé* ọba Júdà ni a mú jáde wá sọ́dọ̀ àwọn ìjòyè ọba Bábílónì,+ wọ́n sì ń sọ pé,
‘Àwọn ọkùnrin tí o fọkàn tán* ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ.+
Wọ́n ti mú kí ẹsẹ̀ rẹ rì sínú ẹrọ̀fọ̀.
Ní báyìí, wọ́n ti sá pa dà lẹ́yìn rẹ.’
23 Gbogbo ìyàwó rẹ àti àwọn ọmọ rẹ ni wọ́n á kó wá fún àwọn ará Kálídíà, o ò sì ní lè sá mọ́ wọn lọ́wọ́, àmọ́ ọba Bábílónì+ máa mú ọ, nítorí rẹ sì ni wọ́n á fi dáná sun ìlú yìí.”+
24 Sedekáyà sì sọ fún Jeremáyà pé: “Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ nípa àwọn nǹkan yìí, kí o má bàa kú. 25 Tí àwọn ìjòyè bá sì gbọ́ pé mo bá ọ sọ̀rọ̀, tí wọ́n wá bá ọ, tí wọ́n sì sọ fún ọ pé, ‘Jọ̀wọ́, sọ fún wa, ohun tí o bá ọba sọ. Má fi ohunkóhun pa mọ́ fún wa, a ò ní pa ọ́.+ Kí ni ọba sọ fún ọ?’ 26 kí o fún wọn lésì pé, ‘Ṣe ni mò ń bẹ ọba pé kó má ṣe dá mi pa dà sí ilé Jèhónátánì láti kú sí ibẹ̀.’”+
27 Nígbà tó yá, gbogbo àwọn ìjòyè wọlé wá bá Jeremáyà, wọ́n sì bi í ní ìbéèrè. Ó sọ gbogbo ohun tí ọba pa láṣẹ fún un pé kó sọ fún wọn. Torí náà, wọn kò bá a sọ̀rọ̀ mọ́, nítorí ẹnikẹ́ni kò mọ ohun tí òun àti ọba jọ sọ. 28 Jeremáyà kò kúrò ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́+ títí di ọjọ́ tí wọ́n gba Jerúsálẹ́mù; ibẹ̀ ló ṣì wà nígbà tí wọ́n gba Jerúsálẹ́mù.+
39 Ní ọdún kẹsàn-án Sedekáyà ọba Júdà, ní oṣù kẹwàá, Nebukadinésárì* ọba Bábílónì àti gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ wá sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì dó tì í.+
2 Ní ọdún kọkànlá Sedekáyà, ní oṣù kẹrin, ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù náà, wọ́n fọ́ ògiri ìlú náà wọlé.+ 3 Gbogbo ìjòyè ọba Bábílónì wọlé, wọ́n sì jókòó ní Ẹnubodè Àárín,+ àwọn ni, Nẹgali-ṣárésà tó jẹ́ Samugari, Nebo-sásékímù tó jẹ́ Rábúsárísì,* Nẹgali-ṣárésà tó jẹ́ Rábúmágì* àti gbogbo àwọn tó kù lára àwọn ìjòyè ọba Bábílónì.
4 Nígbà tí Sedekáyà ọba Júdà àti gbogbo ọmọ ogun rí wọn, wọ́n fẹsẹ̀ fẹ,+ wọ́n gba ọ̀nà ọgbà ọba jáde kúrò nínú ìlú náà lóru, wọ́n gba ẹnubodè tó wà láàárín ògiri oníbejì kọjá, wọ́n sì gba ọ̀nà Árábà jáde.+ 5 Àmọ́ àwọn ọmọ ogun Kálídíà lé wọn, wọ́n sì bá Sedekáyà ní aṣálẹ̀ tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò.+ Wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì ní Ríbúlà+ ní ilẹ̀ Hámátì,+ ibẹ̀ ló sì ti dá a lẹ́jọ́. 6 Ọba Bábílónì ní kí wọ́n pa àwọn ọmọ Sedekáyà níṣojú rẹ̀ ní Ríbúlà, ọba Bábílónì sì ní kí wọ́n pa gbogbo èèyàn pàtàkì Júdà.+ 7 Lẹ́yìn náà, ó fọ́ ojú Sedekáyà, ó sì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà dè é kó lè mú un wá sí Bábílónì.+
8 Ìgbà náà ni àwọn ará Kálídíà dáná sun ilé* ọba àti ilé àwọn èèyàn náà,+ wọ́n sì wó àwọn odi Jerúsálẹ́mù lulẹ̀.+ 9 Nebusarádánì+ olórí ẹ̀ṣọ́ kó àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn èèyàn tó wà ní ìlú náà lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì àti àwọn tó sá wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí ó ṣẹ́ kù.
10 Àmọ́ Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ fi lára àwọn aláìní sílẹ̀ ní ilẹ̀ Júdà, àwọn tí kò ní nǹkan kan. Lọ́jọ́ yẹn, ó tún fún wọn ní ọgbà àjàrà àti oko láti máa ṣiṣẹ́.*+
11 Nebukadinésárì* ọba Bábílónì sì pàṣẹ fún Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ nípa Jeremáyà, pé: 12 “Mú un, kí o sì tọ́jú rẹ̀; má hùwà ìkà sí i, kí o sì fún un ní ohunkóhun tó bá béèrè lọ́wọ́ rẹ.”+
13 Torí náà, Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ àti Nebuṣásíbánì tó jẹ́ Rábúsárísì* àti Nẹgali-ṣárésà tó jẹ́ Rábúmágì* pẹ̀lú gbogbo èèyàn sàràkí-sàràkí ọba Bábílónì ránṣẹ́ 14 pé kí wọ́n mú Jeremáyà jáde kúrò ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́,+ wọ́n sì fà á lé ọwọ́ Gẹdaláyà+ ọmọ Áhíkámù+ ọmọ Ṣáfánì,+ láti mú un wá sí ilé rẹ̀. Torí náà, ó ń gbé ní àárín àwọn èèyàn náà.
15 Nígbà tí Jeremáyà wà nínú àhámọ́ ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́,+ Jèhófà bá a sọ̀rọ̀, ó ní: 16 “Lọ sọ fún Ebedi-mélékì+ ará Etiópíà pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nìyí: “Wò ó, màá mú ọ̀rọ̀ tí mo sọ sórí ìlú yìí ṣẹ, pé àjálù ni màá mú bá a, kì í ṣe ire, á ṣojú rẹ lọ́jọ́ tó bá ṣẹlẹ̀.”’
17 “‘Àmọ́, màá gbà ọ́ lọ́jọ́ yẹn,’ ni Jèhófà wí, ‘wọn kò sì ní fà ọ́ lé ọwọ́ àwọn èèyàn tí ò ń bẹ̀rù.’
18 “‘Nítorí ó dájú pé màá jẹ́ kí o sá àsálà, idà kò sì ní pa ọ́. Wàá jèrè ẹ̀mí rẹ,*+ torí pé o gbẹ́kẹ̀ lé mi,’+ ni Jèhófà wí.”
40 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jeremáyà sọ lẹ́yìn tí Nebusarádánì+ olórí ẹ̀ṣọ́ jẹ́ kó lọ ní òmìnira láti Rámà.+ Ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ wà lọ́wọ́ rẹ̀ nígbà tó mú un dé ibẹ̀, ó sì wà pẹ̀lú gbogbo àwọn tí wọ́n kó nígbèkùn láti Jerúsálẹ́mù àti Júdà, ìyẹn àwọn tí wọ́n ń kó lọ sí Bábílónì. 2 Ìgbà náà ni olórí ẹ̀ṣọ́ mú Jeremáyà, ó sì sọ fún un pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ló sọ pé àjálù yìí máa bá ibí yìí, 3 Jèhófà sì ti mú kó ṣẹlẹ̀ bó ṣe sọ, nítorí pé ẹ̀yin èèyàn yìí ti ṣẹ Jèhófà, ẹ kò sì ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí èyí fi ṣẹlẹ̀ sí yín.+ 4 Ní báyìí, màá tú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ tó wà ní ọwọ́ rẹ kúrò lónìí. Tí o bá fẹ́ bá mi lọ sí Bábílónì, jẹ́ ká lọ, màá sì tọ́jú rẹ. Ṣùgbọ́n bí o kò bá fẹ́ tẹ̀ lé mi lọ sí Bábílónì, dúró ẹ. Wò ó! Gbogbo ilẹ̀ náà pátá wà níwájú rẹ. Ibikíbi tí o bá fẹ́ ni kí o lọ.”+
5 Kí Jeremáyà tó pẹ̀yìn dà, Nebusarádánì sọ pé: “Pa dà sọ́dọ̀ Gẹdaláyà+ ọmọ Áhíkámù+ ọmọ Ṣáfánì,+ ẹni tí ọba Bábílónì yàn ṣe olórí àwọn ìlú Júdà, sì máa gbé pẹ̀lú rẹ̀ ní àárín àwọn èèyàn náà tàbí kí o lọ sí ibikíbi tí o bá fẹ́.”
Olórí ẹ̀ṣọ́ wá fún un ní oúnjẹ díẹ̀ àti ẹ̀bùn, ó sì jẹ́ kó máa lọ. 6 Torí náà, Jeremáyà lọ sọ́dọ̀ Gẹdaláyà ọmọ Áhíkámù ní Mísípà,+ ó sì ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ ní àárín àwọn èèyàn tó ṣẹ́ kù ní ilẹ̀ náà.
7 Nígbà tó yá, gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun tó wà ní pápá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin wọn gbọ́ pé ọba Bábílónì ti yan Gẹdaláyà ọmọ Áhíkámù ṣe olórí ilẹ̀ náà àti pé ó ti yàn án sórí àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké tí wọ́n jẹ́ aláìní, tó ṣẹ́ kù sí ilẹ̀ náà, tí wọn ò kó lọ sí Bábílónì.+ 8 Nítorí náà, wọ́n wá sọ́dọ̀ Gẹdaláyà ní Mísípà.+ Àwọn ni Íṣímáẹ́lì+ ọmọ Netanáyà, Jóhánánì+ àti Jónátánì, àwọn ọmọ Káréà, Seráyà ọmọ Táńhúmétì, àwọn ọmọ Éfáì ará Nétófà àti Jesanáyà+ ọmọ ará Máákátì, pẹ̀lú àwọn ọkùnrin wọn. 9 Gẹdaláyà ọmọ Áhíkámù ọmọ Ṣáfánì sì búra fún wọn àti fún àwọn ọkùnrin wọn pé: “Ẹ má bẹ̀rù láti sin àwọn ará Kálídíà. Ẹ máa gbé ní ilẹ̀ yìí, kí ẹ máa sin ọba Bábílónì, nǹkan á sì máa lọ dáadáa fún yín.+ 10 Ní tèmi, màá dúró ní Mísípà láti ṣojú yín lọ́dọ̀* àwọn ará Kálídíà tó ń wá sọ́dọ̀ wa. Àmọ́, ẹ kó wáìnì jọ àti èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti òróró, ẹ kó wọn sínú àwọn ohun tí ẹ̀ ń kó nǹkan sí, kí ẹ sì máa gbé nínú àwọn ìlú tí ẹ gbà.”+
11 Gbogbo àwọn Júù tó wà ní Móábù, ní Ámónì àti ní Édómù títí kan àwọn tó wà ní gbogbo àwọn ilẹ̀ yòókù náà gbọ́ pé ọba Bábílónì ti fi àwọn kan sílẹ̀ kí wọ́n máa gbé ní Júdà àti pé ó ti yan Gẹdaláyà ọmọ Áhíkámù ọmọ Ṣáfánì ṣe olórí wọn. 12 Torí náà gbogbo àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í pa dà wá láti gbogbo ibi tí wọ́n fọ́n wọn ká sí, wọ́n sì wá sí ilẹ̀ Júdà, sọ́dọ̀ Gẹdaláyà ní Mísípà. Wọ́n sì kó wáìnì àti èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn jọ lọ́pọ̀lọpọ̀.
13 Jóhánánì ọmọ Káréà àti gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun tó wà ní pápá wá sọ́dọ̀ Gẹdaláyà ní Mísípà. 14 Wọ́n sọ fún un pé: “Ṣé o kò mọ̀ pé Báálísì, ọba àwọn ọmọ Ámónì,+ ti rán Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà láti wá pa ọ́?”*+ Ṣùgbọ́n Gẹdaláyà ọmọ Áhíkámù kò gbà wọ́n gbọ́.
15 Ìgbà náà ni Jóhánánì ọmọ Káréà yọ́ ọ̀rọ̀ sọ fún Gẹdaláyà ní Mísípà pé: “Mo fẹ́ lọ pa Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà, ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ̀. Kí ló dé tó fi máa pa ọ́,* tí gbogbo àwọn èèyàn Júdà tí wọ́n kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ á fi tú ká, tí àwọn tó ṣẹ́ kù ní Júdà á sì pa run?” 16 Ṣùgbọ́n Gẹdaláyà+ ọmọ Áhíkámù sọ fún Jóhánánì ọmọ Káréà pé: “Má ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ohun tí ò ń sọ nípa Íṣímáẹ́lì kì í ṣe òótọ́.”
41 Ní oṣù keje, Íṣímáẹ́lì+ ọmọ Netanáyà ọmọ Élíṣámà, tó wá láti ìdílé ọba,* tó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èèyàn sàràkí-sàràkí ọba, wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá míì sọ́dọ̀ Gẹdaláyà ọmọ Áhíkámù ní Mísípà.+ Bí wọ́n ṣe ń jẹun lọ́wọ́ ní Mísípà, 2 Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tó wà pẹ̀lú rẹ̀ dìde, wọ́n sì fi idà pa Gẹdaláyà ọmọ Áhíkámù ọmọ Ṣáfánì. Nípa bẹ́ẹ̀, ó pa ẹni tí ọba Bábílónì yàn ṣe olórí ilẹ̀ náà. 3 Íṣímáẹ́lì tún pa gbogbo àwọn Júù tó wà pẹ̀lú Gẹdaláyà ní Mísípà àti àwọn ọmọ ogun Kálídíà tó wà níbẹ̀.
4 Ní ọjọ́ kejì lẹ́yìn tí wọ́n ti pa Gẹdaláyà, kí ẹnikẹ́ni tó mọ̀ nípa rẹ̀, 5 ọgọ́rin (80) ọkùnrin wá láti Ṣékémù,+ láti Ṣílò+ àti láti Samáríà.+ Wọ́n fá irùngbọ̀n wọn, wọ́n ti fa ẹ̀wù wọn ya, wọ́n sì ti kọ ara wọn lábẹ,+ ọrẹ ọkà àti oje igi tùràrí+ sì wà ní ọwọ́ wọn tí wọ́n mú wá sí ilé Jèhófà. 6 Torí náà, Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà jáde kúrò ní Mísípà láti lọ pàdé wọn, ó ń sunkún bó ṣe ń rìn lọ. Nígbà tó pàdé wọn, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ Gẹdaláyà ọmọ Áhíkámù.” 7 Ṣùgbọ́n bí wọ́n ṣe wọnú ìlú náà, Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà àti àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ pa wọ́n, ó sì sọ òkú wọn sínú kòtò omi.
8 Ṣùgbọ́n mẹ́wàá lára àwọn ọkùnrin náà sọ fún Íṣímáẹ́lì pé: “Má pa wá, nítorí pé a ní àlìkámà,* ọkà bálì, òróró àti oyin ní ìpamọ́ nínú oko.” Torí náà, ó dá wọn sí, kò sì pa wọ́n pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn. 9 Íṣímáẹ́lì wá sọ òkú gbogbo àwọn ọkùnrin tó pa sínú kòtò omi ńlá kan tí Ọba Ásà ṣe nítorí Ọba Bááṣà ti Ísírẹ́lì.+ Inú kòtò omi yìí ni Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà kó òkú àwọn tó pa sí títí ó fi kún.
10 Íṣímáẹ́lì mú gbogbo àwọn tó kù ní Mísípà lẹ́rú,+ títí kan àwọn ọmọbìnrin ọba àti gbogbo èèyàn tó ṣẹ́ kù ní Mísípà, àwọn tí Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ ti fi sí ìkáwọ́ Gẹdaláyà+ ọmọ Áhíkámù. Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà mú wọn lẹ́rú, ó sì lọ láti sọdá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì.+
11 Nígbà tí Jóhánánì+ ọmọ Káréà àti gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun tó wà pẹ̀lú rẹ̀ gbọ́ gbogbo ohun búburú tí Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà ti ṣe, 12 wọ́n kó gbogbo ọkùnrin, wọ́n sì lọ láti bá Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà jà, wọ́n rí i lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi ńlá* tó wà ní Gíbíónì.
13 Inú gbogbo àwọn èèyàn tó wà pẹ̀lú Íṣímáẹ́lì dùn nígbà tí wọ́n rí Jóhánánì ọmọ Káréà àti gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun tó wà pẹ̀lú rẹ̀. 14 Ni gbogbo àwọn tí Íṣímáẹ́lì ti mú lẹ́rú láti Mísípà bá yíjú pa dà,+ wọ́n sì bá Jóhánánì ọmọ Káréà pa dà. 15 Àmọ́ Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà àti mẹ́jọ lára àwọn ọkùnrin rẹ̀ sá mọ́ Jóhánánì lọ́wọ́, wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì.
16 Jóhánánì ọmọ Káréà àti gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun tó wà pẹ̀lú rẹ̀ kó àwọn èèyàn tó ṣẹ́ kù ní Mísípà, ìyẹn àwọn tó gbà sílẹ̀ lọ́wọ́ Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà, lẹ́yìn tó ti pa Gẹdaláyà+ ọmọ Áhíkámù. Wọ́n kó àwọn ọkùnrin, àwọn ọmọ ogun, àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé àti àwọn òṣìṣẹ́ ààfin pa dà dé láti Gíbíónì. 17 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n lọ, wọ́n sì dé sí ibùwọ̀ Kímúhámù tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ láti lọ sí Íjíbítì+ 18 torí àwọn ará Kálídíà. Ẹ̀rù wọn ń bà wọ́n, nítorí Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà ti pa Gẹdaláyà ọmọ Áhíkámù, ẹni tí ọba Bábílónì yàn ṣe olórí ilẹ̀ náà.+
42 Nígbà náà, gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun àti Jóhánánì+ ọmọ Káréà àti Jesanáyà ọmọ Hóṣáyà pẹ̀lú gbogbo àwọn èèyàn náà wá, látorí ẹni tó kéré jù dórí ẹni tó dàgbà jù, 2 wọ́n sì sọ fún wòlíì Jeremáyà pé: “Jọ̀wọ́, gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa, kí o sì bá wa gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ nítorí gbogbo àṣẹ́kù yìí, torí a pọ̀ gan-an tẹ́lẹ̀, àmọ́ àwa díẹ̀ ló ṣẹ́ kù báyìí,+ bí ìwọ náà ṣe rí i. 3 Kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ sọ ọ̀nà tó yẹ kí a rìn fún wa àti ohun tó yẹ ká ṣe.”
4 Wòlíì Jeremáyà fèsì pé: “Mo ti gbọ́ yín, màá bá yín gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run yín bí ẹ ṣe sọ; gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá fi dá yín lóhùn ni màá sì sọ fún yín. Mi ò ní ṣẹ́ ọ̀rọ̀ kankan kù.”
5 Wọ́n sọ fún Jeremáyà pé: “Kí Jèhófà jẹ́ ẹlẹ́rìí tòótọ́ àti olódodo sí wa tí a bá ṣe ohunkóhun tó yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fi rán ọ sí wa. 6 Bóyá ó dára ni o tàbí ó burú, a ó ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run wa, ẹni tí à ń rán ọ sí, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún wa nítorí pé a ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run wa.”
7 Ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́yìn náà, Jèhófà bá Jeremáyà sọ̀rọ̀. 8 Nítorí náà, ó pe Jóhánánì ọmọ Káréà àti gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun tó wà pẹ̀lú rẹ̀ àti gbogbo àwọn èèyàn náà látorí ẹni tó kéré jù dórí ẹni tó dàgbà jù.+ 9 Ó sọ fún wọn pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ẹni tí ẹ rán mi sí pé kí n bá yín bẹ̀ pé kó ṣojú rere sí yín, ó ní: 10 ‘Bí ẹ kò bá kúrò ní ilẹ̀ yìí, màá gbé yín ró, mi ò sì ní ya yín lulẹ̀, màá gbìn yín, mi ò sì ní fà yín tu, torí màá pèrò dà* lórí àjálù tí mo mú bá yín.+ 11 Ẹ má fòyà nítorí ọba Bábílónì, ẹni tí ẹ̀ ń bẹ̀rù.’+
“‘Ẹ má bẹ̀rù rẹ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘torí mo wà pẹ̀lú yín, láti gbà yín àti láti yọ yín lọ́wọ́ rẹ̀. 12 Màá fi àánú hàn sí yín,+ yóò sì ṣàánú yín, yóò sì dá yín pa dà sí ilẹ̀ yín.
13 “‘Ṣùgbọ́n tí ẹ bá sọ pé, “Rárá, a ò ní dúró ní ilẹ̀ yìí!” tí ẹ sì ṣàìgbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín, 14 tí ẹ sọ pé, “Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀, ilẹ̀ Íjíbítì ni a máa lọ,+ níbi tí a ò ti ní rí ogun, tí a ò ní gbọ́ ìró ìwo, tí ebi kò sì ní pa wá; ibẹ̀ sì ni a ó máa gbé,” 15 torí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ìwọ àṣẹ́kù Júdà. Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nìyí: “Tí ẹ bá kọ̀ jálẹ̀ pé dandan ni ẹ máa lọ sí Íjíbítì, tí ẹ sì lọ ń gbé ibẹ̀,* 16 idà tí ẹ̀ ń bẹ̀rù rẹ̀ yẹn gan-an ni yóò lé yín bá níbẹ̀, ní ilẹ̀ Íjíbítì, ìyàn tó sì ń dẹ́rù bà yín yẹn ni yóò tẹ̀ lé yín dé Íjíbítì, ibẹ̀ sì ni ẹ ó kú sí.+ 17 Gbogbo àwọn tí ó fi dandan lé e pé àwọn yóò lọ máa gbé ní Íjíbítì ni idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn* yóò pa. Kò sí ẹnì kankan tó máa sá àsálà tàbí tó máa la àjálù tí màá mú bá wọn já.”’
18 “Nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Bí mo ṣe da ìbínú mi àti ìrunú mi sórí àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù,+ bẹ́ẹ̀ ni màá da ìrunú mi sórí yín tí ẹ bá lọ sí Íjíbítì, ẹ ó sì di ẹni ègún àti ohun àríbẹ̀rù, ẹni ìfiré àti ẹni ẹ̀gàn,+ ẹ kò sì ní rí ibí yìí mọ́.’
19 “Jèhófà ti sọ̀rọ̀ sí yín, ẹ̀yin àṣẹ́kù Júdà. Ẹ má lọ sí Íjíbítì. Ẹ̀yin náà mọ̀ dájú lónìí pé mo ti kìlọ̀ fún yín 20 pé ẹ̀ṣẹ̀ yín máa gba ẹ̀mí* yín. Nítorí ẹ̀yin fúnra yín ni ẹ rán mi sí Jèhófà Ọlọ́run yín pé, ‘Bá wa gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run wa, kí o sì sọ gbogbo ohun tí Jèhófà Ọlọ́run wa bá sọ fún wa, a ó sì ṣe é.’+ 21 Mo kúkú sọ fún yín lónìí, ṣùgbọ́n ẹ kò ní ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín, ẹ kò sì ní ṣe ìkankan lára ohun tó ní kí n sọ fún yín.+ 22 Nítorí náà, ẹ mọ̀ dájú pé idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn ni yóò pa yín ní ibi tí ẹ fẹ́ lọ máa gbé.”+
43 Nígbà tí Jeremáyà parí gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run wọn ní kó sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà, ìyẹn gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run wọn fi rán an sí wọn, 2 Asaráyà ọmọ Hóṣáyà àti Jóhánánì+ ọmọ Káréà pẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin tó jẹ́ agbéraga wá sọ fún Jeremáyà pé: “Irọ́ lò ń pa! Jèhófà Ọlọ́run wa kò rán ọ kí o sọ pé, ‘Ẹ má lọ sí Íjíbítì láti máa gbé ibẹ̀.’ 3 Bárúkù+ ọmọ Neráyà ló ń dẹ ọ́ sí wa láti fi wá lé ọwọ́ àwọn ará Kálídíà, kí wọ́n lè pa wá tàbí kí wọ́n kó wa lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì.”+
4 Torí náà, Jóhánánì ọmọ Káréà àti gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun pẹ̀lú gbogbo àwọn èèyàn náà kò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà pé kí wọ́n dúró sí ilẹ̀ Júdà. 5 Dípò bẹ́ẹ̀, Jóhánánì ọmọ Káréà àti gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun kó gbogbo àṣẹ́kù Júdà tó pa dà láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí a fọ́n wọn ká sí, láti máa gbé ní ilẹ̀ Júdà.+ 6 Wọ́n kó àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọbìnrin ọba, pẹ̀lú gbogbo àwọn* tí Nebusarádánì+ olórí ẹ̀ṣọ́ fi sílẹ̀ sọ́dọ̀ Gẹdaláyà+ ọmọ Áhíkámù+ ọmọ Ṣáfánì,+ wọ́n sì tún mú wòlíì Jeremáyà àti Bárúkù ọmọ Neráyà. 7 Wọ́n wọ ilẹ̀ Íjíbítì, nítorí wọn kò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà, wọ́n sì lọ títí dé Tápánẹ́sì.+
8 Nígbà náà, Jèhófà bá Jeremáyà sọ̀rọ̀ ní Tápánẹ́sì, ó ní: 9 “Fi ọwọ́ rẹ kó òkúta ńlá, kí o kó wọn pa mọ́ sí ibi onípele tí wọ́n fi bíríkì ṣe tó wà ní ẹnu ọ̀nà ilé Fáráò ní Tápánẹ́sì níṣojú àwọn ọkùnrin Júù, kí o sì fi amọ̀ bò wọ́n mọ́ ibẹ̀. 10 Kí o wá sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Wò ó, màá ránṣẹ́ pe Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, ìránṣẹ́ mi,+ màá sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ lé orí àwọn òkúta tí mo fi pa mọ́ yìí, á sì na àgọ́ ìtẹ́ rẹ̀ lé wọn lórí.+ 11 Ó máa wọlé, á sì kọ lu ilẹ̀ Íjíbítì.+ Ẹni tó bá yẹ fún àjàkálẹ̀ àrùn ni àjàkálẹ̀ àrùn máa pa, ẹni tó bá yẹ fún oko ẹrú ló máa lọ sí oko ẹrú, ẹni tó bá sì yẹ fún idà ni idà máa pa.+ 12 Màá sọ iná sí ilé* àwọn ọlọ́run Íjíbítì, ọba náà á sun wọ́n,+ á sì kó wọn lọ sí oko ẹrú. Á da ilẹ̀ Íjíbítì bora bí olùṣọ́ àgùntàn ti ń da ẹ̀wù bo ara rẹ̀, á sì jáde kúrò níbẹ̀ ní àlàáfíà.* 13 Á fọ́ àwọn òpó* Bẹti-ṣémẹ́ṣì* tó wà nílẹ̀ Íjíbítì sí wẹ́wẹ́, á sì dáná sun ilé* àwọn ọlọ́run Íjíbítì.”’”
44 Ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà gbọ́ nípa gbogbo Júù tó ń gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ ìyẹn àwọn tó ń gbé ní Mígídólì,+ ní Tápánẹ́sì,+ ní Nófì*+ àti ní ilẹ̀ Pátírọ́sì,+ pé: 2 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Ẹ ti rí gbogbo àjálù tí mo mú bá Jerúsálẹ́mù+ àti gbogbo àwọn ìlú Júdà, wọ́n ti di àwókù lónìí yìí, kò sì sí ẹni tó ń gbé inú wọn.+ 3 Ìdí ni pé wọ́n hùwà ibi láti mú mi bínú, torí wọ́n lọ ń rú ẹbọ,+ wọ́n sì ń sin àwọn ọlọ́run míì tí wọn kò mọ̀, tí ẹ̀yin tàbí àwọn baba ńlá yín náà kò sì mọ̀.+ 4 Mò ń rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sí yín, mo sì ń rán wọn léraléra,* pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣe ohun ìríra tí mi ò fẹ́ yìí.”+ 5 Ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sí mi, wọn kò sì fetí sílẹ̀ láti yí pa dà kúrò nínú ìwà ibi wọn, kí wọ́n má ṣe rú ẹbọ sí àwọn ọlọ́run míì.+ 6 Nítorí náà, ìrunú mi àti ìbínú mi tú jáde, ó sì jó bí iná ní àwọn ìlú Júdà àti ní àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì di àwókù àti ahoro bí wọ́n ṣe rí lónìí yìí.’+
7 “Ní báyìí, ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Kí nìdí tí ẹ fi ń fa àjálù ńlá bá ara* yín, tí ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti ọmọ jòjòló á fi ṣègbé ní Júdà, tí kò fi ní sí ẹni tó máa ṣẹ́ kù? 8 Kí nìdí tí ẹ fi ń fi iṣẹ́ ọwọ́ yín mú mi bínú, tí ẹ̀ ń rú ẹbọ sí àwọn ọlọ́run míì ní ilẹ̀ Íjíbítì tí ẹ lọ ń gbé? Ẹ ó ṣègbé, ẹ ó sì di ẹni ègún àti ẹni ẹ̀gàn láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.+ 9 Ṣé ẹ ti gbàgbé ìwà burúkú àwọn baba ńlá yín, ìwà burúkú àwọn ọba Júdà+ àti ìwà burúkú àwọn aya wọn,+ ìwà burúkú tiyín àti ìwà burúkú àwọn aya yín,+ tí gbogbo yín hù ní ilẹ̀ Júdà àti ní àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù? 10 Títí di òní yìí, wọn kò rẹ ara wọn sílẹ̀,* ẹ̀rù kò bà wọ́n,+ bẹ́ẹ̀ ni wọn kò rìn nínú òfin mi àti nínú àwọn ìlànà mi tí mo fi lélẹ̀ fún ẹ̀yin àti àwọn baba ńlá yín.’+
11 “Nítorí náà, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Wò ó, mo ti pinnu láti mú àjálù bá yín kí n lè pa gbogbo Júdà run. 12 Màá sì kó àṣẹ́kù Júdà tí wọ́n ti pinnu láti lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì kí wọ́n lè máa gbé ibẹ̀, gbogbo wọn sì máa ṣègbé ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Idà yóò pa wọ́n, ìyàn yóò sì mú kí wọ́n ṣègbé; látorí ẹni tó kéré jù dórí ẹni tó dàgbà jù, idà àti ìyàn ni yóò pa wọ́n. Wọ́n á sì di ẹni ègún, ohun àríbẹ̀rù, ẹni ìfiré àti ẹni ẹ̀gàn.+ 13 Ṣe ni màá fìyà jẹ àwọn tó ń gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì, bí mo ṣe fìyà jẹ Jerúsálẹ́mù nípasẹ̀ idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn.*+ 14 Àṣẹ́kù Júdà tí wọ́n lọ ń gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì kò ní lè sá àsálà tàbí kí wọ́n yè bọ́ láti pa dà sí ilẹ̀ Júdà. Á wù wọ́n* pé kí wọ́n pa dà, kí wọ́n sì máa gbé ibẹ̀, àmọ́ wọn ò ní lè pa dà, àyàfi àwọn díẹ̀ tó máa sá àsálà.’”
15 Gbogbo ọkùnrin tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ìyàwó wọn ti ń rú ẹbọ sí àwọn ọlọ́run míì àti gbogbo àwọn ìyàwó tí wọ́n wà níbẹ̀, tí wọ́n jẹ́ àwùjọ ńlá àti gbogbo èèyàn tó ń gbé nílẹ̀ Íjíbítì,+ ní Pátírọ́sì,+ dá Jeremáyà lóhùn pé: 16 “A ò ní fetí sí ọ̀rọ̀ tí o sọ fún wa ní orúkọ Jèhófà. 17 Kàkà bẹ́ẹ̀, a ó rí i dájú pé a ṣe gbogbo ohun tó ti ẹnu wa jáde, láti rú ẹbọ sí Ọbabìnrin Ọ̀run* àti láti da ọrẹ ohun mímu jáde sí i,+ bí àwa àti àwọn baba ńlá wa, àwọn ọba wa àti àwọn ìjòyè wa ti ṣe ní àwọn ìlú Júdà àti ní àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù, nígbà tí a máa ń jẹ oúnjẹ ní àjẹtẹ́rùn, tí nǹkan sì ń dáa fún wa, tí a kò sì rí àjálù kankan. 18 Láti ìgbà tí a ò ti rúbọ sí Ọbabìnrin Ọ̀run* mọ́, tí a ò sì da ọrẹ ohun mímu jáde sí i ni a ti ṣaláìní ohun gbogbo, tí idà àti ìyàn sì ti mú kí á ṣègbé.”
19 Àwọn obìnrin náà sọ pé: “Nígbà tí à ń rú ẹbọ sí Ọbabìnrin Ọ̀run,* tí a sì ń da ọrẹ ohun mímu jáde sí i, ṣebí àwọn ọkọ wa lọ́wọ́ sí i pé kí a máa ṣe àkàrà ìrúbọ ní ìrísí rẹ̀, kí a sì máa da ọrẹ ohun mímu jáde sí i?”
20 Nígbà náà, Jeremáyà sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà, ìyẹn àwọn ọkùnrin àti àwọn ìyàwó wọn àti gbogbo àwọn tó ń bá a sọ̀rọ̀, ó ní: 21 “Ẹbọ tí ẹ rú, tí àwọn baba ńlá yín, àwọn ọba yín, àwọn ìjòyè yín àti àwọn èèyàn ilẹ̀ náà rú ní àwọn ìlú Júdà àti ní àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù,+ ni Jèhófà ti rántí, wọ́n sì wá sí i lọ́kàn! 22 Níkẹyìn, Jèhófà kò lè fara da ìwà ibi yín mọ́ àti àwọn ohun ìríra tí ẹ ti ṣe, torí náà ilẹ̀ yín pa run, ó di ohun àríbẹ̀rù àti ègún, kò sì sí ẹnikẹ́ni tó ń gbé ibẹ̀, bó ṣe rí lónìí yìí.+ 23 Nítorí ẹ ti rú àwọn ẹbọ yìí àti pé ẹ ti ṣẹ̀ sí Jèhófà, tí ẹ kò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà, tí ẹ kò sì pa òfin àti ìlànà rẹ̀ mọ́ pẹ̀lú àwọn ìránnilétí rẹ̀, ìdí nìyẹn tí àjálù yìí fi bá yín bó ṣe rí lónìí yìí.”+
24 Jeremáyà sì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà àti gbogbo àwọn obìnrin náà pé: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ará Júdà tó wà ní ilẹ̀ Íjíbítì. 25 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Ohun tí ẹ̀yin àti àwọn ìyàwó yín ti fi ẹnu yín sọ, ni ẹ fi ọwọ́ yín mú ṣẹ, torí ẹ sọ pé: “Àá rí i dájú pé a mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ pé a ó rú ẹbọ sí Ọbabìnrin Ọ̀run,* a ó sì da ọrẹ ohun mímu jáde sí i.”+ Ó dájú pé ẹ̀yin obìnrin yìí máa mú ẹ̀jẹ́ yín ṣẹ, ẹ ó sì pa ẹ̀jẹ́ yín mọ́.’
26 “Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ará Júdà tó ń gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì: ‘“Wò ó, mo fi orúkọ ńlá mi búra,” ni Jèhófà wí, “pé èyíkéyìí lára èèyàn Júdà+ tó wà ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì kò ní pe orúkọ mi mọ́ nígbà ìbúra pé, ‘Bí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti wà láàyè!’+ 27 Wò ó, ojú mi wà lára wọn fún àjálù, kì í ṣe fún ohun rere;+ gbogbo àwọn ọkùnrin Júdà tó wà ní ilẹ̀ Íjíbítì ni idà àti ìyàn yóò pa, títí wọn kò fi ní sí mọ́.+ 28 Àwọn díẹ̀ ló máa bọ́ lọ́wọ́ idà, tí wọ́n á sì pa dà láti ilẹ̀ Íjíbítì sí ilẹ̀ Júdà.+ Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù nílẹ̀ Júdà, tí wọ́n wá sí ilẹ̀ Íjíbítì láti máa gbé ibẹ̀, máa mọ ẹni tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ, bóyá tèmi ni tàbí tiwọn!”’”
29 “‘Àmì tó wà fún yín nìyí,’ ni Jèhófà wí, ‘pé màá fìyà jẹ yín ní ibí yìí, kí ẹ lè mọ̀ pé àjálù tí mo ṣèlérí fún yín yóò ṣẹ dájúdájú. 30 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Wò ó, màá fi Fáráò Hófírà, ọba Íjíbítì, lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀ àti lé ọwọ́ àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀,* bí mo ṣe fi Sedekáyà ọba Júdà lé ọwọ́ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, ẹni tó jẹ́ ọ̀tá rẹ̀, tó sì fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀.”’”*+
45 Ọ̀rọ̀ tí wòlíì Jeremáyà sọ fún Bárúkù+ ọmọ Neráyà nìyí, nígbà tó ń kọ ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà ń sọ fún un sínú ìwé+ ní ọdún kẹrin Jèhóákímù+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà:
2 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nípa rẹ nìyí, ìwọ Bárúkù, 3 ‘O sọ pé: “Mo gbé! Nítorí pé Jèhófà ti fi ẹ̀dùn ọkàn kún ìrora mi. Àárẹ̀ mú mi nítorí ìrora mi, mi ò sì rí ibi ìsinmi kankan.”’
4 “Kí o sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Wò ó! Ohun tí mo ti kọ́ ni màá ya lulẹ̀, ohun tí mo sì ti gbìn ni màá fà tu, ìyẹn gbogbo ilẹ̀ náà.+ 5 Ṣùgbọ́n ìwọ ń wá* àwọn ohun ńlá fún ara rẹ. Má ṣe wá wọn mọ́.”’
“‘Nítorí mo máa tó mú àjálù wá bá gbogbo èèyàn,’*+ ni Jèhófà wí, ‘àmọ́ màá jẹ́ kí o jèrè ẹ̀mí rẹ* ní ibikíbi tí o bá lọ.’”+
46 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún wòlíì Jeremáyà nípa àwọn orílẹ̀-èdè nìyí:+ 2 Sí Íjíbítì,+ nípa àwọn ọmọ ogun Fáráò Nékò + ọba Íjíbítì, tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Yúfírétì, ẹni tí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì ṣẹ́gun ní Kákémíṣì, ní ọdún kẹrin Jèhóákímù+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà:
3 “Ẹ to asà* àti apata ńlá,
Ẹ sì jáde lọ sójú ogun.
4 Ẹ fi ìjánu sí ẹṣin, kí ẹ sì gùn ún, ẹ̀yin agẹṣin.
Ẹ lọ dúró sí àyè yín, kí ẹ sì dé akoto.*
Ẹ dán aṣóró, kí ẹ sì wọ ẹ̀wù irin.
5 ‘Kí nìdí tí mo fi rí wọn tí jìnnìjìnnì bò wọ́n?
Wọ́n ń sá pa dà, àwọn jagunjagun wọn ni a ti lù bolẹ̀.
Wọ́n ti sá lọ tẹ̀rùtẹ̀rù, àwọn jagunjagun wọn kò sì bojú wẹ̀yìn.
Ìbẹ̀rù wà níbi gbogbo,’ ni Jèhófà wí.
6 ‘Àwọn tí ẹsẹ̀ wọn yá nílẹ̀ kò lè sá lọ, àwọn jagunjagun kò sì lè sá àsálà.
Ní àríwá, lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Yúfírétì,
Wọ́n ti kọsẹ̀, wọ́n sì ti ṣubú.’+
7 Ta ló ń bọ̀ yìí bí odò Náílì,
Bí odò tí omi rẹ̀ ń ru gùdù?
8 Íjíbítì ń gòkè bọ̀ bí odò Náílì,+
Bí odò tí omi rẹ̀ ń ru gùdù,
Ó sì sọ pé, ‘Màá gòkè lọ, màá sì bo ilẹ̀ ayé.
Màá pa ìlú náà àti àwọn tó ń gbé inú rẹ̀ run.’
9 Ẹ gòkè lọ, ẹ̀yin ẹṣin!
Ẹ sá eré àsápajúdé, ẹ̀yin kẹ̀kẹ́ ẹṣin!
Kí àwọn jagunjagun jáde lọ,
Kúṣì àti Pútì, tí wọ́n mọ apata lò,+
Pẹ̀lú àwọn Lúdímù,+ tí wọ́n mọ ọrun tẹ̀,* tí wọ́n sì mọ̀ ọ́n lò,+
10 “Ọjọ́ yẹn jẹ́ ti Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ọjọ́ ẹ̀san tó máa gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀. Idà máa pa wọ́n ní àpatẹ́rùn, á sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn ní àmuyó, nítorí Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ní ẹbọ* kan ní ilẹ̀ àríwá lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Yúfírétì.+
11 Gòkè lọ sí Gílíádì láti mú básámù wá,+
Ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Íjíbítì.
Asán ni o sọ oògùn rẹ di púpọ̀,
Torí kò sí ìwòsàn fún ọ.+
12 Àwọn orílẹ̀-èdè ti gbọ́ nípa àbùkù rẹ,+
Igbe ẹkún rẹ sì ti kún ilẹ̀ náà.
Nítorí jagunjagun ń kọsẹ̀ lára jagunjagun,
Àwọn méjèèjì sì jọ ṣubú lulẹ̀.”
13 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún wòlíì Jeremáyà nípa bí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì ṣe máa wá pa ilẹ̀ Íjíbítì rẹ́ nìyí:+
14 “Sọ ọ́ ní Íjíbítì, sì kéde rẹ̀ ní Mígídólì.+
Kéde rẹ̀ ní Nófì* àti ní Tápánẹ́sì.+
Sọ pé, ‘Ẹ dúró sí àyè yín, kí ẹ sì múra sílẹ̀,
Nítorí idà kan máa pani run ní gbogbo àyíká yín.
15 Kí nìdí tí a fi gbá àwọn alágbára ọkùnrin yín lọ?
Wọn kò lè dúró,
Nítorí Jèhófà ti tì wọ́n ṣubú.
16 Iye àwọn tó ń kọsẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣubú pọ̀ gan-an.
Ẹnì kìíní ń sọ fún ẹnì kejì rẹ̀ pé:
“Dìde! Jẹ́ kí a pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn wa àti sí ìlú ìbílẹ̀ wa
Nítorí idà tó ń hanni léèmọ̀.”’
18 ‘Bí mo ti wà láàyè,’ ni Ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,
‘Ó* máa wọlé wá bíi Tábórì+ láàárín àwọn òkè
Àti bíi Kámẹ́lì+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun.
19 Di ẹrù tí o máa gbé lọ sí ìgbèkùn,
Ìwọ ọmọbìnrin tó ń gbé ní Íjíbítì.
20 Íjíbítì dà bí abo ọmọ màlúù tó lẹ́wà,
Àmọ́ kòkòrò tó ń tani máa wá bá a láti àríwá.
21 Kódà àwọn ọmọ ogun tí ó háyà tó wà láàárín rẹ̀ dà bí ọmọ màlúù àbọ́sanra,
Ṣùgbọ́n àwọn náà ti pẹ̀yìn dà, wọ́n sì jọ sá lọ.
22 ‘Ìró rẹ̀ dà bíi ti ejò tó ń sá lọ,
Nítorí wọ́n ń fi àáké lé e tagbáratagbára,
Bí àwọn ọkùnrin tó ń gé igi.*
23 Wọ́n á gé igbó rẹ̀ lulẹ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘bó tiẹ̀ dà bíi pé inú rẹ̀ kò ṣeé wọ̀.
Nítorí wọ́n pọ̀ ju eéṣú lọ, wọn ò sì níye.
24 Ojú máa ti ọmọbìnrin Íjíbítì.
A ó fà á lé ọwọ́ àwọn èèyàn àríwá.’+
25 “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ pé: ‘Wò ó, màá yíjú sí Ámọ́nì+ láti Nóò*+ àti sí Fáráò àti Íjíbítì àti àwọn ọlọ́run rẹ̀+ àti àwọn ọba rẹ̀, àní màá yíjú sí Fáráò àti gbogbo àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e.’+
26 “‘Màá fà wọ́n lé ọwọ́ àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí* wọn, lé ọwọ́ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì+ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n á máa gbé inú rẹ̀ bíi ti àtijọ́,’ ni Jèhófà wí.+
27 ‘Ní tìrẹ, má fòyà, ìwọ Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi,
Má sì jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, ìwọ Ísírẹ́lì.+
Jékọ́bù á pa dà, ara rẹ̀ á balẹ̀, kò ní rí ìyọlẹ́nu,
Ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.+
28 Torí náà, má fòyà, ìwọ Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi,’ ni Jèhófà wí, ‘torí pé mo wà pẹ̀lú rẹ.
47 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nìyí fún wòlíì Jeremáyà nípa àwọn Filísínì,+ kí Fáráò tó pa Gásà run. 2 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Wò ó! Omi ń bọ̀ láti àríwá.
Ó máa di ọ̀gbàrá tó kún àkúnya.
Á sì kún bo ilẹ̀ náà àti gbogbo ohun tó wà lórí rẹ̀,
Pẹ̀lú ìlú náà àti àwọn tó ń gbé inú rẹ̀.
Àwọn ọkùnrin á figbe ta,
Gbogbo ẹni tó ń gbé ilẹ̀ náà á sì pohùn réré ẹkún.
3 Nígbà tí pátákò àwọn akọ ẹṣin rẹ̀ bá ń kilẹ̀,
Tí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ń dún
Tí àgbá kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ń rọ́ gìrìgìrì,
Àwọn bàbá kò tiẹ̀ ní bojú wẹ̀yìn wo àwọn ọmọ wọn,
Nítorí ọwọ́ wọn ti rọ,
4 Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ tí gbogbo Filísínì máa pa run;+
Gbogbo olùrànlọ́wọ́ tó ṣẹ́ kù ní Tírè+ àti Sídónì+ la máa gé kúrò.
5 Orí pípá* máa dé bá Gásà.
A ti pa Áṣíkẹ́lónì lẹ́nu mọ́.+
6 Áà! Idà Jèhófà!+
Ìgbà wo lo máa tó gbé jẹ́ẹ́?
Pa dà sínú àkọ̀ rẹ.
Sinmi, kí o sì dákẹ́.
7 Báwo ló ṣe máa gbé jẹ́ẹ́
Nígbà tí Jèhófà ti pàṣẹ fún un?
Ó ti yàn án pé kí ó gbéjà ko
Áṣíkẹ́lónì àti etí òkun.”+
48 Sí Móábù,+ ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nìyí:
“Nébò gbé! + nítorí wọ́n ti pa á run.
Ìtìjú ti bá Kiriátáímù,+ wọ́n sì ti gbà á.
Ìtìjú ti bá ibi ààbò,* wọ́n sì ti wó o lulẹ̀.+
2 Wọn ò yin Móábù mọ́.
Hẹ́ṣíbónì+ ni wọ́n ti gbèrò ìṣubú rẹ̀, pé:
‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á run, kí ó má ṣe jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́.’
Kí ìwọ Mádíménì pẹ̀lú dákẹ́,
Torí idà ń tẹ̀ lé ọ.
3 Ìró ẹkún wá láti Hórónáímù,+
Ti ìparun àti ìwópalẹ̀ tó bùáyà.
4 A ti pa Móábù run.
Àwọn ọmọ rẹ̀ kéékèèké figbe ta.
5 Bí wọ́n ṣe ń gòkè lọ ní Lúhítì, wọn ò dákẹ́ ẹkún.
Nígbà tí wọ́n sì ń sọ̀ kalẹ̀ láti Hórónáímù, wọ́n ń gbọ́ igbe ìdààmú nítorí àjálù.+
6 Ẹ fẹsẹ̀ fẹ, ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí* yín!
Kí ẹ sì dà bí igi júnípà ní aginjù.
7 Nítorí o gbẹ́kẹ̀ lé iṣẹ́ rẹ àti àwọn ìṣúra rẹ,
A ó mú ìwọ náà lẹ́rú.
Kémóṣì+ máa lọ sí ìgbèkùn,
Pẹ̀lú àwọn àlùfáà rẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀.
8 Apanirun máa wá sórí gbogbo ìlú,
Ìlú kankan ò sì ní yè bọ́.+
9 Ẹ ṣe àmì tó máa fọ̀nà han Móábù,
Torí nígbà tí àwọn ìlú rẹ̀ bá di àwókù, á sá lọ,
Àwọn ìlú rẹ̀ á sì di ohun àríbẹ̀rù,
Ẹnì kankan kò sì ní gbé ibẹ̀.+
10 Ègún ni fún ẹni tó ń fi ọwọ́ dẹngbẹrẹ mú iṣẹ́ tí Jèhófà rán an!
Ègún ni fún ẹni tí kò fi idà rẹ̀ ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀!
11 Àwọn ọmọ Móábù ti wà láìsí ìyọlẹ́nu látìgbà èwe wọn,
Bíi wáìnì tó silẹ̀ sórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀.
A kò dà á látinú ohun èlò kan sínú ohun èlò míì,
Wọn ò sì lọ sí ìgbèkùn rí.
Ìdí nìyẹn tí ìtọ́wò wọn kò fi yí pa dà,
Tí ìtasánsán wọn kò sì yàtọ̀.
12 “‘Nítorí náà, wò ó! ọjọ́ ń bọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘tí màá rán àwọn ọkùnrin láti dojú wọn dé. Wọ́n á dojú wọn kọlẹ̀, wọ́n á da gbogbo ohun tó wà nínú ohun èlò wọn jáde, wọ́n á sì fọ́ àwọn ìṣà ńlá wọn sí wẹ́wẹ́. 13 Ojú á ti àwọn ọmọ Móábù nítorí Kémóṣì, bí ojú ṣe ti ilé Ísírẹ́lì nítorí Bẹ́tẹ́lì tí wọ́n gbọ́kàn lé.+
14 Ẹ ṣe lè sọ pé: “Jagunjagun tó lákíkanjú ni wá, a ti múra ogun”?’+
15 ‘Wọ́n ti pa Móábù run,
Wọ́n ti ya wọnú àwọn ìlú rẹ̀,+
Àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn tó dára jù lọ ni a ti pa,’+
Ni Ọba tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.+
16 Àjálù àwọn ọmọ Móábù kò ní pẹ́ dé mọ́,
Ìṣubú wọn sì ń yára bọ̀ kánkán.+
17 Gbogbo àwọn tó yí wọn ká máa ní láti bá wọn kẹ́dùn,
Gbogbo àwọn tó mọ orúkọ wọn.
Ẹ sọ fún wọn pé: ‘Ẹ wo bí a ti ṣẹ́ ọ̀pá tó lágbára, ọ̀pá ẹwà!’
18 Sọ̀ kalẹ̀ kúrò nínú ògo rẹ,
Sì jókòó nínú òùngbẹ,* ìwọ ọmọbìnrin tó ń gbé ní Díbónì,+
Nítorí ẹni tó pa Móábù run ti wá gbéjà kò ọ́,
Ó sì máa pa àwọn ibi olódi rẹ run.+
19 Dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, kí o sì máa ṣọ́nà, ìwọ tó ń gbé ní Áróérì.+
Béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin tó ń sá lọ àti lọ́wọ́ obìnrin tó ń sá àsálà pé, ‘Kí ló ṣẹlẹ̀?’
20 Ìtìjú ti bá Móábù, jìnnìjìnnì sì ti bò ó.
Ẹ pohùn réré ẹkún, kí ẹ sì figbe ta.
Ẹ kéde rẹ̀ ní Áánónì+ pé wọ́n ti pa Móábù run.
21 “Ìdájọ́ ti dé sí ilẹ̀ tó tẹ́jú,*+ sórí Hólónì àti Jáhásì+ àti sórí Mẹ́fáátì;+ 22 sórí Díbónì+ àti Nébò+ àti sórí Bẹti-dibilátáímù; 23 sórí Kiriátáímù + àti Bẹti-gámúlì àti sórí Bẹti-méónì;+ 24 sórí Kéríótì+ àti Bósírà àti sórí gbogbo àwọn ìlú tó wà ní ilẹ̀ Móábù, àwọn tó jìnnà àti àwọn tó wà nítòsí.
25 ‘A ti gba agbára* Móábù;
A sì ti ṣẹ́ apá rẹ̀,’ ni Jèhófà wí.
26 ‘Ẹ rọ ọ́ yó,+ nítorí ó ti gbé ara rẹ̀ ga sí Jèhófà.+
Móábù ń yíràá nínú èébì rẹ̀,
Ó sì ti di ẹni ẹ̀sín.
27 Ǹjẹ́ kì í ṣe ẹni ẹ̀sín ni Ísírẹ́lì jẹ́ lójú rẹ?+
Ṣé o rí i láàárín àwọn olè ni,
Tí o fi mi orí rẹ, tí o sì sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí i?
28 Ẹ fi àwọn ìlú sílẹ̀, kí ẹ sì lọ máa gbé lórí àpáta, ẹ̀yin tó ń gbé ní Móábù,
Kí ẹ sì dà bí àdàbà tó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àfonífojì.’”
29 “A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Móábù, ó gbéra ga gan-an,
Nípa ìjọra-ẹni-lójú rẹ̀, ìgbéraga rẹ̀, ìṣefọ́nńté rẹ̀ àti nípa ọkàn gíga rẹ̀.”+
30 “‘Mo mọ̀ pé inú bí i gan-an,’ ni Jèhófà wí,
‘Àmọ́, ó kàn ń fọ́nnu lásán ni.
Kò lè ṣe nǹkan kan.
31 Ìdí nìyẹn tí màá fi pohùn réré ẹkún lórí Móábù,
Màá figbe ta nítorí gbogbo Móábù
Màá sì kédàárò nítorí àwọn ọkùnrin Kiri-hérésì.+
Àwọn ọ̀mùnú rẹ tó yọ ti sọdá òkun.
Wọ́n ti dé òkun, wọ́n sì ti dé Jásérì.
Apanirun ti balẹ̀+
Sórí èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn rẹ àti èso àjàrà tí o kó jọ.
33 Ìdùnnú àti ayọ̀ ti kúrò nínú ọgbà eléso
Àti ní ilẹ̀ Móábù.+
Mo sì ti mú kí wáìnì dá níbi tí wọ́n ti ń fún wáìnì.
Kò sí ẹni tí á máa kígbe ayọ̀ bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ ẹ́.
Igbe náà máa yàtọ̀ pátápátá.’”+
34 “‘Igbe kan dún láti Hẹ́ṣíbónì+ títí lọ dé Éléálè.+
Àní omi Nímúrímù máa gbẹ.+
35 Màá mú kí òpin dé bá wọn ní Móábù,’ ni Jèhófà wí,
‘Á dé bá ẹni tó ń mú ọrẹ wá sí ibi gíga
Àti ẹni tó ń rú ẹbọ sí ọlọ́run rẹ̀.
36 Ìdí nìyẹn tí ọkàn mi á fi kédàárò* nítorí Móábù bíi fèrè,*+
Ọkàn mi á sì kédàárò* nítorí àwọn ọkùnrin Kiri-hérésì bíi fèrè.*
Nítorí ọrọ̀ tí ó kó jọ máa ṣègbé.
37 Nítorí gbogbo orí ti pá,+
Gbogbo irùngbọ̀n ni a sì gé mọ́lẹ̀.
38 “‘Lórí gbogbo òrùlé Móábù
Àti ní àwọn gbàgede ìlú rẹ̀,
Kò sí nǹkan míì, àfi ìpohùnréré ẹkún.
Nítorí mo ti fọ́ Móábù
Bí ìṣà tí a sọ nù,’ ni Jèhófà wí.
39 ‘Ẹ wo bi ẹ̀rù ti bà á tó! Ẹ pohùn réré ẹkún!
Ẹ wo bí Móábù ṣe sá pa dà nítorí ìtìjú!
Móábù ti di ẹni ẹ̀sín,
Ó sì jẹ́ ohun tó ń bani lẹ́rù sí gbogbo àwọn tó yí i ká.’”
40 “Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
41 Wọ́n á gba àwọn ìlú rẹ̀,
Wọ́n á sì gba àwọn odi agbára rẹ̀.
Ní ọjọ́ yẹn, ọkàn àwọn jagunjagun Móábù
Máa dà bí ọkàn obìnrin tó ń rọbí.’”
43 Ìbẹ̀rù àti kòtò àti pańpẹ́ wà níwájú rẹ,
Ìwọ tó ń gbé ní Móábù,’ ni Jèhófà wí.
44 ‘Ẹnikẹ́ni tó bá ń sá lọ nítorí ìbẹ̀rù á já sínú kòtò,
Pańpẹ́ sì máa mú ẹnikẹ́ni tó bá jáde látinú kòtò.’
‘Nítorí màá jẹ́ kí ọdún ìyà Móábù dé bá a,’ ni Jèhófà wí.
45 ‘Lábẹ́ òjìji Hẹ́ṣíbónì ni àwọn tó ń sá lọ ti dúró láìní agbára.
Nítorí iná máa jáde wá láti Hẹ́ṣíbónì
Àti ọwọ́ iná láti àárín Síhónì.+
Á jó iwájú orí Móábù
Àti agbárí àwọn ọmọ ìdàrúdàpọ̀.’+
46 ‘O gbé! Ìwọ Móábù.
Àwọn èèyàn Kémóṣì+ ti ṣègbé.
Nítorí a ti mú àwọn ọmọkùnrin rẹ lẹ́rú,
Àwọn ọmọbìnrin rẹ sì ti lọ sí ìgbèkùn.+
47 Ṣùgbọ́n màá kó àwọn ará Móábù tó wà lóko ẹrú jọ ní ọjọ́ ìkẹyìn,’ ni Jèhófà wí.
‘Ibí ni ìdájọ́ Móábù parí sí.’”+
49 Sí àwọn ọmọ Ámónì,+ ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Ṣé Ísírẹ́lì kò ní ọmọ ni?
Ṣé kò ní ẹni tó máa jogún rẹ̀ ni?
Kí ló dé tí Málíkámù+ fi gba Gádì?+
Tí àwọn èèyàn rẹ̀ sì ń gbé inú àwọn ìlú Ísírẹ́lì?”
2 “‘Nítorí náà, wò ó! ọjọ́ ń bọ̀,’ ni Jèhófà wí,
Ó máa di àwókù,
Wọ́n á sì dáná sun àwọn àrọko* rẹ̀.’
‘Ísírẹ́lì á sì sọ àwọn tó gba tọwọ́ rẹ̀ di ohun ìní,’+ ni Jèhófà wí.
3 ‘Pohùn réré ẹkún, ìwọ Hẹ́ṣíbónì nítorí wọ́n ti pa Áì run!
Ẹ figbe ta, ẹ̀yin àrọko Rábà.
Wọ aṣọ ọ̀fọ̀.*
Pohùn réré ẹkún, kí o sì lọ káàkiri láàárín àwọn ọgbà ẹran tí a fi òkúta ṣe,*
Nítorí Málíkámù máa lọ sí ìgbèkùn,
Pẹ̀lú àwọn àlùfáà rẹ̀ àti àwọn ọmọ aládé rẹ̀.+
4 Kí nìdí tí o fi ń fọ́nnu nípa àwọn àfonífojì* rẹ,
Nípa pẹ̀tẹ́lẹ̀ rẹ tó lọ́ràá,* ìwọ aláìṣòótọ́ ọmọbìnrin,
Tí o gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìṣúra rẹ
Tí o sì ń sọ pé: “Ta ló lè wá bá mi jà?”’”
5 “‘Wò ó, màá mú ohun tó ń dẹ́rù bani wá bá ọ,’ ni Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí,
‘Láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó yí ọ ká.
Wọ́n á fọ́n yín ká sí ibi gbogbo,
Ẹnikẹ́ni kò sì ní kó àwọn tó sá lọ jọ.’”
6 “‘Àmọ́ lẹ́yìn náà, màá kó àwọn ọmọ Ámónì tó wà lóko ẹrú jọ,’ ni Jèhófà wí.”
7 Sí Édómù, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:
“Ṣé kò sí ọgbọ́n mọ́ ní Témánì ni?+
Ṣé kò sí ìmọ̀ràn rere mọ́ lọ́dọ̀ àwọn olóye ni?
Ṣé ọgbọ́n wọn ti jẹrà ni?
8 Ẹ sá pa dà!
Ẹ lọ máa gbé ní àwọn ibi tó jin kòtò, ẹ̀yin tó ń gbé ní Dédánì!+
Nítorí màá mú àjálù bá Ísọ̀
Nígbà tí àkókò tí màá yí ojú mi sí i bá tó.
9 Bí àwọn tó ń kó èso àjàrà jọ bá wá bá ọ,
Ṣé wọn ò ní ṣẹ́ díẹ̀ kù fáwọn tó ń pèéṣẹ́?*
Bí àwọn olè bá wá bá ọ ní òru,
Gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́ nìkan ni wọ́n á kó.+
10 Ṣùgbọ́n, ṣe ni màá tú Ísọ̀ sí borokoto.
Màá tú àwọn ibi tó ń sá pa mọ́ sí síta,
Kó má lè rí ibi sá pa mọ́ sí mọ́.
11 Fi àwọn ọmọ rẹ tí kò ní baba sílẹ̀,
Màá sì mú kí wọ́n máa wà láàyè,
Àwọn opó rẹ á sì gbẹ́kẹ̀ lé mi.”
12 Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Wò ó! Bí àwọn tí kò jẹ̀bi láti mu ife náà bá ní láti mu ún ní dandan, ṣé ó wá yẹ kí a fi ọ́ sílẹ̀ láìjìyà? A ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láìjìyà, nítorí o gbọ́dọ̀ mu ún.”+
13 “Nítorí mo ti fi ara mi búra,” ni Jèhófà wí, “pé Bósírà á di ohun àríbẹ̀rù,+ ohun ẹ̀gàn, ibi ìparun àti ègún; gbogbo àwọn ìlú rẹ̀ á sì di àwókù títí láé.”+
14 Mo ti gbọ́ ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Jèhófà,
Aṣojú kan ti lọ jíṣẹ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè pé:
“Ẹ kóra jọ, ẹ wá gbéjà kò ó;
Ẹ sì múra ogun.”+
15 “Nítorí, wò ó! Mo ti sọ ọ́ di ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,
O ti tẹ́ láàárín àwọn èèyàn.+
16 Bí o ṣe ń kó jìnnìjìnnì bá àwọn èèyàn
Àti ìgbéraga* ọkàn rẹ ti tàn ọ́ jẹ,
Ìwọ tó ń gbé ihò inú àpáta,
Tí ò ń gbé ní òkè tó ga jù lọ.
Bí o bá tiẹ̀ kọ́ ìtẹ́ rẹ sí ibi gíga bí ẹyẹ idì,
Màá rẹ̀ ọ́ wálẹ̀ láti ibẹ̀,” ni Jèhófà wí.
17 “Édómù á di ohun àríbẹ̀rù.+ Gbogbo ẹni tó bá ń kọjá lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ á wò ó, ẹ̀rù á bà á, á sì súfèé nítorí gbogbo ìyọnu tó bá Édómù. 18 Bí Sódómù àti Gòmórà àti àwọn ìlú tó yí wọn ká ṣe pa run,”+ ni Jèhófà wí, “kò ní sí ẹnì kankan tí á máa gbé ibẹ̀, kò sì ní sí èèyàn kankan tó máa tẹ̀ dó síbẹ̀.+
19 “Wò ó! Ẹnì kan máa wá gbéjà ko àwọn ibi ìjẹko Édómù tó wà ní ààbò bíi kìnnìún+ tó jáde látinú igbó kìjikìji lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì, ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan, màá mú kí ó sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Màá sì yan àyànfẹ́ lé e lórí. Nítorí ta ló dà bí èmi, ta ló lè sọ pé kí ni mò ń ṣe? Olùṣọ́ àgùntàn wo ló sì lè dúró níwájú mi?+ 20 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ìpinnu* tí Jèhófà ṣe lórí Édómù àti ohun tí ó ti rò nípa àwọn tó ń gbé ní Témánì:+
Ó dájú pé, a ó wọ́ àwọn ẹran kéékèèké inú agbo ẹran lọ.
Ó máa sọ ibùgbé wọn di ahoro nítorí wọn.+
21 Nígbà tí wọ́n ṣubú, ìró wọn mú kí ilẹ̀ mì tìtì.
Igbe ẹkún wà!
A gbọ́ ìró wọn títí dé Òkun Pupa.+
Ní ọjọ́ yẹn, ọkàn àwọn jagunjagun Édómù
Máa dà bí ọkàn obìnrin tó ń rọbí.”
23 Sí Damásíkù:+
“Ìtìjú ti bá Hámátì+ àti Áápádì,
Nítorí wọ́n ti gbọ́ ìròyìn búburú.
Ìbẹ̀rù mú kí ọkàn wọn domi.
Wọ́n dà bí òkun tó ń ru gùdù, tí kò ṣeé mú rọlẹ̀.
24 Damásíkù ti rẹ̀wẹ̀sì.
Ó pẹ̀yìn dà láti sá lọ, àmọ́ jìnnìjìnnì bò ó.
Ìdààmú àti ìrora ti bá a,
Bí obìnrin tó ń rọbí.
25 Báwo ló ṣe jẹ́ pé a kò tíì pa ìlú ìyìn tì,
Ìlú ayọ̀?
26 Nítorí àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀ á ṣubú ní àwọn gbàgede rẹ̀,
Gbogbo àwọn ọmọ ogun á ṣègbé ní ọjọ́ yẹn,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
27 “Màá sọ iná sí ògiri Damásíkù,
Á sì jó àwọn ilé gogoro tó láàbò ti Bẹni-hádádì run.”+
28 Sí Kídárì+ àti àwọn ìjọba Hásórì, àwọn tí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì pa run, ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Ẹ dìde, ẹ gòkè lọ sí Kídárì,
Kí ẹ sì pa àwọn ọmọ Ìlà Oòrùn.
29 A ó gba àgọ́ wọn àti àwọn agbo ẹran wọn,
Aṣọ àgọ́ wọn àti gbogbo ohun ìní wọn.
Àwọn ràkúnmí wọn ni a ó kó lọ,
Wọ́n á sì kígbe sí wọn pé, ‘Ìbẹ̀rù wà níbi gbogbo!’”
30 “Ẹ sá, ẹ lọ jìnnà!
Ẹ lọ máa gbé ní àwọn ibi tó jin kòtò, ẹ̀yin tó ń gbé ní Hásórì,” ni Jèhófà wí.
“Nítorí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì ti gbèrò ohun kan tó fẹ́ ṣe sí yín,
Ó sì ti ro ohun kan tó fẹ́ ṣe sí yín.”
31 “Ẹ dìde, ẹ gòkè lọ láti gbéjà ko orílẹ̀-èdè tó wà lálàáfíà,
Tó ń gbé lábẹ́ ààbò!” ni Jèhófà wí.
“Kò ní ilẹ̀kùn, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ọ̀pá ìdábùú; ṣe ni wọ́n ń dá gbé.
32 A ó kó ràkúnmí wọn lọ,
Ohun ọ̀sìn wọn tó pọ̀ rẹpẹtẹ ni a ó sì kó bí ẹrù ogun.
Màá tú wọn ká síbi gbogbo,*
Àwọn tí wọ́n gé irun wọn mọ́lẹ̀ ní ẹ̀bátí,+
Màá sì mú àjálù wọn wá láti ibi gbogbo,” ni Jèhófà wí.
33 “Hásórì máa di ibi tí ajáko* ń gbé,
Á di ahoro títí láé.
Ẹnì kankan ò ní gbé ibẹ̀,
Èèyàn kankan ò sì ní tẹ̀ dó sí ibẹ̀.”
34 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún wòlíì Jeremáyà nípa Élámù+ ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso Sedekáyà+ ọba Júdà, nìyí: 35 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Wò ó, màá ṣẹ́ ọrun Élámù,+ tó jẹ́ agbára tó gbójú lé.* 36 Màá mú ẹ̀fúùfù mẹ́rin láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run wá sórí Élámù, màá sì tú wọn ká sí gbogbo ẹ̀fúùfù yìí. Kò ní sí orílẹ̀-èdè kankan tí àwọn tí a fọ́n ká láti Élámù kò ní dé.’”
37 “Màá fọ́ àwọn ọmọ Élámù túútúú níwájú àwọn ọ̀tá wọn àti níwájú àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí wọn,”* ni Jèhófà wí, “màá sì mú àjálù bá wọn, ìbínú mi tó ń jó bí iná. Màá sì rán idà tẹ̀ lé wọn títí màá fi pa wọ́n run.”
38 “Màá gbé ìtẹ́ mi kalẹ̀ ní Élámù,+ màá sì pa ọba àti àwọn ìjòyè run kúrò níbẹ̀,” ni Jèhófà wí.
39 “Àmọ́ ní ọjọ́ ìkẹyìn, màá kó àwọn ará Élámù tó wà lóko ẹrú jọ,” ni Jèhófà wí.
50 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa Bábílónì,+ nípa ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà, nípasẹ̀ wòlíì Jeremáyà nìyí:
2 “Ẹ sọ ọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè kí ẹ sì kéde rẹ̀.
Ẹ gbé àmì kan dúró,* ẹ sì kéde rẹ̀.
Ẹ má fi nǹkan kan pa mọ́!
Ẹ sọ pé, ‘Wọ́n ti gba Bábílónì.+
Ìtìjú ti bá Bélì.+
Méródákì wà nínú ìbẹ̀rù.
Ìtìjú ti bá àwọn ère rẹ̀.
Àwọn òrìṣà ẹ̀gbin rẹ̀* wà nínú ìbẹ̀rù.’
3 Nítorí orílẹ̀-èdè kan ti wá gbéjà kò ó láti àríwá.+
Ó ti sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ohun àríbẹ̀rù;
Kò sì sí ẹni tó ń gbé inú rẹ̀.
Èèyàn àti ẹranko ti fẹsẹ̀ fẹ;
Wọ́n ti lọ.”
4 “Ní àwọn ọjọ́ yẹn àti ní àkókò yẹn,” ni Jèhófà wí, “àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti àwọn èèyàn Júdà máa kóra jọ.+ Wọ́n á máa sunkún bí wọ́n ṣe ń rìn lọ,+ wọ́n á sì jọ máa wá Jèhófà Ọlọ́run wọn.+ 5 Wọ́n á béèrè ọ̀nà tó lọ sí Síónì, wọ́n á yíjú sí apá ibẹ̀,+ wọ́n á ní, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a bá Jèhófà dá májẹ̀mú tó máa wà títí láé, tí kò sì ní ṣeé gbàgbé.’+ 6 Àwọn èèyàn mi ti di agbo àgùntàn tó sọ nù.+ Àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọn ti kó wọn ṣìnà.+ Wọ́n dà wọ́n lọ sórí àwọn òkè ńlá, wọ́n ń rìn látorí òkè ńlá dórí òkè kékeré. Wọ́n ti gbàgbé ibi ìsinmi wọn. 7 Gbogbo àwọn tó rí wọn ti pa wọ́n jẹ,+ àwọn ọ̀tá wọn sì ti sọ pé, ‘A ò jẹ̀bi, nítorí wọ́n ti ṣẹ Jèhófà, wọ́n ti ṣẹ ibùgbé òdodo àti ìrètí àwọn baba ńlá wọn, Jèhófà.’”
8 “Ẹ sá kúrò nínú Bábílónì,
Ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà,+
Kí ẹ sì dà bí àgbò tó ń ṣíwájú agbo ẹran.
9 Nítorí wò ó, màá gbé àwọn orílẹ̀-èdè ńlá dìde láti ilẹ̀ àríwá
Màá sì mú kí wọ́n gbéjà ko Bábílónì.+
Wọ́n á tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti gbógun tì í;
Ibẹ̀ ni wọ́n á ti gbà á.
10 Wọ́n á kó Kálídíà bí ẹrù ogun.+
Gbogbo àwọn tó bá ń kó ẹrù látinú rẹ̀ á tẹ́ ara wọn lọ́rùn,”+ ni Jèhófà wí.
Nítorí ẹ̀ ń fi ẹsẹ̀ talẹ̀ kiri bí abo ọmọ màlúù lórí koríko,
Ẹ sì ń yán bí akọ ẹṣin.
12 Ìtìjú ti bá ìyá yín.+
Ìjákulẹ̀ ti bá ẹni tó bí yín lọ́mọ.
Wò ó! Òun ló kéré jù láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,
Aginjù tí kò lómi àti aṣálẹ̀.+
Ẹnikẹ́ni tó bá ń kọjá lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Bábílónì á wò ó, ẹ̀rù á bà á
Á sì súfèé nítorí gbogbo ìyọnu rẹ̀.+
14 Ẹ jáde lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti gbógun ti Bábílónì láti ibi gbogbo,
Gbogbo ẹ̀yin tó ń tẹ* ọrun.
15 Ẹ kígbe ogun mọ́ ọn láti ibi gbogbo.
Ó ti juwọ́ sílẹ̀.*
Ẹ gbẹ̀san lára rẹ̀.
Bí ó ti ṣe síni ni kí ẹ ṣe sí i gẹ́lẹ́.+
16 Ẹ mú afúnrúgbìn kúrò ní Bábílónì
Àti ẹni tó ń lo dòjé ní ìgbà ìkórè.+
Nítorí idà tó ń hanni léèmọ̀, kálukú á pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀,
Kálukú á sì sá lọ sí ilẹ̀ rẹ̀.+
17 “Àwọn èèyàn Ísírẹ́lì jẹ́ àwọn àgùntàn tó tú ká.+ Àwọn kìnnìún ti fọ́n wọn ká.+ Ọba Ásíríà ló kọ́kọ́ jẹ wọ́n;+ lẹ́yìn náà, Nebukadinésárì* ọba Bábílónì jẹ egungun wọn.+ 18 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Wò ó, màá fìyà jẹ ọba Bábílónì àti ilẹ̀ rẹ̀ bí mo ṣe fìyà jẹ ọba Ásíríà.+ 19 Màá mú Ísírẹ́lì pa dà sí ibi ìjẹko rẹ̀,+ á jẹko ní Kámẹ́lì àti ní Báṣánì,+ á* sì ní ìtẹ́lọ́rùn lórí àwọn òkè Éfúrémù+ àti ti Gílíádì.’”+
20 “Ní ọjọ́ yẹn àti ní àkókò yẹn,” ni Jèhófà wí,
“A ó wá ẹ̀bi Ísírẹ́lì kiri,
Ṣùgbọ́n a kò ní rí ìkankan,
A kò sì ní rí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Júdà,
Nítorí màá dárí ji àwọn tí mo jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù.”+
21 “Lọ gbéjà ko ilẹ̀ Mérátáímù àti àwọn tó ń gbé ní Pékódù.+
Jẹ́ kí wọ́n pa wọ́n ní ìpakúpa, sì jẹ́ kí wọ́n pa wọ́n rẹ́,”* ni Jèhófà wí.
“Ṣe gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún ọ.
22 Ìró ogun wà ní ilẹ̀ náà,
Àjálù ńlá.
23 Ẹ wo bí wọ́n ṣe ṣẹ́ òòlù irin* gbogbo ayé, tí wọ́n sì fọ́ ọ!+
Ẹ wo bí Bábílónì ṣe di ohun àríbẹ̀rù láàárín àwọn orílẹ̀-èdè!+
24 Mo ti dẹkùn fún ọ, ó sì ti mú ọ, ìwọ Bábílónì,
Ìwọ kò sì mọ̀.
Wọ́n rí ọ, wọ́n sì gbá ọ mú,+
Torí pé Jèhófà ni o ta kò.
25 Jèhófà ti ṣí ilé ìṣúra rẹ̀,
Ó sì ń mú àwọn ohun ìjà ìbínú rẹ̀ jáde.+
Nítorí Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ní iṣẹ́ kan
Ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà.
26 Ẹ wá gbéjà kò ó láti àwọn ibi tó jìnnà.+
Ẹ ṣí àwọn àká rẹ̀.+
Ẹ kó o jọ bí òkìtì ọkà.
Kó má sì ní ẹnikẹ́ni tó máa ṣẹ́ kù.
27 Pa gbogbo akọ ọmọ màlúù rẹ̀ ní ìpakúpa;+
Kí wọ́n sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ibi tí wọ́n ti máa pa wọ́n.
Wọ́n gbé, nítorí ọjọ́ wọn ti dé,
Àkókò ìyà wọn!
28 Ìró àwọn tó ń sá lọ ń dún,
Àwọn tó ń sá àsálà láti ilẹ̀ Bábílónì,
Láti kéde ẹ̀san Jèhófà Ọlọ́run wa ní Síónì,
Ẹ̀san nítorí tẹ́ńpìlì rẹ̀.+
Ẹ pàgọ́ yí i ká; kí ẹnikẹ́ni má ṣe sá àsálà.
Ẹ san án fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.+
Bí ó ti ṣe sí àwọn èèyàn ni kí ẹ ṣe sí i gẹ́lẹ́.+
Nítorí pé ó ti gbéra ga sí Jèhófà,
Sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.+
30 Torí náà, àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀ á ṣubú ní àwọn gbàgede rẹ̀,+
Gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ á sì ṣègbé* ní ọjọ́ yẹn,” ni Jèhófà wí.
31 “Wò ó! Mo dojú ìjà kọ ọ́,+ ìwọ aláìgbọràn,”+ ni Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí,
“Nítorí ọjọ́ rẹ gbọ́dọ̀ dé, ní àkókò tí màá pè ọ́ wá jíhìn.
32 Ìwọ aláìgbọràn, wàá kọsẹ̀, wàá sì ṣubú,
Kò sì sí ẹni tó máa gbé ọ dìde.+
Màá sọ iná sí àwọn ìlú rẹ,
Á sì jó gbogbo ohun tó yí ọ ká run.”
33 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:
“Àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti Júdà ni à ń ni lára,
Gbogbo àwọn tó sì mú wọn lẹ́rú kò fi wọ́n sílẹ̀.+
Wọn ò jẹ́ kí wọ́n lọ.+
34 Àmọ́, Olùtúnrà wọn lágbára.+
Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.+
Ó dájú pé á gba ẹjọ́ wọn rò,+
Kí ó lè fún ilẹ̀ náà ní ìsinmi+
Kí ó sì mú rúkèrúdò bá àwọn tó ń gbé ní Bábílónì.”+
35 “Idà kan wà tó dojú kọ àwọn ará Kálídíà,” ni Jèhófà wí,
“Ó dojú kọ àwọn tó ń gbé ní Bábílónì, ó sì dojú kọ àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀.+
36 Idà kan wà tó dojú kọ àwọn tó ń sọ ọ̀rọ̀ asán,* wọ́n á sì hùwà òmùgọ̀.
Idà kan wà tó dojú kọ àwọn jagunjagun rẹ̀, jìnnìjìnnì á sì bò wọ́n.+
37 Idà kan wà tó dojú kọ àwọn ẹṣin wọn àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn,
Tó sì dojú kọ onírúurú àjèjì tó wà láàárín rẹ̀,
Wọ́n á dà bí obìnrin.+
Idà kan wà tó dojú kọ àwọn ìṣúra rẹ̀, ṣe ni wọ́n á kó wọn lọ.+
38 Ìparun máa wà yí ká omi rẹ̀, a ó mú kó gbẹ táútáú.+
Nítorí ilẹ̀ ère gbígbẹ́ ni,+
Wọ́n sì ń ṣe bíi wèrè nítorí àwọn ìran tó ń bani lẹ́rù tí wọ́n ń rí.
39 Nítorí náà, àwọn ẹranko tó ń gbé ní aṣálẹ̀ á máa gbé pẹ̀lú àwọn ẹranko tó ń hu,
Inú rẹ̀ sì ni ògòǹgò á máa gbé.+
Ẹnikẹ́ni ò sì ní gbé ibẹ̀ mọ́ láé,
Bẹ́ẹ̀ ni kò ní jẹ́ ibi tí àwọn èèyàn á máa gbé láti ìran dé ìran.”+
40 “Bí Ọlọ́run ṣe pa Sódómù àti Gòmórà+ àti àwọn ìlú tó yí wọn ká run,”+ ni Jèhófà wí, “kò ní sí ẹnì kankan tí á máa gbé ibẹ̀, kò sì ní sí èèyàn kankan tó máa tẹ̀ dó síbẹ̀.+
41 Wò ó! Àwọn èèyàn kan ń wọlé bọ̀ láti àríwá;
Orílẹ̀-èdè ńlá àti àwọn atóbilọ́lá ọba+ ni a ó gbé dìde
Láti àwọn ibi tó jìnnà jù lọ láyé.+
42 Wọ́n ń lo ọrun àti ọ̀kọ̀.*+
Ìkà ni wọ́n, wọn ò sì lójú àánú.+
Ìró wọn dà bíi ti òkun,+
Bí wọ́n ṣe ń gun ẹṣin wọn.
Bí ọkùnrin kan ṣoṣo ni wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti gbógun tì ọ́, ìwọ ọmọbìnrin Bábílónì.+
Ìdààmú ti bá a,
Ìrora bíi ti obìnrin tó ń rọbí.
44 “Wò ó! Ẹnì kan máa wá gbéjà ko àwọn ibi ìjẹko Bábílónì tó wà ní ààbò bíi kìnnìún tó jáde látinú igbó kìjikìji lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì, ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan, màá mú kí wọ́n sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Màá sì yan àyànfẹ́ lé e lórí.+ Nítorí ta ló dà bí èmi, ta ló lè sọ pé kí ni mò ń ṣe? Olùṣọ́ àgùntàn wo ló sì lè dúró níwájú mi?+ 45 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ìpinnu* tí Jèhófà ṣe lórí Bábílónì + àti ohun tí ó ti rò nípa àwọn tó ń gbé ní Kálídíà.
Ó dájú pé, a ó wọ́ àwọn ẹran kéékèèké inú agbo ẹran lọ.
Ó máa sọ ibùgbé wọn di ahoro nítorí wọn.+
46 Nígbà tí wọ́n bá gba Bábílónì, ìró rẹ̀ á mú kí ilẹ̀ mì tìtì,
A ó sì gbọ́ igbe ẹkún láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.”+
51 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Wò ó, màá ru ẹ̀fúùfù tó ń pani run sókè
Sí Bábílónì+ àti sí àwọn tó ń gbé ní Lẹbu-kámáì.*
2 Màá rán àwọn tó ń fẹ́ ọkà sí Bábílónì,
Wọ́n á fẹ́ ẹ bí ọkà, wọ́n á sì sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro;
Wọ́n á wá dojú kọ ọ́ láti ibi gbogbo ní ọjọ́ àjálù.+
3 Kí tafàtafà má lè tẹ* ọrun rẹ̀.
Kí ẹnikẹ́ni tó wọ ẹ̀wù irin má sì lè nàró.
Ẹ má ṣàánú àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀.+
Ẹ pa gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ run pátápátá.
4 Wọ́n á ṣubú, wọ́n á sì kú ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà,
A ó sì gún wọn ní àgúnyọ ní àwọn ojú ọ̀nà rẹ̀.+
5 Nítorí Ọlọ́run Ísírẹ́lì àti Júdà, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.*+
Àmọ́, ẹ̀bi kún ilẹ̀* wọn lójú Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.
Ẹ má ṣègbé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
Nítorí àkókò ẹ̀san Jèhófà ti tó.
Ó máa san ohun tó ṣe pa dà fún un.+
7 Bábílónì jẹ́ ife wúrà ní ọwọ́ Jèhófà;
Ó mú kí gbogbo ayé mu àmupara.
8 Lójijì, Bábílónì ṣubú, ó sì fọ́.+
Ẹ pohùn réré ẹkún fún un! +
Ẹ fún un ní básámù nítorí ìrora rẹ̀; bóyá ara rẹ̀ máa yá.”
9 “A gbìyànjú láti mú Bábílónì lára dá, ṣùgbọ́n ara rẹ̀ kò yá.
Ẹ fi í sílẹ̀, kí kálukú máa lọ sí ilẹ̀ rẹ̀.+
Nítorí ìdájọ́ rẹ̀ ti dé ọ̀run;
Ó ti ga sókè bíi sánmà.+
10 Jèhófà ti mú ìdájọ́ òdodo ṣẹ fún wa.+
Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a ròyìn iṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run wa ní Síónì.”+
11 “Ẹ dán ọfà;+ ẹ gbé àwọn apata ribiti.*
Jèhófà ti ru ẹ̀mí àwọn ọba Mídíà sókè,+
Torí ó ní in lọ́kàn láti pa Bábílónì run.
Nítorí ẹ̀san Jèhófà nìyí, ẹ̀san nítorí tẹ́ńpìlì rẹ̀.
12 Ẹ gbé àmì kan sókè*+ sí àwọn ògiri Bábílónì.
Ẹ túbọ̀ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì yan àwọn olùṣọ́ sẹ́nu iṣẹ́.
Ẹ múra àwọn tó máa lúgọ de Bábílónì sílẹ̀.
Nítorí Jèhófà ti ro ohun tó máa ṣe,
Ó sì máa ṣe ohun tí ó ti ṣèlérí pé òun máa ṣe sí àwọn tó ń gbé ní Bábílónì.”+
14 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti fi ara* rẹ̀ búra pé,
‘Màá fi èèyàn kún inú rẹ, wọ́n á pọ̀ bí eéṣú,
Wọ́n á sì kígbe ìṣẹ́gun lórí rẹ.’+
15 Òun ni Aṣẹ̀dá ayé tó fi agbára rẹ̀ dá a,
Ẹni tó fi ọgbọ́n rẹ̀ dá ilẹ̀ tó ń mú èso jáde+
Tó sì fi òye rẹ̀ na ọ̀run bí aṣọ.+
17 Kálukú ń hùwà láìronú, wọn ò sì ní ìmọ̀.
18 Ẹ̀tàn* ni wọ́n,+ iṣẹ́ yẹ̀yẹ́ sì ni wọ́n.
Nígbà tí ọjọ́ ìbẹ̀wò wọn bá dé, wọ́n á ṣègbé.
19 Ọlọ́run* Jékọ́bù kò dà bí àwọn nǹkan yìí,
Nítorí òun ni Ẹni tó dá ohun gbogbo,
Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.”+
20 “Kùmọ̀ ogun lo jẹ́ fún mi, ohun ìjà ogun,
Màá fi ọ́ fọ́ àwọn orílẹ̀-èdè túútúú.
Màá fi ọ́ pa àwọn ìjọba run.
21 Màá fi ọ́ fọ́ ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún túútúú.
Màá fi ọ́ fọ́ kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹni tí ó gùn ún túútúú.
22 Màá fi ọ́ fọ́ ọkùnrin àti obìnrin túútúú.
Màá fi ọ́ fọ́ àgbà ọkùnrin àti ọmọkùnrin túútúú.
Màá fi ọ́ fọ́ ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin túútúú.
23 Màá fi ọ́ fọ́ olùṣọ́ àgùntàn àti agbo ẹran rẹ̀ túútúú.
Màá fi ọ́ fọ́ àgbẹ̀ àti àwọn ẹran ìtúlẹ̀ rẹ̀ túútúú.
Màá fi ọ́ fọ́ àwọn gómìnà àti àwọn ìjòyè túútúú.
24 Màá san án pa dà fun Bábílónì àti fún gbogbo àwọn tó ń gbé ní Kálídíà
Nítorí gbogbo búburú tí wọ́n ti ṣe ní Síónì lójú yín,”+ ni Jèhófà wí.
Màá na ọwọ́ mi sí ọ, màá sì yí ọ wálẹ̀ látorí àwọn àpáta
Màá sì sọ ọ́ di òkè tó ti jóná.”
26 “Àwọn èèyàn kò ní mú òkúta igun ilé tàbí òkúta ìpìlẹ̀ nínú rẹ,
Nítorí pé wàá di ahoro títí láé,”+ ni Jèhófà wí.
27 “Ẹ gbé àmì kan sókè* ní ilẹ̀ náà.+
Ẹ fun ìwo láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.
Ẹ yan àwọn orílẹ̀-èdè* lé e lórí.
Ẹ pe àwọn ìjọba Árárátì,+ Mínì àti Áṣíkénásì+ láti wá gbéjà kò ó.
Ẹ yan agbanisíṣẹ́ ogun láti wá gbéjà kò ó.
Ẹ jẹ́ kí àwọn ẹṣin gòkè wá bí eéṣú onírun gàn-ùn gàn-ùn.
28 Ẹ yan àwọn orílẹ̀-èdè* lé e lórí,
Àwọn ọba Mídíà,+ àwọn gómìnà rẹ̀ àti gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀
Àti gbogbo ilẹ̀ tí wọ́n ń ṣàkóso lé lórí.
29 Ilẹ̀ ayé á mì tìtì, jìnnìjìnnì á sì bá a,
Nítorí pé èrò Jèhófà sí Bábílónì máa ṣẹ
Láti sọ ilẹ̀ Bábílónì di ohun àríbẹ̀rù, tí ẹnì kánkán kò ní gbé ibẹ̀.+
30 Àwọn jagunjagun Bábílónì ti ṣíwọ́ ìjà.
Wọ́n jókòó sínú àwọn odi agbára wọn.
Okun wọn ti tán.+
Wọ́n ti di obìnrin.+
Wọ́n ti sọ iná sí àwọn ilé rẹ̀.
Wọ́n ti ṣẹ́ àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀.+
31 Asáréjíṣẹ́ kan sá lọ pàdé asáréjíṣẹ́ míì,
Òjíṣẹ́ kan sì lọ pàdé òjíṣẹ́ míì,
Láti ròyìn fún ọba Bábílónì pé wọ́n ti gba ìlú rẹ̀ láti apá ibi gbogbo,+
32 Pé wọ́n ti gba ibi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà kọjá nínú odò lọ́wọ́ rẹ̀,+
Pé wọ́n ti dáná sun ọkọ̀ ojú omi tí a fi òrépèté* ṣe
Àti pé jìnnìjìnnì ti bá àwọn ọmọ ogun.”
33 Nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nìyí:
“Ọmọbìnrin Bábílónì dà bí ibi ìpakà.
Ó tó àkókò láti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ kí o lè ki.
Láìpẹ́ àkókò ìkórè rẹ̀ máa dé.”
Ó ti gbé mi kalẹ̀ bí òfìfo ìkòkò.
Ó ti gbé mi mì bí ejò ńlá ṣe ń gbé nǹkan mì;+
Ó ti fi àwọn ohun rere mi kún ikùn ara rẹ̀.
Ó ti fi omi ṣàn mí dà nù.
35 ‘Kí ìwà ipá tí wọ́n hù sí mi àti sí ara mi wá sórí Bábílónì!’ ni ẹni tó ń gbé Síónì wí.+
‘Kí ẹ̀jẹ̀ mi sì wá sórí àwọn tó ń gbé Kálídíà!’ ni Jerúsálẹ́mù wí.”
36 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
Màá mú kí omi òkun rẹ̀ gbẹ, màá sì mú kí àwọn kànga rẹ̀ gbẹ.+
38 Gbogbo wọn á jọ ké ramúramù bí ọmọ kìnnìún.*
Wọ́n á kùn bí àwọn ọmọ kìnnìún.”
39 “Nígbà tí ọ̀fun wọn bá ń dá tòló, màá se àsè fún wọn, màá sì rọ wọ́n yó,
Kí wọ́n lè yọ̀;+
Nígbà náà, wọ́n á sùn títí lọ,
Tí wọn kò ní jí,”+ ni Jèhófà wí.
40 “Màá mú wọn sọ̀ kalẹ̀ bí ọ̀dọ́ àgùntàn tí à ń mú lọ sí ibi ti a ti fẹ́ pa á,
Bí àwọn àgbò pẹ̀lú àwọn ewúrẹ́.”
Ẹ wo bí Bábílónì ṣe di ohun àríbẹ̀rù láàárín àwọn orílẹ̀-èdè!
42 Òkun ti bo Bábílónì mọ́lẹ̀.
Ìgbì rẹ̀ tó ń ru gùdù ti bò ó mọ́lẹ̀.
43 Àwọn ìlú rẹ̀ ti di ohun àríbẹ̀rù, ilẹ̀ tí kò lómi àti aṣálẹ̀.
Ilẹ̀ tí ẹnì kankan kò ní gbé, tí èèyàn kankan kò sì ní gba ibẹ̀ kọjá.+
Àwọn orílẹ̀-èdè kò sì ní rọ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́,
Ògiri Bábílónì sì máa ṣubú.+
45 Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin èèyàn mi!+
Ẹ sá nítorí ẹ̀mí* yín+ kí ẹ lè bọ́ lọ́wọ́ ìbínú Jèhófà tó ń jó bí iná.+
46 Ẹ má ṣojo, ẹ má sì bẹ̀rù ìròyìn tí ẹ ó gbọ́ ní ilẹ̀ náà.
Ní ọdún kan, ìròyìn náà á dé,
Ní ọdún tó tẹ̀ lé e, ìròyìn míì á tún dé,
Nípa ìwà ipá ní ilẹ̀ náà àti nípa alákòóso kan tó dojú ìjà kọ alákòóso míì.
47 Nítorí náà, wò ó! ọjọ́ ń bọ̀
Tí màá yíjú sí àwọn ère gbígbẹ́ Bábílónì.
Ìtìjú á bá gbogbo ilẹ̀ rẹ̀,
Òkú gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ á sì wà nílẹ̀ láàárín rẹ̀.+
48 Àwọn ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú wọn
Máa kígbe ayọ̀ lórí Bábílónì,+
Nítorí pé àwọn apanirun máa wá bá a láti àríwá,”+ ni Jèhófà wí.
49 “Kì í ṣe pé Bábílónì kàn pa àwọn èèyàn Ísírẹ́lì nìkan ni+
Àmọ́ ó tún pa àwọn èèyàn gbogbo ayé tó wà ní Bábílónì.
50 “Ẹ̀yin tí ẹ bọ́ lọ́wọ́ idà, ẹ máa sá lọ, ẹ má ṣe dúró!+
Ẹ rántí Jèhófà láti ibi tó jìnnà,
Kí ẹ sì máa ronú nípa Jerúsálẹ́mù.”+
51 “Ìtìjú ti bá wa, nítorí a ti gbọ́ ẹ̀gàn.
52 “Torí náà, wò ó! ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí,
“Tí màá yíjú sí àwọn ère gbígbẹ́ rẹ̀,
Àwọn tó fara pa yóò máa kérora ní gbogbo ilẹ̀ rẹ̀.”+
53 “Bí Bábílónì tiẹ̀ gòkè lọ sí ọ̀run,+
Bó bá tiẹ̀ fi ààbò yí àwọn odi agbára rẹ̀ gíga ká,
Látọ̀dọ̀ mi ni àwọn tó máa pa á run ti máa wá,”+ ni Jèhófà wí.
54 “Ẹ fetí sílẹ̀! Igbe ẹkún kan ń dún ní Bábílónì,+
Ìró àjálù ńlá ń dún láti ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà,+
55 Nítorí Jèhófà ń pa Bábílónì run,
Á sì pa ohùn ńlá mọ́ ọn lẹ́nu,
Ariwo ìgbì wọn á ròkè bíi ti omi púpọ̀.
A ó sì gbọ́ ìrò ohùn wọn.
56 Nítorí apanirun máa dé sórí Bábílónì;+
A ó mú àwọn jagunjagun rẹ̀,+
A ó ṣẹ́ ọfà* wọn sí wẹ́wẹ́,
Nítorí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ẹ̀san.+
Ó dájú pé ó máa gbẹ̀san.+
57 Màá mú kí àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn amòye rẹ̀ mutí yó,+
Àwọn gómìnà rẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn jagunjagun rẹ̀,
Wọ́n á sì sùn títí lọ,
Wọn ò sì ní jí,”+ ni Ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.
58 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:
“Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ògiri Bábílónì fẹ̀, a ó wó o palẹ̀,+
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹnubodè rẹ̀ ga, a ó sọ iná sí i.
Àwọn èèyàn ibẹ̀ á sì ṣe làálàá lásán;
Àwọn orílẹ̀-èdè á ṣiṣẹ́ títí á fi rẹ̀ wọ́n, torí iná náà kò ní ṣeé pa.”+
59 Ọ̀rọ̀ tí wòlíì Jeremáyà pa láṣẹ fún Seráyà ọmọ Neráyà+ ọmọ Maseáyà nígbà tó bá Sedekáyà ọba Júdà lọ sí Bábílónì ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀; Seráyà sì ni olórí ibùdó. 60 Jeremáyà kọ gbogbo àjálù tó máa bá Bábílónì sínú ìwé kan, ìyẹn gbogbo ọ̀rọ̀ yìí tó kọ nípa Bábílónì. 61 Lẹ́yìn náà, Jeremáyà sọ fún Seráyà pé: “Tí o bá dé Bábílónì, tí o sì fojú kàn án, ka gbogbo ọ̀rọ̀ yìí sókè. 62 Kí o sì sọ pé, ‘Jèhófà, o ti sọ nípa ibí yìí pé wọ́n á pa á run, ohunkóhun kò sì ní gbé inú rẹ̀, ì báà jẹ́ èèyàn tàbí ẹranko àti pé á di ahoro títí láé.’+ 63 Nígbà tí o bá ti ka ìwé yìí tán, so òkúta kan mọ́ ọn, kí o sì jù ú sí àárín odò Yúfírétì. 64 Kí o sọ pé, ‘Bí Bábílónì ṣe máa wọlẹ̀ nìyí, tí kò sì ní gbérí mọ́,+ nítorí àjálù tí Ọlọ́run màá mú wá sórí rẹ̀; àárẹ̀ á sì mú wọn.’”+
Ibí ni ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà sọ parí sí.
52 Ẹni ọdún mọ́kànlélógún (21) ni Sedekáyà+ nígbà tó jọba, ọdún mọ́kànlá (11) ló sì fi jọba ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hámútálì+ ọmọ Jeremáyà ará Líbínà. 2 Ó sì ń ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, gbogbo ohun tí Jèhóákímù ṣe ni òun náà ṣe.+ 3 Ìbínú Jèhófà ló mú kí àwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù àti ní Júdà, títí ó fi gbá wọn dà nù kúrò níwájú rẹ̀.+ Sedekáyà sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Bábílónì.+ 4 Ní ọdún kẹsàn-án ìjọba Sedekáyà, ní oṣù kẹwàá, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, Nebukadinésárì* ọba Bábílónì dé pẹ̀lú gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ láti gbéjà ko Jerúsálẹ́mù. Wọ́n pàgọ́ tì í, wọ́n sì mọ òkìtì yí i ká.+ 5 Wọ́n sì dó ti ìlú náà títí di ọdún kọkànlá ìṣàkóso Ọba Sedekáyà.
6 Ní oṣù kẹrin, ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù náà,+ ìyàn mú gan-an ní ìlú náà, kò sì sí oúnjẹ kankan tí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà máa jẹ.+ 7 Níkẹyìn, wọ́n fọ́ ògiri ìlú náà wọlé, gbogbo ọmọ ogun sì sá kúrò ní ìlú lóru, wọ́n gba ẹnubodè tó wà láàárín ògiri oníbejì nítòsí ọgbà ọba jáde kúrò nínú ìlú náà, lákòókò yìí, àwọn ará Kálídíà yí ìlú náà ká; wọ́n gba ọ̀nà Árábà lọ.+ 8 Àmọ́ àwọn ọmọ ogun Kálídíà lé ọba, wọ́n sì bá Sedekáyà+ ní aṣálẹ̀ tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò, gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ sì tú ká kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 9 Lẹ́yìn náà, wọ́n gbá ọba mú, wọ́n mú un wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbúlà ní ilẹ̀ Hámátì, ó sì dá a lẹ́jọ́. 10 Ọba Bábílónì pa àwọn ọmọ Sedekáyà níṣojú rẹ̀, ó sì tún pa gbogbo àwọn ìjòyè Júdà níbẹ̀ ní Ríbúlà. 11 Lẹ́yìn náà, ọba Bábílónì fọ́ ojú Sedekáyà,+ ó sì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà dè é, ó mú un wá sí Bábílónì, ó sì fi í sẹ́wọ̀n títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.
12 Ní oṣù karùn-ún, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, ìyẹn, ní ọdún kọkàndínlógún Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́, tó jẹ́ ẹmẹ̀wà* ọba Bábílónì, wá sí Jerúsálẹ́mù.+ 13 Ó dáná sun ilé Jèhófà+ àti ilé* ọba pẹ̀lú gbogbo ilé tó wà ní Jerúsálẹ́mù; ó sì tún sun gbogbo ilé ńlá. 14 Gbogbo ògiri tó yí Jerúsálẹ́mù ká ni gbogbo àwọn ọmọ ogun Kálídíà tó wà pẹ̀lú olórí ẹ̀ṣọ́ wó lulẹ̀.+
15 Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ sì kó àwọn kan lára àwọn aláìní nínú àwọn èèyàn náà àti àwọn tó ṣẹ́ kù sí ìlú náà lọ sí ìgbèkùn. Ó tún kó àwọn tó sá lọ sọ́dọ̀ ọba Bábílónì àti ìyókù àwọn àgbà oníṣẹ́ ọnà lọ sí ìgbèkùn.+ 16 Àmọ́ Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ fi lára àwọn aláìní sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà kí wọ́n lè máa rẹ́ ọwọ́ àjàrà, kí wọ́n sì máa ṣe lébìrà àpàpàǹdodo.+
17 Àwọn ará Kálídíà fọ́ àwọn òpó bàbà+ ilé Jèhófà àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù + àti Òkun bàbà+ tó wà ní ilé Jèhófà sí wẹ́wẹ́, wọ́n sì kó gbogbo bàbà náà lọ sí Bábílónì.+ 18 Wọ́n tún kó àwọn garawa, àwọn ṣọ́bìrì, àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa fìtílà, àwọn abọ́,+ àwọn ife+ àti gbogbo nǹkan èlò bàbà tí wọ́n ń lò nínú tẹ́ńpìlì. 19 Olórí ẹ̀ṣọ́ kó àwọn bàsíà,+ àwọn ìkóná, àwọn abọ́, àwọn garawa, àwọn ọ̀pá fìtílà,+ àwọn ife àti àwọn abọ́ tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe àti àwọn tí wọ́n fi ojúlówó fàdákà ṣe.+ 20 Ní ti àwọn òpó méjèèjì àti Òkun, àwọn akọ màlúù méjìlá (12)+ tí wọ́n fi bàbà ṣe tó wà lábẹ́ Òkun náà àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Ọba Sólómọ́nì ṣe fún ilé Jèhófà, bàbà tó wà lára gbogbo àwọn nǹkan èlò yìí kọjá wíwọ̀n.
21 Ní ti àwọn òpó náà, gíga ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* méjìdínlógún (18), okùn ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ méjìlá (12) lè yí i ká;+ ìnípọn rẹ̀ jẹ́ ìbú ìka* mẹ́rin, ihò sì wà nínú rẹ̀. 22 Bàbà ni wọ́n fi ṣe ọpọ́n tó wà lórí rẹ̀; gíga ọpọ́n kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún;+ bàbà ni wọ́n fi ṣe àwọ̀n àti àwọn pómégíránétì tó yí ọpọ́n náà ká. Òpó kejì dà bíi ti àkọ́kọ́ gẹ́lẹ́, bákan náà sì ni àwọn pómégíránétì rẹ̀. 23 Àwọn pómégíránétì mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún (96) ló wà lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ rẹ̀; lápapọ̀, gbogbo pómégíránétì tó yí àwọ̀n náà ká jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100).+
24 Olórí ẹ̀ṣọ́ tún mú Seráyà+ olórí àlùfáà àti Sefanáyà+ àlùfáà kejì pẹ̀lú àwọn aṣọ́nà mẹ́ta.+ 25 Ó mú òṣìṣẹ́ ààfin kan tó jẹ́ kọmíṣọ́nnà lórí àwọn ọmọ ogun láti inú ìlú náà àti àwọn ọkùnrin méje tó rí nínú ìlú náà tí wọ́n sún mọ́ ọba àti akọ̀wé olórí àwọn ọmọ ogun, tó máa ń pe àwọn èèyàn ilẹ̀ náà jọ àti ọgọ́ta (60) ọkùnrin lára àwọn èèyàn ilẹ̀ náà, tó tún rí nínú ìlú náà. 26 Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ mú wọn, ó sì kó wọn wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbúlà. 27 Ọba Bábílónì ṣá wọn balẹ̀, ó sì pa wọ́n ní Ríbúlà+ ní ilẹ̀ Hámátì. Bí Júdà ṣe lọ sí ìgbèkùn láti ilẹ̀ rẹ̀ nìyẹn.+
28 Àwọn èèyàn tí Nebukadinésárì* kó lọ sí ìgbèkùn nìyí: ní ọdún keje, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé mẹ́tàlélógún (3,023) àwọn Júù.+
29 Ní ọdún kejìdínlógún Nebukadinésárì,*+ ó kó ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé méjìlélọ́gbọ̀n (832) èèyàn* láti Jerúsálẹ́mù.
30 Ní ọdún kẹtàlélógún Nebukadinésárì,* Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ kó àwọn Júù lọ sí ìgbèkùn, àwọn èèyàn* náà jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó lé márùndínláàádọ́ta (745).+
Lápapọ̀, ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (4,600) èèyàn* ni wọ́n kó lọ sí ìgbèkùn.
31 Ní ọdún kẹtàdínlógójì tí Jèhóákínì+ ọba Júdà ti wà ní ìgbèkùn, ní oṣù kejìlá, ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù náà, Efili-méródákì ọba Bábílónì, ní ọdún tó jọba, dá Jèhóákínì ọba Júdà sílẹ̀,* ó sì mú un kúrò lẹ́wọ̀n.+ 32 Ó bá a sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́, ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ìtẹ́ àwọn ọba yòókù tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Bábílónì. 33 Torí náà, Jèhóákínì bọ́ ẹ̀wù ẹ̀wọ̀n rẹ̀, iwájú ọba ló sì ti ń jẹun déédéé ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. 34 Ó ń rí oúnjẹ gbà déédéé látọ̀dọ̀ ọba Bábílónì, lójoojúmọ́ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.
Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Jèhófà Ń Gbéni Ga.”
Tàbí “yàn.”
Ní Héb., “Kí o tó jáde láti inú ilé ọmọ.”
Tàbí “yà ọ́ sọ́tọ̀.”
Tàbí “ọ̀dọ́.”
Ní Héb., “ẹni tó ń tètè jí.”
Tàbí “ìkòkò ìsebẹ̀ ẹlẹ́nu fífẹ̀.”
Ní Héb., “tí wọ́n fẹ́ atẹ́gùn sí,” èyí tó fi hàn pé iná ń jó lala lábẹ́ rẹ̀.
Ní Héb., “de àmùrè mọ́ ìbàdí rẹ.”
Tàbí “ṣẹ́gun.”
Tàbí “ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.”
Tàbí “erékùṣù.”
Tàbí “wa àwọn kòtò omi,” bóyá sínú àpáta.
Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
Tàbí “Mémúfísì.”
Ní Héb., “fi ọ́ ṣe oúnjẹ jẹ ní àtàrí rẹ.”
Ìyẹn, odò tó ya láti ara odò Náílì.
Ìyẹn, odò Yúfírétì.
Tàbí “ákáláì.”
Tàbí “ohun tó wù ú lọ́kàn.”
Ní Héb., “oṣù.”
Tàbí “àwọn ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè.”
Tàbí “ìborùn ìgbéyàwó.”
Tàbí “àwọn ọkàn.”
Ní Héb., “ará Arébíà.”
Ní Héb., “Iwájú orí rẹ rí bíi ti.”
Tàbí “ọkàn òun.”
Ní Héb., “lejú mọ́ ọ.”
Tàbí “àwọn ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè.”
Tàbí kó jẹ́, “ọkọ.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ ogun àwọn orílẹ̀-èdè.”
Ní Héb., “alábàákẹ́gbẹ́.”
Tàbí “ọlọ́run ìtìjú.”
Tàbí “dá ara yín ládọ̀dọ́.”
Tàbí “dádọ̀dọ́.”
Tàbí “fi òpó ṣe àmì.”
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “Ẹ lu àyà yín.”
Tàbí “ọba kì yóò ní ìgboyà.”
Tàbí “Àwọn ìjòyè kì yóò ní ìgboyà.”
Tàbí “nígbà tí idà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ̀mí wa.”
Ọ̀rọ̀ ewì tó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí àánú tàbí ìgbatẹnirò bíi pé èèyàn ni wọ́n.
Ní Héb., “Àwọn olùṣọ́,” ìyẹn, àwọn tó ń ṣọ́ ìlú kan, kí wọ́n lè mọ ìgbà tó yẹ kí wọ́n gbéjà kò ó.
Ní Héb., “Ìfun mi.”
Ní Héb., “Ògiri ọkàn mi.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí kó jẹ́, “ariwo ogun.”
Tàbí “òpó tí a fi ṣe àmì.”
Tàbí “Ọlọ́gbọ́n.”
Tàbí “yí ìpinnu mi pa dà.”
Tàbí “lẹ́ẹ̀dì.”
Tàbí “wọ́n ń lépa ọkàn rẹ.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Ní Héb., “wọn ò ṣàárẹ̀.”
Ní Héb., “ọ̀já.”
Tàbí “ń lé aya ọmọnìkejì rẹ̀ kiri.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “ilẹ̀ onípele.”
Tàbí kó jẹ́, “Kò sí níbì kankan.”
Ní Héb., “ẹ̀yin òmùgọ̀ tí kò ní ọkàn.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Ní Héb., “Ẹ ya ara yín sí mímọ́.”
Tàbí “kòtò omi.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Ní Héb., “pèéṣẹ́.”
Ní Héb., “Wọn ò dádọ̀dọ́ etí.”
Ní Héb., “àwọn tí wọ́n lọ́jọ́ lórí.”
Tàbí “ọgbẹ́.”
Tàbí “fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́.”
Tàbí “ọkàn yín.”
Tàbí “ìtọ́ni.”
Esùsú tó ń ta sánsán.
Ní Héb., “ọrun.”
Tàbí “ẹ̀ṣín.”
Ní Héb., “Ìrora ìrọbí.”
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Ìyẹn, Jeremáyà.
Ìyẹn, ohun tí àwọn alágbẹ̀dẹ fi ń fẹ́ná.
Ní Héb., “Wọ́n jẹ́,” ìyẹn gbogbo àwọn ilé tó wà ní tẹ́ńpìlì náà.
Tàbí “àwọn ọmọ aláìníbaba.”
Tàbí “láti ayérayé dé ayérayé.”
Tàbí “mú ẹbọ rú èéfín.”
Ní Héb., “dìde ní kùtùkùtù láti bá yín sọ̀rọ̀.”
Orúkọ oyè abo ọlọ́run tí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà ń jọ́sìn; ó ṣeé ṣe kó jẹ́ abo ọlọ́run ìbímọlémọ.
Tàbí “ṣẹ̀ sí?”
Tàbí “ìmọ̀ràn.”
Ní Héb., “mò ń jí ní kùtùkùtù lójoojúmọ́, mo sì ń rán wọn.”
Ní Héb., “wọ́n mú ọrùn wọn le.”
Ní Héb., “a ti gé e kúrò ní ẹnu wọn.”
Tàbí “irun ìyàsọ́tọ̀.”
Tàbí “orin ọ̀fọ̀.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Gẹ̀hẹ́nà.”
Tàbí “ohun tí èmi kò ronú rẹ̀ rí.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Gẹ̀hẹ́nà.”
Tàbí “ìgbà tí àkókò bá tó.”
Tàbí kó jẹ́, “ẹyẹ òfú.”
Tàbí “ṣí lọ.”
Tàbí “ìtọ́ni.”
Tàbí “àwọn akọ̀wé.”
Tàbí “gègé.”
Tàbí “irọ́.”
Tàbí “ọgbẹ́.”
Tàbí “fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́.”
Tàbí “òróró ìtura.”
Tàbí “oníṣègùn.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “orin ọ̀fọ̀.”
Tàbí “akátá.”
Tàbí “ìtọ́ni.”
Ìyẹn, igi kan tó korò gan-an.
Tàbí “orin ọ̀fọ̀.”
Tàbí “orin ọ̀fọ̀.”
Tàbí “wíńdò.”
Tàbí “dádọ̀dọ́.”
Tàbí “dádọ̀dọ́.”
Tàbí “aláìdádọ̀dọ́.”
Tàbí “aláìdádọ̀dọ́.”
Tàbí “asán.”
Tàbí “ọ̀bẹ aboríkọdọrọ.”
Tàbí “Hámà.”
Tàbí “apálá.”
Tàbí “asán.”
Èdè Árámáíkì ni wọ́n fi kọ ẹsẹ 11 ní ìbẹ̀rẹ̀.
Tàbí “oruku.”
Tàbí kó jẹ́, “ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀.”
Tàbí “ère dídà.”
Tàbí “èémí.”
Tàbí “Asán.”
Ní Héb., “Ìpín.”
Tàbí “ogún.”
Tàbí “fi àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà sọ̀kò.”
Tàbí “egungun mi fọ́.”
Tàbí “akátá.”
Ó jọ pé Jeremáyà ló ń bá sọ̀rọ̀.
Tàbí “Kó rí bẹ́ẹ̀.”
Ní Héb., “mò ń dìde ní kùtùkùtù, mo sì ń kìlọ̀.”
Tàbí “mú ẹbọ rú èéfín.”
Tàbí “ọlọ́run ìtìjú.”
Ìyẹn, Jeremáyà.
Ìyẹn, àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú nínú tẹ́ńpìlì.
Tàbí “inú lọ́hùn-ún.” Ní Héb., “kíndìnrín.”
Tàbí “tí wọ́n ń lépa ọkàn rẹ.”
Tàbí “inú wọn lọ́hùn-ún.” Ní Héb., “kíndìnrín wọn.”
Tàbí “ẹni tí ọkàn mi fẹ́.”
Tàbí “aláwọ̀ tó-tò-tó.”
Tàbí kó jẹ́, “Ó ń ṣọ̀fọ̀.”
Ní Héb., “ẹran ara èyíkéyìí.”
Tàbí “wíìtì.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “Ọkàn mi á.”
Tàbí “ìyáàfin.”
Tàbí “dó ti àwọn ìlú gúúsù.”
Tàbí “ará Etiópíà.”
Tàbí “dójú tini.”
Tàbí “ọ̀gbẹlẹ̀.”
Tàbí “ẹni kékeré.”
Tàbí “àwọn àmù; àwọn ìkùdu.”
Tàbí “akátá.”
Tàbí “àìsàn.”
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Tàbí “ọkàn mi ò ní wà lọ́dọ̀.”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́, “oríṣi ìdájọ́ mẹ́rin.” Ní Héb., “ìdílé mẹ́rin.”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́, “Ò ń pa dà sẹ́yìn.”
Tàbí “Mi ò ní bá ọ kẹ́dùn mọ́.”
Tàbí “Ọkàn rẹ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “Ojú tì í, ó sì ti kan àbùkù.”
Ní Héb., “Má ṣe mú mi lọ.”
Tàbí “ìkéde ìdálẹ́bi.”
Ní Héb., “Wàá dà bí ẹnu fún mi.”
Tàbí “ṣẹ́gun.”
Àṣà àwọn abọ̀rìṣà nígbà ọ̀fọ̀ tó jọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà ń tẹ̀ lé.
Ní Héb., “ní gbogbo ọ̀nà wọn.”
Ní Héb., “òkú.”
Tàbí “gègé.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí kó jẹ́, “Nítorí ìbínú mi ti mú kí ẹ ràn bí iná.”
Tàbí “ọkùnrin alágbára.”
Ní Héb., “tó fi ẹlẹ́ran ara ṣe apá rẹ̀.”
Tàbí “ọkùnrin alágbára.”
Tàbí “ṣe békebèke.”
Tàbí kó jẹ́, “kò ṣeé wò sàn.”
Tàbí “inú lọ́hùn-ún.” Ní Héb., “kíndìnrín.”
Tàbí “ìwà àìtọ́.”
Ní Héb., “lọ́dọ̀ mi,” ó jọ pé Jèhófà ló ń tọ́ka sí.
Tàbí “pa wọ́n ní àpatúnpa.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “wọ́n mú ọrùn wọn le.”
Tàbí “gúúsù.”
Ní Héb., “bó ṣe tọ́ ní ojú amọ̀kòkò náà láti ṣe.”
Tàbí “yí ìpinnu mi pa dà.”
Tàbí “yí ìpinnu mi pa dà.”
Tàbí “mú ẹbọ rú èéfín.”
Tàbí “tí wọn kò ṣe.”
Tàbí “ìtọ́ni.”
Ní Héb., “fi ahọ́n lù ú.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “akónilẹ́rù.”
Ìyẹn, ohun tí a fi amọ̀ ṣe tó dà bí ìgò ńlá.
Tàbí “tí mi ò ronú nípa rẹ̀ rí.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “mú ọrùn wọn le.”
Tàbí “inú lọ́hùn-ún.” Ní Héb., “kíndìnrín.”
Tàbí “ọkàn àwọn aláìní.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “yí pa dà sí yín.”
Tàbí “Àìsàn.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “tó ń lépa ọkàn wọn.”
Tàbí “sá àsálà fún ọkàn rẹ̀.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “aláìlóbìí.”
Ní Héb., “ya àwọn apanirun sí mímọ́.”
Wọ́n tún ń pè é ní Jèhóáhásì.
Tàbí “wíńdò.”
Ní Héb., “ṣe olùṣọ́ àgùntàn rẹ.”
Ní Héb., “Ìrora ìrọbí.”
Wọ́n tún ń pè é ní Jèhóákínì àti Jekonáyà.
Tàbí “tó ń lépa ọkàn rẹ.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “tí ọkàn wọn fà sí.”
Ní Héb., “ní ọjọ́ ayé rẹ̀.”
Tàbí “ajogún.”
Tàbí “apẹ̀yìndà.”
Ní Héb., “Wọ́n ń fún ọwọ́ àwọn aṣebi lókun.”
Ìyẹn, igi kan tó korò gan-an.
Tàbí “Ìrètí asán ni wọ́n ń fún yín.”
Ìyẹn, hámà ńlá tí àwọn alágbẹ̀dẹ máa ń lò.
Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n túmọ̀ níbí yìí sí “ẹrù tó wúwo,” tún lè túmọ̀ sí “ìkéde.” Ńṣe ni wọ́n fi ọ̀rọ̀ yìí dárà ní ẹsẹ 33-38.
Tàbí “Ọ̀rọ̀.”
Tàbí “ọ̀rọ̀.”
Tàbí “ọ̀rọ̀.”
Tàbí “Ọ̀rọ̀.”
Tàbí “ọ̀rọ̀.”
Tàbí “Ọ̀rọ̀.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Wọ́n tún ń pè é ní Jèhóákínì àti Konáyà.
Tàbí kó jẹ́, “àwọn tó ń kọ́ odi ààbò.”
Tàbí “àìsàn.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “sí.”
Ní Héb., “mò ń dìde ní kùtùkùtù, mo sì ń sọ̀rọ̀.”
Ní Héb., “ó ń dìde ní kùtùkùtù, ó sì ń rán wọn.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “fìyà jẹ ọba Bábílónì àti orílẹ̀-èdè yẹn.”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ orúkọ àṣírí tí wọ́n fi ń pe Bábélì (Bábílónì).
Ní Héb., “gbogbo ẹlẹ́ran ara.”
Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
Tàbí “nípa.”
Tàbí “forí balẹ̀.”
Tàbí “yí ìpinnu mi pa dà.”
Tàbí “ìtọ́ni.”
Ní Héb., “tí mò ń dìde ní kùtùkùtù, tí mo sì ń rán níṣẹ́.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “yí ìpinnu rẹ̀ pa dà.”
Tàbí “ìjọ.”
Tàbí “Òkè tẹ́ńpìlì.”
Tàbí “òkè tí igi pọ̀ sí.”
Tàbí “gbìyànjú láti tu Jèhófà lójú.”
Tàbí “yí ìpinnu rẹ̀ pa dà.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “ẹni tí ó tọ́ lójú mi.”
Tàbí “àìsàn.”
Ní Héb., “sinmi.”
Tàbí “ààfin.”
Ìyẹn, Òkun bàbà tó wà ní tẹ́ńpìlì.
Tàbí “ààfin.”
Ní Héb., “àwọn ọdún tó jẹ́ ọjọ́.”
Tàbí “Kó rí bẹ́ẹ̀.”
Tàbí “àìsàn.”
Tàbí “ìyáàfin.”
Tàbí kó jẹ́, “àwọn tó ń kọ́ odi ààbò.”
Tàbí “àìsàn.”
Tàbí kó jẹ́, “fífọ́.”
Ní Héb., “mò ń jí ní kùtùkùtù, mo sì ń rán wọn.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ọrùn.” Egìran túmọ̀ sí igi méjì tí wọ́n fi ń de apá àti ọrùn ẹni tí wọ́n bá fẹ́ pẹ̀gàn.
Tàbí “abẹ́nú.”
Ní Héb., “ńlá.”
Ní Héb., “ìdè.”
Tàbí “ọmọ ilẹ̀ òkèèrè.”
Tàbí “fi í.”
Tàbí “tọ́ ọ sọ́nà.”
Tàbí kó jẹ́, “kí wọ́n ní iyì.”
Ní Héb., “ta ló lè fi ọkàn rẹ̀ jẹ́jẹ̀ẹ́.”
Tàbí “tí mò ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ọ.”
Tàbí “máa jó lọ bí àwọn tó ń jó tẹ̀ríntẹ̀rín.”
Tàbí “àfonífojì.”
Tàbí “gbà á pa dà.”
Tàbí “àwọn ohun rere látọ̀dọ̀.”
Tàbí “Ọkàn wọn.”
Ní Héb., “sísanra.”
Tàbí “ọkàn àwọn àlùfáà.”
Tàbí “ọmọ.”
Ní Héb., “ìfun.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “eyín wọn kò mú.”
Tàbí kó jẹ́, “ọkọ wọn.”
Tàbí “pa àṣẹ.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “eérú ọlọ́ràá,” ìyẹn, eérú tí ọ̀rá tí wọ́n fi rúbọ ti rin.
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “ààfin.”
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “ní oókan àyà.”
Tàbí “Àwọn ohun tí o ní lọ́kàn.”
Tàbí “àìsàn.”
Ní Héb., “gbogbo ẹran ara.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Ní Héb., “ń dìde ní kùtùkùtù tí mo sì ń kọ́ wọn.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Gẹ̀hẹ́nà.”
Tàbí “ohun tí èmi kò ronú rẹ̀ rí.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Tàbí “ohun rere.”
Tàbí “ajogún.”
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “àṣẹ.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Ní Héb., “Lónìí.”
Tàbí “wu ọkàn wọn.”
Tàbí “àìsàn.”
Tàbí “àwọn tó ń lépa ọkàn wọn.”
Tàbí “àwọn tó ń lépa ọkàn wọn.”
Tàbí “yàrá ńlá.”
Ní Héb., “Jónádábù,” ìkékúrú Jèhónádábù.
Ní Héb., “Jónádábù,” ìkékúrú Jèhónádábù.
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Ní Héb., “mò ń dìde ní kùtùkùtù láti bá yín sọ̀rọ̀.”
Ní Héb., “mò ń dìde ní kùtùkùtù, mo sì ń rán wọn.”
Ní Héb., “Jónádábù,” ìkékúrú Jèhónádábù.
Tàbí “ìwé.”
Tàbí “ìwé.”
Tàbí “yàrá ìjẹun.”
Tàbí “akọ̀wé òfin.”
Tàbí “ìwé.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “òṣìṣẹ́ ààfin.”
Tàbí “ìwé.”
Tàbí “ìwé.”
Ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù November sí ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù December. Wo Àfikún B15.
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “ìwé.”
Wọ́n tún ń pè é ní Jèhóákínì àti Jekonáyà.
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb, “wọ́n fi í sínú ilé ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀.”
Ní Héb., “ilé kòtò omi.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “àìsàn.”
Ní Héb., “jáde sí.”
Tàbí “á sì sá àsálà fún ọkàn rẹ̀.”
Ní Héb., “ọwọ́.”
Tàbí “òṣìṣẹ́ láàfin.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “ẹni tó dá ọkàn yìí fún wa.”
Tàbí “tó ń lépa ọkàn rẹ.”
Ní Héb., “jáde sí.”
Tàbí “ọkàn rẹ yóò máa wà láàyè.”
Ní Héb., “jáde sí.”
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Ní Héb., “jáde sí.”
Tàbí “ààfin.”
Ní Héb., “Àwọn ọkùnrin tó wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “Nẹgali-ṣárésà, Samugari-nébò, Sásékímù, Rábúsárísì.” Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń pín ọ̀rọ̀ Hébérù lọ́nà tó yàtọ̀.
Tàbí “olórí onídán (awòràwọ̀).”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “ààfin.”
Tàbí kó jẹ́, “ṣiṣẹ́ ọ̀ranyàn.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “olórí òṣìṣẹ́ láàfin.”
Tàbí “olórí onídán (awòràwọ̀).”
Tàbí “Wàá sá àsálà fún ọkàn rẹ̀.”
Ní Héb., “láti dúró níwájú.”
Tàbí “láti pa ọkàn rẹ?”
Tàbí “pa ọkàn rẹ.”
Ní Héb., “látinú èso ìjọba náà.”
Tàbí “wíìtì.”
Tàbí kó jẹ́, “odò ńlá.”
Tàbí “kẹ́dùn.”
Tàbí “láti gbé fúngbà díẹ̀ níbẹ̀.”
Tàbí “àìsàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “àwọn tẹ́ńpìlì.”
Tàbí “láìséwu.”
Tàbí “òpó ìrántí onígun mẹ́rin.”
Tàbí “Ilé (Tẹ́ńpìlì) Oòrùn,” ìyẹn Hẹlipólísì.
Tàbí “àwọn tẹ́ńpìlì.”
Tàbí “Mémúfísì.”
Ní Héb., “mò ń jí ní kùtùkùtù, mo sì ń rán wọn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “banú jẹ́.”
Tàbí “àìsàn.”
Tàbí “Ọkàn wọn á fà sí i.”
Orúkọ oyè abo ọlọ́run tí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà ń jọ́sìn; ó ṣeé ṣe kó jẹ́ abo ọlọ́run ìbímọlémọ.
Orúkọ oyè abo ọlọ́run tí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà ń jọ́sìn; ó ṣeé ṣe kó jẹ́ abo ọlọ́run ìbímọlémọ.
Orúkọ oyè abo ọlọ́run tí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà ń jọ́sìn; ó ṣeé ṣe kó jẹ́ abo ọlọ́run ìbímọlémọ.
Orúkọ oyè abo ọlọ́run tí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà ń jọ́sìn; ó ṣeé ṣe kó jẹ́ abo ọlọ́run ìbímọlémọ.
Tàbí “àwọn tó ń lépa ọkàn rẹ̀.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “tó sì ń lépa ọkàn rẹ̀.”
Tàbí “retí.”
Ní Héb., “ẹlẹ́ran ara.”
Tàbí “màá jẹ́ kí o sá àsálà fún ọkàn rẹ.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Apata kékeré tí àwọn tafàtafà sábà máa ń gbé dání.
Irú èyí tí àwọn ọmọ ogun máa ń dé.
Ní Héb., “fi okùn sí.”
Tàbí “ìpakúpa.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “Mémúfísì.”
Ní Héb., “àkókò tí a yàn.”
Ìyẹn, ẹni tó ṣẹ́gun Íjíbítì.
Tàbí “Mémúfísì.”
Tàbí kó jẹ́, “yóò di ahoro.”
Tàbí “tó ń kó igi jọ.”
Ìyẹn, Tíbésì.
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “tọ́ ọ sọ́nà.”
Ìyẹn, Kírétè.
Ìyẹn ni pé wọ́n á fá irun orí wọn torí pé wọ́n ń ṣọ̀fọ̀ àti pé ìtìjú bá wọn.
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “ibi gíga tó láàbò.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “Òkè tí orí rẹ̀ rí pẹrẹsẹ.”
Tàbí kó jẹ́, “lórí ilẹ̀ gbígbẹ.”
Tàbí “òkè tí orí rẹ̀ rí pẹrẹsẹ.”
Ní Héb., “ṣẹ́ ìwo.”
Tàbí “gbé sókè.”
Ìyẹn, fèrè tí wọ́n máa ń fun nígbà tí wọ́n bá ń kédàárò níbi ìsìnkú.
Tàbí “gbé sókè.”
Ìyẹn, fèrè tí wọ́n máa ń fun nígbà tí wọ́n bá ń kédàárò níbi ìsìnkú.
Ní Héb., “Aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí kó jẹ́, “ariwo ogun.”
Tàbí “ìlú tó yí i ká.”
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “ọgbà àgùntàn.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Ní Héb., “tó ń ṣàn.”
Ó túmọ̀ sí ṣíṣà lára irè oko tí wọ́n bá fi sílẹ̀.
Lédè Hébérù, ó tún túmọ̀ sí “ìgbójú” tàbí “ìkọjá àyè.”
Tàbí “ìmọ̀ràn.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Ní Héb., “sínú afẹ́fẹ́.”
Tàbí “akátá.”
Ní Héb., “ìbẹ̀rẹ̀ agbára wọn.”
Tàbí “àwọn tó ń lépa ọkàn wọn.”
Tàbí “fi òpó ṣe àmì.”
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Ní Héb., “fi okùn sí.”
Ní Héb., “fi ọwọ́ rẹ̀ fúnni.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “ọkàn rẹ̀ á.”
Tàbí “sì pa wọ́n run pátápátá.”
Ìyẹn, hámà ńlá tí àwọn alágbẹ̀dẹ máa ń lò.
Tàbí “pa á run pátápátá.”
Ní Héb., “fi okùn sí.”
Ní Héb., “ni a ó pa lẹ́nu mọ́.”
Tàbí “àwọn wòlíì èké.”
Tàbí “ẹ̀ṣín.”
Tàbí “ìmọ̀ràn.”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ orúkọ àṣírí tí wọ́n fi ń pe Kálídíà.
Ní Héb., “fi okùn sí.”
Ní Héb., “Ísírẹ́lì àti Júdà kì í ṣe opó lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”
Ìyẹn, ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà.
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí kó jẹ́, “ẹ kó ọfà kún apó.”
Tàbí “fi òpó ṣe àmì.”
Ní Héb., “òpin òṣùwọ̀n.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “oruku.”
Tàbí kó jẹ́, “ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀.”
Tàbí “ère dídà.”
Tàbí “èémí.”
Tàbí “Asán.”
Ní Héb., “Ìpín.”
Tàbí “ogún.”
Tàbí “fi òpó ṣe àmì.”
Ní Héb., “Ẹ ya àwọn orílẹ̀-èdè sí mímọ́.”
Ní Héb., “Ẹ ya àwọn orílẹ̀-èdè sí mímọ́.”
Ìyẹn, pápírọ́sì.
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “akátá.”
Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ orúkọ àṣírí tí wọ́n fi ń pe Bábélì (Bábílónì).
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “àwọn àlejò.”
Ní Héb., “ọrun.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “ìránṣẹ́.”
Tàbí “ààfin.”
Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.
Ìbú ìka kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 1.85 (ínǹṣì 0.73). Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “gbé orí Jèhóákínì ọba Júdà sókè.”