Ìròyìn Orí Tẹlifíṣọ̀n—Mélòó Ló Jẹ́ Ìròyìn Gidi?
Lẹ́yìn tí àwùjọ àwọn alákìíyèsí kan ṣàyẹ̀wò ìròyìn méjìlélọ́gọ́rùn-ún tí wọ́n sọ lórí tẹlifíṣọ̀n ní àwọn àgbègbè ìlú ńlá méjìléláàádọ́ta ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà àti ọ̀nà tí wọ́n gbà gbé wọn kalẹ̀, wọ́n rí i pé nǹkan bí ìpín mọ́kànlélógójì àtààbọ̀ péré lára gbogbo ẹ̀ ló jẹ́ ìròyìn gidi. Kí ló wá wà nínú ìyókù ìròyìn náà?
Ó kéré tán, ìpín ọgbọ̀n lára gbogbo àkókò tí wọ́n fi ń sọ̀ròyìn ní àwọn ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n ló jẹ́ ọjà ni wọ́n fi ń polówó. Ní gidi, díẹ̀ lára àwọn ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n tí wọ́n ti ṣe ìwádìí wọn ló jẹ́ pé àkókò tí wọ́n fi ń ṣèpolówó ọjà pọ̀ ju èyí tí wọ́n fi ń sọ̀ròyìn lọ. Ní àfikún sí i, àkọsílẹ̀ tí wọ́n fi ṣàlàyé ohun tí wọ́n ṣàwárí nínú ìwádìí náà sọ pé, gbogbo àkókò tó yẹ kí wọ́n fi sọ ìròyìn ló jẹ́ pé ohun tí ò ní láárí ni wọ́n ń gbé sáfẹ́fẹ́.a “Àkókò tó ṣẹ́jọ tí àwọn olóòtú ètò fi ń tàkúrọ̀sọ, àkókò tí wọ́n fi ń ṣe ìkéde àti èyí tí wọ́n fi ń sọ kókó inú ìròyìn, ìròyìn ‘tó ń múni ronú’ tàbí èyí tí ò já mọ́ nǹkankan àti àwọn ètò ìjíròrò pẹ̀lú àwọn olókìkí èèyàn” ni àwọn ohun tí ìwé náà tò sábẹ́ àkọlé tí wọ́n pè ní “Ohun Ti Ò Ní Láárí.” Àpẹẹrẹ àwọn ìròyìn tí ò ní láárí tí wọ́n ń sọ ni: “Ìdíje Ohùn Tí Kò Dára,” “Oníròyìn Gun Jangirọ́fà ‘Tó Kàmàmà, Tó sì Ṣeni Ní Kàyéfì,’” àti “Ní Àwọn Ilé Ìtajà, Ọ̀pọ̀ Èèyàn Túbọ̀ Ń Ra Ohun Tí A Ń Fi Jẹ Búrẹ́dì.”
Èwo gan-an wá ni ìròyìn gidi? Ọ̀rọ̀ nípa ìwà ọ̀daràn ló pọ̀ jù nínú ìròyìn orí tẹlifíṣọ̀n, ó kó nǹkan bí ìpín mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n lára gbogbo àkókò tí wọ́n fi ń sọ̀ròyìn. “Gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ń sọ ìròyìn lórí tẹlifíṣọ̀n la máa ń fojú ara wa rí i pé, ‘ìròyìn nípa ìwà ipá àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ lọba ìròyìn.‘ . . . Ó lè jẹ́ pé ìwà ọ̀daràn ò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà láàárín ọdún mélòó kan sẹ́yìn, ṣùgbọ́n bí i pé wákàtí wákàtí ló ń ṣẹlẹ̀ ni wọ́n ṣe ń sọ ọ́ nínú ìròyìn lórí tẹlifíṣọ̀n.” Kí ló dé tó fi rí bẹ́ẹ̀? Àwọn tó kọ ìwé lórí ìwádìí náà sọ pé, “ọ̀ràn nípa ìwà ọ̀daràn máa ń gbàfiyèsí, ó sì máa ń jẹ àwọn ènìyàn lọ́kàn.”
Lẹ́yìn ìròyìn nípa ìwà ọ̀daràn, ìròyìn nípa ìjábá ló tún kàn, irú bí iná, jàǹbá ọkọ̀, omíyalé, fífi bọ́ǹbù fọ́lé (ìyẹn lé díẹ̀ ní ìpín méjìlá nínú gbogbo ìròyìn tí wọ́n ń sọ), ìròyìn nípa eré ìdárayá ló tẹ̀ lé e (ìyẹn jẹ́ nǹkan bí ìpín mọ́kànlá ààbọ̀). Ẹ̀yìn náà ló wá kan ìròyìn nípa ìlera (ìyẹn lé ní ìpín mẹ́wàá), ìròyìn nípa ìjọba (ìyẹn jẹ́ nǹkan bí ìpín mẹ́sàn-án), àti ìròyìn nípa ètò ọrọ̀ ajé (ìyẹn jẹ́ ìpín mẹ́jọ ààbọ̀). Wọn kì í fún àwọn ọ̀rọ̀ nípa ẹ̀kọ́, àyíká, iṣẹ́ ọnà, àti sáyẹ́ǹsì láfiyèsí tó pọ̀ (ìyẹn jẹ́ láti orí nǹkan bí ìpín kan ààbọ̀ sí ìpín mẹ́ta ààbọ̀). Ṣùgbọ́n ìròyìn nípa ojú ọjọ́ kó ìpíndọ́gba ìpín mẹ́wàá lára gbogbo ìròyìn tí wọ́n ń sọ. Àwọn olùwádìí náà sọ pé: “Gbogbo èèyàn ló fẹ́ràn láti máa sọ̀rọ̀ nípa ipò ojú ọjọ́, ìròyìn orí tẹlifíṣọ̀n pẹ̀lú ò sì gbẹ́yìn.” Wọ́n tún sọ pé: “Bó ti wù kí ojú ọjọ́ rí, yálà ó dáa ni tàbí kò dáa, yálà oòrùn ń mú ni tàbí òtútù ń mú, yálà òjò ń rọ̀ ni tàbí ilẹ̀ gbẹ, kò sí èyí tí tẹlifíṣọ̀n ò lè sọ di ìròyìn ńlá.”
Ìròyìn náà wá sọ̀rọ̀ gidi kan o, ó sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn akọ̀ròyìn àti àwọn tó ń gbọ́ròyìn ti wá rí i pé ìyípadà pọndandan. Ṣùgbọ́n ìwádìí náà sọ pé irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ ò lè lọ geere nítorí pé, “pípọ̀ tí àwọn tó fẹ́ máa gbọ́ wọn ń pọ̀ sí i àti ìwà ìwọra lè máa ṣàkóbá fún iṣẹ́ ìròyìn tó jẹ́ ojúlówó.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé tí wọ́n pè ní Not in the Public Interest—Local TV News in America náà ni ìwé ìwádìí ọlọ́dọọdún tí wọ́n ṣe ṣìkẹrin lórílẹ̀-èdè náà tó gbé ọ̀ràn nípa ohun tí wọ́n máa ń sọ nínú ìròyìn yẹ̀ wò. Àwọn tó kọ ìwé náà ni Ọ̀mọ̀wé Paul Klite, Ọ̀mọ̀wé Robert A. Bardwell, àti Jason Salzman, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ Rocky Mountain Media Watch.