ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w12 10/1 ojú ìwé 15
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ta Ni Yóò La “Ọjọ́ Jèhófà” Já?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Àwọn Ọmọ Ogun Jèhófà
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpẹẹrẹ Ìfara-Ẹni-Rúbọ àti Ìdúróṣinṣin
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
w12 10/1 ojú ìwé 15

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ àwọn Kristẹni sá kúrò ní Jùdíà kí Jerúsálẹ́mù tó pa run lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni?

Jésù sọ pé: “Nígbà tí ẹ bá rí tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti sún mọ́lé. Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àárín rẹ̀ fi ibẹ̀ sílẹ̀.” (Lúùkù 21:20, 21) Ìtọ́ni tó fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nìyí nípa ìparun tí yóò dé bá Jerúsálẹ́mù. Ǹjẹ́ ẹ̀rí kankan tiẹ̀ wà pé wọ́n tẹ̀ lé ìkìlọ̀ tó fún wọn yìí?

Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ikú Jésù, ọ̀gágun kan tó ń jẹ́ Cestius Gallus kó àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Róòmù wá sí Palẹ́sínì láti wá paná ọ̀tẹ̀ tó wà níbẹ̀. Òpìtàn àwọn Júù tó ń jẹ́ Josephus, tó gbé ayé nígbà yẹn jẹ́rìí sí ogun yìí. Àwọn ọmọ ogun náà yí Jerúsálẹ́mù ká, ó sì dà bíi pé wọ́n máa ṣẹ́gun ìlú náà. Ṣàdédé ni Gallus pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ ogun náà kúrò níbẹ̀. Yùsíbíọ̀sì tó jẹ́ òpìtàn nípa ṣọ́ọ̀ṣì sọ pé àwọn Kristẹni tó wà ní Jùdíà lo àǹfààní yìí láti sá lọ sí ìlú Pẹ́là tó wà ní orí òkè kan ní àgbègbè Dekapólì.

Ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, ìyẹn ní ọdún 70 Sànmánì Kristẹni, ọ̀gágun kan ní ilẹ̀ Róòmù tó ń jẹ́ Titus, kó àwọn ọmọ ogun míì wá gbógun ti Jerúsálẹ́mù. Lọ́tẹ̀ yìí, àwọn ọmọ ogun yìí ṣe ohun tí Gallus kò ṣe, wọ́n pa ìlú náà run. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí wọ́n ká mọ́ Jerúsálẹ́mù ló kú.

Àwọn wo ni “àwọn ọmọ àwọn wòlíì”?

Ìtàn tí Bíbélì sọ nípa wòlíì Sámúẹ́lì, Èlíjà àti Èlíṣà mẹ́nu kan àwọn kan tí wọ́n pè ní “àwọn ọmọ àwọn wòlíì.” Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kan nínú “àwọn ọmọ àwọn wòlíì” ni Èlíṣà rán láti lọ fi òróró yan Jéhù gẹ́gẹ́ bí ọba Ísírẹ́lì.—2 Àwọn Ọba 9:1-4.

Àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì gbà pé kì í ṣe àwọn ọmọ tí àwọn wòlíì bí ni ọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n jẹ́ àwùjọ èèyàn kan tó ń gba ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ àwọn wòlíì tàbí àwùjọ èèyàn kan tó ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ tí wọ́n sì jọ ń gbé pọ̀. Ìwé Journal of Biblical Literature sọ pé ó ṣeé ṣe kí àwọn wọ̀nyí jẹ́ “àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìsìn Yahweh [ìyẹn Jèhófà], tí wọ́n sì wà lábẹ́ ìdarí wòlíì kan tó jẹ́ . . . baba wọn lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run.” (2 Àwọn Ọba 2:12) Nínú ìtàn bí wọ́n ṣe fi òróró yan Jéhù, “ẹmẹ̀wà wòlíì” ni Bíbélì pe aṣojú tí Èlíṣà rán lọ ṣe iṣẹ́ yẹn.—2 Àwọn Ọba 9:4.

Ó dà bíi pé ìgbé ayé tálákà ni “àwọn ọmọ àwọn wòlíì” ń gbé. Bíbélì fi hàn pé nígbà ayé Èlíṣà, ṣe ni ọ̀kan lára irú àwùjọ yìí kọ́ ibì kan tí wọ́n lè máa gbé fúnra wọn, àti pé wọ́n lọ yá àáké tí wọ́n lò ni. (2 Àwọn Ọba 6:1-5) Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn kan lára wọn ní ìyàwó, torí Bíbélì sọ pé opó kan jẹ́ aya ọ̀kan lára “àwọn ọmọ àwọn wòlíì.” (2 Àwọn Ọba 4:1) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ mọyì àwọn ọmọ àwọn wòlíì, torí ìtàn kan nínú Bíbélì fi hàn pé wọ́n kó àwọn ẹ̀bùn oúnjẹ wá fún wọn.—2 Àwọn Ọba 4:38, 42.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́