-
Diutarónómì 13:6-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 “Tí arákùnrin rẹ, ọmọ ìyá rẹ tàbí ọmọkùnrin rẹ tàbí ọmọbìnrin rẹ tàbí ìyàwó rẹ tí o fẹ́ràn tàbí ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́,* bá gbìyànjú láti tàn ọ́ ní ìkọ̀kọ̀ pé, ‘Jẹ́ ká lọ sin àwọn ọlọ́run míì,’+ àwọn ọlọ́run tí ìwọ àtàwọn baba ńlá rẹ kò mọ̀, 7 lára àwọn ọlọ́run àwọn èèyàn tó yí yín ká, ì báà jẹ́ nítòsí tàbí àwọn tó jìnnà sí yín, láti ìpẹ̀kun kan ilẹ̀ náà dé ìpẹ̀kun rẹ̀ kejì, 8 o ò gbọ́dọ̀ dá a lóhùn tàbí kí o fetí sí i,+ o ò gbọ́dọ̀ káàánú rẹ̀ tàbí kí o yọ́nú sí i, o ò sì gbọ́dọ̀ dáàbò bò ó; 9 kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kí o pa á.+ Ọwọ́ rẹ ni kó kọ́kọ́ bà á láti pa á, lẹ́yìn náà, kí gbogbo èèyàn dáwọ́ jọ kí wọ́n lè pa á.+
-
-
Diutarónómì 32:17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Àwọn ẹ̀mí èṣù ni wọ́n rúbọ sí, kì í ṣe Ọlọ́run,+
Wọ́n ń rúbọ sí àwọn ọlọ́run tí wọn ò mọ̀,
Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé lẹ́nu àìpẹ́ yìí,
Sí àwọn ọlọ́run tí àwọn baba ńlá yín ò mọ̀.
-