Àwọn Ìdílé Tí Kò Ti Sí Bàbá—Fífòpin Sí Ìṣòro Náà
BÍ NǸKAN bá ń lọ bó ṣe ń lọ yìí, àwọn ìdílé tí kò ti sí bàbá ló máa pọ̀ jù lọ láyé. Ìròyìn kan láti Iléeṣẹ́ Ìjọba Amẹ́ríkà Tí Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Ìlera àti Ìpèsè fún Aráàlú sọ pé: “Àwọn ọmọ tó jẹ́ òbí kan ló tọ́ wọn dàgbà kì í mọ̀wé, wọ́n kì í mọ̀wàáhù, wọ́n sì máa ń ní àrùn tó le àti àrùn ọpọlọ. . . . Ewu gidi wà pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí ìyá nìkan tọ́ lè bímọ nígbà tí wọn kò tíì tó ogún ọdún, wọ́n sì lè sá fi ilé ìwé sílẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú wọ́n [sì] lè ṣẹ̀wọ̀n.”
Abájọ tí àwọn onímọ̀ nípa àwùjọ ẹ̀dá, àwọn tí ń gba ìdílé nímọ̀ràn, àwọn olùkọ́, àti àwọn òṣèlú pàápàá fi ń forí fọrùn ṣe, kí wọ́n lè fòpin sí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń bani nínú jẹ́ yìí. Wọ́n ti ṣe àwọn àpérò ńlá fáwọn ọkùnrin kí wọ́n lè máa fi ipò jíjẹ́ bàbá yangàn, kí àwọn ọkùnrin sì lè máa gbé ẹrù iṣẹ́ wọn nínú ìdílé. Àwọn ìwé tó ń sọ nípa ipò jíjẹ́ bàbá kún orí àtẹ. Wọ́n tiẹ̀ ti sapá láti mú un lọ́ranyàn fún àwọn bàbá láti gbé ẹrù iṣẹ́ wọn. Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, àwọn adájọ́ ń na “àwọn bàbá tí wọ́n kọ̀ láti bójú tó àwọn ọmọ wọn” lẹ́gba ọ̀rọ̀, wọ́n ń sọ̀rọ̀ sí wọn lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹlifíṣọ̀n, wọ́n tilẹ̀ ń tẹ́ wọn ní gbangba. Àmọ́, irú ìsapá wọ̀nyẹn ò ran ìṣòro tó wà ńlẹ̀ rárá.
Ojútùú Kíákíá
Wíwá ojútùú kíákíá pẹ̀lú lè yọrí sí iyèméjì. Fún àpẹẹrẹ, obìnrin kan tọ́kọ rẹ̀ ti kọ̀ sílẹ̀ lè tètè lọ fẹ́ ẹlòmíràn, kí òun lè rí ẹlòmíì tó máa ṣe bàbá fáwọn ọmọ òun. Lóòótọ́ fífẹ́ ẹlòmíì lè ṣàǹfààní láyè tiẹ̀, ṣùgbọ́n ìṣòro lè wà o. Nígbà míì, àwọn ọmọ lè máà fẹ́ tẹ́wọ́ gba ẹni tuntun kan gẹ́gẹ́ bí bàbá wọn. Nígbà míì wọn kì í gbà rárá. Ìwádìí kan fi hàn pé, “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá méjì nínú mẹ́ta lára àwọn obìnrin tó gbé inú ìdílé onígbèéyàwó àtúnṣe tó fi ilé sílẹ̀ kí wọ́n tó pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún . . . , tí a bá fi wé ìpín àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin tí ò gbé inú ìdílé onígbèéyàwó àtúnṣe.” Kódà nínú àwọn ìdílé onígbèéyàwó àtúnṣe tó kẹ́sẹ járí pàápàá, nígbà míì, ó máa ń gba ọ̀pọ̀ ọdún kí àwọn ọmọ tó lè tẹ́wọ́ gba ọkọ ìyá wọn.a
Bákan náà, kò sí ojútùú kíákíá tí a lè fi yanjú ọ̀ràn àwọn ọmọ tó lọ ń gboyún láìtíì pé ọmọ ogún ọdún. Fún àpẹẹrẹ, ìṣẹ́yún lòdì sí òfin Ọlọ́run, ó sì ń jẹ́ kí ọ̀dọ́bìnrin fọ́ ojú àánú tó yẹ kó ní sí ẹ̀mí ọmọ inú ọlẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà nínú rẹ̀. (Ẹ́kísódù 20:13; 21:22, 23; Sáàmù 139:14-16; fi wé 1 Jòhánù 3:17.) Ìgbà wo lẹ̀rí ọkàn ò ní máa dààmú ẹni tó bá ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀? Gbígbé ọmọ sílẹ̀ kí ẹlòmíràn fi ṣe ọmọ jẹ́ ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ èèyàn kà sí ojútùú tó bójú mu, ṣùgbọ́n ìyẹn náà lè dá ọgbẹ́ sọ́kàn ìyá àti ọmọ.
Rárá o, ojútùú kíákíá kò ní yanjú ìṣòro wíwà tí ìdílé ń wà láìsí bàbá. Àfi bí àwọn èèyàn bá ṣe tán láti ṣe àwọn ìyípadà pàtàkì nínú ìrònú wọn, ìhùwàsí wọn, àti ìwà rere wọn ni ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ nínú ìdílé kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́. A nílò ohun tó lágbára ju ọ̀rọ̀ dídùn lásán àti ríru ìmọ̀lára àwọn èèyàn sókè láti lè mú kí wọ́n ṣe irú ìyípadà tegbòtigaga bẹ́ẹ̀. Inú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la ti lè rí “ohun tó lágbára” yẹn. Ó ṣe tán, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló gbé ètò ìdílé kalẹ̀. (Éfésù 3:14, 15) Ó mọ ohun tí àwọn ọmọ ń fẹ́ ju ẹnikẹ́ni lọ.
Àwọn Ìlànà Bíbélì Ń Ran Ìdílé Lọ́wọ́ Láti Fara Dà Á
Ṣùgbọ́n ṣé Bíbélì lè ran àwọn ọmọ tí ọ̀kan lára òbí wọn kò sí nítòsí lọ́wọ́ lóòótọ́? Ṣé ọ̀ràn wọn ò tíì kọjá àtúnṣe ni? Rárá o. Níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, a fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìròyìn kan tí ìjọba Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ, níbi tó ti to púpọ̀ lára ewu tí àwọn ọmọ wọ̀nyí dojú kọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ níbẹ̀ dẹ́rù bani, ìròyìn náà parí ọ̀rọ̀ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rí rẹpẹtẹ wà pé ewu ńlá ńbẹ, ìwádìí náà tún fi hàn pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọdé tó jẹ́ òbí kan ṣoṣo ló ń tọ́ wọn máa ń ṣe dáadáa.” Òótọ́ ni, a lè mú ìṣòro wíwà láìsí bàbá kúrò tàbí ká tiẹ̀ dín in kù. Èyí máa ń rí bẹ́ẹ̀, ní pàtàkì bí a bá fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú títọ́ ọmọ náà.
Èyí ń béèrè iṣẹ́ ńlá lọ́wọ́ òbí tó ń dá ọmọ tọ́—ó sì lè jọ pé iṣẹ́ náà pọ̀ jù fún un níbẹ̀rẹ̀. Ṣùgbọ́n bó bá jẹ́ ìwọ lọ̀rọ̀ náà ṣẹlẹ̀ sí, o lè kọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run ní kíkún. (Òwe 3:1, 2) Àwọn obìnrin Kristẹni kan tí wọ́n wà nígbà tí a kọ Bíbélì kojú àwọn ìṣòro tó le gan-an, bíi jíjẹ́ opó. Bíbélì sọ nípa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pé: “Obìnrin tí ó jẹ́ opó ní ti gidi, tí a sì fi sílẹ̀ ní aláìní, ti fi ìrètí rẹ̀ sínú Ọlọ́run, ó sì tẹpẹlẹ mọ́ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ àti àdúrà lóru àti lọ́sàn-án.” (1 Tímótì 5:5) Rántí pé Jèhófà sọ pé òun ni “baba àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba.” (Sáàmù 68:5) A sì lè mú un dá ọ lójú pé òun yóò ran obìnrin tó bá bẹ̀rù Ọlọ́run lọ́wọ́ bó ti ń sapá láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀.
Bíbá àwọn ọmọ ẹni ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé déédéé jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tí a lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dàgbà di ẹni tó gbọ́n, tó sì dàgbà dénú. (Diutarónómì 6:6-9) Púpọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń dá tọ́mọ ń lo àwọn ìwé tí a gbé karí Bíbélì, tí a ṣe ní pàtàkì fún àwọn ọ̀dọ́, àwọn ìwé bíi Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́.b Àwọn ìsọfúnni tó wà nínú rẹ̀ ń ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti mú ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà rere dàgbà, èyí tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yàgò fún ṣíṣe irú àṣìṣe táwọn òbí wọ́n ṣe. Tí àwọn ọmọ wọ̀nyí bá mọ Jèhófà Ọlọ́run, wọ́n lè wá mọ̀ pé àwọ́n ní Bàbá kan lọ́run tó bìkítà gidigidi nípa àwọn. (Sáàmù 27:10) Èyí lè mú kí wọ́n ṣẹ́pá ìrònú pé a pa àwọn tì. Ọmọdébìnrin kan láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí àwọn òbí rẹ̀ kọra wọn sílẹ̀ rántí pé: “Ní gbogbo àkókò yẹn, Mọ́mì tẹ ìjẹ́pàtàkì àdúrà àti ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá nínú Jèhófà mọ́ mi lọ́kàn. Ìyẹn ló mú ká lè fara dà á.”
Má Ṣe Jẹ́ Kí Àjọṣe Òbí àti Ọmọ Bà Jẹ́
Bíbélì sọ kedere pé ọmọ gbọ́dọ̀ bọlá fún ìyá àti bàbá rẹ̀. (Ẹ́kísódù 20:12) Ìkọ̀sílẹ̀ kò sì fòpin sí àjọṣe àárín bàbá àti ọmọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ àtijọ́ náà kò báa yín gbélé mọ́, àwọn ọmọ ṣì lè jàǹfààní látinú ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀.c Ìṣòro tó wà níbẹ̀ ni pé ìyá wọ́n lè bínú sí ọkùnrin náà, kó má sì fẹ́ kí àwọn ọmọ ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú rẹ̀. Báwo ni ìyá náà ṣe lè borí ìmọ̀lára yìí?
Ìmọ̀ràn rere ni Bíbélì fún wa nígbà tó kìlọ̀ pé: “Ṣọ́ra kí ìhónú má bàa dẹ ọ́ lọ sínú [híhùwà] lọ́nà ìpẹ̀gàn . . . Ṣọ́ra kí o má ṣe yíjú sí ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́.” (Jóòbù 36:18-21) Lóòótọ́ kò rọrùn láti sọ̀rọ̀ ẹni tó ṣe ọ́ lọ́ṣẹ́ tàbí tó já ọ́ jù sílẹ̀ níre. Ṣùgbọ́n bi ara rẹ léèrè pé: ‘Ǹjẹ́ ọmọdébìnrin kan lè kọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé ọkùnrin bí a bá ń sọ fún un léraléra nípa bí bàbá rẹ̀ ṣe burú tó? Ǹjẹ́ ọkàn ọmọdékùnrin kan lè balẹ̀, kó sì ṣọkàn akin bí a bá ń sọ pé, “Bàbá ẹ lo jọ,” nígbà tí a bá ń bá a wí? Ǹjẹ́ àwọn ọmọ lè ní èrò jíjọjú nípa pípa òfin mọ́ bí a bá ń kọ́ wọn láti tẹ́ńbẹ́lú bàbá wọn tàbí tí a kò fẹ́ kí wọ́n rí bàbá wọn rárá?’ Ó ṣe kedere pé bíba ìbátan àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú bàbá wọn jẹ́ kò bójú mu.
Ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé Bíbélì kò sọ pé ó lòdì láti bínú lọ́nà tó tọ́. Bíbélì sọ pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀.” (Éfésù 4:26) Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ ni láti bínú, ṣùgbọ́n jíjẹ́ kí “ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú” jọba lórí wa ni ẹ̀ṣẹ̀. (Kólósè 3:8) Nítorí náà, má ṣe máa ‘sọ̀rọ̀ sí bàbá’ lójú àwọn ọmọ. Bí o bá lérò pé o ní láti sọ bí nǹkan ṣe dùn ọ́ sí, fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò nípa sísọ “àníyàn” rẹ fún ẹnì kan, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún àwọn ọmọ rẹ—bóyá ọ̀rẹ́ kan tí o fọkàn tán. (Òwe 12:25) Gbìyànjú láti fi ẹ̀mí dáadáa hàn, kí o sì yé ro ohun tó ti kọjá. (Oníwàásù 7:10) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ kí ìbínú ẹ rọlẹ̀.
Paríparí rẹ̀, rántí pé Bíbélì pàṣẹ fún ọmọ láti bọ̀wọ̀ fún bàbá rẹ̀—kódà bí ìwà bàbá rẹ̀ bá tiẹ̀ kù díẹ̀ káàtó. (Éfésù 6:2, 3) Nítorí náà, gbìyànjú láti ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti má ṣe sọ àṣìṣe bàbá wọn di ńlá. Ọ̀dọ́bìnrin kan tí wọ́n tọ́ ní ilé tí kò ti sí bàbá sọ pé: “Nítorí pé mi ò sọ ọ̀ràn bàbá mi di ńlá—tí mo wò ó bí ẹni tó lè ṣàṣìṣe, bí ẹ̀dá aláìpé—ọ̀rọ̀ wa ti wọ̀ báyìí.” Nípa fífún àwọn ọmọ rẹ níṣìírí láti bọ̀wọ̀ fún bàbá wọn, wàá ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní èrò tó jọjú nípa ọlá àṣẹ tí o ní gẹ́gẹ́ bí òbí!
Bákan náà ló ṣe pàtàkì pé kí o má kọjá àyè rẹ lọ́dọ̀ àwọn ọmọ rẹ. Wọ́n ṣì wà lábẹ́ ‘òfin ìyá wọn.’ (Òwe 1:8) A lè fayé sú àwọn ọmọkùnrin bí a bá retí pé kí wọ́n máa ṣe bíi ‘baálé ilé.’ Ìdààmú lè bá àwọn ọmọbìnrin pẹ̀lú tí wọ́n bá ní láti jẹ́ alábàárò ìyá wọn. O ní láti mú un dá àwọn ọmọ lójú pé ìwọ tóo bí wọn á tọ́jú wọn—kì í ṣe pé àwọn ni wọ́n máa tọ́jú ẹ. (Fi wé 2 Kọ́ríńtì 12:14.) Mímú irú nǹkan bẹ́ẹ̀ dá wọn lójú lè mú kọ́kàn wọ́n balẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò tí ìdílé wọ́n wà kù díẹ̀ káàtó.
Ẹni Tó Ń Ṣe Bíi Bàbá Fọ́mọ
Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé bàbá wọn ò tiẹ̀ yọjú mọ́ rárá ńkọ́? Àwọn ògbógi sọ pé àwọn ọmọ lè jàǹfààní nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ ọkùnrin kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ tí àbúrò ìyá tàbí bàbá tàbí tí aládùúgbò ní nínú ọmọ kan lè ṣàǹfààní títí dé àyè kan, ọmọ náà á jàǹfààní ní pàtàkì láti inú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tó gbámúṣé pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tó wà nínú ìjọ Kristẹni. Jésù ṣèlérí pé ìjọ á dà bí ìdílé tí ń ṣètìlẹ́yìn.—Máàkù 10:29, 30.
Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọ̀dọ́mọdé Tímótì dàgbà di ojúlówó èèyàn Ọlọ́run, láìsí ìtìlẹ́yìn bàbá tó jẹ́ onígbàgbọ́. Ìyá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ àgbà ni Bíbélì yìn fún èyí. (Ìṣe 16:1; 2 Tímótì 1:1-5) Ṣùgbọ́n ó tún jàǹfààní látinú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin Kristẹni kan—àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Pọ́ọ̀lù pe Tímótì ní “ọmọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n àti olùṣòtítọ́ nínú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 4:17) Bákan náà, a rọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí láti ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Bíbélì pé kí á “máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó.” (Jákọ́bù 1:27) A rọ̀ wọ́n láti ‘gba àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba sílẹ̀’ nípa níní ìfẹ́ àtọkànwá, tó sì wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì sí irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀. (Jóòbù 29:12) Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Annette rántí ìfẹ́ jíjọjú tí Kristẹni alàgbà kan ní nínú rẹ̀ nígbà tó wà lọ́mọdé, ó sọ pé: “Òun nìkan ló ń ṣe bí bàbá gidi fún mi.”
Yíyanjú Ìṣòro Náà
Àwọn ìlànà yìí lè ran àwọn ọmọ tí kò ní bàbá lọ́wọ́ láti ní láárí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò rọgbọ fún wọn nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé, wọ́n lè wá di àgbàlagbà tó lẹ́mìí ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, tó dáńgájíá àti òbí onífẹ̀ẹ́, olùṣòtítọ́, tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó sàn kéèyàn sá fún wàhálà ju pé kéèyàn jẹ́ kí wàhálà ṣẹlẹ̀ ká tó máa wá ojútùú rẹ̀ kiri. Àti pé níkẹyìn, a lè yanjú ìṣòro wíwà tí ìdílé ń wà láìsí bàbá kìkì tí àwọn ọkùnrin àti obìnrin bá ṣe tán láti fi ọ̀rọ̀ Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé wọn—fún àpẹẹrẹ, nípa ṣíṣègbọràn sófin Bíbélì tó sọ pé ó lòdì láti ní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó àti nípa lílo àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n tí Bíbélì fi lélẹ̀ fún tọkọtaya.—1 Kọ́ríńtì 6:9; Éfésù 5:21-33.
Láyé ìsinyìí, ọ̀pọ̀ ọmọ làwọn bàbá wọn ń bá wọn gbélé ṣùgbọ́n tí a tún lè sọ pé wọn ò ní bàbá. Ẹnì kan tó jẹ́ ògbóǹkangí nínú ọ̀ràn ìdílé sọ pé: “Ìṣòro tó tóbi jù lọ tí . . . àwọn ọmọ ń kojú lónìí ni àyè àti àkókò tí àwọn bàbá wọn kì í ní fún wọn.” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa ọ̀ràn yìí tààràtà. Ó pàṣẹ fún àwọn bàbá nípa àwọn ọmọ wọn pé: “Ẹ fún wọn ní ìtọ́ni, àti ìbáwí, tí í ṣe ìtọ́sọ́nà ti Kristẹni.” (Éfésù 6:4, New English Bible; Òwe 24:27) Tí àwọn bàbá bá fi àmọ̀ràn Bíbélì sílò, àwọn ọmọ ò ní bẹ̀rù pé a óò já àwọn sílẹ̀.
Àmọ́ ṣé ó bọ́gbọ́n mu láti gbà gbọ́ pé gbogbo èèyàn á wá yíjú sí Bíbélì? Ó dájú pé kò lè rí bẹ́ẹ̀. (Mátíù 7:14) Ṣùgbọ́n àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ran ẹgbàágbèje èèyàn lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ nínú ìgbésí ayé ìdílé wọn nípasẹ̀ ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.d Lóòótọ́ Bíbélì kìlọ̀ pé gbogbo àwọn tọkọtaya tó ṣègbéyàwó yóò ní “ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn” nítorí àìpé ẹ̀dá. (1 Kọ́ríńtì 7:28) Ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n lọ́wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ti gidi máa ń wá ọ̀nà láti yanjú àwọn ìṣòro wọn, wọn kì í kàn kọra wọn sílẹ̀ gbàrà tí ọ̀rọ̀ bá ti fẹ́ ṣe bí ọ̀rọ̀. Lóòótọ́, àwọn ipò kan lè mú kí Kristẹni kan kó kúrò lọ́dọ̀ ẹnì kejì rẹ̀ tàbí kí ó tilẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ pàápàá. (Mátíù 5:32) Ṣùgbọ́n tí Kristẹni náà bá ro ti ìṣòro tí èyí lè fà fún àwọn ọmọ rẹ̀, yóò wá ọ̀nà tó lè fi dá ìgbéyàwó rẹ̀ sí, ìyẹn bó bá ṣeé ṣe.
Fífi ọ̀rọ̀ Bíbélì sílò yóò ṣe ju dídáàbò bo ìdílé rẹ lọ nísinsìnyí. Ó lè mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo yín láti wà láàyè títí láé! Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Kíka ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí ẹ sì máa fi wọ́n sílò jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tó dára jù lọ láti fi rí i dájú pé ìdílé rẹ wà pa pọ̀ títí láé.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ àwọn ìsọfúnni tó lè ran àwọn òbí tí wọ́n fẹ́ ẹlòmíràn lọ́wọ́ jáde nínú ìwé ìròyìn wa kejì, ìyẹn Ilé Ìṣọ́ ti March 1, 1999.
b Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.
c Èyí kò ní ṣeé fi sílò tọ́mọ kan bá wà nínú ewu dídi ẹni tí bàbá kan ń hàn léèmọ̀ tàbí tó fẹ́ bá a ṣèṣekúṣe.
d Ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé (tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe) ní ọ̀pọ̀ àmọ̀ràn tó dá lórí Bíbélì tó lè ran àwọn ìdílé lọ́wọ́. Ẹ lè rí ìwé náà gbà tí ẹ bá béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò yín.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Nípa fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, òbí kan tó ń dá ọmọ tọ́ lè ṣàṣeyọrí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn ọkùnrin Kristẹni lè máa ‘gba ọmọdékùnrin aláìníbaba sílẹ̀’ nípa níní ìfẹ́ jíjọjú, tó sì dénú ọkàn sí ọmọ náà