Wọ́n Gbé Òtítọ́ Pa Mọ́ fún Àádọ́ta Ọdún—Èé Ṣe?
Rum jẹ́ erékùṣù kékeré kan ní Inner Hebrides, tó yọ sí etíkun ìhà ìwọ̀ oòrùn Scotland. Ní nǹkan bí àádọ́rin ọdún sẹ́yìn, ẹni tó ni ín gba onímọ̀ nípa ewéko náà, John Heslop Harrison, tó jẹ́
ọ̀jọ̀gbọ́n ní yunifásítì kan, tó tún jẹ́ mẹ́ńbà Àwùjọ Àwọn Lọ́balọ́ba tó lọ́lá ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, láyè láti ṣèwádìí nípa àwọn ewéko tó wà níbẹ̀.
Ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, Harrison ròyìn pé òún rí oríṣiríṣi ewéko tí kò wọ́pọ̀ níbẹ̀, ìyẹn àwọn ewéko tó jẹ́ pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà níhà gúúsù nìkan ni wọ́n ti rí wọn rí tí wọ́n ń hù. Inú wọ́n dùn, wọ́n sì kan sáárá sí Harrison gidigidi, àwọn àṣeyọrí rẹ̀ sì ń fi kún iyì tó ní. Ṣùgbọ́n bí àwọn oríṣi ewéko tó ń ṣàkọsílẹ̀ ti ń pọ̀ sí i ni iyèméjì àwọn yòókù tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ nípa ewéko ń pọ̀ sí i.
Ní ọdún 1948, John Raven, tí í ṣe ògbógi nínú ìmọ̀ lítíréṣọ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga jù lọ Cambridge, tó tún nífẹ̀ẹ́ nínú ìmọ̀ nípa ewéko gidigidi, tẹ́wọ́ gba ìpèníjà láti ṣe iṣẹ́ ìwádìí. Ṣùgbọ́n wọn kò tẹ àbájáde ìwádìí tó ṣe jáde. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n gbé e pa mọ́, ọdún 1999 ni wọ́n sì tó gbé e jáde. Èé ṣe? Nítorí pé Raven ṣàlàyé pé oníjìbìtì ni Harrison. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn New Scientist ti sọ, ibòmíràn ni wọ́n ti gbin àwọn ewéko náà, ńṣe ni wọ́n sì dọ́gbọ́n lọ lẹ́ wọn sí Rum.
Raven tètè máa ń dá àwọn ewéko tó bá hù síbi táa gbìn wọ́n sí mọ̀, kò sì pẹ́ tó fi rí gbòǹgbò àwọn koríko mélòó kan lára èyí tí Harrison “ṣàwárí” tó wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣùgbọ́n tó ṣọ̀wọ́n ní Rum. Kòkòrò kantíkantí ti jẹ àwọn ewéko yòókù, ibi méjì péré ni a sì gbọ́ pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ti ṣẹ̀ ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì—oko Harrison ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sì jẹ́ ọ̀kan lára rẹ̀. Gbòǹgbò ewéko kan báyìí tún pèsè ẹ̀rí mìíràn, tí ó ní èérún èròjà quartz—tí kò sí ohun tó jọ ọ́ nílẹ̀ Rum.
Kò tán síbẹ̀ o. A tún gbọ́ pé awúrúju ni ohun tí Harrison sọ nípa àwọn labalábá àti ọ̀bọ̀n-ùnbọn-ùn erékùṣù náà. Ìwé ìròyìn The Sunday Telegraph Magazine sọ pé ẹnì kan tó ń gbé ní Rum sọ láṣìírí pé: “Ọ̀jọ̀gbọ́n náà fi ohun kan pa mọ́ síbì kan ni—ó lè jẹ́ labalábá tàbí ewéko—tó ń sọ pé òún ṣàwárí lọ́dọọdún.” Nítorí náà, kí ló dé tí wọn ò tú àṣírí Harrison látijọ́ yìí?
Olùwádìí Karl Sabbagh sọ pé yíyàn tí wọ́n yàn láti má ṣe ohunkóhun nípa rẹ̀ jẹ́ nítorí àtifi inúure dáàbò bo ìdílé Harrison, ṣùgbọ́n wọ́n tún lè ti ronú nípa pé alágbára ọkùnrin ni Harrison jẹ́, ó sì léwu láti takò ó. Sabbagh tún sọ pé ká ní wọ́n ṣèwé láti tú àṣírí rẹ̀ ni, “ìyẹn ì bá sọ iṣẹ́ ìmọ̀ nípa ewéko látòkè délẹ̀ di aláìníláárí lójú àwọn èèyàn.”