ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/09 ojú ìwé 6-8
  • Ìbùkún Tó Ju Ọrọ̀ Lọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbùkún Tó Ju Ọrọ̀ Lọ
  • Jí!—2009
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀kọ́ Líle Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Kọ́
  • Bá A Ṣe Lè Rí Ìbùkún Àìnípẹ̀kun Gbà
  • Ọrọ̀ Ha Lè Mú Ọ Láyọ̀ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ayọ̀—Ó Ti Dàléèbá Pátápátá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ojúlówó Aásìkí Ń Bọ̀ Nínú Ayé Tuntun ti Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àwọn Èèyàn Ń Wá Ohun Tó Máa Fún Wọn Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Jí!—2009
g 4/09 ojú ìwé 6-8

Ìbùkún Tó Ju Ọrọ̀ Lọ

IṢẸ́ agbaninímọ̀ràn ni Ọ̀gbẹ́ni Jon ń ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó sì ń rówó púpọ̀ nídìí ẹ̀. Kódà, nígbà tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, kò síbi tí kì í rìnrìn àjò dé, ó sì ni owó gidi lọ́wọ́. Òun àti ìyàwó rẹ̀ ń gbélé tó dáa, wọ́n sì ń gbádùn ara wọn. Lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, inú ìgbádùn kẹlẹlẹ ni wọ́n wà.

Tún gbé ọ̀ràn míì yẹ̀ wò. Láàárín ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] èèyàn tó ń wáṣẹ́, Kostasa jẹ́ ọ̀kan lára ìwọ̀nba ọgọ́rin [80] èèyàn tí wọ́n gbà síṣẹ́ ní báńkì kan tó lókìkí nílẹ̀ Yúróòpù. Láàárín ọdún díẹ̀, ó tún rí ọ̀pọ̀ iṣẹ́ míì tó dáa ṣe, kò sì pẹ́ tó fi dọ̀gá ní ẹ̀ka báńkì mìíràn. Nígbà tó fiṣẹ́ yẹn sílẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tara ẹ̀, owó tó ń wọlé fún un lọ́dún ju iye tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń rí ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn. Ìbùkún ńláǹlà ló kà á sí.

Síbẹ̀, àwọn ọkùnrin méjèèjì yìí gbà pé àwọn ìbùkún kan ṣì tún wà tó ju ọrọ̀ lọ. Bí àpẹẹrẹ, ohun tí Jon ń ṣe báyìí ni pé ó yọ̀ǹda ara ẹ̀ láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Jon sọ pé: “Èmi fúnra mi ti rí i, mo sì ti mọ̀ pé ọrọ̀ tara kì í fúnni láyọ̀. Kìràkìtà àtilówó lọ́wọ́, kéèyàn sì tún máa ní àníkún owó, kì í jẹ́ kéèyàn ráyè ṣe àwọn nǹkan míì. Ẹ̀wẹ̀, béèyàn bá ń fàwọn ìlànà Bíbélì sílò, ọ̀pọ̀ ìbùkún ló máa tìdí ẹ̀ wá, bíi kí ìgbéyàwó ẹni túbọ̀ láyọ̀, kéèyàn ní ìbàlẹ̀ ọkàn, kéèyàn sì ní ẹ̀rí ọkàn rere.”

Kostas pẹ̀lú sọ pé: “Ọlọ́run ò fẹ́ ká máa gbé ìgbé ayé yàlà yòlò. Ó dá mi lójú gbangba pé bó bá fún wa ní ohunkóhun, àwa pẹ̀lú wà lábẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti lò ó ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀.” Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, Kostas àti ìdílé rẹ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè míì kí wọ́n bàa lè kọ́ àwọn èèyàn púpọ̀ sí i láwọn ìlànà Bíbélì. Ó sọ pé, “A tí kẹ́kọ̀ọ́ pé fífúnni máa ń mú kéèyàn láyọ̀ ju rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

Ká sòótọ́, Jon àti Kostas ti kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn ìbùkún tẹ̀mí ṣe pàtàkì gan-an ju ọrọ̀ tara lọ. Ọ̀jọ̀gbọ́n Daniel Gilbert, ti ilé ìwé gíga Harvard, kíyè sí i pé àwọn ògbógi onímọ̀ nípa ìtọ́jú ọpọlọ “ti lo ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún láti fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ àjọṣe tó wà láàárín ọrọ̀ àti ayọ̀, wọ́n sì ti parí ẹ̀ sí pé ọrọ̀ máa ń pa kún ayọ̀ ẹ̀dá nígbà tó bá sọ òtòṣì paraku di ọlọ́rọ̀.” Lẹ́yìn náà ló wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, “Àmọ́, agbára káká ló fi ń mú kí ayọ̀ pọ̀ sí i.”

Ẹ̀kọ́ Líle Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Kọ́

Ẹnì kan tó fara balẹ̀ kíyè sí bí nǹkan ṣe ń lọ sọ pé, “gbàrà téèyàn bá ti kúrò nípò òṣì, àníkún owó kì í fi bẹ́ẹ̀ fúnni láyọ̀.” Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, oníròyìn kan kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì yìí nígbà tó ń fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu Andrew Carnegie, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó dá ilé iṣẹ́ irin sílẹ̀ àti ọ̀kan lára àwọn tó lówó jù lọ lágbàáyé nígbà yẹn. Carnegie sọ fún un pé: “Kò yẹ káwọn èèyàn máa jowú mi. Báwo ni ọrọ̀ tí mo ní ṣe lè ràn mí lọ́wọ́? Ọmọ ọgọ́ta [60] ọdún ni mí, oúnjẹ kì í sì í dà nínú mi. Ká ní ó ṣeé ṣe kí n pa dà di ọ̀dọ́ kí n sì ní ìlera tó dáa, mo ṣe tán láti kó gbogbo owó mi sílẹ̀.”

Oníròyìn náà wá fi kún un pé: “Ọ̀gbẹ́ni Carnegie wá yí pa dà bìrí, ó fohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn tó kọjá sísọ ṣàlàyé pé: ‘Mo ṣe tán láti ta gbogbo ohun tí mo ní kí n lè tún ayé mi gbé.’” Ọ̀gbẹ́ni J. Paul Getty, èèkàn nídìí iṣẹ́ epo rọ̀bì, tóun náà lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, gbà pẹ̀lú ohun tó sọ yìí nígbà tó yá. Ó sọ pé: “Bí ohun kan bá wà tówó ń mú wá, ó lè jẹ́ àìláyọ̀, àmọ́ kì í ṣe ayọ̀.”

Ìwọ náà lè gbà pẹ̀lú òǹkọ̀wé Bíbélì tó bẹ Ọlọ́run pé: “Má ṣe fún mi ní ipò òṣì tàbí ti ọrọ̀. Jẹ́ kí n jẹ ìwọ̀n oúnjẹ tí ó jẹ́ ìpín tèmi, kí n má bàa yó tán kí n sì sẹ́ ọ ní ti tòótọ́, kí n sì wí pé: ‘Ta ni Jèhófà?’ kí n má sì di òtòṣì kí n sì jalè ní ti tòótọ́ kí n sì kọjú ìjà sí orúkọ Ọlọ́run mi.”—Òwe 30:8, 9.

Ọba Sólómọ́nì ti Ísírẹ́lì ìgbàanì ṣàlàyé pé: “Mo tóbi, mo sì pọ̀ sí i ju ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ pé ó wà ṣáájú mi ní Jerúsálẹ́mù.” Síbẹ̀, ó fi kún un pé: “Asán ni gbogbo rẹ̀ àti lílépa ẹ̀fúùfù.” Sólómọ́nì tún sọ pé: “Ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.”—Oníwàásù 2:9-11; 5:12, 13; Òwe 10:22.

Bá A Ṣe Lè Rí Ìbùkún Àìnípẹ̀kun Gbà

Ó dájú pé ìgbà tá a bá ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run nìkan la tó lè ní ojúlówó ayọ̀ tó máa tọ́jọ́. Bá a bá fi ti Ọlọ́run ṣáájú, a máa rí i pé gbogbo apá ìgbésí ayé wa ló máa túbọ̀ nítumọ̀ tó sì máa ṣe wá láǹfààní.

Ó yẹ ká máa dúpẹ́ pé kì í ṣe títí ayé la ó máa ṣàníyàn nípa owó. Bíbélì mú kó dá wa lójú pé ọjọ́ kan ń bọ̀ wá jọ́kan tí ètò ìṣòwò tó jẹ́ oníwọra tó sì ń múni sìn á di àfẹ́kù pátápátá. (1 Jòhánù 2:15-17) Lẹ́yìn náà ni ètò àwọn nǹkan tuntun ti Ọlọ́run máa wọlé dé, àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run lá sì máa darí rẹ̀. Ọlọ́run máa sọ ayé di Párádísè bó ti fẹ́ kó rí ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, nígbà tó fi tọkọtaya àkọ́kọ́ síbẹ̀. Ìbùkún ńlá gbáà ló máa jẹ́ nígbà tí ayọ̀, àlàáfíà àti ìfẹ́ bá jọba kárí ayé!—Aísáyà 2:2-4; 2 Pétérù 3:13; 1 Jòhánù 4:8-11.

Nígbà yẹn, ayé ò ní máa sú èèyàn láti gbé. Ìbùkún tara á tún kún àjọṣe rere tá a bá ti ní pẹ̀lú Ọlọ́run nígbà tí aráyé bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé títí láé nínú Párádísè gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ó dájú pé gbogbo èèyàn máa ní ànító oúnjẹ, ibùgbé àti iṣẹ́ tó gbádùn mọ́ni. Òṣì á sì ti kásẹ̀ nílẹ̀ pátápátá.—Sáàmù 72:16; Aísáyà 65:21-23; Míkà 4:4.

Gbogbo ẹni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, Ọlọ́run tó mí sí Bíbélì, kò ní pòfo. (Róòmù 10:11-13) Torí náà, ẹ wo bó ti bọ́gbọ́n mu tó láti máa lépa àwọn ìbùkún tó pọ̀ ju owó lọ!—1 Tímótì 6:6-10.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orúkọ rẹ̀ gan-an kọ́ nìyí.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]

Bá a bá ń fi ti Ọlọ́run ṣáájú, ayé wa á dùn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Béèyàn ò bá náwó ní ìnákúnàá, ó máa túbọ̀ gbádùn ayé ẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́