ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 7/8 ojú ìwé 3-4
  • Ṣé Ẹ̀mí Èèyàn Kò Jẹ́ Nǹkan Kan Mọ́ Ni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ẹ̀mí Èèyàn Kò Jẹ́ Nǹkan Kan Mọ́ Ni?
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ló Fa “Àṣà Ká Máa Pààyàn”?
  • Báwo Ni Wọ́n Ṣe Ń Gbé “Àṣà Ká Máa Pààyàn” Lárugẹ?
    Jí!—2000
  • Kí Ló Dé Táwọn Ìwà Ìkà Bíburú Jáì Fi Wọ́pọ̀ Tó Báyìí?
    Jí!—2003
  • Àwọn Ògiri Ìdènà Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀
    Jí!—1996
  • Ìṣòro Náà Ń tàn Kálẹ̀
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 7/8 ojú ìwé 3-4

Ṣé Ẹ̀mí Èèyàn Kò Jẹ́ Nǹkan Kan Mọ́ Ni?

“Ayé tí ẹ̀mí èèyàn kò ti jẹ́ nǹkan kan mọ́ la wà yìí o. Èèyàn lè fi ọgọ́rùn-ún pọ́n-ùn mélòó kan bẹ àwọn apààyàn lọ́wẹ̀, àwọn tó sì ṣetán láti gba iṣẹ́ náà ṣe kò wọ́n.”—The Scotsman.

Láàárín oṣù April ọdún 1999, àwọn ọ̀dọ́ méjì da Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga Columbine rú, ní Littleton, Colorado, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, wọ́n sì pa èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ìwà ipá tí wọ́n hù yìí já gbogbo ayé láyà. Ìwádìí fi hàn pé ọ̀kan lára àwọn ọmọ tó hùwà ipá náà ní ibi kan tó ń kó ìsọfúnni sí nínú Íńtánẹ́ẹ̀tì, ohun tó kọ síbẹ̀ ni pé: “ÒKÚ KÌ Í JIYÀN!” Àwọn méjèèjì kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

KÒ SÍBI tí ìpànìyàn kò ti ń ṣẹlẹ̀ láyé, àìmọye èèyàn ni wọ́n sì ń fikú oró pa lójoojúmọ́. Gúúsù Áfíríkà ni ìpànìyàn ti pọ̀ jù láyé, lọ́dún 1995, àwọn tí wọ́n pa jẹ́ ìpín márùnléláàádọ́rin lára ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] àwọn olùgbé ibẹ̀. Ní pàtàkì, ẹ̀mí èèyàn kò jẹ́ nǹkan kan mọ́ ní orílẹ̀-èdè kan ní Ilẹ̀ Gúúsù Amẹ́ríkà, níbi tí wọ́n ti pa èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà látàrí ọ̀ràn ìṣèlú lọ́dún 1997. Àwọn èèyàn ti sọ òwò gbígba èèyàn pa di àṣà níbẹ̀. Ìròyìn kan tí wọ́n kọ nípa orílẹ̀-èdè yẹn sọ pé: “Ó bani lẹ́rù pé iye àwọn ọmọdé táwọn èèyàn tún ń pa ti pọ̀ gan-an: Ní ọdún 1996, wọ́n pa ẹgbẹ̀rún mẹ́rin àti ọ̀ọ́dúnrún lé méjìlélógún ọmọdé, èyí fi ìpín ogójì pọ̀ sí i láàárín ọdún méjì péré.” Ṣùgbọ́n ṣá o, àwọn ọmọdé pàápàá ti wá ń di apànìyàn—wọ́n ń pa àwọn ọmọdé mìíràn àti àwọn òbí tiwọn fúnra wọn. Ẹ̀mí èèyàn kò jẹ́ nǹkan kan mọ́ lóòótọ́ o.

Kí Ló Fa “Àṣà Ká Máa Pààyàn”?

Kí ni àwọn òkodoro ọ̀rọ̀ yìí àti àwọn iye tí a kọ yìí fi hàn? Àìnáání ìwàláàyè ń pọ̀ sí i. Àwọn èèyàn tí wọ́n ń wá agbára àti owó sáà kàn ń pààyàn lọ láìbẹ̀rù ni. Àwọn babaàsàlẹ̀ nínú òwò oògùn líle á kàn pàṣẹ pé kí wọ́n lọ pa odindi ìdílé ni. Wọ́n sì máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀ kan láti fi tọ́ka sí àṣà ìpànìyàn tí wọ́n ń dá, àwọn ọ̀rọ̀ náà ni “ṣá a balẹ̀,” “dá ẹ̀mí ẹ̀ légbodò,” “yanjú ẹ̀,” tàbí “gbẹ̀mí ẹ̀” nígbà tí wọ́n bá fẹ́ pa àwọn tí wọ́n pè ní ìjẹ. Pípa ẹ̀yà run àti pípa ìran run ti mú kí iye àwọn tó ń kú pọ̀ sí i, ó sì ti sọ ẹ̀mí èèyàn di yẹpẹrẹ. Látàrí èyí, ọ̀ràn nípa ìpànìyàn ti di nǹkan tí a ń gbọ́ lójoojúmọ́ nínú ìròyìn tẹlifíṣọ̀n lágbàáyé.

Báa bá fi ìwà ipá àti ìṣeniléṣe tí tẹlifíṣọ̀n àti sinimá ń gbé lárugẹ kún èyí, ńṣe ló máa jọ pé àwùjọ èèyàn ti kó wọnú àṣà ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ kan tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa ikú ni wọ́n ń sọ ṣáá. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ nípa èyí pé: “Ní apá ìparí ọ̀rúndún ogún yìí, ó yani lẹ́nu pé ọ̀ràn nípa ikú wá wọ́ pọ̀ gan-an ni. Ó tún lè yani lẹ́nu pé ṣáájú ìgbà yẹn, ikú jẹ́ kókó kan tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kì í fi bẹ́ẹ̀ mẹ́nu kàn, ìméfò tó sì ń wá látinú ìmọ̀ ọgbọ́n orí kì í tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ lọ sápá ibẹ̀ rárá.” Gẹ́gẹ́ bí Josep Fericgla, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀dá ènìyàn, tó wá láti àgbègbè Catalonia, ti sọ “ikú ti wá di ohun èèwọ̀ táwọn èèyàn ń lò láwùjọ wa, nítorí ìdí èyí, ó ti wá di ọ̀kan lára àwọn orísun èròǹgbà tó ṣe pàtàkì jù lọ táwọn èèyàn ń lò láti tẹ́ ara wọn lọ́rùn lónìí.”

Bóyá ohun tó fara hàn jù lọ nínú “àṣà ká máa pààyàn” yìí ni ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́, pé agbára, ìyọrí ọlá, owó, àti fàájì ló ṣe pàtàkì ju ẹ̀mí èèyàn àti ìwà ọmọlúwàbí lọ.

Báwo ni “àṣà ká máa pààyàn” yìí ṣe tàn kálẹ̀? Kí ni àwọn òbí lè ṣe láti ṣẹ́gun ìwàkiwà tó yí wọn ká yìí, tó sì ń nípa lórí àwọn ọmọ wọn? Díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè tí a óò dáhùn nìyẹn nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Báwo Ni Ẹ̀mí Èèyàn Ṣe Níye Lórí Tó?

◼ “Àwọn tó jẹ́ ọ̀dọ́ nínú ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ìta [ní Mumbai, Íńdíà] máa ń gbékú tà pátápátá ni, wọ́n lè gba iṣẹ́ ìpààyàn ní iye tí kò ju ẹgbẹ̀rún márùn-ún rupee [dọ́là márùndínlọ́gọ́fà] péré lọ.”—Far Eastern Economic Review.

◼ “Ó Pa Ẹnì Kan Tó Ń Kọjá Lọ Tó Kọ̀ Láti Fún Un Ní Sìgá.”—Àkọlé inú ìwé ìròyìn La Tercera, Santiago, Chile.

◼ “Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, ó máa ń tó ẹgbẹ̀rún méje dọ́là láti ṣètò fún ìpànìyàn ní Rọ́ṣíà [ní ọdún 1995] . . . Gbígbaṣẹ́ ìpànìyàn ti yára pọ̀ sí i nígbà ìbúrẹ́kẹ́ ọrọ̀ ajé ní Rọ́ṣíà lẹ́yìn tí ìjọba Kọ́múníìsì kásẹ̀ nílẹ̀.”—Ìròyìn Reuters, tó dá lórí ìròyìn kan nínú ìwé ìròyìn Moscow News.

◼ “Àwọn ọlọ́pàá mú ọkùnrin kan tó jẹ́ alágbàtà ilé ní Brooklyn . . . wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó san àsansílẹ̀ lára ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ dọ́là tó ṣàdéhùn láti san fún ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó fẹ́ bá a pa aláboyún kan tí í ṣe ìyàwó ọkùnrin kan báyìí àti ìyá obìnrin náà.”—The New York Times.

◼ ‘Iye tí wọ́n ń san fún ìpànìyàn ti ń wálẹ̀ ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Iye tí wọ́n ń gbà láti pààyàn ti wálẹ̀ láti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n pọ́n-ùn lọ́dún márùn-ún sẹ́yìn sí iye táwọn èèyàn lè san, ìyẹn ẹgbẹ̀rún márùn-ún sí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá pọ́n-ùn.’—The Guardian.

◼ ‘Àwọn ọmọ ìta oníjàgídíjàgan ní Balkan ti gbọ̀gá mọ́ àwọn Amòòkùn-Ṣọṣẹ́ lọ́wọ́. Oríṣi ọ̀daràn tuntun kan tún lèyí, ó ní òfin tuntun àti àwọn ohun ìjà tuntun. Ó ní àwọn ohun ìjà abúgbàù àti àwọn ìbọn arọ̀jò ọta, kì í sì í rò ó lẹ́ẹ̀mejì kó tó yìn wọ́n.’—The Guardian Weekly.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́