ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 28:3-8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 “Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ọrẹ àfinásun tí ẹ máa mú wá fún Jèhófà nìyí: kí ẹ máa mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjì tó jẹ́ ọlọ́dún kan tí ara wọn dá ṣáṣá wá lójoojúmọ́ láti fi rú ẹbọ sísun nígbà gbogbo.+ 4 Kí o mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan wá ní àárọ̀, kí o sì mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kejì wá ní ìrọ̀lẹ́,*+ 5 pẹ̀lú ìyẹ̀fun kíkúnná tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà* tí wọ́n pò mọ́ òróró tí wọ́n fún tó jẹ́ ìlàrin òṣùwọ̀n hínì* láti fi ṣe ọrẹ ọkà.+ 6 Ẹbọ sísun ìgbà gbogbo+ ni, èyí tí a fi lélẹ̀ ní Òkè Sínáì láti mú òórùn dídùn* jáde, ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, 7 pẹ̀lú ọrẹ ohun mímu rẹ̀, ìlàrin òṣùwọ̀n hínì fún akọ ọ̀dọ́ àgùntàn+ kọ̀ọ̀kan. Da ohun mímu tó ní ọtí náà sínú ibi mímọ́ láti fi ṣe ọrẹ ohun mímu fún Jèhófà. 8 Kí o sì mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kejì wá ní ìrọ̀lẹ́.* Kí o fi ṣe ọrẹ àfinásun tó ń mú òórùn dídùn*+ jáde sí Jèhófà, pẹ̀lú ọrẹ ọkà kan náà tí o mú wá láàárọ̀ àti ọrẹ ohun mímu rẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́