ÌDÁRÒ
א [Áléfì]*
1 Ẹ wo bí Jerúsálẹ́mù tí àwọn èèyàn kún inú rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ṣe wá dá páropáro!+
Ẹ wo bó ṣe dà bí opó, ìlú tó ti jẹ́ eléèyàn púpọ̀ rí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè!+
Ẹ wo bí ẹni tó jẹ́ ọbabìnrin láàárín àwọn ìpínlẹ̀* ṣe wá di ẹrú!+
ב [Bétì]
2 Ó ń sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ ní òru,+ omijé sì ń dà ní ojú rẹ̀.
Kò sí ìkankan nínú gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ tó máa tù ú nínú.+
Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti dà á;+ wọ́n ti di ọ̀tá rẹ̀.
ג [Gímélì]
3 Júdà ti lọ sí ìgbèkùn+ nínú ìpọ́njú, ó sì ń ṣe ẹrú nínú ìnira.+
Ó gbọ́dọ̀ máa gbé láàárín àwọn orílẹ̀-èdè;+ kò rí ibi ìsinmi kankan.
Ọwọ́ gbogbo àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí i ti tẹ̀ ẹ́ nínú ìdààmú rẹ̀.
ד [Dálétì]
4 Àwọn ọ̀nà tó lọ sí Síónì ń ṣọ̀fọ̀, nítorí kò sí ẹni tó ń bọ̀ wá sí àjọyọ̀.+
Gbogbo ẹnubodè rẹ̀ di ahoro;+ àwọn àlùfáà rẹ̀ ń kẹ́dùn.
Ẹ̀dùn ọkàn ti bá àwọn wúńdíá* rẹ̀, ó sì wà nínú ìbànújẹ́ ńlá.
ה [Híì]
5 Àwọn elénìní rẹ̀ ti wá di ọ̀gá* rẹ̀; àwọn ọ̀tá rẹ̀ kò sì ṣàníyàn.+
Jèhófà ti mú ẹ̀dùn ọkàn bá a nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tó pọ̀.+
Àwọn ọmọ rẹ̀ ti lọ sí oko ẹrú níwájú àwọn elénìní.+
ו [Wọ́ọ̀]
6 Gbogbo ògo ọmọbìnrin Síónì ti kúrò lára rẹ̀.+
Àwọn olórí rẹ̀ dà bí àwọn akọ àgbọ̀nrín tí kò rí ibi ìjẹko,
Àárẹ̀ ti mú wọn bí wọ́n ṣe ń rìn lọ níwájú ẹni tó ń lépa wọn.
ז [Sáyìn]
7 Ní ọjọ́ ìdààmú Jerúsálẹ́mù àti nígbà tí kò rílé gbé, ó rántí
Gbogbo ohun iyebíye tó ní látijọ́.+
Nígbà tí àwọn èèyàn rẹ̀ ṣubú sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá, tí kò sì ní olùrànlọ́wọ́ kankan,+
ח [Hétì]
8 Jerúsálẹ́mù ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó pọ̀.+
Ìdí nìyẹn tó fi di ohun ìríra.
Gbogbo àwọn tó ń bọlá fún un tẹ́lẹ̀ ti wá ń fojú ẹ̀gàn wò ó, nítorí wọ́n ti rí ìhòòhò rẹ̀.+
Òun fúnra rẹ̀ kérora,+ ó sì yíjú pa dà pẹ̀lú ìtìjú.
ט [Tétì]
9 Àìmọ́ rẹ̀ wà lára aṣọ rẹ̀.
Kò ronú nípa ọjọ́ ọ̀la rẹ̀.+
Ìṣubú rẹ̀ yani lẹ́nu; kò sì ní ẹni tó máa tù ú nínú.
Jèhófà, wo ìpọ́njú mi, nítorí ọ̀tá ti gbé ara rẹ̀ ga.+
י [Yódì]
10 Elénìní ti kó gbogbo ìṣúra rẹ̀.+
Nítorí ìṣojú rẹ̀ ni àwọn orílẹ̀-èdè wá sínú ibi mímọ́ rẹ̀,+
Àwọn tí o pàṣẹ pé kí wọ́n má ṣe wá sínú ìjọ rẹ.
כ [Káfì]
11 Gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ ń kẹ́dùn; wọ́n ń wá oúnjẹ.*+
Wọ́n ti fi ohun iyebíye wọn pààrọ̀ oúnjẹ, kí wọ́n lè máa wà láàyè.*
Wò ó Jèhófà, wo bí mo ṣe dà bí obìnrin tí kò ní láárí.*
ל [Lámédì]
12 Ṣé kò já mọ́ nǹkan kan lójú gbogbo ẹ̀yin tó ń kọjá lójú ọ̀nà ni?
Ẹ wò ó, kí ẹ sì rí i!
Ǹjẹ́ ìrora kankan wà tó dà bí ìrora tí a mú kí ó dé bá mi,
Èyí tí Jèhófà mú kí n jìyà rẹ̀ ní ọjọ́ tí ìbínú rẹ̀ ń jó bí iná?+
מ [Mémì]
13 Láti ibi gíga ló ti rán iná sínú egungun mi,+ ó sì jó ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn.
Ó ti ta àwọ̀n fún ẹsẹ̀ mi; ó mú kí n pa dà sẹ́yìn.
Ó ti sọ mí di obìnrin tí a pa tì.
Láti àárọ̀ ṣúlẹ̀ ni mò ń ṣàìsàn.
נ [Núnì]
14 Ó fi ọwọ́ rẹ̀ so àwọn ìṣìnà mi pọ̀ bí àjàgà.
Ó fi wọ́n kọ́ ọrùn mi, mi ò sì lókun mọ́.
Jèhófà ti fi mí lé ọwọ́ àwọn tí mi ò lè dojú kọ.+
ס [Sámékì]
15 Jèhófà ti ti gbogbo àwọn alágbára tó wà láàárín mi sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.+
Ó ti pe àwọn èèyàn jọ sí mi kí wọ́n lè pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin mi.+
Jèhófà ti tẹ wúńdíá ọmọbìnrin Júdà bí àjàrà níbi tí wọ́n ti ń fún wáìnì.+
ע [Áyìn]
16 Nítorí nǹkan wọ̀nyí ni mo ṣe ń sunkún;+ omijé sì ń dà lójú mi.
Nítorí ẹni tó lè tù mí nínú tàbí tó lè tù mí* lára ti jìnnà réré sí mi.
Àwọn ọmọ mi kò nírètí, nítorí ọ̀tá ti borí.
פ [Péè]
17 Síónì ti tẹ́ ọwọ́ rẹ̀;+ kò ní ẹni tó máa tù ú nínú.
Gbogbo àwọn tó yí Jékọ́bù ká ni Jèhófà ti pàṣẹ fún pé kí wọ́n máa bá a ṣọ̀tá.+
Jerúsálẹ́mù ti di ohun ìríra sí wọn.+
צ [Sádì]
18 Jèhófà jẹ́ olódodo,+ èmi ni mo ṣàìgbọràn sí àṣẹ* rẹ̀.+
Ẹ fetí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin èèyàn, kí ẹ sì rí ìrora tí mò ń jẹ.
Àwọn wúńdíá* mi àti àwọn ọ̀dọ́kùnrin mi ti lọ sí oko ẹrú.+
ק [Kófì]
19 Mo pe àwọn olólùfẹ́ mi, àmọ́ wọ́n pa mí tì.+
Àwọn àlùfáà mi àti àwọn àgbààgbà mi ti ṣègbé nínú ìlú,
ר [Réṣì]
20 Wò ó, Jèhófà, mo wà nínú ìdààmú ńlá.
Inú* mi ń dà rú.
Ọkàn mi gbọgbẹ́, nítorí mo ti ya ọlọ̀tẹ̀ paraku.+
Idà ń pani ní ìta;+ ikú ń pani nínú ilé.
ש [Ṣínì]
21 Àwọn èèyàn ti gbọ́ bí mo ṣe ń kẹ́dùn; kò sí ẹnì kankan tó máa tù mí nínú.
Gbogbo àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ nípa àjálù tó dé bá mi.
Inú wọn dùn, nítorí o mú kí ó ṣẹlẹ̀.+
Àmọ́, o máa mú ọjọ́ tí o kéde wá,+ tí wọ́n á dà bí mo ṣe dà.+
ת [Tọ́ọ̀]
22 Kí gbogbo ìwà búburú wọn wá síwájú rẹ, kí o sì fìyà jẹ wọ́n,+
Bí o ṣe fìyà jẹ mí nítorí gbogbo àṣìṣe mi.
Nítorí ẹ̀dùn ọkàn mi pọ̀, ọkàn mi sì ń ṣàárẹ̀.
א [Áléfì]
2 Wo bí Jèhófà ṣe fi ìkùukùu* ìbínú rẹ̀ bo ọmọbìnrin Síónì!
Ó ti ju ẹwà Ísírẹ́lì láti òkè ọ̀run sí ilẹ̀ ayé.+
Kò sì rántí àpótí ìtìsẹ̀+ rẹ̀ ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀.
ב [Bétì]
2 Jèhófà ti gbé gbogbo ibùgbé Jékọ́bù mì, kò sì ṣàánú rẹ̀ rárá.
Ó ti ya àwọn ibi olódi ọmọbìnrin Júdà lulẹ̀ nínú ìbínú rẹ̀.+
Ó ti rẹ ìjọba + náà àti àwọn olórí+ rẹ̀ wálẹ̀, ó sì ti sọ wọ́n di aláìmọ́.
ג [Gímélì]
3 Ó ti gba agbára* Ísírẹ́lì, nínú ìbínú tó gbóná.
Ó fa ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sẹ́yìn nígbà tí ọ̀tá dé,+
Ó sì ń jó nínú Jékọ́bù bí iná tó ń run gbogbo ohun tó wà ní àyíká rẹ̀.+
ד [Dálétì]
4 Ó ti tẹ* ọrun rẹ̀ bí ọ̀tá; ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ti múra tán láti jà bí elénìní;+
Ó ń pa gbogbo àwọn tó jojú ní gbèsè.+
Ó da ìrunú rẹ̀ jáde bí iná+ sínú àgọ́ ọmọbìnrin Síónì.+
ה [Híì]
5 Jèhófà ṣe bí ọ̀tá;+
Ó ti gbé Ísírẹ́lì mì.
Ó ti gbé gbogbo ilé gogoro rẹ̀ mì;
Ó ti run gbogbo ibi olódi rẹ̀.
Ó sì sọ ọ̀fọ̀ àti ìdárò ọmọbìnrin Júdà di púpọ̀.
ו [Wọ́ọ̀]
6 Ó ṣe àtíbàbà rẹ̀ ṣúkaṣùka+ bí ahéré tó wà nínú oko.
Jèhófà ti mú kí a gbàgbé àjọyọ̀ àti sábáàtì ní Síónì,
Kò sì ka ọba àti àlùfáà sí nígbà tí inú ń bí i gan-an.+
ז [Sáyìn]
7 Jèhófà ti pa pẹpẹ rẹ̀ tì;
Ó ti ta ibi mímọ́ rẹ̀ nù.+
Ó ti fi ògiri àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò lé ọ̀tá lọ́wọ́.+
Wọ́n ti gbé ohùn wọn sókè ní ilé Jèhófà,+ bíi ti ọjọ́ àjọyọ̀.
ח [Hétì]
8 Jèhófà ti pinnu láti run ògiri ọmọbìnrin Síónì.+
Ó ti na okùn ìdíwọ̀n.+
Kò fa ọwọ́ rẹ̀ sẹ́yìn láti mú ìparun wá.*
Ó ń mú kí odi ààbò àti ògiri máa ṣọ̀fọ̀.
Gbogbo wọn sì ti di aláìlágbára.
ט [Tétì]
9 Àwọn ẹnubodè rẹ̀ ti rì wọlẹ̀.+
Ọlọ́run ti ba ọ̀pá ìdábùú rẹ̀ jẹ́, ó sì ti ṣẹ́ ẹ.
Ọba rẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀ wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+
Kò sí òfin;* kódà àwọn wòlíì rẹ̀ kò rí ìran láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.+
י [Yódì]
10 Àwọn àgbààgbà ọmọbìnrin Síónì jókòó sórí ilẹ̀ láìsọ̀rọ̀.+
Wọ́n da iyẹ̀pẹ̀ sí orí ara wọn, wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀.*+
Àwọn wúńdíá Jerúsálẹ́mù ti tẹrí ba mọ́lẹ̀.
כ [Káfì]
11 Ojú mi ti di bàìbàì nítorí omijé.+
Inú* mi ń dà rú.
A ti tú ẹ̀dọ̀ mi jáde sí ilẹ̀, nítorí ìṣubú ọmọbìnrin* àwọn èèyàn mi,+
Nítorí àwọn ọmọdé àti ọmọ jòjòló ń dá kú ní àwọn ojúde ìlú.+
ל [Lámédì]
12 Wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ìyá wọn pé: “Ọkà àti wáìnì dà?”+
Bí wọ́n ti ń kú lọ bí ẹni tó fara gbọgbẹ́ ní àwọn gbàgede ìlú,
Tí ẹ̀mí* wọn sì ń kú lọ lọ́wọ́ ìyá wọn.
מ [Mémì]
13 Kí ni màá fi ṣe ẹ̀rí,
Àbí kí ni màá fi ọ́ wé, ìwọ ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù?
Kí ni màá fi ọ́ wé, kí n lè tù ọ́ nínú, ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Síónì?
Nítorí ọgbẹ́ rẹ pọ̀ gan-an, ó fẹ̀ bí omi òkun.+ Ta ló lè wò ọ́ sàn?+
נ [Núnì]
14 Ìran tí àwọn wòlíì rẹ rí fún ọ jẹ́ èké àti asán,+
Wọn kò fi àṣìṣe rẹ hàn ọ́ láti gbà ọ́ lọ́wọ́ oko ẹrú,+
Ṣùgbọ́n ìran tí wọ́n ń rí, tí wọ́n sì ń kéde fún ọ jẹ́ èké àti ìṣìnà.+
ס [Sámékì]
15 Gbogbo àwọn tó ń kọjá lọ lójú ọ̀nà ń fi ọ́ ṣẹ̀sín, wọ́n sì ń pàtẹ́wọ́.+
Wọ́n ń súfèé nítorí ìyàlẹ́nu,+ wọ́n sì ń mi orí wọn sí ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù, pé:
“Ṣé ìlú yìí ni wọ́n máa ń sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Ẹwà rẹ̀ pé, ó jẹ́ ayọ̀ gbogbo ayé’?”+
פ [Péè]
16 Gbogbo ọ̀tá rẹ ti la ẹnu wọn sí ọ.
Wọ́n ń súfèé, wọ́n sì wa eyín pọ̀, wọ́n ń sọ pé: “A ti gbé e mì.+
Ọjọ́ tí à ń retí nìyí! + Ó ti dé, a sì ti rí i!”+
ע [Áyìn]
Ó ti ya ọ́ lulẹ̀, kò sì ṣàánú rẹ.+
Ó ti mú kí ọ̀tá yọ̀ lórí rẹ; ó ti mú kí agbára* àwọn elénìní rẹ borí.
צ [Sádì]
18 Ọkàn wọn ké jáde sí Jèhófà, ìwọ ògiri ọmọbìnrin Síónì.
Kí omijé máa ṣàn wálẹ̀ bí ọ̀gbàrá lọ́sàn-án àti lóru.
Má sinmi, má sì jẹ́ kí ojú* rẹ ṣíwọ́ ẹkún.
ק [Kófì]
19 Dìde! Bú sẹ́kún ní òru, ní ìbẹ̀rẹ̀ àkókò ìṣọ́.
Tú ọkàn rẹ jáde bí omi níwájú Jèhófà.
Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí Ọlọ́run nítorí ẹ̀mí* àwọn ọmọ rẹ,
ר [Réṣì]
20 Wò ó Jèhófà, wo ẹni tí o fìyà jẹ.
Ṣé ó yẹ kí àwọn obìnrin máa jẹ ọmọ* tiwọn fúnra wọn, àwọn ọmọ tí wọ́n bí láìní àbùkù,+
Àbí, ṣé ó yẹ kí wọ́n pa àwọn àlùfáà àti wòlíì nínú ibi mímọ́ Jèhófà?+
ש [Ṣínì]
21 Òkú ọmọdékùnrin àti àgbà ọkùnrin wà nílẹ̀ ní àwọn ojú ọ̀nà.+
Àwọn wúńdíá* mi àti àwọn ọ̀dọ́kùnrin mi ni idà sì ti pa sílẹ̀.+
O ti pa wọ́n ní ọjọ́ ìbínú rẹ; o sì ti pa wọ́n láìṣàánú wọn.+
ת [Tọ́ọ̀]
22 O ránṣẹ́ pe ohun ẹ̀rù láti ibi gbogbo wá, bí ìgbà tí à ń peni sí ọjọ́ àjọyọ̀.+
Ní ọjọ́ ìrunú Jèhófà, kò sí ẹni tó sá àsálà, kò sì sí ẹni tó là á já;+
א [Áléfì]
3 Èmi ni ọkùnrin tó ti rí ìpọ́njú nítorí ọ̀pá ìbínú rẹ̀.
2 Ó ti lé mi jáde, ó sì mú kí n rìn nínú òkùnkùn, kì í ṣe nínú ìmọ́lẹ̀.+
3 Ní tòótọ́, ó ti fi ọwọ́ rẹ̀ gbá mi léraléra láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.+
ב [Bétì]
4 Ó ti mú kí ara mi ṣàárẹ̀, àwọ̀ mi sì ti ṣá;
Ó ti fọ́ egungun mi.
5 Ó ti dó tì mí; ó sì ti fi májèlé kíkorò+ àti ìnira yí mi ká.
6 Ó ti fipá mú mi jókòó síbi tó ṣókùnkùn, bí àwọn tó ti kú tipẹ́tipẹ́.
ג [Gímélì]
7 Ó ti fi ògiri ká mi mọ́, kí n má bàa sá lọ;
Ó ti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà tó wúwo dè mí.+
8 Nígbà tí mo bá ké pè é fún ìrànlọ́wọ́, kì í gbọ́* àdúrà mi.+
9 Ó ti fi òkúta gbígbẹ́ dí àwọn ọ̀nà mi pa;
Ó ti lọ́ àwọn ojú ọ̀nà mi po.+
ד [Dálétì]
10 Ó lúgọ dè mí bíi bíárì àti bíi kìnnìún tó fara pa mọ́.+
12 Ó ti fa ọfà* rẹ̀, ó sì gbé mi kalẹ̀ bí ohun tí a fẹ́ ta ọfà sí.
ה [Híì]
13 Ó ti ta ọfà* inú apó rẹ̀ lu kíndìnrín mi.
14 Mo ti di ẹni yẹ̀yẹ́ lójú gbogbo èèyàn, ọ̀rọ̀ mi sì ni wọ́n fi ń ṣe orin kọ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.
15 Ó ti fi àwọn ohun tó korò kún inú mi, ó sì fún mi ní iwọ* mu ní àmuyó.+
ו [Wọ́ọ̀]
17 O ti gba àlàáfíà mi;* mo ti gbàgbé ohun rere.
18 Torí náà mo sọ pé: “Ògo mi ti pa rẹ́ àti ohun tí mò ń retí lọ́dọ̀ Jèhófà.”
ז [Sáyìn]
19 Rántí ìyà tó ń jẹ mí àti bí mi ò ṣe rílé gbé,+ má gbàgbé pé mo jẹ iwọ* àti májèlé kíkorò.+
20 Ó dájú pé o* máa rántí, wàá sì bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ kí o lè ràn mí lọ́wọ́.+
21 Mo rántí èyí nínú ọkàn mi; ìdí nìyẹn tí màá ṣe fi sùúrù dúró dè ọ́.+
ח [Hétì]
23 Tuntun ni wọ́n láràárọ̀;+ ìṣòtítọ́ rẹ pọ̀ gan-an.+
24 Mo* sọ pé, “Jèhófà ni ìpín mi,+ ìdí nìyẹn tí màá ṣe fi sùúrù dúró dè é.”+
ט [Tétì]
25 Jèhófà jẹ́ ẹni rere sí ẹni tó gbẹ́kẹ̀ lé e,+ ìyẹn ẹni* tó ń wá a.+
26 Ó dáa kí èèyàn dúró jẹ́ẹ́*+ de ìgbàlà Jèhófà.+
27 Ó dáa kí ọkùnrin ru àjàgà ní ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀.+
י [Yódì]
28 Kí ó dá jókòó, kí ó sì dákẹ́ jẹ́ẹ́ nígbà tí Ọlọ́run bá gbé e le lórí.+
29 Kí ó dojú bolẹ̀ nínú eruku;+ bóyá ìrètí ṣì lè wà fún un.+
30 Kí ó gbé etí rẹ̀ fún ẹni tó ń gbá a; kí ó gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀gàn.
כ [Káfì]
31 Nítorí Jèhófà kò ní kọ̀ wá sílẹ̀ títí láé.+
32 Bí ó tilẹ̀ fa ẹ̀dùn ọkàn, á tún fi àánú hàn nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.+
33 Nítorí kò ní in lọ́kàn láti kó ìdààmú tàbí ẹ̀dùn ọkàn bá ọmọ èèyàn.+
ל [Lámédì]
34 Láti tẹ àwọn ẹlẹ́wọ̀n gbogbo ayé mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ ẹni,+
35 Láti yí ìdájọ́ ẹnì kan po níwájú Ẹni Gíga Jù Lọ,+
36 Láti rẹ́ ẹnì kan jẹ nínú ẹjọ́ rẹ̀,
Jèhófà kò fàyè gba irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀.
מ [Mémì]
37 Ta ló wá lè sọ̀rọ̀ kó sì mú un ṣẹ láìjẹ́ pé Jèhófà pa á láṣẹ?
38 Ohun búburú àti ohun rere
Kì í ti ẹnu Ẹni Gíga Jù Lọ jáde.
39 Kí nìdí tí alààyè yóò fi ráhùn nítorí àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀? +
נ [Núnì]
40 Ẹ jẹ́ ká yẹ ọ̀nà wa wò, ká wò ó fínnífínní,+ ẹ sì jẹ́ ká pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.+
41 Ẹ jẹ́ ká gbé ọkàn wa àti ọwọ́ wa sókè sí Ọlọ́run lókè ọ̀run:+
42 “A ti dẹ́ṣẹ̀, a ti ṣọ̀tẹ̀,+ ìwọ kò sì tíì dárí jì wá.+
ס [Sámékì]
44 O ti fi àwọsánmà dí ọ̀nà tó lọ sọ́dọ̀ rẹ, kí àdúrà wa má bàa kọjá.+
45 Ó sọ wá di èérí àti pàǹtírí láàárín àwọn èèyàn.”
פ [Péè]
46 Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti la ẹnu wọn sí wa.+
47 Inú ẹ̀rù àti kòtò la wà,+ a ti di ahoro, a sì ti di àwókù.+
48 Omi ń ṣàn wálẹ̀ ní ojú mi nítorí ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi ti ṣubú lulẹ̀.+
ע [Áyìn]
49 Omijé ń dà lójú mi pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀, kò dáwọ́ dúró,+
50 Títí Jèhófà fi bojú wolẹ̀ láti ọ̀run, tí ó sì rí i.+
51 Ẹ̀dùn ọkàn bá mi nígbà tí mo rí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọbìnrin ìlú mi.+
צ [Sádì]
52 Àwọn ọ̀tá mi ti dẹkùn mú mi bí ẹyẹ, láìnídìí.
53 Wọ́n ti mú kí ẹ̀mí mi dákẹ́ sínú kòtò; wọ́n sì ń sọ òkúta lù mí.
54 Omi ti ṣàn bò mí lórí, mo sì sọ pé: “Tèmi ti tán!”
ק [Kófì]
55 Mo ké pe orúkọ rẹ, Jèhófà, láti inú kòtò tó jìn.+
56 Gbọ́ ohùn mi; má ṣe dí etí rẹ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́ àti fún ìtura.
57 O sún mọ́ tòsí ní ọjọ́ tí mo pè ọ́. O sọ pé: “Má bẹ̀rù.”
ר [Réṣì]
58 O ti gbèjà mi,* Jèhófà, o ti ra ẹ̀mí mi pa dà.+
59 O ti rí àìtọ́ tí wọ́n ṣe sí mi, Jèhófà; jọ̀ọ́ dá mi láre.+
60 O ti rí gbogbo bí wọ́n ṣe ń gbẹ̀san, gbogbo ètekéte wọn sí mi.
ש [Sínì] tàbí [Ṣínì]
61 O ti gbọ́ ẹ̀gàn wọn, Jèhófà, gbogbo ètekéte wọn sí mi,+
62 Ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn tó ń ta kò mí àti ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ tí wọ́n ń sọ nípa mi láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.
63 Wò wọ́n; bóyá wọ́n jókòó ni o àbí wọ́n dúró, èmi ni wọ́n fi ń ṣe yẹ̀yẹ́ nínú orin wọn!
ת [Tọ́ọ̀]
64 Wàá san án pa dà fún wọn, Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
65 Wàá mú kí ọkàn wọn le, gẹ́gẹ́ bí o ti gégùn-ún fún wọn.
66 Wàá lé wọn nínú ìbínú rẹ, Jèhófà, wàá sì pa wọ́n rẹ́ lábẹ́ ọ̀run rẹ.
א [Áléfì]
4 Ẹ wo bí wúrà tó ń dán ṣe di bàìbàì, wúrà tó dára gan-an!+
Ẹ wo bí àwọn òkúta mímọ́+ ṣe fọ́n ká sílẹ̀ ní gbogbo oríta ojú ọ̀nà!*+
ב [Bétì]
2 Ní ti àwọn ọmọ ọ̀wọ́n Síónì, tí wọ́n fìgbà kan rí ṣeyebíye bíi wúrà tí a yọ́ mọ́,
Ẹ wo bí a ti kà wọ́n sí ìkòkò amọ̀,
Iṣẹ́ ọwọ́ amọ̀kòkò!
ג [Gímélì]
3 Àwọn ajáko* pàápàá máa ń fún ọmọ wọn lọ́mú,
Àmọ́ ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi ti ya ìkà,+ bí àwọn ògòǹgò aginjù.+
ד [Dálétì]
4 Ahọ́n ọmọ ẹnu ọmú lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu rẹ̀ nítorí òùngbẹ.
Àwọn ọmọ tọrọ oúnjẹ,*+ àmọ́ kò sí ẹni tó fún wọn.+
ה [Híì]
5 Àwọn tó ti ń jẹ oúnjẹ aládùn tẹ́lẹ̀ ni ebi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa kú* ní àwọn ojú ọ̀nà.+
Àwọn tí a fi aṣọ rírẹ̀dòdò tọ́ dàgbà+ ti wá ń lọ sínú òkìtì eérú.
ו [Wọ́ọ̀]
6 Ìyà tí a fi jẹ* ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi pọ̀ ju ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí a fi jẹ* Sódómù lọ,+
Tí a ṣẹ́gun ní ìṣẹ́jú kan, láìsí ẹnì kankan tó ràn án lọ́wọ́.+
ז [Sáyìn]
7 Àwọn Násírì+ rẹ̀ mọ́ ju yìnyín lọ, wọ́n funfun ju wàrà lọ.
Wọ́n pọ́n ju iyùn lọ; wọ́n ń dán bí òkúta sàfáyà.
ח [Hétì]
8 Àwọ̀ wọn ti wá dúdú ju èédú lọ;
A kò dá wọn mọ̀ ní ojú ọ̀nà.
Wọ́n ti rù kan egungun;+ awọ ara wọn ti gbẹ bí igi.
ט [Tétì]
9 Àwọn tí idà pa sàn ju àwọn tí ìyàn pa,+
Àwọn tó ń kú lọ, tí ìyàn mú débi pé ìrora wọn dà bí ìgbà tí idà gúnni.
י [Yódì]
10 Àwọn obìnrin aláàánú ti fọwọ́ ara wọn se àwọn ọmọ wọn. +
Wọ́n ti di oúnjẹ ọ̀fọ̀ fún wọn nígbà tí ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi wó lulẹ̀.+
כ [Káfì]
11 Jèhófà ti fi ìrunú rẹ̀ hàn;
Ó ti da ìbínú rẹ̀ tó ń jó bí iná jáde.+
Ó sì ti dá iná kan ní Síónì tó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run.+
ל [Lámédì]
12 Àwọn ọba ayé àti gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ tó ń mú èso jáde kò gbà gbọ́
Pé elénìní àti ọ̀tá máa wọ àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù.+
מ [Mémì]
13 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀ àti àṣìṣe àwọn àlùfáà rẹ̀,+
Tí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo sílẹ̀ láàárín rẹ̀.+
נ [Núnì]
14 Wọ́n ti rìn kiri bí afọ́jú+ ní àwọn ojú ọ̀nà.
Ẹ̀jẹ̀ ti sọ wọ́n di aláìmọ́,+
Tí kò fi sí ẹnikẹ́ni tó lè fọwọ́ kan ẹ̀wù wọn.
ס [Sámékì]
15 Àwọn èèyàn ń ké jáde sí wọn pé, “Ẹ kúrò! Ẹ̀yin aláìmọ́! Ẹ kúrò! Ẹ kúrò! Ẹ má fọwọ́ kàn wá!”
Nítorí wọn ò rí ilé gbé, wọ́n sì ń rìn kiri.
Àwọn èèyàn ń sọ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé: “Wọn ò lè gbé ibí yìí pẹ̀lú wa.*+
פ [Péè]
16 Ojú Jèhófà ti fọ́n wọn ká;+
Kò ní ṣojú rere sí wọn mọ́.
Àwọn èèyàn kò ní bọ̀wọ̀ fún àwọn àlùfáà,+ wọn kò sì ní ṣàánú àwọn àgbààgbà.”+
ע [Áyìn]
17 Kódà ní báyìí, ojú wa ti di bàìbàì bí a ṣe ń retí ìrànwọ́ tí kò sì dé.+
A wá ìrànwọ́ títí lọ́dọ̀ orílẹ̀-èdè tí kò lè gbà wá.+
צ [Sádì]
18 Àwọn ọ̀tá wa ń dọdẹ wa kiri+ débi pé a ò lè rìn mọ́ ní àwọn ojúde ìlú wa.
Òpin wa ti sún mọ́lé; ọjọ́ wa ti pé, nítorí òpin wa ti dé.
ק [Kófì]
19 Àwọn tó ń lé wa yára ju ẹyẹ idì ojú ọ̀run lọ.+
Wọ́n lépa wa lórí àwọn òkè; wọ́n lúgọ dè wá nínú aginjù.
ר [Réṣì]
20 Èémí wa, ẹni àmì òróró Jèhófà,+ ni wọ́n ti mú nínú kòtò ńlá wọn,+
Ẹni tí a sọ nípa rẹ̀ pé: “Abẹ́ òjìji rẹ̀ la ó máa gbé láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.”
ש [Sínì]
21 Máa yọ̀ kí inú rẹ sì máa dùn, ìwọ ọmọbìnrin Édómù,+ bí o ṣe ń gbé ní ilẹ̀ Úsì.
Àmọ́ wọ́n á gbé ife náà fún ìwọ pẹ̀lú,+ wàá mu àmupara, wàá sì tú ara rẹ sí ìhòòhò.+
ת [Tọ́ọ̀]
22 Ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ti dòpin, ìwọ ọmọbìnrin Síónì.
Ẹnikẹ́ni kò ní gbé ọ lọ sí ìgbèkùn mọ́.+
Àmọ́ Ọlọ́run yóò fiyè sí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, ìwọ ọmọbìnrin Édómù.
Yóò tú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ síta.+
5 Jèhófà, rántí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa.
Wò wá, kí o sì rí ìtìjú wa.+
2 Ogún wa ti bọ́ sọ́wọ́ àwọn àjèjì, àwọn ilé wa sì ti bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè.+
3 A ti di ọmọ aláìlóbìí, a kò ní bàbá; àwọn ìyá wa dà bí opó.+
4 Ńṣe là ń sanwó ká tó lè rí omi wa mu,+ wọ́n sì ń ta igi wa fún wa.
5 Àwọn tó ń lé wa ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bá wa;
Ó ti rẹ̀ wá tẹnutẹnu, síbẹ̀ wọn ò fún wa ní ìsinmi.+
6 A ti tẹ́ ọwọ́ wa sí Íjíbítì+ àti Ásíríà,+ ká lè rí oúnjẹ tí ó tó jẹ.
7 Àwọn baba ńlá wa tó dẹ́ṣẹ̀ kò sí mọ́, àmọ́ àwa là ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
8 Àwọn ìránṣẹ́ ló wá ń ṣàkóso lé wa lórí; kò sí ẹni tó máa gbà wá lọ́wọ́ wọn.
9 À ń fi ẹ̀mí* wa wewu ká tó lè kó oúnjẹ wa wọlé,+ nítorí idà tó wà ní aginjù.
10 Awọ ara wa ti gbóná bí iná ìléru, nítorí ebi tó ń hanni léèmọ̀.+
11 Àwọn aya tó wà ní Síónì àti àwọn wúńdíá tó wà ní àwọn ìlú Júdà ni wọ́n ti kó ẹ̀gàn bá.*+
12 Wọ́n so àwọn ìjòyè rọ̀ ní ọwọ́ wọn,+ wọn kò sì bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbààgbà.+
13 Àwọn ọ̀dọ́kùnrin gbé ọlọ, àwọn ọmọdékùnrin sì kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń ru igi tó wúwo.
14 Àwọn àgbààgbà kò jókòó sí ẹnubodè ìlú mọ́;+ àwọn ọ̀dọ́kùnrin kò sì fi ohun èlò kọ orin mọ́.+
15 Ọkàn wa kò láyọ̀ mọ́; ijó wa ti di ọ̀fọ̀.+
16 Adé ti já bọ́ lórí wa. A gbé, nítorí a ti dẹ́ṣẹ̀!
17 Nítorí èyí, ọkàn wa ń ṣàárẹ̀,+
Ojú wa sì ti di bàìbàì nítorí àwọn nǹkan yìí,+
18 Nítorí Òkè Síónì ti di ahoro,+ àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ti wá ń rìn káàkiri lórí rẹ̀.
19 Ní tìrẹ, Jèhófà, o jókòó lórí ìtẹ́ títí láé.
Ìtẹ́ rẹ jẹ́ láti ìran dé ìran.+
20 Kí nìdí tí o fi gbàgbé wa pátápátá, tí o sì pa wá tì títí di àkókò yìí?+
21 Mú wa pa dà sọ́dọ̀ rẹ, Jèhófà, a ó sì tètè pa dà sọ́dọ̀ rẹ.+
Sọ ọjọ́ wa di ọ̀tun bíi ti àtijọ́.+
22 Ńṣe lo kọ̀ wá sílẹ̀ pátápátá.
O ṣì ń bínú sí wa gidigidi.+
Orí 1 sí 4 jẹ́ orin arò tí wọ́n fi álífábẹ́ẹ̀tì èdè Hébérù tàbí ọ̀rọ̀ ewì tò.
Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”
Tàbí “àwọn ọ̀dọ́bìnrin.”
Ní Héb., “olórí.”
Tàbí “wọ́n yọ̀ ọ́.”
Ní Héb., “búrẹ́dì.”
Tàbí “dá ọkàn wọn pa dà.”
Àkànlò èdè fífi nǹkan wé èèyàn, èyí tó ń tọ́ka sí Jerúsálẹ́mù.
Tàbí “tu ọkàn mi.”
Ní Héb., “ẹnu.”
Tàbí “Àwọn ọ̀dọ́bìnrin.”
Tàbí “dá ọkàn wọn pa dà.”
Ní Héb., “Ìfun.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Ní Héb., “ṣẹ́ ìwo.”
Ní Héb., “fi ẹsẹ̀ tẹ.”
Tàbí “run.”
Ní Héb., “láti gbé mì.”
Tàbí “ìtọ́ni.”
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Ní Héb., “Ìfun.”
Ọ̀rọ̀ ewì tó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka si àánú tàbí ìgbatẹnirò bíi pé èèyàn ni wọ́n.
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “ìwo.”
Ní Héb., “ọmọbìnrin ojú.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “ìkóríta.”
Tàbí “èso.”
Tàbí “Àwọn ọ̀dọ́bìnrin.”
Tàbí “Àwọn tí mo bí láìní àbùkù.”
Tàbí “ó ń dínà.”
Tàbí kó jẹ́, “ó ti jẹ́ kí n dà bí ilẹ̀ tí a pa tì.”
Ní Héb., “tẹ ọrun.”
Ní Héb., “ọmọ.”
Ìyẹn, igi kan tó korò gan-an.
Tàbí “ọkàn mi.”
Ìyẹn, igi kan tó korò gan-an.
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Tàbí “Ọkàn mi.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “fi sùúrù dúró.”
Tàbí “gba ẹjọ́ ọkàn mi rò.”
Ní Héb., “ìkóríta.”
Tàbí “akátá.”
Ní Héb., “búrẹ́dì.”
Ní Héb., “ni ó ti di ahoro.”
Ní Héb., “Àṣìṣe.”
Ní Héb., “ẹ̀ṣẹ̀.”
Tàbí “ṣe àjèjì níbí yìí.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ti fipá bá lò pọ̀.”