-
Àwọn Onídàájọ́ 10:13-15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Àmọ́ ẹ fi mí sílẹ̀, ẹ sì ń sin àwọn ọlọ́run míì.+ Ìdí nìyẹn tí mi ò fi ní gbà yín sílẹ̀ mọ́.+ 14 Ẹ lọ bá àwọn ọlọ́run tí ẹ yàn, kí ẹ sì ké pè wọ́n pé kí wọ́n ràn yín lọ́wọ́.+ Kí wọ́n gbà yín sílẹ̀ nígbà tí wàhálà dé bá yín.”+ 15 Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ fún Jèhófà pé: “A ti ṣẹ̀. Ohunkóhun tó bá dáa lójú rẹ ni kí o ṣe sí wa. Jọ̀ọ́, ṣáà ti gbà wá sílẹ̀ lónìí.”
-
-
Sáàmù 78:34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 Àmọ́ tó bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í pa wọ́n, wọ́n á wá a;+
Wọ́n á pa dà, wọ́n á sì wá Ọlọ́run,
-
Àìsáyà 26:16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Jèhófà, wọ́n yíjú sí ọ nígbà wàhálà;
Wọ́n gbàdúrà sí ọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ látọkàn wá nígbà tí o bá wọn wí.+
-
-
-