Bí Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Lákòókò Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì—Àwọn Olórin àti Àwọn Ohun Èlò Ìkọrin
“Ẹ fi ìwo fífun yìn [Ọlọ́run]. Ẹ fi ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù yìn ín. Ẹ fi ìlù tanboríìnì àti ijó àjóyípo yìn ín. Ẹ fi àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti fèrè ape yìn ín. Ẹ fi àwọn aro tí ó ní ìró orin atunilára yìn ín. Ẹ fi àwọn aro tí ń dún gooro yìn ín.”—SÁÀMÙ 150:3-5.
LÁTI ọjọ́ pípẹ́ ni orin àtàwọn olórin ti ń kó ipa pàtàkì nínú ìjọsìn Jèhófà Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò nínú Òkun Pupa lọ́nà ìyanu, Míríámù tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Mósè ṣáájú àwọn obìnrin nínú orin ìṣẹ́gun àti ijó. Àwọn èèyàn náà ń lu ìlù tanboríìnì, wọ́n sì ń jó. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí fi bí orin ti ṣe pàtàkì tó lójú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì hàn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Íjíbítì, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ lára àwọn obìnrin wọn mú àwọn ohun èlò ìkọrin lọ́wọ́, wọ́n sì ṣe tán láti fi wọ́n kọrin. (Ẹ́kísódù 15:20) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Dáfídì Ọba ṣètò fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún akọrin láti máa lo àwọn ohun èlò ìkọrin wọn gẹ́gẹ́ bí apá kan ìjọsìn ní tẹ́ńpìlì tí ọmọ rẹ̀ Sólómọ́nì kọ́.—1 Kíróníkà 23:5.
Kí ni wọ́n fi ṣe àwọn ohun èlò ìkọrin wọ̀nyẹn? Báwo ni wọ́n ṣe rí? Irú ìró wo ni wọ́n ń mú jáde? Ìgbà wo ni wọ́n sì máa ń lò wọ́n?
Oríṣiríṣi Ohun Èlò Ìkọrin
Àwọn nǹkan tí wọ́n fi ṣe àwọn ohun èlò ìkọrin tó wà nínú Bíbélì ni igi iyebíye, awọ ẹran, irin àti egungun. Wọ́n fi eyín erin dárà sí àwọn kan lára. Okùn igi tàbí ìfun ẹran ni wọ́n fi ṣe àwọn okùn tín-ín-rín. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kò sí ohun èlò ìkọrin ayé àtijọ́ tó ṣì wà títí di ìsinsìnyí, àmọ́ àwòrán wọ́n ṣì wà.
A lè pín àwọn ohun èlò ìkọrin tí wọ́n ń lò lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì sí oríṣi mẹ́ta: ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín, irú bíi háàpù, lírè (lyre, ní èdè Gẹ̀ẹ́sì) (1), àti gòjé (2); ohun èlò ìkọrin tí wọ́n ń fọn, irú bí ìwo tàbí ṣófà (3), kàkàkí (4), ohun èlò ìkọrin kan táwọn èèyàn fẹ́ràn gan-an ni fèrè tàbí fèrè ape (5); ohun èlò ìkọrin tí wọ́n máa ń lù, irú bí ìlù tanboríìnì (6), sítírọ́mù (7), àwọn aro (8), àti agogo (9). Àwọn olórin máa ń lo àwọn ohun èlò ìkọrin wọ̀nyí sí ewì, sí ijó àti sí orin. (1 Sámúẹ́lì 18:6, 7) Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé wọ́n máa ń fi wọ́n jọ́sìn Ọlọ́run tó fi ẹ̀bùn orin jíǹkí wọn. (1 Kíróníkà 15:16) Ẹ jẹ́ ká ṣàlàyé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ohun èlò ìkọrin tí a pín sí oríṣi mẹ́ta yìí.
Ohun Èlò Ìkọrin Olókùn Tín-ín-rín Háàpù àti lírè jẹ́ ohun èlò tó fúyẹ́, tí wọ́n sì ṣeé gbé káàkiri, wọ́n ní àwọn okùn tín-ín-rín tí a so mọ́ férémù igi. Dáfídì fi ọwọ́ ta ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín kan tó mú ara tu Sọ́ọ̀lù Ọba tí ìdààmú bá. (1 Sámúẹ́lì 16:23) Ẹgbẹ́ olórin lo àwọn ohun èlò ìkọrin wọ̀nyí ní ibi ayẹyẹ ṣíṣí tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì àti ní àwọn ibi ayẹyẹ míì, irú bíi nígbà àwọn àjọyọ̀.—2 Kíróníkà 5:12; 9:11.
Ìrísí gòjé yàtọ̀ sí ti háàpù. Ó sábà máa ń ní okùn tín-ín-rín mélòó kan tí wọ́n so mọ́ igi gbọọrọ tó ní férémù rùbùtù nísàlẹ̀. Nígbà tí okùn rẹ̀ bá ń gbọ̀n, ó lè mú ìró atunilára jáde, èyí tó jọ ti gìtá òde òní. Okùn igi tàbí ìfun ẹran ni wọ́n fi ṣe àwọn okùn tín-ín-rín rẹ̀.
Ohun Èlò Ìkọrin Tí Wọ́n Ń Fọn Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Bíbélì mẹ́nu kan àwọn ohun èlò ìkọrin tí wọ́n ń fọn. Ọ̀kan lára àwọn tó ti pẹ́ jù lọ ni ìwo àwọn Júù tá a mọ̀ sí ṣófà. Ìwo àgbò ni, ó ní ihò tó máa ń mú ìró gooro jáde. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń lo ṣófà láti fi kó àwọn ọmọ ogun jọ lójú ogun, wọ́n sì tún máa ń lò ó láti mú kí orílẹ̀-èdè náà lápapọ̀ mọ ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe lákòókò kan pàtó.—Onídàájọ́ 3:27; 7:22.
Ohun èlò ìkọrin míì tí wọ́n ń fọn ni kàkàkí tí á fí irin ṣe. Àkọsílẹ̀ kan tí a rí láàárín Àkájọ Ìwé Òkun Òkú fi hàn pé àwọn olórin lè fi àwọn ohun èlò ìkọrin yìí mú onírúurú ìró jáde lọ́nà tó kàmàmà. Jèhófà sọ fún Mósè pé kó ṣe kàkàkí fàdákà méjì tí wọ́n á máa lò ní àgọ́ ìjọsìn. (Númérì 10:2-7) Lẹ́yìn náà, ní ibi ayẹyẹ ṣíṣí tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì, ọgọ́fà [120] kàkàkí tí ó ń dún kíkankíkan ṣàlékún ohùn àjọyọ̀ náà. (2 Kíróníkà 5:12, 13) Àwọn oníṣẹ́ ọnà máa ń ṣe kàkàkí tí gígùn wọn yàtọ̀ síra. Àwọn kan gùn tó ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ta (91 sẹ̀ǹtímítà) tí ìdí rẹ̀ rí tẹ́ẹ́rẹ́ ẹnu rẹ̀ sì rí bí agogo.
Èyí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ràn jù nínú wọn ni fèrè. Ohùn fèrè tó ń múnú ẹni dùn, tó sì ń túni lára máa ń mú ara àwọn èèyàn yá gágá nígbà tí ìdílé bá kóra jọ, nígbà àsè àti nígbà ìgbéyàwó. (1 Àwọn Ọba 1:40; Aísáyà 30:29) Wọ́n tún lè fi fèrè fọn ohùn arò ní ibi ìsìnkú, níbi táwọn olórin ti máa ń kọ orin gẹ́gẹ́ bí apá kan ọ̀fọ̀ òkú (wo ojú ìwé 14).—Mátíù 9:23.
Ohun Èlò Ìkọrin Tí Wọ́n Máa Ń Lù Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ń ṣayẹyẹ, wọ́n máa ń lo oríṣiríṣi ohun èlò ìkọrin tí wọ́n máa ń lù. Ìró wọn tó ń dún ní àdún-tẹ̀léra máa ń mú orí ẹni wú. Ìlù tanboríìnì jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Wọ́n fi férémù igi roboto tí wọ́n fi awọ ẹran bò ṣe é, ó máa ń mú ìró tó ń dún bí ìlù jáde bí olórin tàbí ẹni tó ń jó ṣe ń fọwọ́ lù ú. Nígbà tí olórin bá mi férémù náà, tí wọ́n fi àwọn ṣaworo sí létí, ńṣe ló máa ń dún woroworo.
Ohun èlò ìkọrin míì tí wọ́n máa ń lù ni sítírọ́mù. Ó jẹ́ irin fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó rí roboto bí ẹyin, ó ní kùkù gbọọrọ, àwọn irin gbọọrọ tó tún ní irin kéékèèké lára dábùú rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá mì ín, ó máa ń dún jinginjingin.
Àwọn aro tí a fi idẹ ṣe máa ń dún ju ìyẹn lọ. Aro rí bí àwo, ó sì jẹ́ oríṣi méjì. Wọ́n máa ń fi àwọn aro ńlá tí ń dún gooro gbá ara wọn ni. Àmọ́, àárín ọwọ́ ni wọ́n máa ń fi àwọn aro kékeré tó ní ìró atunilára sí nígbà tí wọ́n bá ń lò wọ́n. Aro kékeré àti ńlá máa ń mú ìró tí ń dún gooro jáde àmọ́ ọ̀kan máa ń pariwo ju èkejì lọ.—Sáàmù 150:5.
À Ń Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Wọn
Lóde òní, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fi orin àti ohùn orin bẹ̀rẹ̀ ìpàdé ìjọsìn wọn, wọ́n sì máa ń fi orin àti ohùn orin parí wọn. Ní àwọn àpéjọ wọn ńlá, àwọn olórin tí wọ́n ṣe orin tá a gbà sílẹ̀ máa ń lo àwọn ohun èlò ìkọrin tòde òní tó jẹ́ olókùn tín-ín-rín, ohun èlò ìkọrin tí wọ́n ń fọn àti ohun èlò ìkọrin tí wọ́n ń lù.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé àtijọ́ àtàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nípa lílo orin àti ohùn orin nínú ìjọsìn wọn. (Éfésù 5:19) Bíi ti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń dùn lónìí bí wọ́n ti ń fi ọ̀rọ̀ orin àti ohùn orin yin Jèhófà.
[Àwọn Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
(A kò lo ìdiwọ̀n láti fi ya àwọn ohun èlò ìkọrin tó wà níbí yìí)
(Wo ìtẹ̀jáde)