ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w11 10/1 ojú ìwé 6
  • 3 Ọlọ́run Kì Í Dárí Jini—Ṣé Òótọ́ Ni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 3 Ọlọ́run Kì Í Dárí Jini—Ṣé Òótọ́ Ni?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Fa Àwọn Ìjábá Láti Máa Fi Jẹ Àwa Èèyàn Níyà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ṣé Ọlọ́run Máa Finá Sun Àwọn Èèyàn Búburú ní Ọ̀run Àpáàdì?
    Jí!—2009
  • Àjálù—Kí Nìdí Tó Fi Pọ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
w11 10/1 ojú ìwé 6

3 Ọlọ́run Kì Í Dárí Jini​—Ṣé Òótọ́ Ni?

Ohun táwọn èèyàn ń sọ: “Ọlọ́run máa ń ṣàkọsílẹ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn dá, á sì fi ìyà rẹ̀ jẹ wọ́n títí láé nínú iná ọ̀run àpáàdì.”

“Ọlọ́run máa ń mú kí àjálù dé bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ láti fi jẹ wọ́n níyà.”

Ohun tí Bíbélì kọ́ni: Ìwé 2 Pétérù 3:9 sọ pé, Jèhófà “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” Kàkà kí Ọlọ́run máa fiyè sí àwọn àṣìṣe wa, ibi tá a dára sí ló máa ń wò. “Ojú [Ọlọ́run] ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.”—2 Kíróníkà 16:9.

Bíbélì kò kọ́ni pé ọ̀run àpáàdì wà. Ẹ̀kọ́ náà pé àwọn èèyàn á máa joró títí láé nínú iná jẹ́ ohun tó burú gan-an lójú Ọlọ́run. Ìyà tó ga jù lọ tí Ọlọ́run máa fi jẹ àwọn èèyàn búburú ni pé, ó máa pa wọ́n. (Jeremáyà 7:31; Róòmù 6:7) Àwọn àjálù tí àwọn ohun àdáyébá ń fà máa ń pa gbogbo nǹkan run láìfi ìyàtọ̀ sí wọn, kì í sì í ṣe àmúwá Ọlọ́run, ńṣe ni wọ́n jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ tó lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni.—Oníwàásù 9:11.

Bí mímọ òtítọ́ ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Mímọ̀ tá a mọ̀ pé Ọlọ́run “ṣe tán láti dárí jini” tí kì í sì í tètè dáni lẹ́bi máa mú kí á sún mọ́ ọn. (Sáàmù 86:5) A kò ní láti máa sin Ọlọ́run nítorí ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì pé tí a kò bá jọ́sìn rẹ̀ ó máa fi ìyà jẹ wá tàbí nítorí kí ẹ̀rí ọkàn wa má bàa dá wa lẹ́bi pé a kò jọ́sìn rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó dára jù lọ tí ó yẹ kó mú ká ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà ni ìfẹ́ tá a ní fún un. Irú ìfẹ́ yìí á máa fún wa ní okun tí á mú kí a máa ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti wù ú.—Mátíù 22:36-38; 1 Jòhánù 5:3.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo èèyàn máa ṣe ohun tó dára, ó mọ̀ pé ọ̀pọ̀ kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Tí Ọlọ́run kò bá fìyà jẹ àwọn tí wọ́n ti pinnu pé ibi làwọn á máa ṣe, á jẹ́ pé kò yàtọ̀ sí olùṣàkóso kan tó ṣe òfin àmọ́ tí kò lo òfin náà, tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí àìṣẹ̀tọ́ àti ìjìyà máa báa lọ bẹ́ẹ̀. (Oníwàásù 8:11) Mímọ̀ tá a mọ̀ pé Ọlọ́run kò ní fàyè gba ìwà ibi títí láé mú ká ní ìrètí tó dájú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Ọlọ́run ti ṣèlérí pé òun á mú àwọn tí kò jáwọ́ nínú ìwà ibi kúrò kí “àwọn ọlọ́kàn tútù” lè gbádùn ìyè ayérayé lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ohun tó ní lọ́kàn nígbà tó dá ayé.—Sáàmù 37:10, 11, 29.a

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Láti lè mọ púpọ̀ sí i nípa bí Ọlọ́run ṣe máa sọ ayé di Párádísè, ka orí 3 àti 8 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

Ṣé Ọlọ́run ń fẹ́ ká máa jọ́sìn òun nítorí ìbẹ̀rù pé kó má bàa fìyà jẹ wá?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwòrán tí Doré yà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́