-
2 Kíróníkà 34:20, 21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Ọba wá pa àṣẹ yìí fún Hilikáyà, Áhíkámù+ ọmọ Ṣáfánì, Ábídónì ọmọ Míkà, Ṣáfánì akọ̀wé àti Ásáyà ìránṣẹ́ ọba pé: 21 “Ẹ lọ bá èmi àti àwọn tó ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì àti ní Júdà wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà nípa àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé tí a rí yìí; nítorí ìbínú Jèhófà tó máa tú jáde sórí wa pọ̀ gan-an torí àwọn baba ńlá wa kò pa ọ̀rọ̀ Jèhófà mọ́, wọn ò ṣe gbogbo ohun tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé yìí.”+
-
-
Jeremáyà 39:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Torí náà, Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ àti Nebuṣásíbánì tó jẹ́ Rábúsárísì* àti Nẹgali-ṣárésà tó jẹ́ Rábúmágì* pẹ̀lú gbogbo èèyàn sàràkí-sàràkí ọba Bábílónì ránṣẹ́ 14 pé kí wọ́n mú Jeremáyà jáde kúrò ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́,+ wọ́n sì fà á lé ọwọ́ Gẹdaláyà+ ọmọ Áhíkámù+ ọmọ Ṣáfánì,+ láti mú un wá sí ilé rẹ̀. Torí náà, ó ń gbé ní àárín àwọn èèyàn náà.
-