Àìsáyà 30:10 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 10 Wọ́n ń sọ fún àwọn aríran pé, ‘Ẹ má ṣe ríran,’ Àti fún àwọn olùríran pé, ‘Ẹ má sọ àwọn ìran tó jẹ́ òótọ́ fún wa.+ Ọ̀rọ̀ dídùn* ni kí ẹ bá wa sọ; ìran ẹ̀tàn ni kí ẹ máa rí.+ Jeremáyà 5:31 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 31 Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́,+Àwọn àlùfáà sì ń fi àṣẹ wọn tẹ àwọn èèyàn lórí ba. Àwọn èèyàn mi sì fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀.+ Àmọ́, kí lẹ máa ṣe nígbà tí òpin bá dé?” Jeremáyà 14:14 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 14 Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni àwọn wòlíì náà ń sọ ní orúkọ mi.+ Mi ò rán wọn, bẹ́ẹ̀ ni mi ò pàṣẹ fún wọn, mi ò sì bá wọn sọ̀rọ̀.+ Ìran èké àti ìwoṣẹ́ asán àti ẹ̀tàn ọkàn wọn ni wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín.+
10 Wọ́n ń sọ fún àwọn aríran pé, ‘Ẹ má ṣe ríran,’ Àti fún àwọn olùríran pé, ‘Ẹ má sọ àwọn ìran tó jẹ́ òótọ́ fún wa.+ Ọ̀rọ̀ dídùn* ni kí ẹ bá wa sọ; ìran ẹ̀tàn ni kí ẹ máa rí.+
31 Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́,+Àwọn àlùfáà sì ń fi àṣẹ wọn tẹ àwọn èèyàn lórí ba. Àwọn èèyàn mi sì fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀.+ Àmọ́, kí lẹ máa ṣe nígbà tí òpin bá dé?”
14 Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni àwọn wòlíì náà ń sọ ní orúkọ mi.+ Mi ò rán wọn, bẹ́ẹ̀ ni mi ò pàṣẹ fún wọn, mi ò sì bá wọn sọ̀rọ̀.+ Ìran èké àti ìwoṣẹ́ asán àti ẹ̀tàn ọkàn wọn ni wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín.+