ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 24:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Níkẹyìn, Jèhóákímù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀;+ Jèhóákínì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

  • 2 Àwọn Ọba 24:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) ni Jèhóákínì+ nígbà tó jọba, oṣù mẹ́ta ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Néhúṣítà ọmọ Élínátánì láti Jerúsálẹ́mù.

  • 2 Àwọn Ọba 24:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Bó ṣe mú Jèhóákínì+ lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì+ nìyẹn; ó tún mú ìyá ọba, àwọn ìyàwó ọba, àwọn òṣìṣẹ́ ààfin àti àwọn aṣáájú ilẹ̀ náà, ó sì kó wọn ní ìgbèkùn láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì.

  • 2 Kíróníkà 36:9, 10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) ni Jèhóákínì+ nígbà tó jọba, oṣù mẹ́ta àti ọjọ́ mẹ́wàá ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù; ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà.+ 10 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún,* Ọba Nebukadinésárì ní kí wọ́n lọ mú un wá sí Bábílónì+ pẹ̀lú àwọn ohun iyebíye tó wà ní ilé Jèhófà.+ Bákan náà, ó fi Sedekáyà arákùnrin bàbá rẹ̀ jọba lórí Júdà àti Jerúsálẹ́mù.+

  • Jeremáyà 22:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 “‘Bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà wí, ‘kódà bí Konáyà*+ ọmọ Jèhóákímù,+ ọba Júdà, bá tiẹ̀ jẹ́ òrùka èdìdì ní ọwọ́ ọ̀tún mi, ibẹ̀ ni màá ti yọ ọ́ kúrò!

  • Jeremáyà 22:30
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 30 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

      ‘Ẹ kọ ọ́ sílẹ̀ pé ọkùnrin yìí kò bímọ,

      Pé ọkùnrin yìí kò ní ṣe àṣeyọrí kankan jálẹ̀ ayé rẹ̀,*

      Nítorí kò sí ìkankan nínú àtọmọdọ́mọ rẹ̀ tó máa ṣàṣeyọrí

      Láti jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì kí ó sì ṣàkóso ní Júdà lẹ́ẹ̀kan sí i.’”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́