-
Léfítíkù 16:29-31Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 “Àṣẹ tó máa wà fún yín títí lọ ni: Ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù keje, kí ẹ pọ́n ara yín* lójú, ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan,+ ì báà jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ tàbí àjèjì tó ń gbé láàárín yín. 30 Ọjọ́ yìí ni wọ́n á ṣe ètùtù+ fún yín láti kéde pé ẹ jẹ́ mímọ́. Ẹ máa di mímọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín níwájú Jèhófà.+ 31 Yóò jẹ́ sábáàtì fún yín, ọjọ́ ìsinmi tí ẹ ò ní ṣiṣẹ́ rárá, kí ẹ sì pọ́n ara yín* lójú.+ Àṣẹ tó máa wà títí lọ ni.
-