Títọ́ Àwọn Ọmọ Di Ẹni Tó Lẹ́kọ̀ọ́—Báwo La Ṣe Lè Ṣe É?
Ìwé ìròyìn kan tó ń jẹ́The Gazette, ní Montreal, ní Kánádà wí pé: “Àwọn ọmọ máa ń kọ́ bí a ṣe ń fi ọ̀wọ̀ wọ ara ẹni àti bí a ṣe ń kó ara ẹni níjàánu nígbà tí àwọn òbí wọ́n bá fi ìfẹ́ hàn sí wọ́n tí wọ́n sì bá wọn wí.” Kí lèyí ní nínú? Gẹ́gẹ́ bí Constance Lalinec, tó jẹ́ afìṣemọ̀rònú tí ń ṣàyẹ̀wò àwọn aláìsàn ní Montreal ṣe sọ, ó yẹ ká fi ààlà tó ṣe kedere lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ kí ọmọ máa hùwà.
Lalinec, tí iṣẹ́ rẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọdé àti ìdílé, tún ṣàlàyé pé, “nígbà tí a kò bá jẹ́ kí àwọn ọmọ jìyà ohun tí wọ́n bá ṣe, ọ̀pọ̀ ohun tó yẹ kí wọ́n kọ́ ni a kò ní jẹ́ kí wọ́n kọ́ pẹ̀lú.” Ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ lè ní ipa búburú lórí ìdàgbàsókè ọmọ kan.
Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí ẹ̀rí fi hàn pé ó gbéṣẹ́, tí a rí nínú Bíbélì, lórí títọ́ àwọn ọmọ ló bá a mu jù lọ. Ó wí pé: “Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́.” (Mátíù 5:37) Bí o bá ti fi àwọn ìlànà tó bọ́gbọ́n mu lélẹ̀, tí àwọn ọmọ rẹ sì lóye wọn, mú kí wọ́n máa tẹ̀ lé e lọ́gán, kí ó sì jẹ́ lọ́nà tó ṣe déédéé. Ọ̀rọ̀ tí o bá ti sọ, rí i pé o gbé ìgbésẹ̀ gidi nípa rẹ̀. Èyí máa ń jẹ́ kí ohun kan yé àwọn ọmọ nípa àwọn ìlànà tí òbí fi lélẹ̀ àti àwọn ohun tí òbí ń retí látọ̀dọ̀ wọn—pé, èèyàn ‘á ká ohun tó bá fúnrúgbìn.’ (Gálátíà 6:7; Róòmù 2:6) Ète táa fi ń fi ìfẹ́ bá àwọn ọmọ wí lọ́nà gbígbéṣẹ́ ni pé a fẹ́ kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ láti máa tẹ̀ lé ìlànà, kí wọ́n sì mọ bí a ti í fara da ìjákulẹ̀ àti èrè tí kò tètè wá, kí wọ́n lè kọ́ àwọn ànímọ́ tí wọ́n nílò kí wọ́n lè di àgbà tó lẹ́kọ̀ọ́ tó sì níláárí.
Ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn láfikún sí i nípa ohun tí Ọlọ́run sọ fún àwọn òbí lórí fífi ìfẹ́ bá àwọn ọmọ wọn wí wà nínú ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. O lè rí ẹ̀dà kan ìwé olójú ewé 192 yìí gbà tí o bá kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bóo bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì táa kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí tí a tò sójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
◻ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.