11 ‘Àwọn ọkùnrin tó kúrò ní Íjíbítì, láti ẹni ogún (20) ọdún sókè kò ní rí ilẹ̀ + tí mo búra pé màá fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù,+ torí pé wọn ò fi gbogbo ọkàn wọn tọ̀ mí lẹ́yìn, 12 àfi Kélẹ́bù+ ọmọ Jéfúnè ọmọ Kénásì àti Jóṣúà+ ọmọ Núnì, torí pé wọ́n fi gbogbo ọkàn wọn tọ Jèhófà lẹ́yìn.’+