ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 22:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Torí náà, àwọn àgbààgbà Móábù àtàwọn àgbààgbà Mídíánì mú owó ìwoṣẹ́ dání, wọ́n rìnrìn àjò lọ sọ́dọ̀ Báláámù,+ wọ́n sì jíṣẹ́ Bálákì fún un.

  • Nọ́ńbà 25:1-3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé ní Ṣítímù,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọmọbìnrin Móábù+ ṣe ìṣekúṣe. 2 Àwọn obìnrin náà pè wọ́n síbi àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú sí àwọn ọlọ́run+ wọn, àwọn èèyàn náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ, wọ́n sì ń forí balẹ̀ fún àwọn ọlọ́run+ wọn. 3 Bí Ísírẹ́lì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn jọ́sìn* Báálì Péórì+ nìyẹn, inú sì bí Jèhófà gidigidi sí Ísírẹ́lì.

  • Nọ́ńbà 25:17, 18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 “Ẹ lọ gbéjà ko àwọn ọmọ Mídíánì, kí ẹ sì ṣá wọn balẹ̀,+ 18 torí wọ́n ti ń dọ́gbọ́n gbéjà kò yín bí wọ́n ṣe fi ẹ̀tàn mú yín nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Péórì+ àti ọ̀rọ̀ Kọ́síbì ọmọ ìjòyè Mídíánì, arábìnrin wọn tí ẹ pa+ lọ́jọ́ tí àjàkálẹ̀ àrùn kọ lù yín torí ọ̀rọ̀ Péórì.”+

  • 1 Kọ́ríńtì 10:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Bákan náà, kí a má ṣe ìṣekúṣe,* bí àwọn kan nínú wọn ti ṣe ìṣekúṣe,* tí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún (23,000) lára wọn fi kú ní ọjọ́ kan ṣoṣo.+

  • Ìfihàn 2:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 “‘Síbẹ̀, àwọn ohun kan wà tí mo rí tí ò ń ṣe tí kò dáa, àwọn kan wà láàárín yín tó ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Báláámù,+ ẹni tó kọ́ Bálákì+ pé kó fi ohun ìkọ̀sẹ̀ síwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n jẹ àwọn ohun tí wọ́n fi rúbọ sí àwọn òrìṣà, kí wọ́n sì ṣe ìṣekúṣe.*+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́