-
Ẹ́kísódù 29:27, 28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Kí o ya igẹ̀ ọrẹ fífì náà sí mímọ́, pẹ̀lú ẹsẹ̀ ìpín mímọ́ tí o fì, èyí tí o gé lára àgbò àfiyanni náà,+ látinú ohun tí o fi rúbọ torí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀. 28 Yóò di ti Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí ó jẹ́ àṣẹ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á máa pa mọ́ títí láé, torí ìpín mímọ́ ló jẹ́, yóò sì di ìpín mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á máa fún wọn.+ Ìpín mímọ́ wọn fún Jèhófà ni, látinú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wọn.+
-
-
Diutarónómì 18:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 “Ohun tó máa jẹ́ ẹ̀tọ́ àwọn àlùfáà látọwọ́ àwọn èèyàn nìyí: Kí ẹnikẹ́ni tó bá fi ẹran rúbọ, ì báà jẹ́ akọ màlúù tàbí àgùntàn, fún àlùfáà ní apá, páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ àti àpòlúkù.
-
-
1 Kọ́ríńtì 9:13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé àwọn ọkùnrin tó ń ṣe iṣẹ́ mímọ́ máa ń jẹ àwọn nǹkan tẹ́ńpìlì àti pé àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nídìí pẹpẹ máa ń gba ìpín nídìí pẹpẹ?+
-