ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 1/8 ojú ìwé 14-16
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Di Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ Tó Dáńgájíá?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Di Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ Tó Dáńgájíá?
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Wọ́n Bá Ní Kó O Wá Bá Àwùjọ Sọ̀rọ̀
  • Bíborí Ìbẹ̀rù Rẹ
  • Àwọn Ìdámọ̀ràn Tó Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́
  • Ìrànwọ́ Látọ̀dọ̀ Olùbánisọ̀rọ̀ Tó Gbéṣẹ́ Jù Lọ
  • Ìbàlẹ̀ Ọkàn
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Wíwo Ojú Àwùjọ
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Jẹ́ Kí Àwùjọ Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 1/8 ojú ìwé 14-16

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Di Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ Tó Dáńgájíá?

“Mò ń rò ó pé àwọn èèyàn ń rí gbogbo àṣìṣe tí mò ń ṣe àti bí ojora ṣe ń mú mi. Mi ò lè pọkàn pọ̀ sórí ọ̀rọ̀ tí mò ń sọ mọ́. Mò ń ronú pé ńṣe ni wọ́n ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.”—Sandy.a

ÀWỌN èèyàn kún gbọ̀ngàn ilé ẹ̀kọ́ fọ́fọ́. O gbọ́ tí wọ́n pe orúkọ rẹ lórí ẹ̀rọ gbohùngbohùn, lójú ẹsẹ̀ sì ni gbogbo wọn ti dojú bò ọ́. Ńṣe ni ẹsẹ̀ bàtà bíi mélòó kan tó o máa gbé kó o tó dé orí tábìlì ìbánisọ̀rọ̀ dà bí ìrìn kìlómítà kan. Àtẹ́lẹwọ́ rẹ bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́ òógùn, ẹsẹ̀ rẹ ò ranlẹ̀ dáadáa mọ́, ẹnu rẹ sì gbẹ fúrúfúrú fún ìdí kan ṣá. Lẹ́yìn èyí, kó o tó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, òógùn ńlá kan ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn lọ síbi ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ. Èyí mà ń kótìjú báni o! O mọ̀ pé kì í ṣe iwájú àwọn sójà tó ń yìnbọn pani lò ń lọ, àmọ́ kò sí àní-àní pé bó ṣe rí lára rẹ nìyẹn.

Ká má purọ́, ọ̀pọ̀ lára wa ló máa ń bẹ̀rù sísọ̀rọ̀ níwájú àwọn ẹlòmíràn. (Jeremáyà 1:5, 6) Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé àwọ́n bẹ̀rù sísọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ ju ikú lọ! Àmọ́, ọ̀nà yòówù kó o gbà wò ó, àwọn ìdí pàtàkì wà tó fi yẹ kó o nífẹ̀ẹ́ sí sísọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ. Jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára wọn, ká sì wo bó o ṣe lè di sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńgájíá.

Bí Wọ́n Bá Ní Kó O Wá Bá Àwùjọ Sọ̀rọ̀

“Sísọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ jẹ́ ohun kan tó yẹ kí gbogbo èèyàn mọ̀.” Ọ̀nà tí wọ́n gbà polówó ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan nípa sísọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ nìyẹn. Bẹ́ẹ̀ ni o, bópẹ́ bóyá, wàá sọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ. Ohun kan ni pé, wọ́n máa ń ṣètò sísọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ ní ọ̀pọ̀ ilé ẹ̀kọ́. Ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Tatiana sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé mo ní láti sọ̀rọ̀ níwájú àwọn ọmọ kíláàsì mi ní ilé ẹ̀kọ́.” Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní láti wà ní ìmúratán lọ́pọ̀ ìgbà láti sọ̀rọ̀, irú bíi kíka ìròyìn níwájú kíláàsì, sísọ àwọn kókó inú ìwé, ṣíṣàlàyé lórí ohun kan tó ń fara hàn nínú àwòrán ara ògiri tàbí tí wọ́n ń gbọ́ lórí rédíò àti jíjiyàn lórí kókó ọ̀rọ̀ kan.

Lẹ́yìn tó o bá ti wá jáde ilé ẹ̀kọ́ tó o sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́, wọ́n lè ké sí ọ láti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn kan lára àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, láti ṣàlàyé àwọn ohun kan fún àwọn tó gbéṣẹ́ wá sí iléeṣẹ́ yín tàbí láti ṣàlàyé ọ̀ràn ìnáwó fún àwọn lọ́gàálọ́gàá níbi iṣẹ́. Ní ti tòótọ́, kíkọ́ béèyàn ṣe ń sọ̀rọ̀ dáadáa wúlò gan-an nínú onírúurú iṣẹ́, títí kan iṣẹ́ ìkọ̀ròyìn, ṣíṣe àbójútó iléeṣẹ́, ṣíṣe aṣojú fún iléeṣẹ́ àti iṣẹ́ ọjà títà.

Àmọ́ ṣá o, ká wá sọ pé o fẹ́ lọ ṣe iṣẹ́ àgbàṣe tàbí iṣẹ́ ọ́fíìsì ńkọ́? Ó dára, mímọ ọ̀rọ̀ sọ dáadáa nígbà téèyàn bá ń wáṣẹ́ lè pinnu bóyá wọ́n á gbani ṣiṣẹ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Nígbà tó o bá sì ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ọ̀hún, jíjẹ́ ẹni tó lè ṣàlàyé ara rẹ̀ lè ṣàǹfààní fún ọ. Corrine ṣiṣẹ́ ọdún mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí agbáwo nílé àrojẹ lẹ́yìn tó parí ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ó sọ pé: “Bó o bá lè sọ̀rọ̀ dáadáa, àwọn èèyàn á máa wò ọ́ bí ẹni tó dàgbà dénú àti ẹni tí wọ́n lè gbé ọ̀pọ̀ ẹrù iṣẹ́ fún. Àní, ó lè túmọ̀ sí pé wàá rí iṣẹ́ tó dára gan-an ṣe, pé owó oṣù rẹ á pọ̀ sí i tàbí pé, lọ́nà kan ṣá àwọn èèyàn á túbọ̀ máa buyì fún ọ.”

Níkẹyìn, àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ sábà máa ń sọ̀rọ̀ níwájú àwọn ẹlòmíràn gẹ́gẹ́ bí apá kan ìjọsìn wọn. (Hébérù 10:23) Taneisha sọ pé: “Ó ṣe pàtàkì láti jẹ́ ẹni tó lè ṣàlàyé ara rẹ̀ yékéyéké. A ní àǹfààní ńláǹlà láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.” (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Nínú ìjọ àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni kò lè “dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí [wọ́n] ti rí tí [wọ́n] sì ti gbọ́.”—Ìṣe 4:20; Hébérù 13:15.

Kíkọ́ béèyàn ṣe ń sọ̀rọ̀ dáadáa lè tipa bẹ́ẹ̀ ṣàǹfààní fún ọ ní onírúurú ọ̀nà. Àní, pẹ̀lú èyí pàápàá, o ṣì lè máa ṣàníyàn nípa sísọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ. Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tó o lè ṣe láti borí ojora tó máa ń mú ọ? Bẹ́ẹ̀ ni o, ó kúkú wà.

Bíborí Ìbẹ̀rù Rẹ

Dókítà Morton C. Orman, ògbógi nípa ìtọ́jú másùnmáwo, tó sì tún jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńgájíá, sọ pé: “Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ dìgbà tó o bá jẹ́ ọ̀mọ̀wé tàbí ẹni pípé kó o tó lè mọ ọ̀rọ̀ sọ. Ìdí pàtàkì téèyàn fi ń bá àwùjọ sọ̀rọ̀ ni láti jẹ́ kí àwọn olùgbọ́ rí ẹ̀kọ́ gidi kọ́.” Lọ́rọ̀ kan, pọkàn pọ̀ sórí ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ, kì í ṣe sí ara rẹ tàbí ojora tó ń mú ọ. Àwọn kan ní ọ̀rúndún kìíní ronú pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kì í ṣe sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńgájíá, àmọ́ nítorí pé ó sábà máa ń ní nǹkan tó ṣe pàtàkì láti sọ fún wọn, iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ṣì gbéṣẹ́. (2 Kọ́ríńtì 11:6) Bákan náà, bó o bá ń sọ ọ̀rọ̀ kan tó ṣe pàtàkì tí ìwọ fúnra rẹ sì mọ̀ bẹ́ẹ̀, kò ní pẹ́ tí ojora rẹ á fi lọ.

Ron Sathoff, sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ mìíràn tó gbajúmọ̀, tó sì tún máa ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ọ̀rọ̀ sísọ, dábàá pé: Má ṣe wo ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ gẹ́gẹ́ bí eré orí ìtàgé. Wò ó gẹ́gẹ́ bí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ kan. Bẹ́ẹ̀ ni o, gbìyànjú láti máa wo ojú àwùjọ rẹ, kì í ṣe lápapọ̀, àmọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí wàá ṣe ṣe tó o bá ń báni sọ̀rọ̀. Fi ìfẹ́ hàn sí àwùjọ rẹ, kó o sì bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó o máa ń gbà sọ̀rọ̀. (Fílípì 2:3, 4) Bí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣe jọ pé ò ń báni fọ̀rọ̀ wérọ̀ sí, bẹ́ẹ̀ ni ara rẹ á ṣe balẹ̀ sí.

Ohun mìíràn tó tún sábà máa ń mú kí àwọn èèyàn ṣàníyàn ni ìtìjú tàbí ìbẹ̀rù pé àwùjọ á máa ṣe àríwísí ọ̀rọ̀ wọn. Lenny Laskowski, sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ kan tó tún máa ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ọ̀rọ̀ sísọ, sọ pé àwọn olùgbọ́ sábà máa ń ní èrò tó dára lọ́kàn nípa ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fẹ́ gbọ́. Laskowski sọ pé: “Ohun tí wọ́n fẹ́ ni pé kó o ṣe iṣẹ́ rẹ ní àṣeyanjú, kì í ṣe pé kó o kùnà.” Nítorí náà, ní èrò tó dára lọ́kàn. Bó bá ṣeé ṣe, gbìyànjú láti kí díẹ̀ lára àwọn olùgbọ́ rẹ bí wọ́n ṣe ń dé. Gbìyànjú láti rí wọn bí ọ̀rẹ́, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá.

Bákan náà, tún rántí pé ojora kì í ṣe ohun tó kúkú wá burú jáì. Ògbógi kan sọ pé: “Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń rò, ojora ṣàǹfààní fún ìwọ àti ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ.” Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ojora díẹ̀ tó mú ọ fi hàn pé o jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, èyí tí kò ní jẹ́ kó o dá ara rẹ lójú ju bó ṣe yẹ lọ. (Òwe 11:2) Ọ̀pọ̀ àwọn eléré ìdárayá, àwọn olórin àtàwọn òṣèré ló sọ pé ojora díẹ̀ tó ń mú àwọn máa ń jẹ́ kí àwọn ṣe dáadáa gan-an, èyí náà sì lè ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ń bá àwùjọ sọ̀rọ̀.

Àwọn Ìdámọ̀ràn Tó Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́

Nípa fífi àwọn kókó tó wà nísàlẹ̀ yìí àtàwọn mìíràn sílò, àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni kan ti ní ìrírí tó pọ̀ sí i, wọ́n sì ti di sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńgájíá sí i ní ilé ẹ̀kọ́, níbi iṣẹ́ àti nínú ìjọ wọn. Wò ó bóyá díẹ̀ lára àwọn ìdámọ̀ràn wọn lè ràn ọ́ lọ́wọ́.

Jade: “Sọ ọ̀rọ̀ náà ní ọ̀rọ̀ ara rẹ. Jẹ́ kí ìjẹ́pàtàkì ohun tóò ń sọ dá ìwọ fúnra rẹ lójú. Bó o bá ronú pé ọ̀rọ̀ rẹ ṣe pàtàkì, ojú tí àwùjọ náà á fi wò ó nìyẹn.”

Rochelle: “Ohun kan tó ń ràn mí lọ́wọ́ ni gbígba àwòrán àti ohùn ara mi sílẹ̀ sórí ẹ̀rọ fídíò. Èyí máa ń jẹ́ kí n mọ ibi tí mo kù sí, àmọ́ ó ń ṣèrànwọ́. Bákan náà, gbìyànjú láti yan àkòrí ọ̀rọ̀ kan tó o fẹ́ràn. Èyí á fara hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ rẹ.”

Margrett: “Mo ti ṣàkíyèsí pé mo máa ń sọ̀rọ̀ bí Ọlọ́run ṣe dá mi ọ̀rọ̀ mi sì máa ń dà bí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ nígbà tí mo bá lo ìwé àkọsílẹ̀ ṣókí dípò kí n kọ gbogbo ọ̀rọ̀ mi sílẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan. Láfikún sí i, mímí kanlẹ̀ ṣáájú kí n tó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ máa ń fi mí lọ́kàn balẹ̀.”

Corrine: “Kọ́ láti máa fi àṣìṣe rẹ rẹ́rìn-ín. Kò sẹ́ni tí kì í ṣe àṣìṣe. Ńṣe ni kó o ṣáà gbìyànjú láti ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe.”

Ká sòótọ́, gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nínú ohun èyíkéyìí téèyàn bá dáwọ́ lé, irú bí eré ìdárayá, iṣẹ́ ọnà tàbí orin, kò sóhun téèyàn lè fi rọ́pò ìrírí àti ọ̀pọ̀ ìdánrawò. Tatiana dábàá mímúra ọ̀rọ̀ rẹ sílẹ̀ tipẹ́tipẹ́ ṣáájú àkókò kó o lè ní àkókò tó tó láti fi ṣe ìdánrawò. Síwájú sí i, má ṣe jáwọ́ o. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ níwájú àwọn ẹlòmíràn lemọ́lemọ́ tó, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi túbọ̀ ń balẹ̀ sí i tó.” Àmọ́, ó ṣì ku orísun ìrànwọ́ kan tóò gbọ́dọ̀ gbàgbé, pàápàá nígbà tí wọ́n bá ní kó o wá sọ̀rọ̀ láti gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ.

Ìrànwọ́ Látọ̀dọ̀ Olùbánisọ̀rọ̀ Tó Gbéṣẹ́ Jù Lọ

Nígbà tí Dáfídì, ọbalọ́la ní Ísírẹ́lì, ṣì jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin, làwọn èèyàn ti mọ̀ ọ́n sí “olùbánisọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ onílàákàyè.” (1 Sámúẹ́lì 16:18) Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ó hàn gbangba pé, nígbà ọ̀dọ́ rẹ̀, ní ọ̀pọ̀ àkókò gígùn tó fi wà lórí pápá lábẹ́ òfuurufú tó ń bójú tó àgùntàn, Dáfídì ti mú kí àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Olùbánisọ̀rọ̀ Tó Gbéṣẹ́ Jù Lọ náà, Jèhófà Ọlọ́run, jinlẹ̀ sí i nípasẹ̀ àdúrà. (Sáàmù 65:2) Ẹ̀wẹ̀, àjọṣe yìí mú un gbára dì láti lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tó yéni yékéyéké, tìtaratìtara àti lọ́nà tó lè yíni lérò padà, kódà láwọn ìgbà tí ipò nǹkan kò fara rọ pàápàá.—1 Sámúẹ́lì 17:34-37, 45-47.

Jẹ́ kó dá ọ lójú pé bó o ṣe ń jọ́sìn Ọlọ́run, yóò tún ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀ lọ́nà tó lè yíni lérò padà, gẹ́gẹ́ bó ṣe ran Dáfídì lọ́wọ́, nípa fífún ọ ní “ahọ́n àwọn tí a kọ́.” (Aísáyà 50:4; Mátíù 10:18-20) Láìsí àní-àní, nípa lílo àwọn àǹfààní tó lè mú kó o túbọ̀ mọ ọ̀rọ̀ sọ dáadáa, o lè di sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńgájíá!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16]

À Ń Kọ́ Wọn Láti Di Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀

Nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé, ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan tí a gbé karí Bíbélì wà tí à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, èyí tó ń jẹ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń kópa nínú ìjíròrò kíláàsì, wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ níwájú ìjọ, wọ́n sì máa ń gba ìtọ́sọ́nà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú. Ǹjẹ́ ètò yìí gbéṣẹ́? Jẹ́ kí Chris, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, sọ ìrírí rẹ̀ fún ọ.

Ó sọ pé: “Kí n tó forúkọ sílẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ yìí, ara mi kì í balẹ̀ níwájú àwọn èèyàn. Mi ò ronú láé pé mo lè dúró sọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ. Àmọ́, àwọn kan nínú ìjọ fún mi níṣìírí, wọ́n ní kódà bó bá jẹ́ pé ńṣe ni mo kàn ń kólòlò ní gbogbo àkókò tí màá fi sọ̀rọ̀, àwọ́n á gbádùn rẹ̀, níwọ̀n bí àwọ́n ti mọ bí mo ṣe sapá tó láti lè dúró níwájú àwọn. Lẹ́yìn èyí, nígbà tí mo bá ti parí iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún mi, wọ́n máa ń gbóríyìn fún mi. Ìyẹn ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni.”

Lónìí, lẹ́yìn ọdún márùn-ún tí Chris ti ń kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́ yìí, ó ti ń múra sílẹ̀ láti sọ ọ̀rọ̀ àsọyé rẹ̀ àkọ́kọ́, èyí tó jẹ́ oníṣẹ̀ẹ́jú márùnlélógójì. Ǹjẹ́ ò ń jàǹfààní látinú ètò yìí?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14, 15]

Dídi sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńgájíá lè ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú gbogbo ohun tó o bá ń ṣe ní ìgbésí ayé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́