11 “‘Àmọ́ ní ti awọ akọ màlúù náà àti gbogbo ẹran rẹ̀ pẹ̀lú orí, ẹsẹ̀, ìfun àti ìgbẹ́+ rẹ̀, 12 gbogbo ohun tó kù lára akọ màlúù náà, kí ó kó o lọ sí ẹ̀yìn ibùdó níbi tó mọ́, tí wọ́n ń da eérú sí, kó sì sun ún lórí igi nínú iná.+ Ibi tí wọ́n ń da eérú sí ni kó ti sun ún.