ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/06 ojú ìwé 10-12
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dẹ́kun Dídọ́gbẹ́ Síra Mi Lára?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dẹ́kun Dídọ́gbẹ́ Síra Mi Lára?
  • Jí!—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àǹfààní Tó Wà Nínú Fífinú Han Èèyàn
  • Ìdí Tí Àdúrà Fi Ṣe Pàtàkì
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Bó O Bá Nílò Ìrànlọ́wọ́ Sí I
  • Kí Nìdí Tí Mo Fi Ń Dọ́gbẹ́ Síra Mi Lára?
    Jí!—2006
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Ohun Tó Ń Ṣe Mí Mọ́ra?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2006
  • Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ìfipá Báni Ṣèṣekúṣe?—Apá 2: Bó O Ṣe Lè Kọ́fẹ Pa Dà
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Àwọn Míì
Jí!—2006
g 4/06 ojú ìwé 10-12

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dẹ́kun Dídọ́gbẹ́ Síra Mi Lára?

“Làásìgbò tó bá mi kọjá àfaradà. Mo wá rí i pé ìrora ọgbẹ́ ṣeé fara dà ju làásìgbò náà lọ.”— Jennifer, ọmọ ogún ọdún.a

“Nígbà tí ọkàn mi bá dà rú, mo máa ń dọ́gbẹ́ síra mi lára. Ìyẹn ni mo máa fi ń rọ́pò ẹkún tó yẹ kí n sun. Bí mo bá sì dọ́gbẹ́ síra mi lára tán, ara mi á balẹ̀ pẹ̀sẹ̀.”—Jessica, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún.

“Á ti tó ọ̀sẹ̀ méjì tí mo ti dọ́gbẹ́ síra mi lára kẹ́yìn. Ṣe ló rí bíi pé ó ti tó ọdún kan. Mi ò rò pé mo lè ṣíwọ́ pátápátá.”—Jamie, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún.

JENNIFER, Jessica, àti Jamie ò mọra wọn rí, ṣùgbọ́n àwọn nǹkan kan wà tí wọ́n fi jọra. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lẹ̀dùn ọkàn bá. Ọ̀nà kan náà làwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì gbà láti wá ojútùú sí ohun tó ń dùn wọ́n. Ṣe ni Jennifer, Jessica àti Jamie ń dọ́gbẹ́ síra wọn lára torí àtirí ìtura.b

Dídọ́gbẹ́ síra ẹni lára lè dà bí nǹkan àrà mérìíyìírí, àmọ́ ọ̀nà tó gbà ń tàn kálẹ̀ lásìkò tá a wà yìí láàárín àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn tó ti ń kúrò lọ́dọ̀ọ́ ń ṣèèyàn ní kàyéfì. Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Kánádà kan, National Post, kíyè sí i pé àṣà ọ̀hún “ń kó ṣìbáṣìbo bá àwọn òbí, ó ń rú àwọn agbaninímọ̀ràn nílé ẹ̀kọ́ lójú, ó sì ń kó àwọn dókítà sí ìṣòro.” Ìwé ìròyìn náà tún sọ pé dídọ́gbẹ́ síra ẹni lára “lè di ọ̀kan lára àṣà bárakú tó le jù lọ táwọn dókítà tíì rí rí.” Àbí àṣà yìí ti wọ ìwọ náà tàbí àwọn kan tó sún mọ́ ẹ lẹ́wù? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló yẹ kó o ṣe?

Lákọ̀ọ́kọ́, gbìyànjú láti mọ ohun tó sún ẹ dédìí dídọ́gbẹ́ síra ẹ lára. Rántí pé, dídọ́gbẹ́ síra ẹni lára yàtọ̀ sí kéèyàn ṣèèṣì gbọgbẹ́ o. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń jẹ́ nítorí àtilé ẹ̀dùn ọkàn sá. Ẹni tó ń dọ́gbẹ́ síra ẹ̀ lára máa ń yàn láti jẹ̀rora ọgbẹ́ dípò ẹ̀dùn ọkàn. Nítorí náà, bi ara ẹ pé: ‘Èrè wo ni mò ń rí látinú dídọ́gbẹ́ síra mi lára? Èrò wo ló máa ń wá sí mi lọ́kàn lásìkò tó bá ń ṣe mí bíi kí n dọ́gbẹ́ síra mi lára?’ Ṣé kì í ṣe àwọn ìṣòro tó ò ń dojú kọ ló ń fa ìrora ọkàn yẹn fún ọ, bóyá láàárín ilé tàbí láàárín ìwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ?

Kò síyè méjì pé wàá nílò ọkàn akin kó o tó lè bi ara rẹ nírú àwọn ìbéèrè yẹn. Ṣùgbọ́n èrè ibẹ̀ pọ̀. Èyí sábà máa ń jẹ́ ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ láti ṣíwọ́ dídọ́gbẹ́ síra ẹni lára. Síbẹ̀, ó ṣì ku àwọn nǹkan míì tó o gbọ́dọ̀ ṣe lẹ́yìn tó o bá ti mọ ohun tó ń sún ọ sí i.

Àǹfààní Tó Wà Nínú Fífinú Han Èèyàn

Bó o bá máa ń dọ́gbẹ́ síra ẹ lára, ì bá ṣe ẹ́ láǹfààní tó o bá sọ ohun tó ń dùn ẹ́ lọ́kàn fún ọ̀rẹ́ kan tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé tó sì níwà àgbà. Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere ní ń mú un yọ̀.” (Òwe 12:25, Today’s English Version) Bó o bá rí ẹni sọ ohun tó ń dùn ẹ́ lọ́kàn fún, wàá lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ìtùnú, ìyẹn àwọn ọ̀rọ̀ tó máa tù ẹ́ lára.—Òwe 25:11.

Ta ló yẹ kó o lọ bá? Ì bá dáa tó o bá yan ẹni tó dàgbà jù ẹ́ lọ, tó máa ń fọgbọ́n hùwà, tó níwà àgbà tó sì láàánú lójú. Àwọn Kristẹni láǹfààní láti tọ àwọn alàgbà ìjọ lọ, àwọn tí wọ́n “dà bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò, bí àwọn ìṣàn omi ní ilẹ̀ aláìlómi, bí òjìji àpáta gàǹgà ní ilẹ̀ gbígbẹ táútáú.”—Aísáyà 32:2.

Ká sòótọ́, ẹ̀rù lè máa bà ẹ́ láti jẹ́ kí ẹlòmíràn mọ àṣírí ẹ. Ó lè ṣe ẹ́ bó ṣe ṣe ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Sara. Ó ní: “Ó kọ́kọ́ ṣòro fún mi láti fọkàn tán ẹnikẹ́ni. Èrò mi ni pé táwọn èèyàn bá ti mọ̀ mí sírú èèyàn bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í wò mí bí ẹni ìríra téèyàn gbọ́dọ̀ sá fún.” Àmọ́ lẹ́yìn tí Sara tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí wá rẹ́ni tó ṣeé finú hàn, ó lóye ohun tí Bíbélì sọ nínú Òwe 18:24, pé: “Ọ̀rẹ́ kan wà tí ń fà mọ́ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ.” Ó sọ lẹ́yìn náà pé: “Pẹ̀lú gbogbo àlàyé tí mo ṣe fàwọn Kristẹni tí òye òtítọ́ yé lórí bí mo ṣe máa ń dọ́gbẹ́ síra mi lára, wọn ò pẹ̀gàn mi rí. Dípò ìyẹn, ṣe ni wọ́n fún mi ní àwọn àbá tó wúlò. Wọ́n fi Ìwé Mímọ́ tọ́ mi sọ́nà, wọn ò sì jẹ́ kó sú wọn láti máa fi mí lọ́kàn balẹ̀ nígbà tí mo bá rẹ̀wẹ̀sì tó sì ń ṣe mí bíi pé mi ò já mọ́ ohunkóhun.”

O ò ṣe wá ẹnì kan sọ ìṣòro dídọ́gbẹ́ síra ẹ lára yìí fún? Bí ojú bá ń tì ẹ́ láti sọ ọ́ síta, o ò ṣe kúkú kọ ọ́ sí lẹ́tà tàbí kó o bá onítọ̀hún sọ ọ́ lórí tẹlifóònù. Bó o bá lè finú han ẹnì kan, o lè tipa bẹ́ẹ̀ rí ọ̀nà àbáyọ. Jennifer sọ pé: “Ohun tó ṣe pàtàkì ni mímọ̀ pé ẹnì kan fi mí sọ́kàn, pé ẹnì kan wà tí mo lè ro ohun tó ń dùn mí lọ́kàn fún nígbà tí nǹkan bá tojú sú mi.”c

Ìdí Tí Àdúrà Fi Ṣe Pàtàkì

Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Donna gungi ré kọjá ewé. Èrò kan sọ sí i lọ́kàn pé Ọlọ́run lè bá òun ṣe é. Èrò míì tó ń sọ sí i lọ́kàn ni pé Ọlọ́run ò ní ran òun lọ́wọ́ láìjẹ́ pé òun kọ́kọ́ ṣíwọ́ dídọ́gbẹ́ síra òun lára. Báwo ni Donna ṣe wá rọ́nà gbé e gbà? Ọ̀kan lára ohun tó ràn án lọ́wọ́ ni ṣíṣàṣàrò lórí 1 Kíróníkà 29:17, èyí tó pe Jèhófà Ọlọ́run ní “olùṣàyẹ̀wò ọkàn-àyà.” Donna sọ pé, “Jèhófà mọ pé nínú ọkàn mi lọ́hùn-ún, ó wù mí kí n dẹ́kun dídọ́gbẹ́ síra mi lára. Lẹ́yìn tí mo ti ń gbàdúrà pé kó ràn mí lọ́wọ́, ohun tó wá ṣẹlẹ̀ yà mí lẹ́nu. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ni mo dẹni tí ò dọ́gbẹ́ síra mi lára mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu tí mo ṣe.”

Onísáàmù náà Dáfídì, tó dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro, sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, Òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.” (Sáàmù 55:22) Láìsí àníàní, Jèhófà mọ ìṣòro tó ò ń fara rọ́. Pabanbarì rẹ̀ wá ni pé “ó bìkítà fún [ọ]” (1 Pétérù 5:7) Bí èrò kan bá ń sọ sí ọ lọ́kàn pé o ò já mọ́ nǹkan kan, rántí pé Ọlọ́run ‘tóbi ju ọkàn-àyà rẹ lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.’ Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, ó mọ ohun tó jẹ́ kó o máa dọ́gbẹ́ síra ẹ lára kò sì ṣàìmọ ohun tó jẹ́ kó nira fún ọ láti ṣíwọ́. (1 Jòhánù 3:19, 20) Bó o bá tọ̀ ọ́ lọ nípasẹ̀ àdúrà tó o sì sapá láti borí àṣà yìí, ó máa “ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́.”—Aísáyà 41:10.

Ká wá ní gbogbo bó o ṣe sapá tó, ó ṣì ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o máa dọ́gbẹ́ síra ẹ lára ńkọ́? Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé o ò lè ṣàṣeyọrí ni? Kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀! Òwe 24:16 sọ pé: “Olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje pàápàá, yóò sì dìde dájúdájú.” Nígbà tí Donna ń sọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ Bíbélì yẹn, ó ní: “Iye ìgbà témi ṣubú tiẹ̀ ju méje lọ, àmọ́ mi ò sọ̀rètí nù.” Ohun pàtàkì tí Donna wá mọ̀ ni pé, èèyàn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó sú òun. Ohun tí Karen náà sọ nìyẹn, ó ní: “Mo wá mọ̀ pé láwọn ìgbà tí mo bá tún ń dọ́gbẹ́ síra mi lára, ó wá bẹ́ẹ̀ ni mo ṣì máa borí ẹ̀. Kì í ṣe pé mo kùnà, mo kàn ní láti máa gba ara mi lọ́wọ́ àṣà náà lágbàtúngbà ni.”

Ohun Tó O Lè Ṣe Bó O Bá Nílò Ìrànlọ́wọ́ Sí I

Jésù alára mọ̀ pé ‘àwọn tí kò lókun ló nílò oníṣègùn.’ (Máàkù 2:17) Nínú irú ipò báyìí, ó yẹ kéèyàn kàn sí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tó bá tóótun tó lè mọ̀ bóyá ó lọ́wọ́ ìṣiṣẹ́gbòdì ọpọlọ nínú, àti irú ìtọ́jú tó yẹ.d Jennifer pinnu láti gba irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ mọ́ ìrànlọ́wọ́ táwọn alábòójútó onífẹ̀ẹ́ nínú ìjọ fún un. Ó sọ pé: “Àwọn alàgbà kì í ṣe dókítà, àmọ́ wọ́n ṣe bẹbẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì máa ń ṣe mí bíi kí n dọ́gbẹ́ síra mi lára lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, síbẹ̀ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ìtìlẹyìn ìjọ àtàwọn ìmọ̀ràn lónírúurú tí mo ti gbà láti lè kojú rẹ̀, ó ti ṣeé ṣe fún mi láti borí àṣà náà.”e

Gbà pé wàá rí nǹkan míì tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní tí wàá máa ṣe láti máa gbé ìṣòro rẹ kúrò lọ́kàn. Gbàdúrà bíi ti onísáàmù náà, ẹni tó sọ pe: “Fi àwọn ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nínú àsọjáde rẹ, kí nǹkan kan tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́ má sì jẹ gàba lé mi lórí.” (Sáàmù 119:133) Ó dájú pé wàá padà nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, wàá sì padà máa níyì lójú ara rẹ nígbà tó o bá lè gba ara ẹ lọ́wọ́ àṣà yìí tó ò sì jẹ́ kó jẹ gàba lé ọ lórí mọ́.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

b Fún àlàyé síwájú sí i nípa dídọ́gbẹ́ síra ẹni lára àti ohun tó máa ń sún àwọn èèyàn sí i—wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Kí Nìdí Tí Mo Fi Ń Dọ́gbẹ́ Síra Mi Lára?” nínú ìtẹ̀jáde Jí! ti January–March 2006.

c Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, o lè gbìyànjú kó o kọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ sílẹ̀. Èèyàn tó mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára làwọn òǹkọ̀wé Sáàmù tó wà nínú Bíbélì, ìyẹn ni wọ́n ṣe mọ àwọn ọ̀rọ̀ tó yẹ láti lò nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa àbámọ̀, ìbínú, ìjákulẹ̀ àti ìbànújẹ́. Bí àpẹẹrẹ, o ò ṣe ṣàyẹ̀wò Sáàmù orí 6, 13, 42, 55, àti 69.

d Lọ́pọ̀ ìgbà dídọ́gbẹ́ síra ẹni lára jẹ́ àtúbọ̀tán àwọn ìṣòro mìíràn bí àárẹ̀ ọkàn, ìṣòro híhùwà lódìlódì, àìlèṣàkóso ìrònú àti ìṣesí ẹni tàbí ìṣòro àìlèjẹun dáadáa. Jí! ò sọ pé irú ìtọ́jú kan pàtó ló dara láti gbà o. Àwọn Kristẹni ní láti rí i dájú pé irú ìtọ́jú èyíkéyìí tí wọ́n bá fẹ́ láti gbà kò ta ko ìlànà Bíbélì.

e Àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àwọn ohun tó máa ń fa dídọ́gbẹ́ síra ẹni lára wà nínú àwọn Jí! tá a ti tẹ̀ nígbà kan. Bí àpẹẹrẹ, wo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Lílóye Àwọn Tí Ìṣesí Wọn Ṣàdédé Ń Yí Padà” (January 8, 2004), “Ìrànwọ́ fún Àwọn Èwe Tó Sorí Kọ́” (September 8, 2001), àti èyí tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ń fa ìṣòro àìjẹun dáadáa tó wà nínú Jí! January 22, 1999, lédè Gẹ̀ẹ́sì, tó fi mọ́ àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Obi Onimukumu-ọti kan—Bawo Ni Mo Ṣe Lè Koju Rẹ̀?” (August 8, 1992).

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

◼ Kí làwọn nǹkan míì tó o lè ṣe dípò dídọ́gbẹ́ síra ẹ lára nígbà tó o bá ní àárẹ̀ ọkàn?

◼ Ta ló yẹ kó o finú hàn bó o bá níṣòro dídọ́gbẹ́ sára?

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

BÓ O ṢE LÈ RAN ẸNI TÓ Ń DỌ́GBẸ́ SÍRA Ẹ̀ LÁRA LỌ́WỌ́

Báwo lo ṣe máa ran aráalé rẹ tàbí ọ̀rẹ́ rẹ kan tó ní ìṣòro dídọ́gbẹ́ síra ẹni lára lọ́wọ́? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹni tó níṣòro náà máa nílò ẹni tó lè finú hàn, o lè jẹ́ kó mọ̀ pé wàá gbọ́ tiẹ̀. Gbìyànjú láti jẹ́ “alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ . . . tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Òótọ́ ni pé, ohun tó bá sọ lè da jìnnìjìnnì bò ẹ́ débi tí wàá fi fẹ́ kó ṣíwọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Àmọ́ tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí ẹni tó níṣòro yẹn sá fún ọ. Yàtọ̀ síyẹn, sísọ fónítọ̀hún pé kó ṣíwọ́ nìkan kò tó o. Ó gba òye láti mú kí ẹni tó ń dọ́gbẹ́ síra ẹ̀ lára gbìyànjú àwọn ọ̀nà mìíràn láti kojú ìṣòro náà. (Òwe 16:23) Ó sì tún máa gba àkókò. Nítorí náà, pẹ̀lẹ́ pẹ̀lẹ́ dọwọ́ ẹ o. Jẹ́ ẹni tó ń “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́,” àmọ́ “lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.”—Jákọ́bù 1:19.

Bó bá jẹ́ ọ̀dọ́ ni ẹ́, má ṣe rò pé wàá lè dá ran ẹni tó ń dọ́gbẹ́ síra ẹ̀ lára lọ́wọ́ o. Rántí pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìṣòro kan tó fara sin ló fà á tàbí kó jẹ́ àrùn kan tó nílò ìtọ́jú ni. Bákan náà, dídọ́gbẹ́ síra ẹni lára lè wu ẹ̀mí léwu kódà kí ẹni tó ń dọ́gbẹ́ síra ẹ̀ lára tiẹ̀ máà lérò àtipara ẹ̀. Nítorí náà, ohun tó máa bọ́gbọ́n mu jù ni pé kó o rọ ẹni tó ń dọ́gbẹ́ síra ẹ̀ lára yẹn pé kó fọ̀rọ̀ ọ̀hún tó àgbàlagbà kan tó ní làákàyè tó sì nífẹ̀ẹ́ létí.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Má ṣe fojú kéré àǹfààní tó wà nínú fífinú han èèyàn ẹ kan, má sì ṣe kóyán ipa pàtàkì tí àdúrà lè kó kéré

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́