ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w21 June ojú ìwé 20-24
  • Má Ṣe Mú Kí “Àwọn Ẹni Kékeré Yìí” Kọsẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Má Ṣe Mú Kí “Àwọn Ẹni Kékeré Yìí” Kọsẹ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÀWỌN WO NI JÉSÙ PÈ NÍ “ẸNI KÉKERÉ YÌÍ”?
  • GBÀ PÉ ÀWỌN MÍÌ SÀN JÙ Ẹ́ LỌ
  • MÁA DÁRÍ JINI “LÁTỌKÀN WÁ”
  • MÁ ṢE JẸ́ KÍ ÌWÀ ÀWỌN MÍÌ MÚ Ẹ KỌSẸ̀
  • ‘Ẹ Máa Bá a Lọ Ní Dídáríji Ara Yín Lẹ́nì Kíní Kejì’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ẹ Máa Dárí Ji Ara Yín Fàlàlà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Máa Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kí Àlàáfíà àti Ìṣọ̀kan Wà Nínú Ìjọ
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Tó O Ní fún Jèhófà Àtàwọn Ará Túbọ̀ Jinlẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
w21 June ojú ìwé 20-24

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 25

Má Ṣe Mú Kí “Àwọn Ẹni Kékeré Yìí” Kọsẹ̀

“Ẹ rí i pé ẹ ò kẹ́gàn ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré yìí.”​—MÁT. 18:10.

ORIN 113 Àlàáfíà Tó Wà Láàárín Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa

1. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa?

BÍBÉLÌ sọ pé ṣe ni Jèhófà fa ẹnì kọ̀ọ̀kan wa wá sọ́dọ̀ ara ẹ̀. (Jòh. 6:44) Ẹ ronú ohun tíyẹn túmọ̀ sí. Jèhófà fara balẹ̀ kíyè sí gbogbo èèyàn tó wà láyé, ó sì kíyè sí i pé o lọ́kàn tó dáa àti pé o fẹ́ mọ òun. (1 Kíró. 28:9) Jèhófà mọ̀ ẹ́ dáadáa, ó lóye bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹ, ó sì nífẹ̀ẹ́ ẹ. Ẹ ò rí i pé ìyẹn fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an!

2. Àpèjúwe wo ni Jésù ṣe tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gan-an?

2 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ gan-an. Àmọ́ kì í ṣe ìwọ nìkan o, ó tún nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Ká lè lóye kókó yìí, Jésù fi Jèhófà wé olùṣọ́ àgùntàn. Tí àgùntàn kan bá sọ nù nínú ọgọ́rùn-ún àgùntàn, kí ni olùṣọ́ àgùntàn kan máa ṣe? Jésù sọ pé ‘ó máa fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) yòókù sílẹ̀ lórí òkè, á sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá èyí tó sọ nù.’ Tí olùṣọ́ àgùntàn náà bá ti rí i, kò ní bínú sí i kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lù ú. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ni inú ẹ̀ á dùn. Kí ni ẹ̀kọ́ ibẹ̀? Ẹ̀kọ́ náà ni pé gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan la ṣe pàtàkì sí Jèhófà. Jésù sọ pé: “Kò wu Baba mi tó wà ní ọ̀run pé kí ọ̀kan péré nínú àwọn ẹni kékeré yìí ṣègbé.”​—Mát. 18:12-14.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Ó dájú pé kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tó máa fẹ́ kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin wa. Kí la lè ṣe tá ò fi ní mú káwọn míì kọsẹ̀? Kí la sì lè ṣe tẹ́nì kan bá múnú bí wa? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí. Àmọ́ lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí Jésù pè ní “ẹni kékeré yìí” nínú Mátíù orí 18.

ÀWỌN WO NI JÉSÙ PÈ NÍ “ẸNI KÉKERÉ YÌÍ”?

4. Àwọn wo ni “ẹni kékeré yìí”?

4 Àwọn “ẹni kékeré yìí” ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Láìka ọjọ́ orí wọn sí, “ọmọdé” ni wọ́n torí pé wọ́n múra tán láti gba ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ Jésù. (Mát. 18:3) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ibi tí wọ́n ti wá, àṣà wọn àti ìwà wọn yàtọ̀ síra, gbogbo wọn ló nígbàgbọ́ nínú Jésù. Jésù náà sì nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an.​—Mát. 18:6; Jòh. 1:12.

5. Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tí ẹnì kan bá mú kí ọ̀kan nínú àwọn èèyàn rẹ̀ kọsẹ̀ tàbí tó hùwà àìdáa sí i?

5 Gbogbo àwọn “ẹni kékeré yìí” ló ṣeyebíye lójú Jèhófà. Ká lè lóye ọwọ́ tí Jèhófà fi mú wọn, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọdé ṣe máa ń rí lára wa. A nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, a sì máa ń fẹ́ dáàbò bò wọ́n torí pé wọn ò ní agbára, wọn ò nírìírí, wọn ò sì gbọ́n tó àwọn àgbàlagbà. Inú wa kì í dùn tí wọ́n bá hùwà àìdáa sẹ́nì kan kódà inú máa ń bí wa gan-an tó bá jẹ́ pé ọmọdé ni wọ́n hùwà àìdáa náà sí. Lọ́nà kan náà, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì máa ń dáàbò bò wá. Torí náà inú ẹ̀ kì í dùn, kódà inú máa ń bí i tí ẹnì kan bá mú kí ọ̀kan nínú àwọn èèyàn ẹ̀ kọsẹ̀ tàbí tó hùwà àìdáa sí i!​—Àìsá. 63:9; Máàkù 9:42.

6. Bó ṣe wà nínú 1 Kọ́ríńtì 1:26-29, ojú wo làwọn èèyàn fi ń wo àwa ọmọlẹ́yìn Jésù?

6 Ọ̀nà míì wo làwa ọmọlẹ́yìn Jésù gbà dà bí àwọn “ẹni kékeré”? Ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí ná. Àwọn wo làwọn èèyàn máa ń kà sí pàtàkì nínú ayé? Àwọn tó lówó, àwọn tó gbajúmọ̀ àtàwọn tó lẹ́nu láwùjọ. Àmọ́, àwa ọmọlẹ́yìn Jésù ò rí bẹ́ẹ̀. Torí náà, àwọn èèyàn máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú wa, wọ́n sì kà wá sí “ẹni kékeré.” (Ka 1 Kọ́ríńtì 1:26-29.) Síbẹ̀, kì í ṣe ojú tí Jèhófà fi ń wò wá nìyẹn.

7. Ojú wo ni Jèhófà fẹ́ ká máa fi wo àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin?

7 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀, yálà ọjọ́ pẹ́ tá a ti ń sìn ín àbí a ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Gbogbo àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ṣeyebíye lójú Jèhófà, torí náà, ó yẹ kí wọ́n ṣeyebíye lójú tiwa náà. Bíbélì sọ pé ká “nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ará,” kì í ṣe díẹ̀ lára wọn. (1 Pét. 2:17) Torí náà, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti dáàbò bò wọ́n ká sì bójú tó wọn. Tá a bá rí i pé a ṣẹ ẹnì kan, kò yẹ ká gbójú fò ó ká sì ronú pé nǹkan ti máa ń ká a lára jù. Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ fi máa ń tètè dun àwọn kan? Àwọn ará wa kan máa ń ronú pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan bóyá torí bí wọ́n ṣe tọ́ wọn dàgbà. Àwọn míì ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, kò sì rọrùn fún wọn láti gbójú fo kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn ará. Èyí ó wù kó jẹ́, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti rí i pé àlàáfíà wà láàárín wa. Bákan náà, ẹni tí ọ̀rọ̀ tètè máa ń dùn gbọ́dọ̀ mọ̀ pé kùdìẹ̀-kudiẹ kan ni òun ní, òun sì gbọ́dọ̀ sapá gan-an láti borí ẹ̀. Ó ṣe pàtàkì kó ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá fẹ́ kí ọkàn òun balẹ̀ kóun sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ará.

GBÀ PÉ ÀWỌN MÍÌ SÀN JÙ Ẹ́ LỌ

8. Èrò wo làwọn èèyàn ní nígbà ayé Jésù tó nípa lórí àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀?

8 Kí ló mú kí Jésù sọ̀rọ̀ nípa àwọn “ẹni kékeré yìí”? Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bi í pé: “Ní tòótọ́, ta ló tóbi jù lọ nínú Ìjọba ọ̀run?” (Mát. 18:1) Nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn Júù gbà pé ó ṣe pàtàkì káwọn wà nípò ọlá, káwọn sì lẹ́nu láwùjọ. Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé: “Ohun tó ṣe pàtàkì jù láyé àwọn èèyàn ni bí wọ́n á ṣe gbayì, tí wọ́n á gbajúmọ̀, tí wọ́n á sì lókìkí.”

9. Kí ló pọn dandan káwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣe?

9 Jésù mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló máa ń bá ara wọn díje, ó sì mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì káwọn ọmọlẹ́yìn òun sapá kí wọ́n lè fa ẹ̀mí burúkú yìí tu lọ́kàn wọn. Ó sọ fún wọn pé: “Kí ẹni tó tóbi jù láàárín yín dà bí ẹni tó kéré jù, kí ẹni tó jẹ́ aṣáájú sì dà bí ẹni tó ń ṣe ìránṣẹ́.” (Lúùkù 22:26) Tá a bá “gbà pé àwọn míì sàn jù” wá lọ, á rọrùn fún wa láti hùwà bí “ẹni tó kéré jù.” (Fílí. 2:3) Tá a bá ń sapá gan-an láti máa hùwà bí ẹni tó kéré jù, a ò ní mú àwọn míì kọsẹ̀.

10. Ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù wo ló yẹ ká fi sọ́kàn?

10 Gbogbo àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló sàn jù wá lọ lọ́nà kan tàbí òmíì. Ó máa rọrùn fún wa láti gbà bẹ́ẹ̀ tó bá jẹ́ pé ibi tí wọ́n dáa sí là ń wò. Ó ṣe pàtàkì ká fi ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Kọ́ríńtì sílò. Ó ní: “Ta ló mú ọ yàtọ̀ sí ẹlòmíràn? Ní tòótọ́, kí lo ní tí kì í ṣe pé o gbà á? Tó bá jẹ́ pé ńṣe lo gbà á lóòótọ́, kí ló dé tí ò ń fọ́nnu bíi pé kì í ṣe pé o gbà á?” (1 Kọ́r. 4:7) Kò yẹ ká máa ṣe ohun táá mú káwọn míì máa pàfiyèsí sí wa ṣáá tàbí táá mú ká máa ronú pé a sàn jù wọ́n lọ. Bí àpẹẹrẹ, tí arákùnrin kan bá mọ bí wọ́n ṣe ń sọ àsọyé tó ń wọni lọ́kàn tàbí tí arábìnrin kan mọ bí wọ́n ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, dípò tí wọ́n á fi jẹ́ káwọn èèyàn máa kan sárá sí wọn, Jèhófà ló yẹ kí wọ́n máa gbé gbogbo ògo náà fún láìjáfara.

MÁA DÁRÍ JINI “LÁTỌKÀN WÁ”

11. Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù fẹ́ ká kọ́ nínú àkàwé tó ṣe nípa ọba kan àti ẹrú rẹ̀?

11 Lẹ́yìn tí Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé kí wọ́n má mú àwọn míì kọsẹ̀, ó sọ àkàwé kan fún wọn nípa ọba kan àti ẹrú rẹ̀. Ẹrú yìí jẹ ọba náà ní gbèsè tí ò lè san láéláé, àmọ́ ọba náà fagi lé gbèsè ẹ̀. Nígbà tó yá, ẹrú yìí rí ẹrú míì tó jẹ ẹ́ ní gbèsè owó díẹ̀, ó sì kọ̀ láti dárí jì í. Inú bí ọba náà, ó sì ju ẹrú burúkú náà sẹ́wọ̀n. Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù fi àkàwé yìí kọ́ wa? Ó ní: “Bẹ́ẹ̀ náà ni Baba mi ọ̀run máa ṣe sí yín tí kálukú yín kò bá dárí ji arákùnrin rẹ̀ látọkàn wá.”​—Mát. 18:21-35.

12. Tá ò bá kí í dárí jini, àkóbá wo nìyẹn máa ṣe fáwọn míì?

12 Ẹrú yìí jìyà ohun tó ṣe, àmọ́ ohun tó ṣe yẹn tún kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn míì. Lọ́nà wo? Lákọ̀ọ́kọ́, ó fìyà jẹ ẹrú ẹlẹgbẹ́ ẹ̀ nígbà tó “ní kí wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n títí ó fi máa san gbèsè tó jẹ pa dà.” Ìkejì, ó dun àwọn ẹrú yòókù nígbà tí wọ́n rí ohun tó ṣe. Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹrú rí ohun tó ṣẹlẹ̀, inú wọn bà jẹ́ gan-an.” Lọ́nà kan náà, ohun tá a bá ṣe lè ṣàkóbá fáwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá, tá ò sì dárí jì í, kí ló lè ṣẹlẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́, a máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹni náà torí pé a ò dárí jì í, a ò sì fìfẹ́ hàn sí i. Ìkejì, inú àwọn tó wà nínú ìjọ ò ní dùn tí wọ́n bá rí i pé àárín àwa àti ẹni náà ò gún.

Arábìnrin kan pe arábìnrin míì tó ń bínú sí i sẹ́gbẹ̀ẹ́ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó sì ń bá a sọ̀rọ̀. Fọ́tò: 1. Àwọn ará pàdé láti lọ sóde ẹ̀rí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ẹni tó darí ìpàdé náà ní kí àwọn arábìnrin méjèèjì náà jọ ṣiṣẹ́, àmọ́ ṣe ni ọ̀kan lára wọn fajú ro. 2. Àwọn arábìnrin méjèèjì náà ń gbádùn bí wọ́n ṣe jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí.

Ṣé wàá di ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́ sínú àbí wàá dárí jì í látọkàn? (Wo ìpínrọ̀ 13 àti 14)b

13. Kí lo rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí aṣáájú-ọ̀nà kan?

13 Tá a bá ń dárí ji àwọn míì, kì í ṣe àwa nìkan la máa jàǹfààní, àwọn míì náà á jàǹfààní. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Crystal nìyẹn. Arábìnrin kan nínú ìjọ ló ṣẹ̀ ẹ́, Crystal wá sọ pé: “Arábìnrin yẹn máa ń fọ̀rọ̀ gún èèyàn lára, ohun tó bá sì sọ máa ń dùn mí gan-an. Kódà, mi kì í fẹ́ kí wọ́n pín wa pọ̀ lóde ẹ̀rí. Nígbà tó yá, òde ẹ̀rí kì í wù mí lọ mọ́, mi ò sì láyọ̀.” Crystal gbà pé arábìnrin yẹn ló ń ṣe ohun tí kò dáa. Àmọ́ kò tìtorí ẹ̀ di arábìnrin náà sínú tàbí kó rẹ̀wẹ̀sì. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ló tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà, “Ẹ Máa Dárí Jini Látọkàn Wá” nínú Ilé Ìṣọ́ October 15, 1999. Ìyẹn mú kó dárí ji arábìnrin náà. Crystal sọ pé: “Mo ti wá rí i pé gbogbo wa là ń sapá láti gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀ àti pé ojoojúmọ́ ni Jèhófà ń dárí jì wá fàlàlà. Ṣe lọkàn mi wá fúyẹ́ àfi bíi pé wọ́n gbé ẹrù tó wúwo kan kúrò lórí mi. Mo ti wá ń láyọ̀ báyìí.”

14. Bó ṣe wà nínú Mátíù 18:21, 22, kí ló ṣòro fún àpọ́sítélì Pétérù láti ṣe, kí la sì rí kọ́ nínú èsì tí Jésù fún un?

14 A mọ̀ pé ohun tó yẹ ká ṣe ni pé ká dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ wá, àmọ́ kì í rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ìgbà kan wà tó ṣe àpọ́sítélì Pétérù náà bẹ́ẹ̀. (Ka Mátíù 18:21, 22.) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló lè ràn wá lọ́wọ́? Àkọ́kọ́, máa ronú lórí bí Jèhófà ṣe ń dárí ji ìwọ náà. (Mát. 18:32, 33) A ò yẹ lẹ́ni tí Jèhófà ń dárí jì, síbẹ̀ ó ń dárí jì wá fàlàlà. (Sm. 103:8-10) Lọ́nà kan náà, “àwa náà gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́” àwọn ará wa. Torí náà, ìdáríjì kì í ṣọ̀rọ̀ bóyá ó wù wá tàbí kò wù wá, ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe ni. A gbọ́dọ̀ dárí ji àwọn ará wa tí wọ́n bá ṣẹ̀ wá. (1 Jòh. 4:11) Ìkejì, ronú lórí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tó o bá dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọkàn ẹni náà máa balẹ̀, ìjọ á wà níṣọ̀kan, wàá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ọkàn tìẹ náà á sì fúyẹ́. (2 Kọ́r. 2:7; Kól. 3:14) Paríparí ẹ̀, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa dárí jini. Má ṣe jẹ́ kí Èṣù da àárín ìwọ àti àwọn ará rú. (Éfé. 4:26, 27) Ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé, tá ò bá fẹ́ kó sọ́wọ́ Sátánì, àfi kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́.

MÁ ṢE JẸ́ KÍ ÌWÀ ÀWỌN MÍÌ MÚ Ẹ KỌSẸ̀

15. Kí ni Kólósè 3:13 sọ pé ká ṣe tí ẹnì kan nínú ìjọ bá ṣe ohun tó dùn wá?

15 Tí ẹnì kan nínú ìjọ bá ṣe ohun tó dùn ẹ́, kí ló yẹ kó o ṣe? Ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti yanjú ọ̀rọ̀ náà. Á dáa kó o sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ fún Jèhófà. Bẹ Jèhófà pé kó bù kún ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́, kó o sì sọ pé kó jẹ́ kó o máa rí ibi tí ẹni náà dáa sí, ìyẹn àwọn ohun tí Jèhófà rí tó fi nífẹ̀ẹ́ ẹni náà. (Lúùkù 6:28) Tó bá jẹ́ pé o ò lè gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn, wá bó o ṣe lè fọgbọ́n bá ẹni náà sọ ọ́. Ohun tó dáa jù ni pé ká gbà nínú ọkàn wa pé ẹni náà ò mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó dùn wá. (Mát. 5:23, 24; 1 Kọ́r. 13:7) Tá a bá ti lọ bá a sọ̀rọ̀, ká gba ohun tó sọ gbọ́. Tí ẹni náà ò bá gbà pẹ̀lú wa ńkọ́? Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa fara dà á fún ara yín.” Torí náà, gbà pé ó ṣì lè ṣàtúnṣe. (Ka Kólósè 3:13.) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, má ṣe di ẹni náà sínú torí ìyẹn lè kó bá àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà. Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun tí ẹnikẹ́ni bá ṣe mú ẹ kọsẹ̀ láé. Tó o bá ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti yanjú ọ̀rọ̀ náà, ìyẹn á fi hàn pé o ka àjọṣe ẹ pẹ̀lú Jèhófà sí pàtàkì ju ohunkóhun míì lọ.​—Sm. 119:165.

16. Ojúṣe wo ni gbogbo wa ní?

16 Gbogbo wa pátá la mọyì àǹfààní tá a ní láti máa sin Jèhófà níṣọ̀kan gẹ́gẹ́ bí “agbo kan” lábẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn kan”! (Jòh. 10:16) Ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 165 sọ pé: “Bí ìwọ náà ṣe ń jàǹfààní ìṣọ̀kan yìí, ó yẹ kó o jẹ́ kó máa gbèrú sí i.” Torí náà, ó yẹ ká ‘jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa ka àwọn ará wa sẹ́ni ọ̀wọ́n.’ Ká má gbàgbé pé gbogbo wa la ṣeyebíye lójú Jèhófà, bá a tiẹ̀ jẹ́ “ẹni kékeré.” Ṣé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa náà ṣeyebíye lójú wa? Ẹ jẹ́ ká máa fi sọ́kàn pé gbogbo bá a ṣe ń fìfẹ́ hàn sí wọn, tá a sì ń bójú tó wọn ni Jèhófà ń kíyè sí.​—Mát. 10:42.

17. Kí la ti pinnu pé a máa ṣe?

17 A nífẹ̀ẹ́ àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà. Torí náà, a ti ‘pinnu pé a ò ní fi ohun ìkọ̀sẹ̀ tàbí ohun ìdènà síwájú àwọn arákùnrin wa.’ (Róòmù 14:13) A gbà pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa sàn jù wá lọ. Torí náà, a fẹ́ máa dárí jì wọ́n látọkàn wá. Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ká má ṣe jẹ́ kí ìwà àwọn míì mú wa kọsẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, “ẹ jẹ́ kí a máa lépa àwọn ohun tó ń mú kí àlàáfíà wà àti àwọn ohun tó ń gbé ẹnì kejì wa ró.”​—Róòmù 14:19.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Àwọn wo ni àwọn “ẹni kékeré yìí” tí Jésù sọ̀rọ̀ wọn nínú Mátíù orí 18?

  • Báwo la ṣe lè fi hàn pé àwọn míì sàn jù wá lọ?

  • Kí la lè ṣe tó bá ṣòro fún wa láti dárí ji ẹni tó sẹ̀ wá?

ORIN 130 Ẹ Máa Dárí Jini

a Torí àìpé wa, a lè ṣe tàbí sọ ohun tó máa dun àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nígbà míì. Kí ló yẹ ká ṣe tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀? Ṣé a máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti yanjú ọ̀rọ̀ náà? Ṣé ó máa ń yá wa lára láti tọrọ àforíjì? Àbí ṣe la máa ń ronú pé tí wọ́n bá bínú wàhálà tiwọn nìyẹn? Ṣé a máa ń tètè bínú torí ohun táwọn èèyàn ṣe tàbí sọ? Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ṣé a máa ń dá ara wa láre, ṣé a sì máa ń sọ pé wọ́n á gbà mí bí mo ṣe rí ni o? Àbí a máa rí i bíi kùdìẹ̀-kudiẹ tó yẹ ká ṣiṣẹ́ lé?

b ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan ń bínú sí arábìnrin míì nínú ìjọ. Lẹ́yìn táwọn méjèèjì jọ sọ̀rọ̀ náà, wọ́n yanjú ẹ̀, wọ́n sì jọ ń fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́