Báwo Ni Wọ́n Ṣe Ń Gbé “Àṣà Ká Máa Pààyàn” Lárugẹ?
“Ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà ni àwọn ọmọdé tí hílàhílo sọ di ẹni tí ń wá ibi ìsádi kiri ní Kosovo fi jìnnà sí àwọn ọmọdé ní Amẹ́ríkà tí wọ́n wà nínú ewu ìwà ipá àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ abaninínújẹ́ mìíràn, ṣùgbọ́n ìdààmú ọkàn wọn kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ síra.”—Marc Kaufman, The Washington Post.
Yálà a nífẹ̀ẹ́ sí i tàbí a kò nífẹ̀ẹ́ sí i, yálà ní tààràtà tàbí lọ́nà tí kò ṣe tààràtà, ọ̀ràn ikú kan gbogbo wa. Òótọ́ lèyí ń ṣẹlẹ̀, láìka ibi yòówù tí à ń gbé sí, yálà a ń gbé ní orílẹ̀-èdè tí rògbòdìyàn ti dà rú tàbí èyí tó ní ìwọ̀n àlàáfíà.
ALÈ rí ẹ̀rí “àṣà ká máa pààyàn” náà nínú bí ìdààmú ọkàn, làásìgbò, ìjoògùnyó, ìṣẹ́yún, àṣà ṣíṣera ẹni ní jàǹbá, gbígbẹ̀mí ara ẹni, àti ìpànìyàn lápalù ṣe ń ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́ lónìí. Ọ̀jọ̀gbọ́n Michael Kearl, tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Ìmọ̀ Nípa Àjọgbépọ̀ Ẹ̀dá àti Ìmọ̀ Nípa Ẹ̀dá Ènìyàn ní Yunifásítì Trinity ní ìlú San Antonio, ìpínlẹ̀ Texas, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ṣàlàyé nípa bí wọ́n ṣe ń yí ojú tí a fi ń wo ọ̀ràn ikú tẹ́lẹ̀ padà pé: “Táa bá fojú bí nǹkan ṣe ń rí lápá ìparí ọ̀rúndún ogún wa [1999] wò ó, a óò rí i pé . . . àwọn èèyàn ti wá ka ikú sí agbára tó ń pinnu ìgbésí ayé èèyàn, okun èèyàn láti máa forí ti nǹkan, àti bí àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn yóò ṣe rí. Ikú ló gbé wa dédìí ṣíṣe àwọn ẹ̀sìn, wíwá ìmọ̀ ọgbọ́n orí, gbígbé àwọn èròǹgbà ètò ìṣèlú kalẹ̀, ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ọnà àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ nípa ìṣègùn. Òun ló ń jẹ́ káwọn ìwé ìròyìn àti àwọn iṣẹ́ abánigbófò tà, òun ló ń fún ìwéwèé àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n wa lókun, bákan náà, . . . òun ló ń fún àwọn ilé iṣẹ́ níṣìírí.” Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò nípa bí ohun àrà yìí, táa pè ní àṣà ká máa pààyàn, ṣe ń ṣẹlẹ̀ ní àkókò wa.
Títa Àwọn Ohun Ìjà
“Àṣà ká máa pààyàn” yìí ń fara hàn lójoojúmọ́ nínú iye ohun ìjà tí wọ́n ń tà. Wọ́n ń fi ohun ìjà pa àwọn sójà, ṣùgbọ́n àwọn aráàlú ni wọ́n ń pa jù, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé tí kò mọwọ́mẹsẹ̀ sì wà lára wọn. Nínú ogun, yálà ogun abẹ́lé tàbí àwọn ogun mìíràn, ẹ̀mí kì í sábà já mọ́ nǹkan kan. Èló tiẹ̀ ni àwọn alágbàpa tàbí àwọn asápamọ́-yìnbọn ń ra ọta?
Rírọrùn tó rọrùn fáwọn aráàlú láti ra ìbọn ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ló ń fà á tí àwọn èèyàn kọ̀ọ̀kan àti àwùjọ àwọn èèyàn tó ń kú fi ń pọ̀ sí i lemọ́lemọ́ lọ́nà tó ń dẹ́rù bani. Lẹ́yìn àjálù ti àwọn ọmọ ilé ìwé gíga tí wọ́n yìnbọn pa ní ìlú Littleton, ìpínlẹ̀ Colorado, àwọn èèyàn ṣe ìwọ́de láti fi ẹ̀dùn ọkàn wọn hàn sí títà tí wọ́n ń ta àwọn ohun ìjà fàlàlà àti bí ó ṣe lè tètè dé ọwọ́ àwọn ọmọ kéékèèké. Ìpíndọ́gba iye àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń pa nípakúpa ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà bani lẹ́rù, wọ́n jẹ́ ogójì láàárín ọ̀sẹ̀ kan—ohun tí ìwé ìròyìn Newsweek sọ nìyẹn. Ìpín àádọ́rùn-ún nínú wọn ni wọ́n fi ìbọn pa. Ó já sí pé àádọ́jọ èèyàn ni wọ́n ń pa nípakúpa lọ́dọọdún bí irú èyí tó ṣẹlẹ̀ ní ìlú Littleton!
Àwọn Ohun Táráyé Fi Ń Najú
Àwọn sinimá ń lo ọ̀ràn ìpànìyàn fun èrè tiwọn. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀nà tí wọ́n gbà gbé eré sinimá kan kalẹ̀ lè mú kí ìwà pálapàla, ìwà ipá, gbígbé oògùn olóró, tàbí ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò dà bí ohun tó gbádùn mọ́ni, á wá tipa bẹ́ẹ̀ sọ ẹ̀mí àti àwọn ìlànà ìwà ọmọlúwàbí di yẹpẹrẹ. Àwọn sinimá kan tiẹ̀ wà tí wọ́n ti ń fi ikú ṣe ẹni inú ìtàn—wọ́n ń fi ìtàn àròsọ nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú hàn àti èrò pé àwọn kan ń jíǹde láti wá bẹ àwọn alààyè wò—tí gbogbo èyí wulẹ̀ jẹ́ láti fi ikú hàn bí nǹkan ṣeréṣeré.
Bí àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n àtàwọn orin kan náà ṣe rí nìyẹn. Ìròyìn sọ pé àwọn ọ̀dọ́ tó pààyàn ní Littleton náà jẹ́ olólùfẹ́ olórin rọ́ọ̀kì kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ pé ó máa ń “lo àwọn àwòrán ẹlẹ́mìí èṣù àti èyí tí kò-ṣakọ kò-ṣabo,” àti àwọn orin “tó ní àkọlé ẹlẹ́mìí ọ̀tẹ̀ àti ikú nínú.”
Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, wọ́n yí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà díwọ̀n àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n padà kí àwọn ọ̀dọ́ má baà máa wo àwọn eré tó lè kọ́ wọn níkọ̀ọ́kúkọ̀ọ́. Àbájáde rẹ̀ kò fi iṣẹ́ yìn wọ́n. Nígbà tí Jonathan Alter ń kọ̀wé nínú ìwé ìròyìn Newsweek, ó sọ pé, ohun tí wọ́n ṣe yìí “lè mú kí àwọn ọmọdé fẹ́ wo àwọn eré tí wọn ò fẹ́ kí wọ́n wò náà.” Ó tún sọ pé, láti lè dójú ti àwọn tó ń ṣètò náà àti láti fi kọ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n lè dín ìwà ipá tí wọ́n ń gbé jáde kù, Ààrẹ Clinton yóò “ní láti ka orúkọ àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá náà fáráyé gbọ́ (àti orúkọ àwọn ọ̀gá pátápátá níbẹ̀)” ìyẹn àwọn tó ń ṣe sinimá gúnbẹ-gúnbẹ àti àwọn àwo ‘orin ọlọ́rọ̀ wótòwótò tó kún fún èdè àwọn ọmọọ̀ta,’ tí wọ́n tún ń ṣe àwọn eré àṣedárayá orí kọ̀ǹpútà tó ń jẹ́ “‘kó dà bíi pé’ àwọn ọmọ ń pààyàn.”
Eré Ikú Lórí Fídíò àti Íńtánẹ́ẹ̀tì
Nínú ìwé tí Robert Waring kọ náà, The Deathmatch Manifesto, ó ṣàlàyé bí àwọn eré àṣedárayá tí ẹni méjì tó fẹ́ pa ara wọn ń lépa ara wọn nínú rẹ̀ ṣe gbajúmọ̀ tó láàárín àwọn ọ̀dọ́langba.a Ọ̀gbẹ́ni Waring gbà gbọ́ pé, àwùjọ àwọn òṣèré kan wà lábẹ́lẹ̀ tó ń rí sí nǹkan tó ń jọni lójú yìí. Ó dájú pé kò sí ẹ̀kọ́ gidi kan tí àwọn eré àṣedárayá yìí ń kọ́ wọn bí kò ṣe bí wọ́n ṣe lè pààyàn. Waring sọ pé: “Bíbá ẹlòmíràn láti ibikíbi mìíràn lágbàáyé ṣeré, àti gbígbìyànjú láti fi hàn pé o tóótun jẹ́ ìrírí ńlá. Ìyẹn sì lè tètè fani lọ́kàn mọ́ra.” Agbára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àrògbéjáde bíi ṣíṣọ́ni níbi ṣọ́ni lọ́hùn-ún, èyí tí wọ́n ṣe kí ó lè gbé ìjàkadì àjàkú-akátá náà yọ, máa ń dẹkùn mú àwọn ọ̀dọ́. Bí àwọn kan kò bá lè débi ìsọfúnni orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, wọ́n máa ń lọ ra ohun èlò eré àṣedárayá orí fídíò tí wọ́n lè máa lò lórí tẹlifíṣọ̀n nínú ilé. Àwọn míì ti sọ lílọ sí àwọn ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń sanwó láti lo àwọn ẹ̀rọ eré àṣedárayá orí fídíò dàṣà, wọ́n á sì máa ṣe eré ‘tó dà bíi pé’ wọ́n ń bá àwọn ẹlòmíì ja ìjà àjàkú-akátá.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n díwọ̀n àwọn eré àṣedárayá “tí ẹni méjì ń ṣọ́ ara wọn láti pa ara wọn” nínú rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ọjọ́ orí ẹni tó ń ṣe eré náà, òtítọ́ ibẹ̀ ni pé wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ lè ṣàkóso wọn. Eddie, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, láti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Àwọn èèyàn sábà máa ń sọ pé a ò tíì dàgbà tó, ṣùgbọ́n wọn kì í sọ pé ká má ra [eré àṣedárayá náà].” Ó máa ń gbádùn àwọn tó ní fífi ìbọn ja àjàkú-akátá nínú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí rẹ̀ mọ̀ pé ó ń ṣe irú eré bẹ́ẹ̀, tí wọn ò sì nífẹ̀ẹ́ sí i, ekukáká ni wọ́n fi máa ń lọ wò ó bóyá ó ń ṣe eré náà. Ọ̀dọ́langba kan sọ èrò rẹ̀ pé: “Ìwà ipá kì í ba ìran tiwa yìí lọ́kàn jẹ́ rárá bó ṣe rí ní àwọn ìran mìíràn. Tẹlifíṣọ̀n ló ń bá àwọn òbí tọ́mọ nísinsìnyí ju báwọn fúnra wọn ṣe ń tọ́ wọn lọ, àwọn ìwà ipá táwọn ọmọ ń fọkàn yàwòrán rẹ̀ sì ni tẹlifíṣọ̀n ń gbé jáde fun wọn.” Nígbà tí John Leland ń kọ̀wé nínú ìwé ìròyìn Newsweek, ó sọ pé: “Pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́langba tí iye wọ́n tó mílíọ̀nù mọ́kànlá tí wọ́n ń yẹ inú Íńtánẹ́ẹ̀tì wò báyìí [ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà], púpọ̀ sí i àwọn ọ̀dọ́ ló ń lo ìgbésí ayé wọn nídìí ìgbòkègbodò kan tí ojú ọ̀pọ̀ òbí kò tó.”
Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tó Ń Yọrí sí Ikú
Ìwà àwọn èèyàn tí kì í ṣe eré àṣedárayá tí wọn kì í sì í wo fíìmù “tí ẹni méjì ń ṣọ́ ara wọn láti pa ara wọn” ńkọ́? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lójú ayé gangan, a ò ní láti bá àwọn ẹ̀dá tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ja àjàkú-akátá, ṣùgbọ́n ọ̀nà ìgbésí ayé púpọ̀ èèyàn ló ní ìwà gbígbẹ̀mí ara ẹni nínú. Fún àpẹẹrẹ, láìka ipa tí ìdílé ní, ètò ìlera tí ìjọba ṣe, àti àwọn aláṣẹ míì tí wọ́n ń kìlọ̀ nípa ewu tó wà nínú sìgá mímu àti ìjoògùnyó sí, àṣà yìí túbọ̀ ń peléke sí i ni. Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ púpọ̀, wọ́n ń yọrí sí ikú tí ò tọ́jọ́. Láti mú kí èrè tí kò bófin mu tí wọ́n ń jẹ pọ̀ sí i, okòwò aládàá ńlá àti àwọn tí ń ṣe fàyàwọ́ oògùn olóró ń bá a lọ láti máa kófà lára àwọn èèyàn nítorí ipò àníyàn, ipò àìnírètí, àti ipò òṣì nípa tẹ̀mí táwọn èèyàn náà wà.
Ta Ló Wà Nídìí Gbogbo Rẹ̀?
Ǹjẹ́ Bíbélì fi ikú hàn bí ohun tó yẹ láti máa fi ṣe eré àṣenajú? Ǹjẹ́ ó tọ́ láti máa tọ ọ̀nà ìgbésí ayé tó lè yọrí sí ikú? Rárá o. “Ọ̀tá” ni àwọn Kristẹni tòótọ́ ka ikú sí, bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà ṣe kà á sí. (1 Kọ́ríńtì 15:26) Àwọn Kristẹni kò ka ikú sí ohun tó ń fani mọ́ra, wọn ò sì kà á sí nǹkan eré, ṣùgbọ́n wọ́n kà á sí ohun tó ta ko àbùdá ẹ̀dá, tó jẹ́ ìyọrísí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìṣọ̀tẹ̀ lòdì sí Ọlọ́run ní tààràtà. (Róòmù 5:12; 6:23) Ikú kì í ṣe apá kan ète àtètèkọ́ṣe Ọlọ́run fún ẹ̀dá rárá.
Sátánì ni a sọ pé ó ní “ọ̀nà àtimú ikú wá.” Pípè tí a sì pè é ní “apànìyàn” kò pọndandan kó jẹ́ nítorí pé ó ń pa àwọn èèyàn ní ti gidi ni, ṣùgbọ́n nítorí pé ó ń ṣe é nípa lílo ẹ̀tàn, nípa sísún àwọn èèyàn dẹ́ṣẹ̀, nípa gbígbé àwọn ìwà tó ń fa ìbàjẹ́ àti ikú lárugẹ, àti nípa mímú ìwà apààyàn dàgbà nínú èrò orí, àti ọkàn àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé pàápàá. (Hébérù 2:14, 15; Jòhánù 8:44; 2 Kọ́ríńtì 11:3; Jákọ́bù 4:1, 2) Bó ti wù kó rí, kí ló dé tó wá jẹ́ àwọn ọ̀dọ́ ló dájú sọ? Kí la lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àtúnyẹ̀wò yìí sọ pé, nínú àwọn eré àṣedárayá “tí ẹni méjì ń ṣọ́ ara wọn láti pa ara wọn, wọ́n máa ń sún àwọn òṣèré náà láti pa ara wọn nípa ṣíṣọ́ ara wọn níbí àti lọ́hùn-ún nínú àwọn eré ẹlẹ́ni púpọ̀.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
“Ìwà ipá kì í ba ìran tiwa yìí lọ́kàn jẹ́ rárá bó ṣe rí ní àwọn ìran mìíràn”