ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 12/8 ojú ìwé 3
  • Kò Sẹ́ni Tí Ò Fẹ́ Lọ́rẹ̀ẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kò Sẹ́ni Tí Ò Fẹ́ Lọ́rẹ̀ẹ́
  • Jí!—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwọ́ Lè Gbádùn Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Pípẹ́ Títí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Bá A Ṣe Lè Máa Ṣe Ọ̀rẹ́ Nínú Ayé Aláìnífẹ̀ẹ́ Yìí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Bá A Ṣe Lè Rẹ́ni Bá Ṣọ̀rẹ́
    Jí!—2004
  • N Kò Ṣe Lè Ní Ọ̀rẹ́ Pẹ́ Títí?
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 12/8 ojú ìwé 3

Kò Sẹ́ni Tí Ò Fẹ́ Lọ́rẹ̀ẹ́

“Ọ̀rẹ́ lẹni téèyàn lè bá sọ̀rọ̀ láìfi nǹkan pa mọ́, téèyàn sì lè pè nígbàkigbà.”—Yaël, láti ilẹ̀ Faransé.

“Ọ̀rẹ́ èèyàn máa ń mọ̀ bí ohun kan bá ń dun èèyàn, nǹkan yẹn á sì máa dun òun náà.”—Gaëlle, láti ilẹ̀ Faransé.

“Ọ̀RẸ́ kan wà tí ń fà mọ́ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ.” (Òwe 18:24) Látìgbà tí ọ̀rọ̀ yìí ti wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọdún sẹ́yìn, ohun tí ẹ̀dá ń fẹ́ ò tíì yí padà. Bí ara ṣe nílò oúnjẹ àtomi bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe pàtàkì fún ẹ̀dá láti lọ́rẹ̀ẹ́. Síbẹ̀, ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti rẹ́ni bá ṣọ̀rẹ́. Káàkiri là ń ráwọn èèyàn tó dá wà. Nínú ìwé wọn, In Search of Intimacy, Carin Rubenstein àti Phillip Shaver sọ pé: “Kò dìgbà tá a bá rìn jìnnà ká tó rí díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó ń fà á.” Lára nǹkan tí wọ́n sọ pó ń fà á ni káwọn èèyàn máa yára kó kúrò níbi tí wọ́n ń gbé, gbígbé láwọn ìlú “tí àwọn èèyàn kì í ti í sú já ara wọn tó sì kún fún ìwà ọ̀daràn,” àti “wíwo tẹlifíṣọ̀n àtàwọn fídíò àgbéléwò dípò bíbá àwọn èèyàn ṣe nǹkan pọ̀ lójúkojú.”

Báyé ṣe rí lónìí tún ń gbani lákòókò ó sì ń mú káwọn èèyàn ṣiṣẹ́ bí ẹrú. Nínú ìwé rẹ̀, Among Friends, Letty Pogrebin sọ pé: “Iye èèyàn táwọn tó ń gbé nígboro lóde òní máa ń bá pàdé lọ́sẹ̀ pọ̀ ju iye èèyàn táwọn tó gbé lábúlé ní nǹkan bí irínwó ọdún sẹ́yìn rí lọ́dún tàbí ní gbogbo àkókò tí wọ́n lò lókè eèpẹ̀.” Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àìmọye èèyàn la lè jọ máa bára wa pàdé, ó lè ṣòro fún wa láti kíyè sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn dáadáa débi tí wọ́n á fi di ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́.

Kódà láwọn ibi tó jẹ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí kìràkìtà lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn, àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe bí wọ́n ṣe ń ṣe síra wọn tẹ́lẹ̀ mọ́. Ulla, tó ń gbé ní ìhà Ìlà Oòrùn Yúróòpù sọ pé: “Ìgbà kan wà táwa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa kì í ya ara wa lẹ́sẹ̀ kan. Ṣùgbọ́n, ní báyìí o, iṣẹ́ kálukú ni wọ́n gbájú mọ́ wàhálà kálukú ni kálukú sì ń bá káàkiri. Ọwọ́ oníkálukú ń dí ní gbogbo ìgbà ṣáá ni, ó wá dà bíi pé àwa ọ̀rẹ́ àtijọ́ ti ń yara wa.” Nínú ayé oníságbàsúlà yìí, èèyàn lè ṣàì ka à ń báni ṣọ̀rẹ́ kún nǹkan kan.

Síbẹ̀ náà, a túbọ̀ ń rí i pé kò dáa kéèyàn jẹ́ kò-rẹ́ni-bá-rìn. Àwọn ọ̀dọ́ ló sábà máa ń wù kí wọ́n rẹ́ni bá rìn. Yaël, tá a fi ọ̀rọ̀ ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé pé, “nígbà téèyàn bá ṣì wà lọ́mọdé, á wù ú kó jẹ́ ẹni àríkí àríyọ̀, á fẹ́ kí ẹnì kan wà tóun lè fojú jọ.” Yálà a jẹ́ ọmọdé tàbí àgbà, gbogbo wa ló wù ká ní ọ̀rẹ́ àtàtà tó sì fara mọ́ni. Láìka nǹkan tá á gbà sí, ọ̀pọ̀ nǹkan la lè ṣe láti rẹ́ni tó dáa bá ṣọ̀rẹ́. Àpilẹ̀kọ́ tó kàn á sọ ohun tá a lè ṣe.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́