12 Ṣe ni kí ẹ pa ẹni tó bá ṣorí kunkun,* tó kọ̀ láti fetí sí àlùfáà tó ń bá Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣiṣẹ́ tàbí sí adájọ́ náà.+ Kí o mú ohun tó burú kúrò ní Ísírẹ́lì.+
26 Torí tí a bá mọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà lẹ́yìn tí a ti gba ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́,+ kò tún sí ẹbọ kankan fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́,+27 àfi ká máa fi ìbẹ̀rù retí ìdájọ́ àti ìbínú tó le, tó sì máa jó àwọn tó ń ṣàtakò run.+