Ǹjẹ́ Ó Ti Tó Àkókò Láti Ní Bẹ́ẹ̀dì Tuntun?
Látọwọ́ akọ̀ròyìn Jí! ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
Ṣé ó máa ń ṣẹlẹ̀ pé o kì í sábà rí oorun sùn, tí wàá máa yí lọ yí bọ̀ kára lè tù ọ́, tó bá wá di òwúrọ̀, tí wàá jí tí gbogbo ara á máa ro ọ́? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè jẹ́ bẹ́ẹ̀dì tí o fi ń sùn ni ìṣòro rẹ.
OHUN èlò yìí lè jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ló sì lè jẹ́ ọ̀tá rẹ. Bó bá jẹ́ ibi tí wọ́n ti máa ń lo bẹ́ẹ̀dì lò ń gbé, á fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé nǹkan bí ìdá mẹ́ta ìgbésí ayé rẹ lò ń lò lórí bẹ́ẹ̀dì, ṣùgbọ́n bó bá yá, bẹ́ẹ̀dì rẹ á gbó. Ṣe o ń gbádùn bẹ́ẹ̀dì tí o ń lò báyìí?
Ǹjẹ́ O Nílò Bẹ́ẹ̀dì Tuntun?
Bí ó ti sábà máa ń rí, bẹ́ẹ̀dì kan á ṣiṣẹ́ dáadáa fún nǹkan bí ọdún mẹ́wàá. Bẹ́ẹ̀dì ẹni tó bá tóbi lè tètè gbó. Fi sọ́kàn pẹ̀lú pé bí o ṣe ń dàgbà sí i, àwọn nǹkan tí o nílò àti ohun tí o fẹ́ á máa yí padà. Láti pinnu bóyá o nílò bẹ́ẹ̀dì tuntun, bi ara rẹ ní ìbéèrè wọ̀nyí. ‘Ṣé ọrùn tàbí ẹ̀yìn máa ń ro mí tí mo bá jí? Ṣé bẹ́ẹ̀dì mi ò kéré jù? Ṣé irin tàbí igi bẹ́ẹ̀dì kì í gún mi lára? Ṣé bẹ́ẹ̀dì mi kì í dún tàbí kó máa pariwo nígbà tí mo bá yíra padà? Ṣé èmi àti ìyàwó mi máa ń yí lu ara wa láìmọ̀ọ́mọ̀? Ṣé abẹ́ bẹ́ẹ̀dì náà kò rí gbágungbàgun tàbí kí ibì kan lọ sókè ju ibì kejì? Ṣé ẹsẹ̀ rẹ̀ àti àwọn táyà ẹsẹ rẹ̀ kò ti gbó?’ Àwọn ìdáhùn rẹ sí ìbéèrè wọ̀nyí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti pinnu bóyá ó ti tó àkókò láti ra bẹ́ẹ̀dì tuntun.
Báwo La Ṣe Ń Mọ Bẹ́ẹ̀dì Tó Dára?
Bẹ́ẹ̀dì tó dára yóò mú kí ara tù ọ́, á sì lágbára láti gbà ọ́ dúró bí o bá sùn, á kúnjú ìwọ̀n ohun tí o nílò àti ohun tí o fẹ́. Ọ̀pọ̀ bẹ́ẹ̀dì máa ń ní mátírẹ́ẹ̀sì àti irin tàbí igi bẹ́ẹ̀dì, ṣùgbọ́n mátírẹ́ẹ̀sì gan-an ló máa ń jẹ́ kí ara tù ọ́. Àwọn nǹkan kan wà tó máa ń para pọ̀ di mátírẹ́ẹ̀sì. Àkọ́kọ́ níbẹ̀ ni aṣọ tó bò ó, tàbí èyí tó mú kó túbọ̀ tóbi sí i, tí a fi máa ń di gbogbo rẹ̀ pa pọ̀. Lẹ́yìn náà ló kan tìmùtìmù táá mú kí ara tù ọ́, tí á sì jẹ́ kí ooru ara rí ibi gbà jáde. Ìpele kẹta, tó máa ń mú kí ó lágbára, kí ó sì dúró sán-ún, sábà máa ń ní irin wọ́lọwọ̀lọ tàbí irin lílọ́ nínú lọ́hùn-ún. Onírúurú àwọn nǹkan ni wọ́n máa ń fi ṣe inú rẹ̀ kó lè lágbára, ṣùgbọ́n ní gbogbo gbòò, bí irin lílọ́ tí wọ́n fi ṣe é bá ṣe pọ̀ tó, àti bí wáyà tí wọ́n lò bá ṣe gbópọn tó ni yóò ṣe lágbára tó. Èyí tó tún wá wọ́pọ̀ báyìí tí àwọn èèyàn tún ń lò ni mátírẹ́ẹ̀sì tí wọ́n fi tìmùtìmù ṣe; kò wúwo bí èyí tí wọ́n fi irin lílọ́ ṣe inú rẹ̀.
Ṣùgbọ́n, mátírẹ́ẹ̀sì tó dáa sábà máa ń ṣe dáadáa bó bá jẹ́ orí ibi tó yẹ la gbé e lé, ìyẹn ni pé kó jẹ́ orí ibi tí wọ́n ṣe é fún. Wọ́n sábà máa ń ta bẹ́ẹ̀dì ìrọ̀gbọ̀kú pẹ̀lú gbogbo ohun tó yẹ, pẹ̀lú mátírẹ́ẹ̀sì àti pátákó tí wọ́n máa gbé e lé. Ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ tó máa ń fẹ̀, tó ní ìsàlẹ̀ tó dà bíi ti àpótí máa ń ṣèrànwọ́ gidigidi láti dáàbò bo mátírẹ́ẹ̀sì, á jẹ́ kátẹ́gùn máa rí ibi fẹ́ sí i, èyí sì ń jẹ́ kó lálòpẹ́ gidigidi. Òmíràn tún ni bẹ́ẹ̀dì tí wọ́n máa ń tẹ́ ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ó sábà máa ń ní ìsàlẹ̀ tí wọ́n tẹ́, ó sì ní ihò lábẹ́, èyí a jẹ́ kí atẹ̀gún máa fẹ́ sí mátírẹ́ẹ̀sì tó bá a mu, tí a gbé sí i. Bó bá jẹ́ pé nǹkan tó le ni wọ́n fi tẹ́ ìsàlẹ̀ rẹ̀, ó máa ń jẹ́ kí ìpìlẹ̀ rẹ̀ le, bó bá sì jẹ́ nǹkan tó lè ta bọ̀n-ùn la lò, ìpìlẹ̀ rẹ̀ máa ń rọ̀.
Yíyan Bẹ́ẹ̀dì Tí Ó Yẹ
Kí ló yẹ kí o fi sọ́kàn nígbà tí o bá fẹ́ ra bẹ́ẹ̀dì? Àlòkù bẹ́ẹ̀dì ti lè fa òógùn ara àwọn ẹlòmíràn mu, ìpẹ́pẹ́ ara wọ́n sì ti lè ṣí mọ́ ọn, ó tún lè ní kòkòrò tó lè bá ara rẹ jà, ó lè fa ikọ́ fée, tàbí ifo. Ó tún lè máà bá ìlànà ìlera àti ààbò mu.
Kí o tó lọ ra bẹ́ẹ̀dì tuntun, a dámọ̀ràn pé kí o pinnu ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ, àwọn nǹkan bí iye owó rẹ̀, ọ̀ràn ìlera, tàbí bí yóò ṣe tóbi tó. Gbìyànjú kí o wá àkókò tí ó pọ̀ tó láti ṣèbẹ̀wò sí àwọn ilé ìtajà tó lórúkọ rere, kí o sì wádìí bó bá ti ṣeé ṣe tó nípa bẹ́ẹ̀dì tàbí mátírẹ́ẹ̀sì kọ̀ọ̀kan. Níwọ̀n bí àwọn bẹ́ẹ̀dì ti sábà máa ń wọ́n, má ṣe jẹ́ kí wọ́n tì ọ́ yan èyí tí kò dáa.
Ó lè ṣòro fún ọ láti yan èyí tí ó yẹ tí o bá lọ nígbà tó ti rẹ̀ ọ́. Wọ aṣọ tó rọ̀ ẹ́ lọ́rùn. Má ṣe ronú pé ìwọ ni gbogbo èèyàn ń wò nígbà tí o bá ń ṣàyẹ̀wò bẹ́ẹ̀dì. Bọ́ aṣọ kóòtù àti bàtà rẹ, kí o sì sùn sórí bẹ́ẹ̀dì kọ̀ọ̀kan fún ìṣẹ́jú díẹ̀. Sùn lóríṣiríṣi ọ̀nà, kí o kíyè sí i dáadáa bóyá ó gba èjìká rẹ dúró, bóyá ó gba itan rẹ dúró, bóyá ó sì gba ìbàdí rẹ dúró.—Wo àpótí tó wà nísàlẹ̀.
Títọ́jú Bẹ́ẹ̀dì Rẹ
Bí o bá ń tọ́jú bẹ́ẹ̀dì rẹ dáadáa, ó dájú pé ìyẹn yóò jẹ́ kí ó lálòpẹ́. Béèrè ìmọ̀ràn lọ́wọ́ àwọn tó ń tà á, kí o sì fara balẹ̀ ka ìtọ́ni tí àwọn tó ṣe é pèsè nípa ìtọ́jú rẹ̀. Nígbà tí o bá gbé bẹ́ẹ̀dì rẹ tuntun délé, já ọ̀rá tó wà lára rẹ̀ kúrò kíákíá. Èyí kò ní jẹ́ kí ó kì pọ̀, tí ó lè jẹ́ kó móoru, kó hewú, kó sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ̀. Àwọn ìmọ̀ràn díẹ̀ sí i ló tẹ̀ lé e yìí.
● Rí i pé o ń yí mátírẹ́ẹ̀sì rẹ tuntun padà, tó bá jẹ́ onírin lílọ́, kí o sì tún yí ibi tí o ń gbórí sí sí ibi tí o ń gbẹ́sẹ̀ sí, kí o máa ṣe èyí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tàbí lọ́sẹ̀ méjìméjì fún oṣù mélòó kan àkọ́kọ́, bó bá sì yá, kí o máa ṣe bẹ́ẹ̀ lóṣù mẹ́tamẹ́ta. Èyí á jẹ́ kí àwọn nǹkan tí wọ́n kó sínú rẹ̀ fara mọ́ra, kò sì ní jẹ́ kí apá kan tètè gbó ju apá kejì. Bí o bá ní ìṣòro ẹ̀yìn dídùn, á dáa kí o ronú nípa níní mátírẹ́ẹ̀sì tó jẹ́ pé kìkìdá tìmùtìmù ni, níwọ̀n bí ìyẹn ti lè máà béèrè pé kí o máa yí i padà déédéé.
● Má ṣe tẹ mátírẹ́ẹ̀sì, má ṣe ká a kólóbó, má sì ṣe fún un pọ̀. Kí o má bàa ba aṣọ ara rẹ̀ jẹ́, ńṣe ni kí o máa fi ìkọ́ rẹ̀ tì í sí àyè rẹ̀, má ṣe fi gbé e.
● Láràárọ̀, ṣí aṣọ tí o fi ń bo bẹ́ẹ̀dì rẹ fún ogún ìṣẹ́jú ó kéré tán, kí atẹ́gùn lè fẹ́ sí bẹ́ẹ̀dì rẹ kí ooru ara sì gbẹ kúrò.
● Kí mátírẹ́ẹ̀sì rẹ má bàa dọ̀tí, máa fi nǹkan tó ṣeé fọ̀ bò ó. Máa gbọn ìdọ̀tí àti eruku kúrò lára mátírẹ́ẹ̀sì rẹ déédéé, kí o sì fi omi tútù tó ní ọṣẹ díẹ̀ nínú nu ìdọ̀tí tó bá ta bá a tàbí ohunkóhun tó bá dà sí i.
● Gbìyànjú kí o má ṣe máa jókòó sí ojú kan náà ní etí mátírẹ́ẹ̀sì rẹ ní gbogbo ìgbà. Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọmọdé tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn fò sórí bẹ́ẹ̀dì rẹ.
Bẹ́ẹ̀dì rẹ ju ohun ìní tóo fi owó rà. Ohun ìní tí o fi ń lo ìdámẹ́ta nínú ìgbésí ayé rẹ ni, ó sì lè ní ipa ńláǹlà lórí ìdáméjì yòókù. Bí o bá fi ọgbọ́n yan ọ̀rẹ́ rẹ tí ń gbà ọ́ dúró yìí, tí o sì ń bójú tó o dáadáa, òun náà á tọ́jú ẹ dáadáa.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20]
Bẹ́ẹ̀dì Wo Ló Yẹ Ọ́?
Ó tura, ó sì lè gba ara dúró. Kò dìgbà tí mátírẹ́ẹ̀sì kan bá le bí igi ká tó sọ pé ó dáa fún ọ́. Ká sòótọ́, a ronú pé bí bẹ́ẹ̀dì kan bá le jù, ó lè dá kún ìṣòro ẹ̀yìn dídùn. Jẹ́ kí ara rẹ sọ ohun tó fẹ́. Fi ẹ̀yìn lélẹ̀. Bí ó bá ṣeé ṣe fún ọ láti ti ọwọ́ rẹ bọ ibi ọ̀pá ẹ̀yìn rẹ, kí ó wọ̀ ọ́ dáadáa, tí ó sì rọrùn fún ẹ láti yí padà, a jẹ́ pé mátírẹ́ẹ̀sì yẹn kò le jù fún ọ. Mátírẹ́ẹ̀sì tó bá gba ara dúró dáadáa kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí eegun ẹ̀yìn rẹ tẹ̀ nígbà tí o bá fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀. Ẹni tó bá tóbi nílò bẹ́ẹ̀dì tó túbọ̀ lágbára dáadáa.
Bí ó ṣe tóbi tó. Yan bẹ́ẹ̀dì tí á jẹ́ kí o lè yí lọ yí bọ̀. Bó bá jẹ́ pé èèyàn méjì ni yóò máa sun orí bẹ́ẹ̀dì kan, fi sọ́kàn pé bí àgbàlagbà méjì bá ń sùn lórí bẹ́ẹ̀dì ńlá ẹlẹ́gbẹ̀ẹ́ méjì, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn yóò ní àyè kan náà bí ìgbà tí ọmọ jòjòló bá sùn lórí bẹ́ẹ̀dì ọmọ ọwọ́.
Mátírẹ́ẹ̀sì tó bá bẹ́ẹ̀dì mu. Bó bá ṣeé ṣe, ra mátírẹ́ẹ̀sì àti bẹ́ẹ̀dì tó bára wọn mu, tí wọ́n sì ṣe láti ṣiṣẹ́ pọ̀ láti tù ọ́ lára kí wọ́n sì gba ara rẹ dúró. Bẹ́ẹ̀dì tó ti gbó lè ba mátírẹ́ẹ̀sì tuntun jẹ́, ó sì lè máà jẹ́ kó lálòpẹ́ tó bí wọ́n ṣe fọwọ́ sọ̀yà fún ọ níbi tóo ti rà á.
Ìníyelórí rẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tí o bá sanwó fún ni wọ́n á tà fún ọ, nítorí náà, ra bẹ́ẹ̀dì tó dára jù lọ tí agbára rẹ ká.
Àyè. Bí kò bá sí àyè, o lè ronú nípa bẹ́ẹ̀dì tó ṣeé ká, tàbí bẹ́ẹ̀dì tí wọ́n ń nàró sára ògiri, tó ṣeé tì mọ́ inú àpótí tó wà nídùúró. Òmíràn tún ni mátírẹ́ẹ̀sì tí wọ́n fi òwú ṣe, tó tètè ṣeé tẹ́ sílẹ̀ lálẹ́. Wọ́n tún máa ń ta mátírẹ́ẹ̀sì olówùú gẹ́gẹ́ bí àga onítìmùtìmù tó ṣeé nà bí ibùsùn, tó sì tún ṣeé ká.
Àìlera. Bí bẹ́ẹ̀dì tó wọ́pọ̀ kò bá tù ọ́ lára, bẹ́ẹ̀dì tó ṣeé yí padà máa ń ní onírúurú ọ̀nà tí èèyàn lè gbà sùn. Bẹ́ẹ̀dì olómi máa ń gba ara èèyàn dúró, kì í jẹ́ kí ìwúwo ara fì sí ibì kan, ó sì lè ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ara máa ń ni nítorí sísún mọ́ tí òpó ẹ̀jẹ̀ sún mọ́ eegun ara jù.
Àwọn tó ní èèwọ̀ ara. Bí ekuru tàbí ìdọ̀tí tín-íntìn-ìntín bá máa ń dààmú rẹ, á dáa kí o yan mátírẹ́ẹ̀sì tó jẹ́ pé aṣọ tí wọ́n fi ṣe é kì í gbọn ìdọ̀tí tín-íntìn-ìntín, tàbí tó jẹ́ pé kìkìdá tìmùtìmù ni. Ó dáa kí o tún mọ̀ pé àwọn ohun tó máa ń jẹ́ èèwọ̀ fún ara kì í tètè kó wọnú bẹ́ẹ̀dì tí wọ́n tẹ́ abẹ́ rẹ̀ tàbí bẹ́ẹ̀dì olómi.
Àwọn arúgbó. Rí i dájú pé àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ lè kan ilẹ̀ nígbà tí o bá jókòó sí etí bẹ́ẹ̀dì rẹ. Bẹ́ẹ̀dì tó bá ní etí tó le yóò lè jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún ọ láti bọ́ sórí bẹ́ẹ̀dì tàbí kí o dìde kúrò lórí bẹ́ẹ̀dì láti ibi tí o jókòó sí yẹn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]
Àwọn Ìmọ̀ràn Tó Lè Dáàbò Bò Ọ́
◼ Wọ aṣọ àwọ̀sùn tí kò lè tètè jóná.
◼ Rí i dájú pé ibi tí o gbé bẹ́ẹ̀dì rẹ sí jìnnà sí iná àti ẹ̀rọ amúlémóoru.
◼ Ṣàyẹ̀wò kúbùsù tó ń bá iná ṣiṣẹ́ bóyá lára àwọn òwú tí wọ́n fi ṣe é ti gbó, bóyá àpá ti wà lára rẹ̀, bóyá àmì wà lára rẹ̀ tó ń fi hàn pé àwọn apá ibì kan lára rẹ̀ ti ń jó díẹ̀díẹ̀, tàbí bóyá okùn iná rẹ̀ ti gbó. Má ṣe lo kúbùsù náà nígbà tí ó bá tutù, ṣùgbọ́n jẹ́ kí ó fúnra rẹ̀ gbẹ. Má ṣe gbé nǹkan tó wúwo sí orí bẹ́ẹ̀dì nígbà tí ẹ bá ti tanná sí kúbùsù náà.
◼ Má ṣe rọ omi tó ń hó yaya sínú rọ́bà tí wọ́n ń rọ omi gbígbóná sí, má sì ṣe lò ó pẹ̀lú kúbùsù tó ń bá iná ṣiṣẹ́. Gbé e kúrò kí ọmọ tó gorí bẹ́ẹ̀dì.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Aṣọ mátírẹ́ẹ̀sì
Aṣọ mátírẹ́ẹ̀sì tí bátànì rẹ̀ fẹ̀
Aṣọ mátírẹ́ẹ̀sì tí bátànì rẹ̀ wẹ́
Òwú tí wọ́n fi ṣe ọ̀ṣọ́
Ìpele onítìmùtìmù
Férémù mátírẹ́ẹ̀sì
Tìmùtìmù
Irin wọ́lọwọ̀lọ
Irin lílọ́
Irin àkìbọnú mátírẹ́ẹ̀sì
[Credit Line]
A ṣàtúntẹ̀ rẹ̀ nípasẹ̀ ìfọwọ́sí onínúure ti Sleep Council
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 19]
A ṣàtúntẹ̀ rẹ̀ nípasẹ̀ ìfọwọ́sí onínúure ti Sleep Council