Kí Ni Ìwọ Ń Fẹ́ Kó Dáa?
Èwo nínú àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní ayé yìí ló máa ń dun ìwọ jù?
EBI
ÀÌLÓWÓ LỌ́WỌ́
ÀRÙN
ÌWÀ Ọ̀DARÀN
ÌRẸ́JẸ
OGUN
ÌBÀYÍKÁJẸ́
Ẹ̀TANÚ
Èwo nínú àwọn àyípadà rere yìí ló wu ìwọ jù?
KÍ ÀLÀÁFÍÀ JỌBA LÁÀÁRÍN ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ
KÍ ÈTÒ ÌLERA DÁA, KÓ MÁ SÌ WỌ́N
KÍ Ẹ̀TANÚ DÓPIN
KÍ OÚNJẸ ÀTI OMI MÍMU PỌ̀ DÁADÁA
KÍ ÀÀBÒ TÓ PÉYE WÀ NÍBI GBOGBO
KÍ ÀYÍKÁ MỌ́ TÓNÍTÓNÍ
KÍ ÌWÀ ÌRẸ́JẸ DÓPIN
Ǹjẹ́ o rò pé ayé yìí ṣì máa dáa bó o ṣe fẹ́ kó rí? Àwọn kan lè sọ pé ọwọ́ àwọn ìjọba ló wà. Ǹjẹ́ àwọn ìjọba lè bá wa tún ayé yìí ṣe? Kí làwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ti fi hàn?